Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ojú Tí Wọ́n Fi Ń Wo Àwọn Arúgbó Ń Yí Padà

Ojú Tí Wọ́n Fi Ń Wo Àwọn Arúgbó Ń Yí Padà

Ojú Tí Wọ́n Fi Ń Wo Àwọn Arúgbó Ń Yí Padà

ỌMỌ ọdún mélòó ni wàá jẹ́ kóo tó lè gbà pé o ti darúgbó? Ó jọ pé ìdáhùn yẹn sinmi lórí irú ẹni tóo bá bi léèrè. Pẹ̀lú ìdùnnú làwọn tí ò tíì pé ọmọ ogun ọdún máa fi sọ pé ẹnikẹ́ni tó bá ti kọjá ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ni.

Àmọ́ ní ti àwọn olórin orí ìtàgé, wọn kì í tètè mókè nígbèésí ayé àfi lẹ́yìn tí wọ́n bá ti dàgbà dáadáa. Nígbà tí ìwé ìròyìn The Sun-Herald ti Ọsirélíà sì ń sọ nípa àwọn tí wọ́n máa ń fi dandan lé e pé àwọ́n gbọ́dọ̀ dé ipò gíga, ó sọ pé: “Ohun tó gbòde kan báyìí ni pé, bí o ò bá tíì rọ́wọ́ mú tí o fi pé ọmọ ogójì ọdún, ó ò lè ri ṣe mọ́ láyé ẹ nìyẹn.”

Èrò Tó Wọ́pọ̀

Àwọn kan lè máa rò pé jàǹbá kò jìnnà sáwọn àgbàlagbà, pé nǹkan kì í yé wọn bọ̀rọ̀ tó sì jẹ́ pé kíákíá ni ara wọn máa ń daṣẹ́ sílẹ̀. Ǹjẹ́ ó tọ́ láti máa nírú èrò yẹn? Àmọ́ o, níbàámu pẹ̀lú ìwádìí tí Àjọ Ìlera Àgbáyé ṣe, “ikú àwọn ọ̀dọ́ tí kò tíì pé ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ló kó ìdá kan nínú ìdá mẹ́ta gbogbo ikú jàǹbá mọ́tò ní gbogbo àgbègbè Yúróòpù pátá.” Síwájú sí i, àárín ọjọ́ orí ọgbọ̀n sí ogójì ni ìlera ara máa ń daṣẹ́ sílẹ̀ jù lọ, kò sì sí ẹ̀rí kankan tó fi hàn pé ńṣe ni òye téèyàn ní láti mọ nǹkan ń dín kù bó ṣe ń dàgbà sí i.

Èrò ti pé àwọn àgbàlagbà ò lè ṣe kí wọ́n má ṣàìsàn ńkọ́? Ìwé àtìgbàdégbà náà, The Medical Journal of Australia sọ pé: “Àròsọ kan tó wọ́pọ̀ ni pé bágbà bá ti ń dé làìsàn á máa yọjú.” Àmọ́ òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ọ̀pọ̀ arúgbó lára wọn dá ṣáṣá dé àyè kan tí wọn ò sí jẹ́ ka ara wọn sẹ́ni tó ti dàgbà. Bí òṣèlú ara Amẹ́ríkà yẹn, Bernard Baruch làwọn kan lára wọ́n rí, ẹni tó sọ pé: “Tí mo bá fi ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ju bí mo ṣe wà lọ ni mo tó gbà pé mo dàgbà.”

Kí wá ló dé nígbà yẹn tí wọ́n fi máa ń pa àwọn àgbàlagbà tì, tí wọ́n á tiẹ̀ ta wọ́n nù pátápátá nígbà mìíràn? Ìdáhùn yẹn ní í ṣe ní pàtàkì pẹ̀lú ojú táwọn èèyàn fi ń wo àwọn arúgbó.

