Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bóo Ṣe Lè Ràn Wọ́n Lọ́wọ́

Bóo Ṣe Lè Ràn Wọ́n Lọ́wọ́

Bóo Ṣe Lè Ràn Wọ́n Lọ́wọ́

“Àwọn èwe tó sorí kọ́ nílò ìrànlọ́wọ́. Àmọ́ àwọn fúnra wọn ò lè ṣèrànwọ́ yẹn. Àgbàlagbà kan ló gbọ́dọ̀ kíyè sí ìṣòro náà kó sì fún un láfiyèsí lójú ẹsẹ̀. Ohun tó sì ṣòro níbẹ̀ gan-an nìyẹn.”—Dókítà Mark S. Gold.

KÍ LO lè ṣe bóo bá fura pé ọmọ rẹ sorí kọ́? Lákọ̀ọ́kọ́, má ṣe kù gìrì sọ pé báyìí báyìí lọ̀ràn rí. Ó ṣe tán, àwọn àmì tóo rí lè jẹ́ àmì ohun mìíràn tó yàtọ̀ pátápátá séyìí tóo rò. a Síwájú sí i, gbogbo àwọn èwe ni wọ́n máa ń ká ṣíóṣíó lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àmọ́ báwọn àmì náà bá wá kọ̀ tí wọn ò lọ, tó sì jọ pé wọ́n kì í ṣe àárẹ̀ ráńpẹ́ mọ́, ohun tó máa dára jù ni pé kóo ké sí oníṣègùn. Bọ́ràn bá rí báyìí, ó dára kéèyàn fi ọ̀rọ̀ Jésù sọ́kàn pé: “Àwọn ẹni tí ó ní ìlera kò nílò oníṣègùn, ṣùgbọ́n àwọn tí ń ṣòjòjò nílò rẹ̀.”—Mátíù 9:12.

Gbogbo bọ́ràn bá ṣe rí pátápátá ni kóo rò fún dókítà, títí kan bí ìwà ọmọ náà ṣe yí padà láìpẹ́ torí èyí lè jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tó fa ìsoríkọ́ rẹ̀. Rí i dájú pé dókítà náà fara balẹ̀ gbọ́ àwọn àmì náà dáadáa kí ó tó ṣàyẹ̀wò. Dókítà David G. Fassler, sọ pé: “Láàárín ogún ìṣẹ́jú péré, èèyàn ò lè rí gbogbo ìsọfúnni tó nílò láti mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó ń ṣe ọmọ kan.”

Gbogbo ìbéèrè tóo bá ní ni kóo béèrè lọ́wọ́ oníṣègùn náà. Fún àpẹẹrẹ, ká ní dókítà ọ̀hún sọ pé ìsoríkọ́ tó lékenkà ló ń yọ ọmọ rẹ lẹ́nu, o lè béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ ìdí tí kò fi ṣe àwọn àyẹ̀wò mìíràn. Bí o bá ń kọminú nípa àyẹ̀wò tí dókítà náà ṣe, sọ fún un pé o fẹ́ kí ẹlòmíràn tún àyẹ̀wò náà ṣe. Ó dájú pé kò sí oníṣègùn gidi kan, tó jẹ́ olóòótọ́ inú tó máa sọ pé o ò gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀.

