Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báa Ṣe Lè Dá Àwọn Àmì Ìsoríkọ́ Mọ̀

Báa Ṣe Lè Dá Àwọn Àmì Ìsoríkọ́ Mọ̀

Báa Ṣe Lè Dá Àwọn Àmì Ìsoríkọ́ Mọ̀

“Kò séwu nínú kéèyàn banú jẹ́, kò lè pààyàn lára; àmọ́ àrùn ni ìsoríkọ́ jẹ́. Ohun tó jẹ́ ìṣòro ibẹ̀ ni lílóye rẹ̀ kéèyàn sì mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín wọn.”—Dókítà David G. Fassler.

BÍI ti ọ̀pọ̀ àrùn mìíràn, ìsoríkọ́ náà ní àwọn àmì táa lè rí . Àmọ́ àwọn àmì náà kò fi bẹ́ẹ̀ rọrùn láti mọ̀. Kí ló dé? Nítorí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí èwe kan tí kì í kárí sọ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan bíi tàwọn àgbàlagbà. Kí ni ìyàtọ̀ láàárín kéèyàn kárí sọ àti pé kó sorí kọ́? Ó sábàá máa ń sinmi lórí bọ́ràn náà ṣe rinlẹ̀ tó àti àkókò tó gbà.

Bó ṣe rinlẹ̀ tó wé mọ́ bí èrò òdì ṣe ń bá èwe kan fínra tó. Ìsoríkọ́ máa ń le ju àìnírètí tó máa ń wà fún àkókò díẹ̀ lọ, ó jẹ́ àìsàn tó máa ń ran gbogbo èrò inú èwe kan tí kò sì ní jẹ́ kó lè ṣe bó ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀. Dókítà Andrew Slaby ṣàpèjúwe bí ọ̀ràn ọ̀hún ṣe máa ń le koko tó lọ́nà yìí: “Ronú nípa ìrora tó burú jáì tóo tíì ní rí láyé rẹ—bóyá o kán léegun, o ní akokoro, tàbí ìrora ìrọbí, wá pa irú rẹ̀ mẹ́wàá pọ̀, tó sì jẹ́ pé o ò mọ ohun tó fa ìrora ọ̀hún; eléyìí á lè jẹ́ kóo fojú díwọ̀n bí ìsoríkọ́ ṣe máa ń dun èèyàn tó.”

Àkókò tó gbà ń tọ́ka sí bí ìrẹ̀wẹ̀sì ọ̀hún ṣe pẹ́ tó. Gẹ́gẹ́ bí Leon Cytryn àti Donald H. McKnew, tí wọ́n jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ìmọ̀ ìṣègùn ti sọ, “bí ọmọ kan tọ́kàn rẹ̀ bà jẹ́ kò bá ṣara gírí tàbí túra ka lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan (láìka ohun yòówù kó fà á sí)—tàbí láàárín oṣù mẹ́fà lẹ́yìn tí àdánù ńlá kan ṣẹlẹ̀ sí i, àfàìmọ̀ ni irú ọmọ bẹ́ẹ̀ kò ní níṣòro ìsoríkọ́.”

Àwọn Àmì Tó Wọ́pọ̀

Béèyàn bá ń rí àwọn àmì bíi mélòó kan lára èwe kan lójoojúmọ́ fún ó kéré tán ọ̀sẹ̀ méjì lèèyàn fi lè mọ̀ pé ó ní ìsoríkọ́. Wọ́n sọ pé ìrẹ̀wẹ̀sì fún àkókò ráńpẹ́ jẹ́ àmì ìsoríkọ́. Báa ṣe lè mọ ìsoríkọ́ tó kọjá kèrémí ni pé àwọn àmì wọ̀nyí kò ní lọ fún ó kéré tán ọdún kan, ó kàn lè fi bí oṣù méjì péré rọwọ́ díẹ̀. Èyí tó wù kó jẹ́ nínú rẹ̀, kí làwọn àmì ìsoríkọ́ tó wọ́pọ̀? a

Kí ìwà àti ìṣesí ṣàdéédéé yí padà. Èwe kan tó jẹ́ ọmọ jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ tẹ́lẹ̀ á kàn ṣàdéédéé di ẹni tó ń ṣàtakò ṣáá. Àwọn èwe tí wọ́n ní ìsoríkọ́ sábàá máa ń ṣọ̀tẹ̀ wọ́n tiẹ̀ lè sá kúrò nílé pàápàá.