Ojú Táwọn Èèyàn Fi Ń Wo Àwọn Arúgbó

Nínú ìwé ìròyìn The New York Times Magazine, Max Frankel sọ pé: “Ńṣe ni jíjẹ́ ọ̀dọ́ máa ń pa àwọn ará Amẹ́ríkà bí ọtí, ìyẹn ló fà á táwọn iléeṣẹ́ ìròyìn fi máa ń gbé ohun tí kò tọ́ jáde nípa àwọn arúgbó.” Ó dárò pé: “Gbogbo àwọn tọ́jọ́ wọn ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìròyìn ni wọ́n ti lé dànù.” Èyí lè jẹ́ ká lóye èrò òde òní kan tó takora tí ìwé ìròyìn The UNESCO Courier gbé jáde pé: “Kò tíì . . . sí àwùjọ kankan tó ṣe nǹkan tó tó báyìí fún àwọn arúgbó rẹ̀. Wọ́n ń jàǹfààní ìpèsè owó àti àwọn ohun amáyédẹrùn, àmọ́ ojú tí wọ́n fi ń wò wọ́n láwùjọ kò bọ́ sí i rárá.”

Kódà ẹ̀tanú yìí tún ń wá látọ̀dọ̀ àwọn oníṣègùn. Gẹ́gẹ́ bi ohun tí ìwé ìròyìn The Medical Journal of Australia sọ: “Ọ̀pọ̀ dókítà àti gbogbo èèyàn lápapọ̀ ló gbà pé kò yẹ káwọn èèyàn tó bá ti ju ọdún márùnlélọ́gọ́ta lọ tún máa wá ìtọ́jú tó ń dènà àìsàn kiri. . . . Ìwà burúkú yìí . . . ni kì í jẹ́ kí wọ́n máa ṣe àwọn ìwádìí ìṣègùn tó ṣe pàtàkì nípa àwọn arúgbó.”

Ìwé ìròyìn yìí kan náà tún sọ pé: “Ìwà tí kò dáa táwọn oníṣègùn ń hù sáwọn arúgbó, tí wọ́n ń sọ pé ‘àìsàn ọjọ́ ogbó’ ló ń yọ wọ́n lẹ́nu ni wọ́n tún lè lò bí àwáwí fún ṣíṣàì fún wọn ni ìtọ́jú tó péye. Àwọn ìṣòro pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tó wọ́pọ̀ bíi kí ojú máà ríran kedere àti kí etí máà gbọ́ràn dáadáa ni wọ́n máa ń gbojú fò dá tàbí kí wọ́n kà á sí ara àìsàn àwọn arúgbó. . . . Àfi tí ìwà tí wọ́n ń hù sáwọn àgbàlagbà bá yí padà nìkan ni ètò ìdènà àrùn fáwọn arúgbó fi lè gbéṣẹ́.”

Ìwé ìròyìn ìṣègùn The Lancet ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì wá dá a lábàá pé: “Ó dà bíi pé àsìkò ti tó báyìí láti wo ohun tí jíjẹ́ arúgbó túmọ̀ sí láwòfín, ì báà jẹ́ láwọn orílẹ̀-èdè tó ti rọ́wọ́ mú nìkan.” Kí nìdí tí èyí fi ṣe pàtàkì? Ìwé ìròyìn ọ̀hún ṣàlàyé pé: “Tí wọ́n bá ṣàtúnṣe náà, ó lè mú àìsírètí, èrò òdì, àtàwọn ọ̀rọ̀ tó ń jáni láyà nípa ọjọ́ iwájú kúrò èyí tí wọ́n sábà máa ń sọ láti fi ta àwọn arúgbó nù pé pípọ̀ tí wọ́n ‘ń pọ̀ sí i’ ló ń kó ‘èyí tó pọ̀ jù lọ’ nínú owó tí kò tó nǹkan tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún ìlera lọ.”