Yáa Gba Kámú

Bí ọmọ rẹ bá níṣòro ìsoríkọ́ tó lékenkà, má ṣe jẹ́ kí èyí kó ìtìjú bá ọ. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé ìsoríkọ́ lè rọ́wọ́ tó ọmọ kan tó já fáfá pàápàá. Kódà, Bíbélì fi yé wa pé ìmọ̀lára tó ń dorí ẹni kodò bá àwọn kan tí wọ́n sa gbogbo ipá wọn láti sin Ọlọ́run, láìka ọjọ́ orí wọn sí. Ìwọ wo Jóòbù olóòótọ́, tó rò pé Ọlọ́run kọ òun sílẹ̀, ó sọ pé òun kórìíra ìgbésí ayé gan-an ni. (Jóòbù 10:1; 29:2, 4, 5) Ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni Hánà, ẹni tó ní “ìkorò ọkàn” débi pé kò lè jẹun. (1 Sámúẹ́lì 1:4-10) Ọkùnrin olùjọ́sìn Ọlọ́run kan tún wà tó ń jẹ́ Jákọ́bù, àìmọye ọjọ́ ló fi ṣọ̀fọ̀ lẹ́yìn tí ọmọkùnrin rẹ̀ kú, ó sì ‘kọ̀ láti gba ìtùnú.’ Àní ó tiẹ̀ sọ pé òun fẹ́ lọ báa nínú sàréè! (Jẹ́nẹ́sísì 37:33-35) Èyí fi hàn pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ni sísoríkọ́ máa ń túmọ̀ sí pé onítọ̀hún kò dúró sán-ún nípa tẹ̀mí.

Síbẹ̀, àwọn òbí máa ń jìyà tó pọ̀ nígbà tí ọmọ kan bá sorí kọ́. Ìyá kan tọ́mọ rẹ̀ sorí kọ́ sọ pé: “Mo máa ń ṣọ́ra gidi gan-an nípa ohun tí mo bá sọ tàbí ṣe. Ẹ̀rù bà mí, àyà mi já, inú bí mi gan-an, ilé ayé sì fẹ́rẹ̀ẹ́ yọ lẹ́mìí mi.” Ìyá mìíràn sọ pé: “Bí mo bá jáde tí mo sì rí ìyá kan tó ń lọ sọ́jà pẹ̀lú ọmọbìnrin rẹ̀, àyà mi á là gààràgà torí ńṣe ló máa ń dà bí ẹni pé mo ti sọ irú àǹfààní bẹ́ẹ̀ láàárín èmi àti [ọmọbìnrin mi] nù pé mi ò sì lè ní in mọ́ láé.”

Kò sóhun tó burú nínú irú ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀. Àmọ́ nígbà míì, wọ́n lè bo èèyàn mọ́lẹ̀. Bó bá ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, kí ló dé tóò fi finú han ọ̀rẹ́ kan tóo fọkàn tán? Ìwé Òwe 17:17 sọ pé: “Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.” Bákan náà, má gbàgbé àdúrà o. Bíbélì mú un dá wa lójú pé báa bá kó ẹrù ìnira wa lọ bá Ọlọ́run, yóò gbé wa ró.—Sáàmù 55:22.

O Lè Fẹ́ Máa Dára Rẹ Lẹ́bi

Ìrẹ̀wẹ̀sì máa ń mú ọ̀pọ̀ àwọn òbí tọ́mọ wọn sorí kọ́ tí wọ́n á fi bẹ̀rẹ̀ sí dára wọn lẹ́bi lórí ìṣòro náà. Ìyá kan sọ pé: “Tí ọmọ rẹ bá sorí kọ́, wàá bẹ̀rẹ̀ sí dá ara rẹ lẹ́bi, ẹnikẹ́ni ò sì lè pàrọwà fún ọ kóo gbọ́. Wàá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe kàyéfì pé, ‘Kí la ṣe tó kù díẹ̀ káà tó? Ibo ni nǹkan ti yí bìrí? Báwo ni mo ṣe dá kún wàhálà yìí?’” Báwo làwọn òbí ṣe lè ronú níwọ̀ntúnwọ̀nsì bọ́ràn bá rí báyìí?

Kò sí àní-àní pé bí ilé kò bá tòrò, ó máa ń kó bá ọmọdé. Ìdí èyí ni Bíbélì fi rọ àwọn bàbá pé: “Ẹ má ṣe máa dá àwọn ọmọ yín lágara, kí wọ́n má bàa soríkodò.” (Kólósè 3:21) Nítorí náà, ìmọ̀ràn fún àwọn òbí ni pé kí wọ́n ṣàyẹ̀wò bí wọ́n ṣe ń bá àwọn ọmọ wọn lò fínnífínní kí wọ́n sì ṣe àwọn àtúnṣe tó bá yẹ.

