Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Ọlọ́run Fara Mọ́ Ṣíṣe Òwò Ẹrú?

Ǹjẹ́ Ọlọ́run Fara Mọ́ Ṣíṣe Òwò Ẹrú?

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ǹjẹ́ Ọlọ́run Fara Mọ́ Ṣíṣe Òwò Ẹrú?

ÒÓGÙN bo àwọn aláwọ̀ dúdú ọ̀hún gbindingbindin, ẹrù òwú tí wọ́n dì lé wọn lórí bàbà tutu sì mú kí wọ́n tẹ̀ kòlòbà, bí wọ́n ti ń tẹ̀ kẹ́jẹ́kẹ́jẹ́ lọ. Àwọn alábòójútó tí kò gba gbẹ̀rẹ́ ń fi bílálà kó wọn ṣiṣẹ́. Wọ́n ń já àwọn ọmọ tó ń ké gbà lọ́wọ́ àwọn ìyá tó ń sunkún, wọ́n sì ń tà wọ́n fún àwọn tó máa san owó gọbọi lórí wọn níbi ọjà gbàǹjo tí wọ́n ti ń tà wọ́n. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé irú àwòrán tó ń fìwà ìkà hàn tó sì ń mú èèyàn gbọ̀n rìrì yìí ló máa wá sọ́kàn rẹ tóo bá ronú nípa òwò ẹrú.

Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́, pé ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ṣe òwò ẹrú yìí àtàwọn tí wọ́n ń tà wọ́n fún ló jẹ́ àwọn èèyàn tó gba ẹ̀sìn kanrí gan-an. Òpìtàn náà, James Walvin kọ̀wé pé: “Irú àwọn èèyàn yìí pọ̀ lọ jàra, ará Yúróòpù àti ará Amẹ́ríkà ni wọ́n, wọ́n máa ń yin Olúwa fún ìbùkún rẹ̀, tí wọ́n á máa ṣọpẹ́ fún èrè tí wọ́n jẹ, fún lílọ láyọ̀ àti bíbọ̀ láyọ̀ látibi òwò tí wọ́n lọ ṣe nílẹ̀ adúláwọ̀ bí wọ́n ti ń la ìgbì okun kọjá padà lọ sí Ìwọ Oòrùn ayé.”

Àwọn èèyàn kan tiẹ̀ sọ pé òwò ẹrú náà dùn mọ́ Ọlọ́run nínú. Fún àpẹẹrẹ, nínú ọ̀rọ̀ tí Alexander McCaine sọ nígbà Ìpàdé Àpérò Gbogbo Gbòò, ti Ìjọ Mẹ́tọ́díìsì Pùròtẹ́sítáǹtì lọ́dún 1842, ó sọ pé “Ọlọ́run fúnra Rẹ̀ ló fàṣẹ sí” ìfiniṣẹrú. Ṣé McCaine tọ̀nà? Ǹjẹ́ Ọlọ́run fọwọ́ sí jíjí tí wọ́n ń jí àwọn ọmọbìnrin gbé tí wọ́n sì ń fipá bá wọn sùn, tí wọ́n ń fi àìláàánú pín àwọn ìdílé sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, àti ìnà ìkà tí wọ́n ń na àwọn ẹrú lásìkò òwò ẹrú ayé ọjọ́ McCaine? Àìmọye mílíọ̀nù àwọn èèyàn tí wọ́n ń fipá mú láti máa gbé kí wọ́n sì máa ṣiṣẹ́ bí ẹrú lábẹ́ àwọn ipò tó burú jáì lónìí ńkọ́? Ṣé Ọlọ́run fọwọ́ sí irú híhùwà ìkà sọ́mọ ẹ̀dá bẹ́ẹ̀?

Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì àti Ìfiniṣẹrú

Bíbélì sọ pé “ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.” (Oníwàásù 8:9) Bóyá ni ibòmíràn tún wà tí èyí ti fara hàn kedere ju ti ọ̀nà rírorò tọ́mọ ẹ̀dá ń gbà fini ṣẹrú lọ. Kì í ṣe pé Jèhófà Ọlọ́run dágunlá rárá sí ìyà tí ìfiniṣẹrú ti dá sílẹ̀.