Àwọn Arúgbó Ń Pọ̀ Sí I

Ohun kan tó jẹ́ òtítọ́ ni pé, àwọn arúgbó kàn ń pọ̀ si ṣáá ni. Ìwé ìròyìn The UNESCO Courier sọ pé: “Láàárín ọdún 1955 sí 2025, iye àwọn èèyàn tọ́jọ́ orí wọn jẹ́ márùnlélọ́gọ́ta àtàwọn tó dàgbà jùyẹn lọ máa fi ìlọ́po mẹ́rin pọ̀ sí i, táa bá sì gbé àpapọ̀ iye wọn ka orí ìpíndọ́gba, á tó ìlọ́po méjì.”

Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, àwọn arúgbó tó wà ní ilẹ̀ Íńdíà ju iye gbogbo èèyàn tó wà ní ilẹ̀ Faransé lọ. Wọ́n tún sọ pé ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, mílíọ̀nù mẹ́rìndínlọ́gọ́rin àwọn tí wọ́n bí ní ọdún méjìdínlógún lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì ló máa fẹ̀yìn tì tí ọ̀rúndún yìí bá fi máa dé ìdajì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bí àwọn tó ń gbé ayé ṣe ń dàgbà sí i ń kó ìdààmú bá ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ nípa ètò ọrọ̀ ajé àtàwọn òṣìṣẹ́ ìlera, síbẹ̀ ó tún ń jẹ́ ká fẹ́ láti tún èrò tó ti wà lọ́kàn wa gbé yẹ̀ wò.

Títún Ọ̀rọ̀ Náà Gbé Yẹ̀ Wò

Àwọn kan lè fi ìgbésí ayé ẹ̀dá wé eré onípele mẹ́ta. Fífò síbí fò sọ́hùn-ún nígbà ọ̀dọ́ àti ẹ̀kọ́ kíkọ́ la máa retí pé kó gbapò iwájú nínú ìpele àkọ́kọ́. Ẹrù bíbójútó ìdílé àti wàhálà bóojí-o-jí-mi tí kò lópin ló máa kún inú ìpele èkejì. Nínú ti ẹ̀kẹta wàyí o, ni wọ́n á ti gba àwọn olùkópa nímọ̀ràn pé kí wọ́n lọ gbélé wọn, pé wọn ò tún nílò wọn mọ́, kí wọ́n lọ wá ibì kan jókòó sí títí tí ikú á fi dé.

Àmọ́ nítorí àwọn ìdí kan, títí kan ìtẹ̀síwájú kíkàmàmà nínú àbójútó ìlera àti ìmọ́tótó ní ọ̀rúndún ogún, iye ọdún táwọn “òṣèré” náà ń lò báyìí ní “ìpele kẹta” ìyẹn lẹ́yìn tí wọ́n ti kúrò lójútáyé ti fi ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n gùn sí i. Ọ̀pọ̀ wọn ni kò gbà láti jókòó gẹlẹtẹ mọ́ láìṣe nǹkankan. Àwọn arúgbó tára wọ́n dá ṣáṣá tí iye wọn túbọ̀ ń pọ̀ sí i yìí ti wá ń béèrè pé kí wọ́n tún ọ̀rọ̀ àwọn gbé yẹ̀ wò.

