Báwo Ni Mo Ṣe Lè Túbọ̀ Gbádùn Bíbélì Kíkà Sí I?
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Báwo Ni Mo Ṣe Lè Túbọ̀ Gbádùn Bíbélì Kíkà Sí I?
“Àwọn ìgbà míì wà tí Bíbélì kì í rọrùn láti lóye, ìyẹn sì lè jẹ́ kó sú èèyàn.”—Annalieza, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún.
“Bíbélì máa ń sú mi láti kà.” —Kimberly, ọmọ ọdún méjìlélógún.
Ọ̀PỌ̀ èèyàn ló jẹ́ pé kò sí nǹkan kan tó máa ń wù wọ́n láti kà. Fún ìdí yìí, Bíbélì tó tún wá jẹ́ ìwé kan tó tóbi lè dà bí èyí tó ń dẹ́rù bani, kódà fáwọn tó jẹ́ ọ̀jẹ̀wé pàápàá. Tammy, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún sọ pé: “Fún èmi o, ìwé kan tó díjú ni Bíbélì, táwọn ọ̀rọ̀ kàǹkà-kàǹkà tó ṣòro o lóye kúnnú rẹ̀. Bíbélì kíkà ń béèrè pé kéèyàn pọkàn pọ̀ gan-an kó sì ní ìfaradà.”
Yàtọ̀ síyẹn, iṣẹ́ àṣetiléwá, àwọn iṣẹ́ ilé pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, àti eré ìtura lè máa gba púpọ̀ nínú àkókò rẹ àti okun rẹ. Èyí tún lè mú kó nira láti pọkàn pọ̀ láti gbádùn kíka Bíbélì. Alicia, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń wáyè láti múra àwọn ìpàdé Kristẹni sílẹ̀ kó sì tún lọ síbẹ̀, táá sì tún wá àkókò láti ṣàjọpín àwọn ohun tó gbà gbọ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ó sọ pé: “Kò rọrùn láti máa ka Bíbélì nítorí pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà nílẹ̀ láti ṣe.”
Síbẹ̀, Alicia, Tammy, àti ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ míì ti borí ìṣòro yẹn. Ní báyìí, wọ́n ń ka Bíbélì déédéé, wọ́n sì ń gbádùn rẹ̀ gan-an ni. Ó lè ṣeé ṣe fún ìwọ náà! Gbé àwọn nǹkan mẹ́ta tóo lè ṣe láti mú kí Bíbélì kíkà túbọ̀ lárinrin yẹ̀ wò.
Wá Àyè Láti Máa Ka Bíbélì
Kelly tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìdínlógún sọ pé: “Mo rò pé ìdí táwọn ọ̀dọ́ fi máa ń sọ pé Bíbélì ń sú àwọn láti kà ni pé, wọ́n ò tẹra mọ́ ọn tó.” Bóo ṣe ń gbádùn eré ìtura tàbí eré ìdárayá tóo máa ń ṣe nígbà gbogbo gẹ́lẹ́ ni wàá ṣe máa gbádùn Bíbélì kíkà tóo bá ń kà á déédéé.
Àmọ́ tí o ò bá ń fi bẹ́ẹ̀ rí àyè ń kọ́? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wá nímọ̀ràn pé: “Ẹ máa ṣọ́ra lójú méjèèjì pé bí ẹ ṣe ń rìn kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n, ní ríra àkókò tí ó rọgbọ padà fún ara yín, nítorí pé àwọn ọjọ́ burú.” (Éfésù 5:15, 16) O lè ‘ra àkókò padà’ nípa dídín àkókò tóo ń lò nídìí àwọn ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì kù, irú bíi wíwo tẹlifíṣọ̀n. Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù lò fún “àkókò” lè túmọ̀ sí àkókò kan táa yà sọ́tọ̀ pé a fẹ́ fi ṣe nǹkan kan pàtó. Ìgbà wo lo lè yà sọ́tọ̀ láti máa fi ka Bíbélì?
