Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ojúṣe Bàbá Ò Ṣeé Fọwọ́ Rọ́ Sẹ́yìn

Ojúṣe Bàbá Ò Ṣeé Fọwọ́ Rọ́ Sẹ́yìn

Ojúṣe Bàbá Ò Ṣeé Fọwọ́ Rọ́ Sẹ́yìn

ÌWÉ ÌRÒYÌN Toronto Star ti Kánádà sọ nípa ìwádìí kan tí Yunifásítì Harvard ṣe láìpẹ́ yìí pé: “Àwọn ọkùnrin tí iye wọn túbọ̀ ń pọ̀ sí i fẹ́ ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti tọ́ àwọn ọmọ wọn. Ìpín méjìlélọ́gọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọkùnrin tó wà láàárín ọdún mọ́kànlélógún sí mọ́kàndínlógójì ló yàn láti ṣe iṣẹ́ tó máa túbọ̀ fún wọn láyè láti wà pẹ̀lú ìdílé wọn.” Níbàámu pẹ̀lú ìwádìí náà, nínú èyí tí wọ́n ti fọ̀rọ̀ wá ẹgbẹ̀rún kan àti mẹ́jọ àwọn ọkùnrin àti obìnrin ará Amẹ́ríkà lẹ́nu wò, tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mọ́kànlélógún sí márùndínláàádọ́rin, ìpín mọ́kànléláàádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọkùnrin tó jẹ́ ọ̀dọ́ ló sọ pé “àwọ́n ṣe tán láti yááfì lára owó oṣù àwọn káwọn lè túbọ̀ ráyè gbọ́ ti ìdílé àwọn.”

Kí ló mú káwọn bàbá túbọ̀ fẹ́ ráyè gbọ́ tàwọn ọmọ wọn? David Blankenhorn, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó dá Ètò Ìjọba fún Ojúṣe Bàbá sílẹ̀, ìyẹn ètò kan tó ń mú kéèyàn jẹ́ bàbá tó mọṣẹ́ ẹ̀ níṣẹ́, tó sì ń fara jìn, sọ pé nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní 1994 fún ẹgbẹ̀jọ ọkùnrin ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ìpín àádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún ló sọ pé, nígbà tí àwọn wà lọ́mọdé, bàbá àwọn kò tẹ́tí sílẹ̀ sí wọn rí láti gbọ́ ohun tó ń dun àwọn lọ́kàn. Ọ̀pọ̀ àwọn tó jẹ́ bàbá lónìí ni kò fẹ́ kí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ tún ṣẹlẹ̀ mọ́.

Àwọn bàbá tó ń ráyè fún àwọn ọmọ wọn dáadáa lè ní ipa tó dára gan-an lórí wọn. Nígbà tí ìwé ìròyìn The Toronto Star ń sọ nípa ìwádìí kan tí Iléeṣẹ́ Ìjọba Amẹ́ríkà Tí Ń Bójú Tó Ìlera àti Ìpèsè fún Aráàlú tẹ̀ jáde, ó sọ pé nígbà táwọn bàbá bá ń jẹun pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn, tí wọ́n ń mú wọn jáde, tí wọ́n sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá wọn, “ìwọ̀nba ni ìpátá wọn máa ń mọ, ìṣesí wọ́n máa ń dára láàárín ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà, àwọn tó jẹ́ ọmọdé àtàwọn ọ̀dọ́langba sì máa ń ṣe dáadáa gan-an níléèwé.”

Ńṣe làwọn ọ̀rọ̀ òkè yìí ń sọ nípa ìlànà ọmọ títọ́ kan tó ti wà lákọọ́lẹ̀ láti nǹkan tó lé lẹ́gbẹ̀rún ọdún mẹ́ta sẹ́yìn tó ṣì wúlò lónìí gẹ́gẹ́ bó ṣe wúlò nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ kọ ọ́. Olùdásílẹ̀ ìdílé dìídì sọ fún àwọn bàbá láti kópa lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ nínú títọ́ àwọn ọmọ wọn. (Éfésù 3:14, 15; 6:4) Ó gba àwọn bàbá nímọ̀ràn láti tẹ ìfẹ́ Ọlọ́run mọ́ àwọn ọmọ wọn lọ́kàn kí wọ́n sì máa sọ àwọn ìlànà Ọlọ́run àti àwọn àṣẹ rẹ̀ fún wọn. Ọlọ́run sọ fún wọn láti máa ṣe èyí ‘nígbà tí wọ́n bá jókòó nínú ilé àti nígbà tí wọ́n bá ń rìn ní ojú ọ̀nà àti nígbà tí wọ́n bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí wọ́n bá dìde.’—Diutarónómì 6:7.

Ẹrù iṣẹ́ ọmọ títọ́ kì í wá ṣe ti ẹnì kan ṣoṣo o. Bíbélì ṣí àwọn ọmọ létí pé: “Fetí sílẹ̀ . . . sí ìbáwí baba rẹ, má sì ṣá òfin ìyá rẹ tì.” (Òwe 1:8) Ipa ti bàbá ń kó kò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn rárá. Ó kan gbígbárùkù ti ìyá àti bíbọ̀wọ̀ fún un àti bíbá a pín nínú iṣẹ́ ọmọ títọ́. Ó tún ń béèrè lílo àkókò láti kàwé fún àwọn ọmọ àti láti bá wọn sọ̀rọ̀. Èyí ń ṣèrànwọ́ láti bójú tó àwọn ohun tó lè máa dààmú ọkàn àwọn ọmọ.

Kò sí tàbí ṣùgbọ́n pé Bíbélì ni orísun ìmọ̀ràn àti àwọn ìlànà tó ṣe sàn-án tó ṣeé gbára lé jù lọ fún ìdílé kan tó máa ṣàṣeyọrí sí rere. Ńṣe ni bàbá kan tó ń bójú tó ìdílé rẹ̀ dáadáa nípa tẹ̀mí, ní ti ẹ̀dùn ọkàn àti nípa tara ń ṣe ojúṣe rẹ̀ tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́.