Ipa Ribiribi Tí Wọ́n Ń Kó

Èrò tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń ní pé èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn àgbàlagbà ló jẹ́ pé àwọn ẹlòmíràn ni wọ́n gbára lé kì í ṣòótọ́ rárá ni. Ìwé ìròyìn The New York Times Magazine sọ pé ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, “èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn àgbàlagbà ni wọn ò lálàṣí ohunkóhun, wọ́n rọ́wọ́ mú, wọ́n sì lówó lọ́wọ́ ju àwọn tọkọtaya tí wọ́n ṣì jẹ́ ọ̀dọ́ lọ . . . àti [pé], àwọn onímọ̀ nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá ti ń wòye pé tó bá yá a máa rí àwùjọ àwọn àgbàlagbà tó rí já jẹ tó sì mọ nǹkan tí wọ́n ń ṣe.” Philip Kotler, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ ọjà títà ní Yunifásítì Àríwá Ìwọ̀ Oòrùn Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà náà sọ nǹkankan nípa ọ̀ràn yìí. Ó sọ pé: “Àwọn onímọ̀ ọjà títà yìí kò ní pẹ́ máa tọ àwọn èèyàn tó lè ra ọjà wọn lọ, ìyẹn àwọn èèyàn tó rí já jẹ tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ láti ọdún márùndínlọ́gọ́ta lọ sókè.”

Ipa táwọn àgbàlagbà tára wọn dá ṣáṣá ń kó ju ọ̀rọ̀ olówó dé lọ fíìfíì. Ìwé ìròyìn The Sunday Telegraph ti Sydney sọ pé ní Ọsirélíà, “àwọn ìyá àgbà ló ń ṣe ìdajì iṣẹ́ títọ́jú àwọn ọmọ kéékèèké láìsí pé wọ́n ń gbowó, tí àwọn obìnrin tó sì jẹ́ pé ìyá àgbà ló ń bá wọn tọ́jú ọmọ wọn nígbà tí wọ́n bá wà níbi iṣẹ́ ju ìdá kan nínú mẹ́ta lọ.”

Láwọn ìlú bíi Troyes ní ilẹ̀ Faransé, ojú kékeré kọ́ ni wọ́n fi ń wo ọgbọ́n rẹpẹtẹ táwọn àgbàlagbà ní. Wọ́n ń gbà lára ọgbọ́n wọn yìí nípa lílo àwọn àgbàlagbà láti máa kọ́ àwọn ọmọ ní àwọn iṣẹ́ bíi gbẹ́nàgbẹ́nà, gíláàsì ṣíṣe, òkúta gbígbẹ́, ilé kíkọ́, àti títún páìpù omi ṣe. Yàtọ̀ sí pé àwọn àgbàlagbà yìí ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, ọ̀pọ̀ wọn ló tún ń lọ sílé ẹ̀kọ́ láti lọ gba ìmọ̀ kún ìmọ̀.

Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn The UNESCO Courier ti January 1999 ṣe sọ, “Ẹgbẹ́ Tó Ń Rí sí Yunifásítì Àwọn Àgbà Láwọn Orílẹ̀-Èdè tó fìdí kalẹ̀ sí ìlú Paris” sọ pé “yunifásítì àwọn àgbààgbà tó wà jákèjádò ayé lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán [1,700].” Nígbà tí ìwé ìròyìn yìí ń sọ nípa àwọn yunifásítì ọ̀hún, ó ní: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bí wọ́n ṣe kọ́ wọn àti ohun tí wọ́n ń ṣe nínú wọn yàtọ̀ síra wọn gan-an láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn, gbogbo àwọn yunifásítì náà ló sábàá máa ń fẹ́ láti ran àwọn àgbàlagbà lọ́wọ́ láti kópa ní kíkún nínú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àti ìgbésí ayé àwùjọ.” Wọ́n sọ pé ọ̀kan lára irú ilé ẹ̀kọ́ yẹn tó wà ní Japan ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlá [2,500] akẹ́kọ̀ọ́!

Alexandre Kalache, tó jẹ́ aṣáájú kan nínú Ètò Àjọ Ìlera Àgbáyé Tó Ń Rí sí Ipò Ọjọ́ Ogbó àti Ìlera sọ pé: “Táa bá ṣàkópọ̀ nǹkan táwọn àgbàlagbà ń ṣe fún ìdílé wọn àti àwùjọ wọn, kì í ṣe kékeré rárá, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn láti gbà bẹ́ẹ̀ nítorí ọ̀pọ̀ rẹ̀ ni a kì í sanwó fún.” Ó tún sọ pé: “Kò . . . yẹ káwọn orílẹ̀-èdè máa wo àwọn àgbàlagbà pé ìṣòro ni wọ́n jẹ́, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ló yẹ kí wọ́n máa wò wọ́n bí àwọn tó lè bá wọn yanjú àwọn ìṣòro . . . , àti ní pàtàkì bí ohun ìní tó wà fún ìlò wọn.”