Fún àpẹẹrẹ, ìwọ wo ipò kan táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bára wọn nínú rẹ̀. Bíbélì sọ fún wa pé àwọn ará Íjíbítì “sì ń mú ìgbésí ayé korò fún wọn nípa ìsìnrú nínira nídìí àpòrọ́ tí a fi amọ̀ ṣe àti bíríkì àti pẹ̀lú gbogbo oríṣi ìsìnrú nínú pápá, bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo oríṣi ìsìnrú wọn nínú èyí tí wọ́n lò wọ́n bí ẹrú lábẹ́ ìfìkà-gboni-mọ́lẹ̀.” Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì “ń bá a lọ láti mí ìmí ẹ̀dùn nítorí ìsìnrú náà, wọ́n sì ń ké jáde nínú ìráhùn, igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́ sì ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́ ṣáá nítorí ìsìnrú náà.” Ǹjẹ́ Jèhófà dágunlá sí ìpọ́njú wọn? Rárá o, kàkà bẹ́ẹ̀, “Ọlọ́run gbọ́ ìkérora wọn, Ọlọ́run sì rántí májẹ̀mú rẹ̀ pẹ̀lú Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù.” Síwájú sí i, Jèhófà sọ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: “Èmi yóò sì mú yín jáde dájúdájú kúrò lábẹ́ ẹrù ìnira àwọn ará Íjíbítì, èmi yóò sì dá yín nídè kúrò nínú ìsìnrú wọn.”—Ẹ́kísódù 1:14; 2:23, 24; 6:6-8.

Ó hàn gbangba pé, Jèhófà kò fọwọ́ sí i pé kí ‘ènìyàn máa jọba lórí ènìyàn’ nípa fífi ara wọn ṣe ẹrú lọ́nà ìkà. Ṣùgbọ́n, ṣebí Ọlọ́run fàyè gba ìfiniṣẹrú láàárín àwọn ènìyàn rẹ̀ lẹ́yìn náà? Bẹ́ẹ̀ ni, ó ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ irú ìfiniṣẹrú tó wáyé ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì yàtọ̀ pátápátá sí irú àwọn ìfiniṣẹrú oníkà tó ti ń ṣẹlẹ̀ jálẹ̀ gbogbo ìtàn.

Òfin Ọlọ́run sọ pé ìyà ikú ni kí wọ́n fi jẹ ẹni tó bá jínìyàn gbé tó sì tà á. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà pèsè àwọn ìlànà kan láti dáàbò bo àwọn ẹrú. Fún àpẹẹrẹ, tí ọ̀gá ẹrú kan bá ṣe é léṣe, wọn gbọ́dọ̀ dá ẹrú náà sílẹ̀ lómìnira. Tí ẹrú kan bá kú nítorí nínà tí ọ̀gá rẹ̀ nà án, wọ́n lè pa ọ̀gá náà dí i. Wọ́n lè fi àwọn obìnrin tí wọ́n mú lójú ogun ṣe ẹrú, tàbí kí wọ́n fi wọ́n ṣe aya. Àmọ́, kì í ṣe pé kí wọ́n wá máa lò wọ́n bí ohun èlò ìbálòpọ̀ lásánlàsàn. Kókó tó wà nínú Òfin náà ti gbọ́dọ̀ sún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ ọlọ́kàn títọ́ láti fọ̀wọ̀ wọ àwọn tó jẹ́ ẹrú kí wọ́n sì fi àánú bá wọn lò, bí wọ́n ṣe máa bá òṣìṣẹ́ tí wọ́n háyà tí wọ́n sì ń sanwó fún lò.—Ẹ́kísódù 20:10; 21:12, 16, 26, 27; Léfítíkù 22:10, 11; Diutarónómì 21:10-14.

Àwọn Júù kan sọ ara wọn di ẹrú fún àwọn Júù ẹgbẹ́ wọn kí wọ́n lè san àwọn gbèsè tí wọ́n jẹ. Ńṣe ni irú àṣà yìí gba àwọn èèyàn lọ́wọ́ ebi tó tiẹ̀ tún mú kó ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ láti jàjàbọ́ lọ́wọ́ ipò òṣì. Láfikún sí i, àwọn àkókò pàtàkì kan wà nínú kàlẹ́ńdà àwọn Júù tí wọ́n gbọ́dọ̀ dá àwọn ẹrú wọn sílẹ̀ lómìnira táwọn ẹrú náà bá fẹ́ bẹ́ẹ̀. a (Ẹ́kísódù 21:2; Léfítíkù 25:10; Diutarónómì 15:12) Nígbà tí Júù akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ náà, Moses Mielziner ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn òfin tó jẹ mọ́ ti ẹrú, ó sọ pé “èèyàn ni ẹrú á máa jẹ́ lọ́jọ́kọ́jọ́, wọ́n sì ka ẹrú kan sí ẹnì kan tó láwọn ẹ̀tọ́ kan pàtó, tó jẹ́ pé ọ̀gá rẹ̀ gan-an alára kò lẹ́tọ̀ọ́ láti tẹ̀ lójú.” Ìyàtọ̀ ńlá gbáà mà lèyí jẹ́ o sí ọ̀nà ìkà tí wọ́n fi ń lo àwọn ẹrú gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ìtàn ti fi han!

