Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wíwo Ayé

Wíwo Ayé

Wíwo Ayé

Ayédèrú Àkẹ̀kù

Ìwé ìròyìn The Guardian ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ pé: “Odindi ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́fà ni àkẹ̀kù egungun ẹranko afàyàfà rírorò kan ti wà rèǹtè-rente nínú gbọ̀ngàn Ìkóhun-Ìṣẹ̀ǹbáyé-Sí Ti Ìjọba ní Wales, Cardiff, èyí tí wọ́n ní ọjọ́ orí rẹ̀ ti wọ igba mílíọ̀nù ọdún tó sì gbé inú okun ní àìmọye ọdún sẹ́yìn. Ìgbà táwọn alábòójútó ní Cardiff pinnu láti sọ egungun ẹranko ichthyosaurus tó ti gbénú òkun rí yìí dọ̀tun ni wọ́n tó mọ̀ pé wọ́n ti tàn wọ́n jẹ.” Caroline Buttler, tó ń tọ́jú rẹ̀ sọ pé: “Nígbà táa ṣí ọ̀dà onípele márùn-ún tí wọ́n fi kùn-ún kúrò, lá bá rí i pé irọ́ gbuu ló wà níbẹ̀. Àpapọ̀ oríṣi ẹranko ichthyosaurus méjì ni wọ́n ṣe síbẹ̀ tí wọ́n sì wá dọ́gbọ́n to àwọn ẹ̀yà ara tó jẹ́ gbàrọgùdù mọ́ ọn.” Dípò tí ilé ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí yìí á fi gbé e sọnù, ńṣe ló máa pàtẹ rẹ̀ bí àpẹẹrẹ àkẹ̀kù kan tó jẹ́ ayédèrú.

Àwọn Adágún Orí Òkè Kò Bọ́ Lọ́wọ́ Èérí

Àwọn adágún omi tó wà lórí àwọn òkè kò mọ́ rárá tó bí ọ̀pọ̀ ṣe rò. Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Jámánì náà, natur & kosmos sọ pé: “Àwọn adágún tó wà lórí àwọn òkè tó tiẹ̀ ga gan-an kò bọ́ lọ́wọ́ òbítíbitì èérí, irú bíi Schwarzsee tó wà lókè Sölden [Austria].” Àwọn ẹja tó wà nínú àwọn adágún lórí àwọn òkè ní ìwọ̀n oògùn apakòkòrò DDT tó fi ẹgbẹ̀rún ìgbà ju tàwọn ẹja tó wà nínú àwọn omi apá ìsàlẹ̀ lọ. Kí nìdí? Láwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ olóoru, kẹ́míkà olóró máa ń bá atẹ́gùn lọ sókè bí oòrùn bá ti ń lá omi gbẹ tí afẹ́fẹ́ á sì gbé e lọ sáwọn apá ibòmíràn láyé. Tí èérún oògùn apakòkòrò DDT bá wá dé àwọn apá ibi tó tutù, bíi nínú àwọn adágún tó wà lórí àwọn òkè, ńṣe ló máa dì tá sì dà sílẹ̀ bí òjò dídì. Ìwé ìròyìn ọ̀hún sọ pé: “Ńṣe ni àwọn adágún orí òkè dídì yìí máa ń fa oògùn apakòkòrò DDT náà látinú atẹ́gùn àyíká táá sì wá mú kó dìpọ̀ mọ́ra.” Wọ́n ti fòfin de DDT tó ń pa kòkòrò àmọ́ tó jẹ́ pé májèlé ni fún èèyàn àti ẹranko láti ohun tó lé ní ogún ọdún sẹ́yìn ní Yúróòpù, ṣùgbọ́n wọ́n ṣì ń lò ó láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà.

Àwọn Sàréè Aládàáni

Ìwé ìròyìn L’Express ti ilẹ̀ Faransé sọ pé: “Àwọn àràmàǹdà sàréè ti wá di àṣà tuntun nínú ààtò ìsìnkú báyìí o.” Àwọn tó ń ṣe sàréè ṣe tán láti ṣe àwọn ọwọ̀n ìrántí tó ní àwọ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ ọnà tuntun, kí wọ́n sì lo àwọn ohun èèlò bíi gíláàsì olóríṣiríṣi àwọ̀ tàbí mẹ́táàlì. Lára àwọn ọwọ̀n ìrántí tí wọ́n ti ṣe ni àwọn kan tí wọ́n gbẹ́ bí agbòjò, àwọn kan dà bí ajá, àwọn kan bíi màlúù, òmíràn dà bí àwókù ọkọ̀ ojú irin, àti ọ̀kan tó dà bí àgbá wáìnì, tí oníṣòwò wáìnì kan bẹ̀ wọ́n. Ilé iṣẹ́ ńlá kan sọ pé òun máa ń ṣe ọwọ̀n tó dà bí alùpùpù “tó tó ọgọ́rin lọ́dún ó kéré tán” láti fi dárà sí sàréè. Gẹ́gẹ́ bí àpilẹ̀kọ náà ṣe sọ, ìlànà àdúgbò kò yọ̀ǹda ju ọwọ̀n tí wọ́n máa ń ṣe sí ìgbèrí sàréè lọ tí wọ́n á sì rẹ́ ìyókù, àmọ́ òfin ilẹ̀ Faransé fara mọ́ pé kí oníkálùkù ṣe ohun tó bá gbà gbọ́ tí wọ́n sì fún àwọn tó ni ilẹ̀ ìsìnkú ní “òmìnira láti kọ́ ohun tó wù wọ́n.”