Òdodo ọ̀rọ̀ pọ́ńbélé ni pé, ojú táwọn ẹlòmíràn fi ń wò wá àti ẹ̀tanú tí wọ́n lè ní sí wa lè nípa lórí báa ṣe máa gbádùn ọjọ́ alẹ́ wa, àmọ́ ojú táwa fúnra wa fi ń wo ìgbésí ayé ló jà jù. Kí lóhun tíwọ fúnra rẹ lè ṣe láti dá ṣáṣá nínú ìrònú rẹ àti nípa tara, ká tilẹ̀ ní ara rẹ ń dàgbà sí i? Jọ̀wọ́ ka àpótí tó wà ní ojú ewé 16 àti 17, kóo sì wo ohun tí àwọn àgbàlagbà kan sọ nípa ohun tó jẹ́ kára wọ́n dá ṣáṣá àtohun tó ń mú wọn gbádùn ìgbésí ayé.

Ṣe Gbogbo Ohun Tóo Bá Lè Ṣe Kára Rẹ Lè Dá Ṣáṣá

Wàá kíyè si pé ohun kan tí gbogbo àwọn àgbàlagbà tí wọ́n ń ta kébékébé yìí fi jọra wọn ni pé wọn ò fìgbà kankan jáwọ́ nínú ṣíṣe iṣẹ́ tó nítumọ̀, bóyá iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ ni o tàbí iṣẹ́ yíyọ̀ǹda ara ẹni. Wọn kì í tún fi eré ìmárale ṣeré rárá, wọ́n nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn láìka ọjọ́ orí wọn sí, wọ́n sì máa ń bójú tó ipò tẹ̀mí wọn. Bí ìwọ náà ṣe mọ̀, tàgbàtèwe ni ohun tó lè máyé ẹni dùn táá sì mú un kún fún ìgbòkègbodò yìí máa ṣàǹfààní fún.

Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, òótọ́ kan tó lè máà bá ẹnikẹ́ni wa lára mu ni pé, bóo ṣe ń ka àpilẹ̀kọ yìí lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ làgbà ń kàn ẹ́ bọ̀. (Oníwàásù 12:1) Síbẹ̀, ó bọ́gbọ́n mu pé kóo fi ohun tí ìwé ìròyìn Bulletin of the World Health Organization fi ṣàkópọ̀ ọ̀rọ̀ yìí sọ́kàn pé: “Bó ṣe jẹ́ pé ìlera ni atọ́kùn gbogbo ìgbòkègbodò, ìgbésí ayé tó kún fún akitiyan ṣì ni ọ̀nà tó dára jù lọ láti jẹ́ ẹni tí ara rẹ̀ le.”

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]

Àìdaranù Ló Ń Mú Wọn Gbádùn Ìgbésí Ayé

GÚÚSÙ ÁFÍRÍKÀ: Piet Wentzel, òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́rin.

“Mo mọ̀ pé tí mo bá fẹ́ kára mi dá ṣáṣá, eré ìmárale ṣe pàtàkì. Láti ọdún díẹ̀ sẹ́yìn ni mo ti ń dá oko kékeré kan. Ńṣe ló máa ń dà bíi pé kì í ṣe èmi kan náà ni nígbà tí mo bá ṣiṣẹ́ tán níbẹ̀. Kí n lè ṣe púpọ̀, mo máa ń rántí ìlànà kan tó sọ pé, ‘Ìfòní-dónìí-fọ̀la-dọ́la ló ń fàkókò ṣòfò; àìwá-kan-ṣe ni ọmọ ìyá rẹ̀.’”