Àmọ́ kì í ṣe gbogbo ìgbà ni ìsoríkọ́ máa ń jẹ́ ẹ̀bi àwọn òbí o. Ká sòótọ́, ìṣòro yìí máa ń wà nílé tó tòrò minimini pàápàá. Nítorí náà, kò yẹ káwọn òbí tí wọ́n ń forí ṣe fọrùn ṣe láti ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ máa ronú pé àwọn ló lẹ̀bi.

Ó tún ṣe pàtàkì bákan náà láti má ṣe dá ọmọ tó sorí kọ́ lẹ́bi. Ó ṣe tán, kò sọ́gbọ́n tóo lè dá sí ìṣòro ọ̀hún. Ìyá kan sọ pé: “Bí àrùn ìgbóná tàbí òtútù àyà bá ń bá ọmọ mi jà, mi ò jẹ́ dá a lẹ́bi láé. Àmọ́ mo máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ tó bá sorí kọ́. Mo máa ń dáa lẹ́bi torí ó máa ń kó mi láyà sókè.” Báwọn òbí àtàwọn mìíràn bá ka ìsoríkọ́ sí àìsàn dípò àìtóótun, wọ́n á lè ronú nípa ọ̀nà tí wọ́n fi lè ran ẹni tó níṣòro náà lọ́wọ́.

Títọ́ ọmọ tó ní ìsoríkọ́ lè kó wàhálà bá àjọṣe láàárín àwọn òbí. Ìyàwó kan sọ pé: “Ńṣe la máa ń dá ara wa lẹ́bi, àgàgà táa bá ronú nípa irú ìgbésí ayé táa ti rò pé a máa gbé àti irú èyí táa wá ń gbé nítorí ọmọkùnrin wa.” Tim, tí ọmọbìnrin rẹ̀ ní ìsoríkọ́ sọ pé: “Ó rọrùn láti dá ọkọ tàbí aya rẹ lẹ́bi. Báwọn òbí bá níṣòro láàárín ara wọn kí ọmọ tó bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn àmì ìsoríkọ́ hàn, àwọn ìwà àjèjì tọ́mọ náà bẹ̀rẹ̀ sí hù lè wá dọ̀rọ̀ rú pátápátá.” Má ṣe jẹ́ kí ìsoríkọ́ ọmọ kan da ìgbéyàwó rẹ rú o! Ká sòótọ́, dídá ara rẹ, ọmọ rẹ, ọkọ tàbí aya rẹ lẹ́bi kò yanjú ọ̀rọ̀ páàpáà. Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kẹ́ẹ ran ẹni tó níṣòro náà lọ́wọ́.

Ṣíṣèrànwọ́

Bíbélì gba àwọn Kristẹni níyànjú pé: “Ẹ máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́.” (1 Tẹsalóníkà 5:14) Ká ní èrò pé òun kò já mọ́ nǹkan kan ló ń bá èwe tó sorí kọ́ jà, o lè ṣèrànwọ́. Lọ́nà wo? Ó dájú pé kì í ṣe nípa sísọ àwọn ọ̀rọ̀ kòbákùngbé bíi, “Kò yẹ kóo máa ṣe báyìí kẹ̀” tàbí, “Ẹ̀míkẹ́mìí ló ní yìí o.” Kàkà bẹ́ẹ̀, jẹ́ olùgbatẹnirò nípa fífi ‘ìfẹ́ fún ọmọnìkejì hàn.’ (1 Pétérù 3:8) Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n máa “sunkún pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń sunkún.” (Róòmù 12:15) Rántí pé ńṣe lara ẹni tó bá sorí kọ́ máa ń gbẹ̀kan. Ìrora ọ̀hún máa ń kọjá sísọ, kì í sì í ṣe pé ńṣe lẹni yẹn ń ṣe bẹ́ẹ̀ kó lè rí àbójútó lọ́tùn-ún lósì.