Ṣọ́ra fún Òjé Inú Àwọn Nǹkan Ọ̀ṣọ́

Ìròyìn Ìlera láti Kánádà kìlọ̀ pé: “Tí o bá mọ̀ pé ó ṣeé ṣe kí ọmọ rẹ jẹ àwọn nǹkan ọ̀ṣọ́ lẹ́nu tàbí kó máa pọ́n wọn lá tó sì lè ní òjé nínú, gbé e sọnù ní kíá mọ́sá.” Ìwádìí ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ tí wọ́n ṣe nípa àwọn ohun ọ̀ṣọ́ pọ́ọ́kú-lowó-ẹ̀ tí wọ́n dìídì ṣe fáwọn ọmọdé fi hàn pé ọ̀pọ̀ lára èyí tí wọ́n fi ṣàyẹ̀wò ló ní òjé tó pọ̀ gan-an nínú. Ìròyìn náà sọ pé: “Kódà jíjẹ òjé tín-ń-tín lè fa ìṣòro ìlera tó léwu nínú ìdàgbàsókè ọpọlọ àti ìhùwàsí àwọn ọmọ ọwọ́ àtàwọn tó ti dàgbà díẹ̀.” Òótọ́ ni pé kò rọrùn láti mọ bí òjé inú nǹkan kan ṣe pọ̀ tó láìsí àyẹ̀wò. Nítorí náà, pẹ̀lú bí iye tí wọ́n ń ta àwọn ohun ọ̀ṣọ́ ọmọdé kì í ti í sábàá wọ́n, ìwé ìròyìn National Post dámọ̀ràn pé ó lè jẹ́ ohun tó máa bọ́gbọ́n mu jù lọ láti ṣe ni pé: “Tóo bá ń ṣiyèméjì, sọ ọ́ nù.”

Ibùgbé Àdánidá Wọn Gan-an—Nibi Ààbò Wọn

Ìwé ìròyìn Times of Zambia sọ pé: “Ṣíṣàìjẹ́ kí ibùgbé àdánidá àwọn ẹran ìgbẹ́ parun [ni] ohun náà gan-an tó lè dáàbò bò wọ́n.” Ìròyìn náà sọ pé olórí ohun tó ń fa bí iye àwọn ẹranko inú igbó ṣe ń dín kù ni pípa ibùgbé àdánidá wọn run. Lára àwọn ohun tó ń fa ìṣòro ọ̀hún ni “jíjẹ́ kí àwọn ẹran máa jẹ koríko àgbègbè kan lájẹjù, iná, ìṣànlọ erùpẹ̀ [àti] oko dídá.” Àpilẹ̀kọ náà sọ pé: “Òtítọ́ pọ́ńbélé ni pé iṣẹ́ àgbẹ̀ ṣe pàtàkì kò sì sí ọgbọ́n táa lè dá sí i ká má ṣe é.” Àmọ́ láwọn àgbègbè tí iṣẹ́ àgbẹ̀ “kò bá ti fi bẹ́ẹ̀ ṣàǹfààní nítorí ilẹ̀ tó ti ṣá,” wọ́n lè fi silẹ̀ kó di ibùgbé àdánidá fún àwọn ẹranko lohun tí ìwé ìròyìn Times sọ. Tí wọ́n bá kó àwọn ẹran agbéléjẹ̀ wá sáwọn àdúgbò yìí, wọn kì í lè fara da àwọn kòkòrò tó máa ń so mọ́ wọn lára bí eégbọn àtàwọn míì, àmọ́ “ó ní ọ̀nà táwọn ẹranko ìgbẹ́ fi máa ń kojú irú àwọn kòkòrò bẹ́ẹ̀,” bíi kí wọ́n máa yí ara mọ́ ẹrẹ̀, kí wọ́n máa yí gbirigbiri nínú eruku tàbí kí àwọn ẹyẹ máa bá wọn ṣà á jẹ.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jagun Mólú Nílé Ẹjọ́ ní Rọ́ṣíà