Àárọ̀ lọ̀pọ̀ máa ń ka Bíbélì, nígbà tí wọ́n bá ṣàyẹ̀wò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ àti àlàyé tó wà nínú ìwé pẹlẹbẹ Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́ a tán. Àwọn mìíràn yàn láti máa kà á lálaalẹ́ kí wọ́n tó sùn. Yan àkókò tóo mọ̀ pé á ṣeé ṣe fún ẹ láti máa kà á kóo sì ṣètò ara rẹ̀ lọ́nà tí wàá fi máa tẹ̀ lé e. Alicia sọ pé: “Mímú kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ mi ṣeé yí padà lohun náà gan-an tó ràn mí lọ́wọ́ láti máa bá ètò tí mo ṣe fún Bíbélì kíkà lọ déédéé.”
Àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni kan ya ìṣẹ́jú mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sọ́tọ̀ fún kíka Bíbélì lójoojúmọ́. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ti mú kí wọ́n lè ka odindi Bíbélì tán ní ọdún kan tàbí méjì! Ká tiẹ̀ wá ní ìyẹn ò ṣeé ṣe fún ẹ, fi ṣe góńgó rẹ pé wàá máa ka apá díẹ̀ nínú Bíbélì lójoojúmọ́. Bí o kò bá yẹ ìpinnu rẹ láti máa ka Bíbélì lákòókò tóo yà sọ́tọ̀ fún un, ìfẹ́ rẹ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run á pọ̀ sí i.—Sáàmù 119:97; 1 Pétérù 2:2.
Gbàdúrà fún Ọgbọ́n
Kò sírọ́ ńbẹ̀ pé, àwọn tó ń ka Bíbélì déédéé pàápàá máa ń rí i pé àwọn ibì kan wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ṣòro láti lóye. Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Orísun Bíbélì fẹ́ kóo lóye Ọ̀rọ̀ òun. Ìwé Ìṣe sọ nípa arìnrìn àjò ará Etiópíà kan tó ṣòro fún láti lóye àsọtẹ́lẹ̀ kan nínú Aísáyà orí 53 lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Ọkùnrin náà ṣe tán láti béèrè fún ìrànwọ́, ni áńgẹ́lì Jèhófà bá rán ajíhìnrere Fílípì sí i láti ṣàlàyé àsọtẹ́lẹ̀ náà fún un.—Ìṣe 8:26-39.
Nígbà náà, Bíbélì kíkà tó gbéṣẹ́ kò ní jẹ́ èyí táa kàn bẹ̀rẹ̀ kíkà rẹ̀ bẹ́ẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀ ó gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àdúrà. Àwọn kan ti sọ́ ọ dàṣà pé kí wọ́n tiẹ̀ tó ṣí Bíbélì wọn rárá, wọ́n á kọ́kọ́ gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún àwọn lọ́gbọ́n láti lóye ẹ̀kọ́ tó wà nínú ohun tí wọ́n fẹ́ kà kí wọ́n sì lè fi sọ́kàn. (2 Tímótì 2:7; Jákọ́bù 1:5) Ẹ̀mí Ọlọ́run tiẹ̀ lè mú kí o rántí àwọn ẹsẹ Bíbélì tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti dáhùn àwọn ìbéèrè tàbí láti kojú àwọn ìṣòro.
Ọ̀dọ́kùnrin kan tó jẹ́ Kristẹni sọ pé: “Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méjìlá, bàbá mi já ìdílé wa sílẹ̀. Lálẹ́ ọjọ́ kan, mo bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà lórí ibùsùn mi pé kí Jèhófà jẹ́ kí bàbá mi padà wá. Bẹ́ẹ̀ ni mo ki Bíbélì mi mọ́lẹ̀ tí mo sì ka Sáàmù 10:14 tó sọ pé: ‘Ìwọ [Jèhófà] ni aláìrìnnàkore, ọmọdékùnrin aláìníbaba, fi ara rẹ̀ lé lọ́wọ́. Ìwọ tìkára rẹ ti di olùrànlọ́wọ́ rẹ̀.’ Mo séra ró fún ìṣẹ́jú kan. Bí ìgbà tí Jèhófà ń bá mi sọ̀rọ̀ ló rí lára mi tó sì ń jẹ́ kí n mọ̀ pé òun ni olùrànlọ́wọ́ mi; òun ni Bàbá mi. Pé bàbá wo ni mo tún lè ní tó dára ju òun lọ?”