Wọ́n á sọ ara wọn di àṣo. Èwe náà tó sorí kọ́ kò ní fẹ́ ní àjọṣe pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Tàbí kó jẹ́ pé àwọn ọ̀rẹ́ ló máa bẹ̀rẹ̀ sí sára fún èwe tó níṣòro ìsoríkọ́ nígbà tí wọ́n kíyè sí àwọn ìyípadà tí kò bá wọn lára mu nínú ìwà rẹ̀.

Àìnífẹ̀ẹ́ sí ìgbòkègbodò èyíkéyìí. Ńṣe ni èwe náà á máa ṣe bí olúńdù láwùjọ, kò ní fẹ́ dá sí ohunkóhun. Àwọn ìgbòkègbodò tó máa ń gbádùn mọ́ ọn tẹ́lẹ̀ rí á wá di èyí tó ń sú u.

Ìṣọwọ́ jẹun rẹ̀ á yí padà. Ọ̀pọ̀ àwọn ògbóǹkangí ló sọ pé lọ́wọ̀ọ̀wọ́ ni àwọn ìṣòro mìíràn bíi kéèyàn máà máa jẹun dáadáa, kí ebi máa pani lódìlódì, tàbí kéèyàn máa jẹun àjẹjù máa ń bá ìsoríkọ́ rìn (ó sì lè jẹ́ òun ló máa fà wọ́n nígbà mìíràn).

Ìṣòro oorun sísùn. Èwe náà lè máà róorun sùn tó tàbí kó máa sùn lásùnjù. Àwọn mìíràn kò ní fojú gán-án-ní oorun ní gbogbo òru tí wọ́n á sì wá máa sùn látàárọ̀ ṣúlẹ̀.

Ìṣòro ní ilé ẹ̀kọ́. Èwe kan tó ní ìsoríkọ́ kì í lè lájọṣe tó gún régé pẹ̀lú àwọn olùkọ́ àtàwọn ẹgbẹ́ rẹ̀, á sì bẹ̀rẹ̀ sí gba òdo. Láìpẹ́ kò ní fẹ́ lọ sí ilé ìwé mọ́ páàpáà.

Àwọn ìwà tó léwu tó lè gbẹ̀mí èèyàn. Àwọn ìwà tó léwu gan-an lè fi hàn pé ayé ti sú èwe kan. Ṣíṣe ara ẹni léṣe (bíi fífi nǹkan gé ara ẹni) tún lè jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àmì náà.

Níní èrò àìjámọ́ nǹkankan tàbí dídá ara ẹni lẹ́bi láìnídìí. Èwe náà á wá di ẹni tí kò mọ ohunkóhun ṣe mọ́ lójú ara rẹ̀, á máa ronú pé ó ti bọ́ lọ́wọ́ òun ráúráú, bẹ́ẹ̀ sì rèé ọ̀ràn lè máà rí bẹ́ẹ̀.

Àwọn ìṣòro ara àti ìrònú. Bí ẹnì kan bá ní ìṣòro ẹ̀fọ́rí, ẹ̀yìn dídùn, inú rírun, àtàwọn ìṣòro mìíràn, tí wọ́n ò sì lè ṣàwárí ohun tó fà á, ìyẹn lè fi hàn pé ẹni náà níṣòro ìsoríkọ́.

Èrò láti kú tàbí kó para rẹ̀ ló máa wà lọ́kàn rẹ̀ látìgbàdégbà. Kí gbogbo ọ̀rọ̀ èwe kan máa dá lórí ikú lè fi hàn pé ó níṣòro ìsoríkọ́. Bákan náà ni gbígbìyànjú láti fọwọ́ ẹni gbẹ̀mí ara ẹni.—Wo àpótí tó wà nísàlẹ̀.