[Àwòrán]

“Mo mọ̀ pé ṣíṣe eré ìmárale déédéé ṣe pàtàkì.” —Piet

JAPAN: Yoshiharu Shiozaki, olùgbaninímọ̀ràn lórí dúkìá ilé àti ilẹ̀ ẹni ọdún mẹ́tàléláàádọ́rin.

“Àìsàn ìrora inú egungun, ẹ̀jẹ̀ ríru, àti àrùn Meniere máa ń bá mi jà. Kẹ̀kẹ́ ni mo máa ń gùn láti ilé mi lọ sí ọ́fíìsì ní ọjọ́ mẹ́rin lọ́sẹ̀; àpapọ̀ ìrìn ọ̀hún jẹ́ kìlómítà méjìlá. Nǹkan tó máa ń mára mi le nìyẹn, nítorí kì í jẹ́ kẹ́yìn ro mí ó sì máa ń fún àwọn iṣan ẹsẹ̀ mi lókun. Mo máa ń gbìyànjú láti bá àwọn èèyàn rẹ́, títí kan àwọn aládùúgbò mi. N kì í wá kùdìẹ̀-kudiẹ àti àṣìṣe àwọn ẹlòmíràn. Mo ti wá rí i pé kíákíá làwọn èèyàn máa ń ṣàtúnṣe nígbà tí wọ́n bá fún wọn níṣìírí ju kéèyàn máa ṣàríwísí wọn lọ.”

[Àwòrán]

“N kì í wá kùdìẹ̀-kudiẹ àwọn ẹlòmíràn.”—Yoshiharu

FARANSÉ: Léone Chalony, ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin, ajíhìnrere alákòókò kíkún.

“Nígbà tí mo fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ ní 1982, kò rọrùn fún mi rárá nítorí mo fẹ́ràn iṣẹ́ atúnrunṣe ti mo ń ṣe gan-an. Mi ò ní bùkátà tí mo ń gbọ́, ni mo bá di aṣáájú ọ̀nà, gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ àwọn oníwàásù alákòókò kíkún ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí. Kíkọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń fífẹ́ hàn sí Bíbélì lẹ́kọ̀ọ́ ti jẹ́ kí ọpọlọ mi máa jí pépé. Mi ò ní mọ́tò, nítorí náà mo máa ń fẹsẹ̀ rìn gan-an. Ìyẹn sì ń jẹ́ kára mi máa le koko.”

[Àwòrán]

“Kíkọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti jẹ́ kí ọpọlọ mi máa jí pépé.”—Léone

BRAZIL: Francisco Lapastina, ẹni ọdún méjìdínlọ́gọ́rin, òjíṣẹ́ alákòókò kíkún.

“N kì í fi gbogbo ìgbà bínú tèèyàn bá ṣẹ̀ mí tàbí tó fojú pa mí rẹ́. Màá kàn fojú wò ó pé bóyá ẹni yẹn ní wàhálà kan tó bò mọ́ra ni tàbí pé ó lè níṣòro. Ojoojúmọ́ kọ́ lára gbogbo wa máa ń yá mọ́ èèyàn. Mo máa ń gbìyànjú láti má ṣe di àwọn èèyàn sínú tí mo sì máa ń fi sọ́kàn pé èmi náà máa ń ṣe àwọn nǹkan kan táwọn èèyàn sì máa ń mú un mọ́ra. Èyí ti ràn mí lọ́wọ́ láti ní àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ tó pọ̀.”

[Àwòrán]

“Mo máa ń gbìyànjú láti má ṣe di àwọn èèyàn sínú.”—Francisco

ỌSIRÉLÍÀ: Don MacLean, ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́rin, ó ṣì ń ṣiṣẹ́ fún ogójì wákàtí lọ́sẹ̀.