Ṣe ìwọ náà lè sọ ọ́ di àṣà rẹ láti kọ́kọ́ gbàdúrà nígbàkigbà tóo bá ti fẹ́ ka Bíbélì? Adrian dá a lábàá pé: “Gbàdúrà kóo tó bẹ̀rẹ̀ sí kà á, àti lẹ́yìn tóo bá kà á tán, kó lè jẹ́ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ gidi láàárín ìwọ àti Jèhófà.” Àdúrà tóo ń gbà látọkàn wá yóò jẹ́ kóo túbọ̀ dúró ti ìpinnu rẹ láti rọ̀ mọ́ ètò tóo ṣe fún kíka Bíbélì yóò sì jẹ́ kí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run lágbára sí i.—Jákọ́bù 4:8.
Jẹ́ Kó Dà Bíi Pé O Wà Níbẹ̀
Bíbélì kíkà ti kọ́kọ́ máa ń sú Kimberly táa fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ níbẹ̀rẹ̀. Òótọ́ ni pé ìwé tọ́jọ́ rẹ̀ ti pẹ́ ni Bíbélì, wọ́n ti kọ ọ́ ṣáájú kí àwọn nǹkan bíi kọ̀ǹpútà, tẹlifíṣọ̀n, tàbí ọkọ̀ òfúúrufú tóó dé, àwọn táa sì ń kà nípa wọn nínú Bíbélì ti kú láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Síbẹ̀, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó Hébérù 4:12) Báwo ni ìwé kan tọ́jọ́ rẹ̀ ti pẹ́ bẹ́ẹ̀ yẹn ṣe lè sa agbára?
sì ń sa agbára.” (Láwọn ọjọ́ Ẹ́sírà tó jẹ́ akọ̀wé, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin, àti “gbogbo àwọn tí ó ní làákàyè tó láti fetí sílẹ̀” kóra jọ sí Jerúsálẹ́mù láti fetí sílẹ̀ sí kíka Òfin Mósè. Nígbà yẹn, Òfin yẹn ti lé lẹ́gbẹ̀rún ọdún tó ti wà! Síbẹ̀, Ẹ́sírà àti àwọn amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ “ń bá a lọ láti ka ìwé náà sókè, láti inú òfin Ọlọ́run tòótọ́, wọ́n ń làdí rẹ̀, wọ́n sì ń fi ìtumọ̀ sí i; wọ́n sì ń mú kí ìwé kíkà náà yéni.” Nígbà táwọn ọkùnrin yìí ṣàlàyé Ìwé Mímọ́ tí wọ́n sì jẹ́ kí ohun tí wọ́n kà yéni, kí ló jẹ́ àbájáde rẹ̀? “Gbogbo àwọn ènìyàn náà lọ láti jẹ, àti láti mu, àti láti fi ìpín ránṣẹ́, wọ́n sì ń bá a lọ nínú ayọ̀ yíyọ̀ ńláǹlà, nítorí wọ́n lóye ọ̀rọ̀ tí a ti sọ di mímọ̀ fún wọn.”—Nehemáyà 8:1-12.
Báwo lo ṣe lè mú kí Bíbélì kíkà rẹ ‘ní ìtumọ̀?’ Ńṣe ni Cathy, tí ìwé kíkà ṣòro fún máa ń kà á sókè ketekete kó lè pọkàn pọ̀. Nicki ní tiẹ̀ máa ń gbìyànjú láti wo ara rẹ̀ bí ẹni pé ó wà níbi tí nǹkan tó ń kà ti ṣẹlẹ̀. Ó sọ pé: “Mo máa ń fojú inú wo bó ṣe máa rí lára mi ká ní mo bá ara mi ní ipò yẹn. Ìtàn tí mo fẹ́ràn jù lọ ni ìtàn Rúùtù àti Náómì. Kò sí iye ìgbà tí mi ò lè kà á. Nígbà tí mo ṣí lọ sí ìlú mìíràn, ìtàn yìí tù mí nínú, nítorí ó jẹ́ kí n mọ bó ṣe rí lára Rúùtù nígbà tó lọ gbé níbi tí kò dé rí tí kò sì ti mọ ẹnì kan. Mo rí bó ṣe gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ìyẹn sì ran èmi náà lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.”—Rúùtù, orí 1-4.