Àrùn Bipolar?

Lára àwọn àmì yìí lè wà nínú àrùn mìíràn kan tó ń ṣeni ní kàyéfì, ìyẹn àrùn bipolar. Gẹ́gẹ́ bí Dókítà Barbara D. Ingersoll àti Sam Goldstein ti sọ, àrùn bipolar (táa tún mọ̀ sí àrùn ọpọlọ tí ìsoríkọ́ máa ń fà) ni “àrùn táá máa mú kéèyàn sorí kọ́ látìgbàdégbà táwọn àkókò kan á wà tí ìmọ̀lára àti agbára èèyàn á wá lọ sókè gan-an, kódà á lọ sókè gan-an ju bó ṣe yẹ fún ọmọlúwàbí.”

Ìgbà tí ìmọ̀lára máa ń lọ sókè yìí ni ọpọlọ máa ń ṣiṣẹ́ lódìlódì. Àwọn àmì rẹ̀ lè ní nínú kéèyàn máa ronú lódìlódì, kéèyàn kàn máa rojọ́ bí àwòko, kéèyàn má sì lè sùn bó ṣe yẹ. Kódà, ẹni tó níṣòro yìí lè má sùn fún ọ̀pọ̀ ọjọ́, ara rẹ̀ á sì mókun. Àmì mìíràn téèyàn fi ń dá àrùn bipolar mọ̀ ni pé tìbínú-tìbínú lèèyàn á fi máa hùwà láìka ohun tó lè gbẹ̀yìn rẹ̀ yọ sí. Ìròyìn kan láti Ibùdó Ìwádìí Nípa Ìlera Ọpọlọ ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Ìṣiṣẹ́gbòdì ọpọlọ yìí sábà máa ń nípa lórí ìrònú, ìpinnu, àti ìwà láàárín ẹgbẹ́ lọ́nà tó máa ń fa ìṣòro ńláǹlà tó sì ń kó ìtìjú báni.” Báwo ni ìṣiṣẹ́ lódìlódì ọpọlọ yìí ṣe máa ń pẹ́ tó? Kì í ju ọjọ́ bíi mélòó kan lọ́ nígbà mìíràn; ó sì máa ń lo ọ̀pọ̀ oṣù lára àwọn mìíràn kí ìsoríkọ́ tó jẹ́ ọmọ ìyá rẹ̀ tó gbapò.

Àwọn tí wọ́n wà nínú ewu níní àrùn bipolar jù lọ ni àwọn táwọn mẹ́ńbà ìdílé wọn ní in. Ìròyìn ayọ̀ tó wà níbẹ̀ ni pé ọ̀nà àbáyọ wà fáwọn tó ní àrùn náà. Ìwé The Bipolar Child sọ pé: “Àwọn ọmọ tó ní àrùn náà àti ìdílé wọn lè gbé láìní ìdààmú bí wọ́n bá tètè kíyè sí àrùn náà kí wọ́n sì wá ìtọ́jú sí i.”

Ó yẹ ká fi sọ́kàn pé kìkì àmì kan péré kò túmọ̀ sí pé ẹni kan ní ìsoríkọ́ tàbí àrùn bipolar. Lọ́pọ̀ ìgbà, báwọn àmì wọ̀nyí bá gbára jọ fún ìwọ̀n àkókò kan ló máa ń jẹ́ kéèyàn mọ̀. Síbẹ̀, ìbéèrè náà ṣì wà nílẹ̀ pé, Kí ló fà á tí irú àìsàn tó ń páni láyà yìí fi ń bá àwọn èwe fínra?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn àmì táa kọ síbí jẹ́ àkópọ̀ ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà, kò túmọ̀ sí pé ẹni tó bá ti ní i ti ní àrùn náà nìyẹn o.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