Ìwé ìròyìn The New York Times ti February 24, 2001, ròyìn pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jàre ẹjọ́ kan lónìí [February 23] ní ilé ẹjọ́ kan ní Moscow tó jọ pé òun ni ìṣẹ́gun rẹ̀ tíì rinlẹ̀ jù lọ, èyí táwọn kan tó ń fẹ́ kí wọ́n fòfin de ẹgbẹ́ náà pè lábẹ́ òfin ọdún 1997 tó ka àwọn ẹ̀ya ìsìn táwọn èèyàn kórìíra tàbí tí wọ́n kò fara mọ́ léèwọ̀.” Wọ́n ti kọ́kọ́ gbé ìgbẹ́jọ́ ọ̀hún tì ní March 12, 1999, tí wọ́n sì yan àwọn ògbóǹkangí márùn-ún láti ṣàyẹ̀wò ohun táwọn Ẹlẹ́rìí gbà gbọ́. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún méjì tí wọ́n fi pa ẹjọ́ ọ̀hún tì láìṣe nǹkan kan sí i. Lẹ́yìn tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ padà ní February 6, 2001, kò gba ilé ẹjọ́ náà tó ọ̀sẹ̀ mẹ́ta tó fi rí i pé ẹ̀sùn táwọn olùpẹ̀jọ́ náà fi kàn wọ́n kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ rárá. Ṣùgbọ́n, ńṣe làwọn tó pe ẹjọ́ náà ní kí Ilé Ẹjọ́ Moscow pàṣẹ pé kí wọ́n tún ẹjọ́ náà gbọ́. Wọ́n gbà á wọlé ní May 30, wọ́n sì dá ẹjọ́ náà padà sí ilé ẹjọ́ tó kọ́kọ́ gbọ́ ọ pé kó tún un gbọ́. Ìwé ìròyìn Los Angeles Times sọ pé: “Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Rọ́ṣíà tó kórìíra iṣẹ́ míṣọ́nnárì bíi nǹkan míì jẹ́ ògúnnágbòǹgbò lára àwọn tó tapo síná òfin ọdún 1997 nípa ìsìn, èyí tó fi tipátipá mú àwọn ẹ̀sìn lọ máa ṣe ìforúkọsílẹ̀ tí kò rọrùn fún wọn.”

Jíjèrè Látinú Aṣọ Táwọn Èèyàn Fi Tọrẹ

Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Jámánì náà Südwest Presse sọ pé: “Ìwọ̀nba díẹ̀ péré” lára aṣọ táwọn èèyàn fi ń tọrẹ fáwọn aláìní ló ń tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́. Nílẹ̀ Jámánì lọ́dọọdún, ó lé ní ìdajì mílíọ̀nù tọ́ọ̀nù aṣọ táwọn èèyàn fi ń tọrẹ láti ran àwọn aláìní lọ́wọ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, títà làwọn àjọ tó ń gba àwọn aṣọ náà jọ máa ń tà wọ́n fún àwọn tó ń ṣòwò, èyí tó ti wá mú kí òwò títa àwọn aṣọ tí wọ́n fi tọrẹ di òwò tó ń mú ọgọ́rọ̀ọ̀rún mílíọ̀nù owó ilẹ̀ Jámánì wọlé. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn àjọ tó ń gba àwọn aṣọ táwọn èèyàn fi tọrẹ náà jọ kì í mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn aṣọ náà. Àpilẹ̀kọ náà sọ pé: “Tóo bá fẹ́ kó dá ọ lójú pé lóòótọ́ làwọn aṣọ rẹ ń ṣe àwọn akúùṣẹ́ láǹfààní, a jẹ́ pé fúnra rẹ ni wàá máa kó o fún àwọn aláìní náà tàbí kóo fi wọ́n ránṣẹ́ sáwọn èèyàn tóo fọkàn tán láwọn àgbègbè tí wàhálà wà náà.”