Kí Bíbélì tó lè “sa agbára,” dandan ni pé ká ṣàṣàrò. Nígbàkigbà tóo bá ń kà á, fàyè sílẹ̀ láti ronú lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ò ń kà náà kóo sì ronú lórí bí wàá ṣe lo àwọn ohun tí o ń kọ́. O lè fẹ́ láti ṣàyẹ̀wò àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde kí Bíbélì kíka rẹ ba lè túbọ̀ nítumọ̀. b
Má Ṣe Jáwọ́ Ńbẹ̀ O!
Títẹ̀lé ìṣètò fún Bíbélì kíkà láìjáwọ́ kò rọrùn. Kódà ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì tó dára gan-an ṣì tún lè nílò yíyí i padà látìgbà dégbà. Báwo lo ṣe lè máa bá ìlépa rẹ láti máa ka Bíbélì lójoojúmọ́ nìṣó láìjáwọ́?
Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ àti ìdílé rẹ lè ṣèrànwọ́. Amber, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sọ pé: “Èmi àti àbúrò mi obìnrin la jọ ń lo yàrá. Alẹ́ mìíràn máa ń wà táa ti rẹ̀ mi gan-an tí màá kàn fẹ́ lọ sùn, àmọ́ arábìnrin mi máa ń rán mi létí pé mi ò tíì ka Bíbélì mi. Nítorí náà mi ò gbàgbé láti kà á rí!” Ká ní o rí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ pàtàkì kan tàbí apá ibì kan tó gbádùn mọ́ ọ, sọ fún àwọn ẹlòmíì nípa rẹ̀. Ìyẹn á jẹ́ kí ìmọrírì tóo ní fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run túbọ̀ ga sí i ó sì tún lè jẹ́ káwọn náà nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì kíkà. (Róòmù 1:11, 12) Ká ní o ti pa Bíbélì kíkà rẹ tì fún ọjọ́ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, máà jáwọ́! Bẹ̀rẹ̀ níbi tóo kà á dé tóo fi dúró, kóo sì wá pinnu ju ti tẹ́lẹ̀ lọ pé óò ní jẹ́ kó bọ́ mọ́.
Má fìgbà kankan gbàgbé àwọn àǹfààní rẹpẹtẹ tó máa ń wá látinú kíka Bíbélì lójoojúmọ́. Nípa títẹ́tí sílẹ̀ sí Jèhófà nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, o lè gbádùn àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀. Wàá wá bẹ̀rẹ̀ sí mọ bí ó ṣe ń ronú àti bí nǹkan ṣe máa ń rí lára rẹ̀. (Òwe 2:1-5) Ààbò làwọn òtítọ́ tó ṣeyebíye tó wá látọ̀dọ̀ Baba wa ọ̀run yìí máa já sí fún ẹ. “Báwo ni ọ̀dọ́kùnrin ṣe lè mú ipa ọ̀nà rẹ̀ mọ́?” ni ìbéèrè tí onísáàmù náà béèrè. “Nípa ṣíṣọ́ra ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ rẹ.” (Sáàmù 119:9) Nítorí náà, bẹ̀rẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíkà, má sì jẹ́ kó dúró. O lè wá rí i pé ó ń gbádùn mọ́ni gan-an ju bóo ṣe rò tẹ́lẹ̀ lọ!
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló tẹ̀ ẹ́ jáde.
b Ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ October 1, 2000, ojú ewé 16-17, pèsè àwọn àbá tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ walẹ̀ jìn nínú Bíbélì.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Àdúrà àti ìwádìí ṣíṣe á túbọ̀ jẹ́ kí Bíbélì kíkà rẹ sunwọ̀n sí i yóò sì ràn ọ́ lọ́wọ́ láti lóye ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Wíwo ara rẹ bí ẹni pé o wà níbi tí nǹkan tí o ń kà ti ṣẹlẹ̀ á jẹ́ kí Ìwé Mímọ́ túbọ̀ yé ọ sí i