NÍGBÀ TÓ BÁ Ń WU ỌMỌ KAN LÁTI KÚ

Gẹ́gẹ́ bí Ibùdó fún Ìkáwọ́ Àrùn ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ṣe sọ, lọ́dún kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, táa bá pa iye àwọn ọmọdé tí àrùn jẹjẹrẹ, àrùn ọkàn, àrùn éèdì, àwọn àrùn ara ọmọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, àrùn ẹ̀gbà, òtútù àyà, àrùn gágá, àti àrùn ẹ̀dọ̀fóró sọ dẹni sàréè pọ̀, wọn kò ì tí ì tó iye àwọn tó fọwọ́ ara wọn gbẹ̀mí ara wọn. Òtítọ́ ọ̀rọ̀ mìíràn tó tún ń kóni lọ́kàn sókè ni pé: Iye àwọn ọmọ ọlọ́dún mẹ́wàá sí mẹ́rìnlá tí wọ́n ròyìn pé wọ́n ń fọwọ́ ara wọn para wọn ti lọ sókè gan-an.

Ǹjẹ́ a lè dẹ́kun kí àwọn èwe máa fọwọ́ ara wọn para wọn? Ó ṣeé ṣe nínú àwọn ọ̀ràn kan. Dókítà Kathleen McCoy kọ ọ́ pé “ìṣirò tó wà lákọọ́lẹ̀ fi hàn pé kí àwọn ọ̀dọ́ tóó gbìyànjú láti pa ara wọn, ńṣe ni wọ́n kọ́kọ́ máa ń jẹ ẹ́ lẹ́nu tàbí ṣe kìlọ̀kìlọ̀. Bí ọmọ rẹ bá lè mẹ́nu ba èròǹgbà pípa ara rẹ̀ pẹ́nrẹ́n, tètè máa ṣọ́ ọ lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀ o sì lè ké sáwọn ọ̀mọ̀ràn fún ìrànlọ́wọ́.”

Bí ìṣòro ìsoríkọ́ àwọn èwe ṣe ń pọ̀ sí i ń tẹnu mọ́ ìdí tó fi ṣe kókó pé, tí àwọn òbí tàbí àwọn àgbàlagbà bá kófìrí pe ọ̀dọ́ kan fẹ́ gbẹ̀mí ara rẹ̀ pẹ́nrẹ́n, kí wọ́n tètè yáa ké gbàjarè. Dókítà Andrew Slaby kọ ọ́ nínú ìwé rẹ̀ No One Saw My Pain pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé nínú gbogbo ọ̀ràn ìfọwọ́ ara ẹni gbẹ̀mí ara ẹni tí mo ti yẹ̀ wò làwọn èèyàn kò ti ka àwọn àmì táwọn èwe náà fi hàn sí. Àwọn mẹ́ńbà ìdílé àtàwọn ọ̀rẹ́ kò lóye bí àwọn ìyípadà tí wọ́n ń rí lára àwọn èwe náà ṣe lágbára tó. Ṣe ni wọ́n fi ẹ̀tẹ̀ sílẹ̀ tí wọ́n ń pa làpálàpá, ‘ìṣòro ìdílé,’ ‘lílo oògùn olóró’ tàbí ‘àìjẹun bó ṣe yẹ’ ni wọ́n ń wá oògùn rẹ̀ kiri. Nígbà míì, wọ́n á fi ìṣòro ìsoríkọ́ sílẹ̀ wọ́n á máa wá oògùn ìbínú, àìbalẹ̀ ọkàn, àti ìkanra kiri. Wọn ò ní fọwọ́ kan olórí ìṣòro, tó ń fa ìrora, tó sì ń peléke sí i.”

Ọ̀rọ̀ ọ̀hún ṣe kedere báyìí: Má ṣe fojú kéré èrò èyíkéyìí tó bá ti jẹ mọ́ gbígbẹ̀mí ara ẹni!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Nígbà mìíràn, ṣíṣọ̀tẹ̀ máa ń jẹ́ àmì ìsoríkọ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Lọ́pọ̀ ìgbà làwọn èwe tó sorí kọ́ kì í nífẹ̀ẹ́ sáwọn ìgbòkègbodò tó máa ń gbádùn mọ́ wọn tẹ́lẹ̀ rí