Tóo bá ti tẹ́tí sí i tán, gbìyànjú láti jẹ́ kẹ́ni tó níṣòro ọ̀hún sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ jáde. Béèrè ohun tó máa ń rò tó fi ń ṣe bó ṣe máa ń ṣe. Lẹ́yìn náà, kóo wá fi pẹ̀lẹ́tù ṣàlàyé fún un ìdí tí kò fi yẹ kó máa tẹ́ńbẹ́lú ara rẹ̀. Fífi ẹni náà lọ́kàn balẹ̀ pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti pé ó jẹ́ aláàánú lè dín hílàhílo rẹ̀ kù.—1 Pétérù 5:6, 7.

Àwọn ìgbésẹ̀ mìíràn lè wà tóo lè gbé. Fún àpẹẹrẹ, o lè ní láti rí i dájú pé ọmọ rẹ tó ní ìsoríkọ́ ní ìsinmi tó tó, oúnjẹ tó ṣara lóore, àti eré ìmárale. (Oníwàásù 4:6) Bí wọ́n bá fún un láwọn oògùn, á dáa kóo jẹ́ kó mọ̀ pé ó yẹ kóun lò ó. Má ṣe jẹ́ kó sú ọ láti ràn án lọ́wọ́, má sì ṣe dáwọ́ fífi ìfẹ́ hàn sí i dúró.

Òótọ́ ni pé ìsoríkọ́ èwe máa ń kó ṣìbáṣìbo gan-an bá ẹni tó níṣòro ọ̀hún àti gbogbo ìdílé. Àmọ́ bó bá yá, sùúrù, ìforítì, àti ìfẹ́ á jẹ́ ká lè ran àwọn èwe tó sorí kọ́ lọ́wọ́.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A gbọ́ pé irú àwọn àìsàn bí àrùn mononucleosis, àrùn àtọ̀gbẹ, àìtó ẹ̀jẹ̀, hypothyroidism, àti àìtó ṣúgà nínú ẹ̀jẹ̀ máa ń ní àwọn àmì bíi ti ìsoríkọ́.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 11]

Ńṣe lara ẹni tó bá sorí kọ́ máa ń gbẹ̀kan. Ìrora ọ̀hún máa ń kọjá sísọ

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 13]

BÓO BÁ JẸ́ ÈWE TÓ NÍ ÌSORÍKỌ́

Àwọn tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ ń bẹ, ó sì dájú pé ìrètí ń bẹ fún ọ. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé (1) àwọn ọ̀nà ìṣiṣẹ́ inú ara rẹ tó gbòdì tàbí (2) àwọn ohun kan nínú ìgbésí ayé rẹ tí o kò rọ́gbọ́n dá sí ló ń fà á. Èyí tó wù kó jẹ́, o kò lẹ́bi fún ipò tóo wà. Síbẹ̀, kí lo lè ṣe nípa rẹ̀?

Bíbélì sọ pé “ọ̀rẹ́ kan wà tí ń fà mọ́ni tímọ́tímọ́ ju arákùnrin lọ.” (Òwe 18:24) O ò ṣe wá irú ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀ kóo sì sọ gbogbo bó ṣe ń ṣe ọ́ fún un? Ọ̀kan lára àwọn òbí rẹ tàbí ẹnì kan tó dàgbà dénú lè pawọ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ láti gbéjà ko ìsoríkọ́.

Tí àwọn òbí rẹ bá kófìrí pé ìsoríkọ́ rẹ máa nílò ìtọ́jú ìṣègùn, wọ́n lè mú ọ lọ sọ́dọ̀ dókítà tó mọ̀ nípa irú ìtọ́jú bẹ́ẹ̀. Ìgbésẹ̀ ọlọ́gbọ́n ni èyí jẹ́, nítorí pé níbi tí irú ìtọ́jú bẹ́ẹ̀ bá ti wà lárọ̀ọ́wọ́tó, ó sábàá máa ń pẹ̀tù sí ìsoríkọ́. Fún àpẹẹrẹ, bó bá jẹ́ pé àwọn ohun kan nínú ara ni kò ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ, wọ́n lè fún ọ láwọn oògùn tó ń gbógun ti ìsoríkọ́. Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ lọ̀ràn rẹ rí, má ṣe tijú láti lo oògùn o. Ńṣe làwọn oògùn náà á mú kí ara rẹ padà bọ̀ sípò, èyí sì lè jẹ́ kóo padà láyọ̀ kóo sì wà déédéé nínú ìgbésí ayé rẹ.