“Ọdún mẹ́rin lẹ́yìn tí mo ṣe iṣẹ́ abẹ ọkàn, koko lára mi ṣì le. Mi ò wo iṣẹ́ abẹ yìí bí ohun tó ti wá sọ mí di aláàbọ̀ ara ní ìgbésí ayé. Mo ṣì máa ń nasẹ̀ jáde lójoojúmọ́ bí mo ti ń ṣe láti ọ̀pọ̀ ọdún wá. Ìgbà tí mo ti wà ní kékeré tí mo ti máa ń rí àwọn kan tí wọ́n ń darúgbó láìtọ́jọ́ ni mo ti sọ pé mi ò jẹ́ jẹ́ kí tèmi rí bẹ́ẹ̀. Dídi ojúlùmọ̀ àwọn èèyàn àti bíbẹ̀rẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ pẹ̀lú wọn máa ń fún mi láyọ̀ gidigidi. Táa bá tún wá wáyè fún nǹkan tẹ̀mí nínú ìgbésí ayé wa, ìyẹn á jẹ́ kọ́rọ̀ wa dà bí èyí tó wà nínú Sáàmù 103:5 tó sọ pé: ‘[Jèhófà] ń fi ohun rere tẹ́ ọ lọ́rùn ní ìgbà ayé rẹ; ìgbà èwe rẹ ń sọ ara rẹ̀ dọ̀tun gẹ́gẹ́ bí ti idì.’”

[Àwòrán]

“Má darúgbó ọ̀sán gangan.”—Don

JAPAN: Chiyoko Chonan, ẹni ọdún méjìdínláàádọ́rin, ajíhìnrere alákòókò kíkún.

“Ọ̀nà téèyàn fi lè máa ní ìlera tó dára ni láti máà jẹ́ kí másùnmáwo máa kóra jọ kó sì máa rẹ èèyàn. Mo máa ń ṣọ́ra láti máà jẹ́ kí nǹkan máa kó ìdààmú bá mi ju bó ṣe yẹ lọ, mo sì ti rí i pé yíyíwọ́ padà nínú àwọn nǹkan tí mo ń ṣe látìgbà dégbà máa ń ràn mí lọ́wọ́. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí mo ti bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ láti ṣe eré ìmárale kan tó ń ṣèrànwọ́ fún ọmọ-ìka mi àti èrò inú mi. Mo gbà pé kíkọ́ àwọn nǹkan tuntun ń ṣàǹfààní.”

[Àwòrán]

“Mo gbà pé kíkọ́ àwọn nǹkan tuntun ń ṣàǹfààní.”—Chiyoko

FARANSÉ: Joseph Kurdudo, ẹni ọdún mẹ́tàléláàádọ́rin, òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ni.

“Ọ̀nà tóo fi lè gbádùn dídarúgbó láìsí wàhálà ni yíyẹra bó bá ti ṣeé ṣe tó fún jíjókòó gẹlẹtẹ. Ṣíṣiṣẹ́ máa ń fúnni ní ìtẹ́lọ́rùn, o sì tún gbọ́dọ̀ ṣọ́ ohun tí ò ń jẹ tí wàá sì máa ṣe àwọn àtúnṣe tó bá yẹ. Mo rò pé nígbà tí ìgbésí ayé èèyàn bá ní ète nínú, ó máa ń mú kéèyàn yàtọ̀. Mo mọ̀ pé jíjẹ́ ẹni tẹ̀mí ṣe pàtàkì gan-an fún níní ìlera tó jí pípé. Kí n tó di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mi ò mọ béèyàn ṣe ń ṣe ìpinnu tí ayé sì máa ń sú mi. Mímọ àwọn òtítọ́ Bíbélì jẹ́ agbára ńlá kan tó máa ń fún èèyàn lókun láti kojú onírúurú ipò.”

[Àwòrán]

“Jíjẹ́ ẹni tẹ̀mí ṣe pàtàkì gan-an.”—Joseph