Ìdí Táwọn Ọmọdé Kò Fi Mọ Bí Wọ́n Ṣe Ń Bá Èèyàn Sọ̀rọ̀

Níbàámu pẹ̀lú ohun tí ìwé ìròyìn Berliner Morgenpost sọ, àwòjù tẹlifíṣọ̀n àti lílo kọ̀ǹpútà lálòjù ni ẹni tó ń ṣojú fún ẹgbẹ́ àwọn dókítà ọmọ wẹ́wẹ́ ní Berlin di ẹ̀bi ìṣòro àwọn ọmọdé tí kò mọ bí wọ́n ṣe ń bá èèyàn sọ̀rọ̀ rù. Ó ní àwọn ọmọ náà, pàápàá àwọn tí kò tíì bẹ̀rẹ̀ iléèwé gbọ́dọ̀ dín àkókò tí wọ́n fi ń wo tẹlifíṣọ̀n kù tàbí tí wọ́n fi ń jókòó ti kọ̀ǹpútà kí wọ́n sì túbọ̀ máa lo àkókò sí i ní bíbá àwọn èèyàn tí wọ́n lè fojú rí sọ̀rọ̀ káwọn èèyàn náà sì máa ta ọpọlọ wọn jí. Láfikún sí i, ìwé ìròyìn The Sunday Times ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ pé ìwádìí tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe fi hàn pé “àwọn èèyàn tí iye wọn túbọ̀ ń pọ̀ sí i láti ọmọ ogún ọdún sókè àti ọmọ ọgbọ̀n ọdún sókè ni gbígbàgbé nǹkan lọ́nà tó burú jáì ń yọ lẹ́nu” tó sì tún jẹ́ pé wọ́n kì í mọ “bí wọ́n ṣe lè fìyàtọ̀ sáàárín àwọn ohun tó ṣe pàtàkì àtohun tí kò ṣe pàtàkì” nítorí ńṣe ni wọ́n “túbọ̀ ń gbára lé kọ̀ǹpútà.”

Àwọn Èdè Tó Ń Pòórá

Ìwé ìròyìn Folha de S. Paulo ti ilẹ̀ Brazil sọ nípa ètò kan tí orílẹ̀-èdè Brazil àti Jámánì pawọ́ pọ̀ gùn lé láti ní àwọn èdè ilẹ̀ Brazil tí ìbẹ̀rù wà pé wọ́n ti fẹ́ pòórá lákọọ́lẹ̀. Àwọn olùwádìí ní i lọ́kàn láti dáàbò bo àwọn èdè bíi Trumai, Aweti, àti Cuicuro nípa wíwá ọ̀nà tí wọ́n lè gbà fi àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ìró rẹ̀ pa mọ́ sínú kọ̀ǹpútà. Gẹ́gẹ́ bí Aryon Rodrigues tó jẹ́ onímọ̀ èdè ṣe sọ, kìkì ọgọ́sàn-án nínú ẹgbẹ̀fà èdè tí wọ́n ń sọ látayébáyé ní Brazil ló ṣẹ́ kù báyìí. Ó kéré tán, àádọ́ta lára àwọn èdè yìí ló jẹ́ pé àwọn tó ń sọ wọ́n kò pé ọgọ́rùn-ún. Èdè kan wà tó ń jẹ́ Makú, tó jẹ́ pé kìkì ẹnì kan ṣoṣo tó ń sọ ọ́ ni opó ẹni àádọ́rin ọdún kan tó ń gbé àríwá Brazil. Rodrigues sọ pé ṣíṣàìjẹ́ kí àwọn èdè àdúgbò parun ni pàtàkì ohun tí kò ní jẹ́ kí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àwọn èèyàn dàwátì.

Pípalẹ̀ Pàǹtí Mọ́ ní Mẹ́síkò Dìṣòro

Ìròyìn kan tó fara hàn láìpẹ́ yìí nínú ìwé ìròyìn El Universal ti Ìlú Mẹ́síkò sọ pé ìpín ọgbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún pàǹtí Ìlú Mẹ́síkò ló fi ojú títí ṣelé tó sì jẹ́ pé ewu ni ìdọ̀tí yìí máa fà tó bá yá. Aarón Mastache Mondragón tó jẹ́ akọ̀wé nípa àyíká sọ pé, kìkì ìpín mẹ́wàá péré nínú ọgọ́rùn-ún pàǹtí tó wà ní Ìlú Mẹ́síkò ni wọ́n ń yí padà sí ohun mìíràn tí nǹkan kan kì í sì í ṣẹlẹ̀ sí ìpín méjìdínláàádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún. Táa bá gbé e karí ìṣirò tó wá láti Iléeṣẹ́ Ìjọba Tó Ń Rí sí Yíyí Pàǹtí Padà sí Nǹkan Míì, ó ń gbà tó oṣù kan kí káàdì ìrajà pélébé tó lè jẹrà; ọparun á gbà tó oṣù kan sí mẹ́ta; aṣọ ìnura á gba oṣù kan sí márùn-ún; ìbọ̀sẹ̀ olówùú á gba ọdún kan; igi tí wọ́n ti kùn lọ́dà á gba ọdún kan; agolo, ọdún mẹ́jọ àtoṣù mẹ́ta; agolo aláyọ́, igba ọdún sí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún; tí ìgò á sì gbà ju mílíọ̀nù kan ọdún lọ.