Ọ̀pọ̀ àwọn tó ní ìṣòro yìí ti rí ìtùnú gbà nípa kíka Bíbélì àti sísún mọ́ Ọlọ́run nínú àdúrà. Bíbélì mú un dá wa lójú pé: “Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà; ó sì ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là.” bSáàmù 34:18.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

b Fún ìsọfúnni síwájú sí i, wo àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Ṣé Kí N Sọ fún Ẹnì Kan Pé Mo Níṣòro Ìsoríkọ́?” tó wà nínú Jí! November 8, 2000.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

ÌRÀNWỌ́ ÀTI ÌRÈTÍ FÁWỌN TÓ NÍ ÌSORÍKỌ́

Ọ̀ràn ńlá ni ọ̀ràn ìsoríkọ́ o, èyí ni ò lè jẹ́ ká mẹ́nu ba gbogbo ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú rẹ̀ nínú ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ yìí. Àmọ́ ṣá, àwọn tó ń ṣe Jí! jáde ní ìgbàgbọ́ pé àwọn kókó tí wọ́n kọ síbẹ̀ lè ran àwọn èwe àtàwọn òbí wọn lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro tí ń sọni di ahẹrẹpẹ yìí.

Ó ṣeé ṣe kóo ti kíyè sí i pé èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ìlànà tó wà nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú la gbé karí Bíbélì. Kò sírọ́ níbẹ̀ pé ìwé tọ́jọ́ rẹ̀ ti pẹ́ ni. Síbẹ̀, bí àwọn ìmọ̀ràn inú rẹ̀ ṣe wúlò nígbà tí wọ́n kọ wọ́n náà ni wọ́n ṣì ṣe wúlò lónìí. Èé ṣe? Nítorí bó tilẹ̀ jẹ́ pé àkókò ti yí padà, àbùdá èèyàn ò tíì yí padà. Àwọn ọ̀ràn kan náà táwọn ìran to ti kọjá dojú kọ làwa náà dojú kọ lónìí. Ìyàtọ̀ tó kàn wà níbẹ̀ ni pé àwọn ìṣòro yìí wá lékenkà sí i lónìí ó sì gbòòrò gan-an.

Ìdí mìíràn tí Bíbélì tún fi wúlò gidi gan-an ni pé: Ọlọ́run mí sí i. (2 Tímótì 3:16) Gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́dàá wa, ó mọ ohun táa nílò ká bàa lè ní ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn nínú ayé wa.

Bíbélì kì í ṣe ìwé ìṣègùn ṣáá o. Nítorí náà, kò sọ pé ká máà wá ìtọ́jú tó bá yẹ fún àrùn, irú bí ìsoríkọ́. Síbẹ̀, Bíbélì ní àwọn ìlànà tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti pẹ̀tù sọ́kàn àwọn tó bá níṣòro ọ̀hún. Kò tán síbẹ̀ o, ìlérí Ọlọ́run pé òun máa tó mú gbogbo àwọn àrùn wa kúrò tún wà nínú rẹ̀. (Sáàmù 103:3) Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà ti pète láti “mú ọkàn-àyà àwọn tí a tẹ̀ rẹ́ sọ jí.”—Aísáyà 57:15.

Ṣé wàá fẹ́ láti mọ púpọ̀ sí i nípa ìrètí ńláǹlà yìí? Jọ̀wọ́ kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ tàbí kóo kọ̀wé sí àdírẹ́sì tó yẹ lójú ìwé 5 ìwé ìròyìn yìí.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Gbìyànjú láti fi ìfẹ́ fún ọmọnìkejì hàn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Bí ìsoríkọ́ èwe kan bá kọ̀ tí kò lọ, á dára kóo kàn sí oníṣègùn

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Gẹ́gẹ́ bí òbí, má ṣe yára láti dá ara rẹ, ọkọ tàbí aya rẹ, tàbí ọmọ rẹ lẹ́bi