Àwọn Kristẹni àti Ìfiniṣẹrú

Fífiniṣẹrú jẹ́ apá kan ètò ọrọ̀ ajé Ilẹ̀ Ọba Róòmù, èyí tó wà nígbà ayé àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní. Ìdí rèé táwọn Kristẹni kan fi jẹ́ ẹrú táwọn mìíràn sì ní ẹrú. (1 Kọ́ríńtì 7:21, 22) Àmọ́ ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé ìlòkulò làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí wọ́n ní ẹrú máa ń lò wọ́n ni? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá! Láìka ohun yòówù tí òfin Róòmù lè fàyè gbà sí, ìdánilójú wà pé àwọn Kristẹni kò lo àwọn tó wà lábẹ́ àṣẹ wọn ní ìlòkulò. Kódà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ Fílémónì láti bá Ónẹ́símù, ẹrú rẹ̀ tó wá di Kristẹni, lò bí “arákùnrin.” bFílémónì 10-17.

Kò sí ẹ̀rí kankan nínú Bíbélì tó fi hàn pé kí ẹnì kan máa fi ẹlòmíràn ṣe ẹrú jẹ́ ara ète tí Ọlọ́run ní fún ọmọ aráyé níbẹ̀rẹ̀. Síwájú sí i, kò sí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì kankan tó tọ́ka sí i pé àwọn èèyàn á máa lo èèyàn ẹlẹgbẹ́ wọn fún ìfiniṣẹrú nínú ayé tuntun Ọlọ́run. Kàkà bẹ́ẹ̀, nínú Párádísè tó ń bọ̀ yẹn, àwọn olódodo “yóò jókòó ní ti tòótọ́, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kì yóò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì.”—Míkà 4:4.

Ní kedere, Bíbélì kò fara mọ́ híhùwà ìkà ní ọ̀nà èyíkéyìí sí àwọn ẹlòmíràn. Kàkà bẹ́ẹ̀, níní ọ̀wọ̀ àti bíbánilò lọ́gbọọgba ló fọwọ́ sí. (Ìṣe 10:34, 35) Ó gba àwọn èèyàn níyànjú láti máa bá àwọn ẹlòmíràn lò lọ́nà tí wọ́n fẹ́ kí wọ́n gbà bá àwọn náà lò. (Lúùkù 6:31) Kò tán síbẹ̀ o, Bíbélì tún rọ àwọn Kristẹni láti ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, kí wọ́n máa wo àwọn mìíràn pé wọ́n sàn ju àwọn lọ, láìka irú ẹni yòówù tí wọ́n jẹ́ sí. (Fílípì 2:3) Àwọn ìlànà yìí yàtọ̀ pátápátá sí bí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ṣe ń fini ṣẹrú lọ́nà ìkà, àgàgà láwọn ọ̀rúndún àìpẹ́ yìí.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Pé ètò kan wà tó fàyè gba àwọn ẹrú kan láti máa bá àwọn ọ̀gá wọn gbé jẹ́ ẹ̀rí tó hàn gbangba pé ọ̀nà ìfiniṣẹrú ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kì í ṣe ti oníkà.

b Bákan náà ló rí lónìí, àwọn Kristẹni kan jẹ́ agbanisíṣẹ́; àwọn mìíràn sì jẹ́ àwọn tí a gbà síṣẹ́. Bí Kristẹni agbanisíṣẹ́ kan kò ti ní lo àwọn tó ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ rẹ̀ ní ìlò omi òjò, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe jẹ́ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní ọ̀rúndún kìíní á ti bá àwọn ìránṣẹ́ wọn lò níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Kristẹni.—Mátíù 7:12.