Ìlú Kan ní Áfíríkà Níbi Tí Àṣà Ìlà Oòrùn àti Ìwọ̀ Oòrùn Ayé Ti Wọnú Ara Wọn
Ìlú Kan ní Áfíríkà Níbi Tí Àṣà Ìlà Oòrùn àti Ìwọ̀ Oòrùn Ayé Ti Wọnú Ara Wọn
LÁTỌWỌ́ ÒǸKỌ̀WÉ JÍ! NÍ GÚÚSÙ ÁFÍRÍKÀ
O HUN tóo máa rí bóo bá ń gba ojú pópó ìlú Durban kọjá mà jojú ní gbèsè o! Wàá rí i pé ọ̀pọ̀ ló ti bẹ̀rẹ̀ sí wọṣọ bíi tàwọn ará Ìwọ̀ Oòrùn ayé, àgàgà àwọn èwe. Àmọ́ tún kíyè sáwọn àgbà obìnrin Zulu tí wọ́n wọ aṣọ gígùn tó wuyì pẹ̀lú gèlè aláràbarà tí wọ́n wé sórí. Àwọn obìnrin Íńdíà náà wà níbẹ̀ tí wọ́n wọṣọ sari tàbí aṣọ àwọn Punjabi tó ní ṣòkòtò. Bóo ti ń sún mọ́ etíkun, ó ṣeé ṣe kóo rí àwọn ọkùnrin Zulu tí wọ́n wọ aṣọ gbàgìẹ̀ tí wọ́n sì ń ti kẹ̀kẹ́. Ká sòótọ́, ìlú kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ní Áfíríkà, níbi tí àṣà Ìlà Oòrùn àti Ìwọ̀ Oòrùn ayé ti wọnú ara wọn ni ìlú Durban. Kí ni ìtàn ìlú tó fani lọ́kàn mọ́ra yìí?
Kò tíì tó ọ̀rúndún méjì táwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìlú Durban tó wà ní Gúúsù Áfíríkà. Àwọn ọmọ ilẹ̀ Yúróòpù bí ogójì tẹ̀dó síbẹ̀ lọ́dún 1824. Nígbà yẹn, ìhà àríwá ìlú Durban ni ìjọba àwọn Zulu àti ọba wọn, Shaka, tó tún jẹ́ jagunjagun fìdí kalẹ̀ sí. Ogún ọdún lẹ́yìn náà, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì gba ìlú Durban àtàwọn ìlú mìíràn lágbègbè rẹ̀. Onírúurú ogun ló wáyé ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún láàárín àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ tẹ̀dó náà àtàwọn Zulu.
Láàárín àkókò náà, àwọn ará ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó wá tẹ̀dó síbẹ̀ rí i pé ìrèké máa ń hù dáadáa láwọn àgbègbè etíkun. Kí iṣẹ́ ọ̀gbìn ìrèké wọn lè máa lọ dáadáa, wọ́n ṣètò pé káwọn alágbàṣe máa wá láti Íńdíà tóun náà wà lábẹ́ àkóso ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nígbà náà. Láàárín ọdún 1860 sí 1911, iye tó lé ní ẹgbàá márùndínlọ́gọ́rin àwọn ará Íńdíà ló dé sí Durban. Ohun tó fà á rèé tí iye èèyàn tó wà ní ìlú Durban àti àgbègbè rẹ̀ fi lé ní mílíọ̀nù mẹ́ta, àgbègbè mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n sì ti ṣẹ̀ wá—àwọn ojúlówó Zulu, àwọn ará Éṣíà tí wọ́n wá láti Íńdíà, àtàwọn èèyàn ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì pẹ̀lú àwọn èèyàn tó wá láti ìhà ìwọ̀ oòrùn Yúróòpù.
Àwọn ohun tó ń fani mọ́ra mìíràn tún wà nílùú náà. Gẹ́gẹ́ bóo ṣe lè rí i nínú fọ́tò tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí, ìlú náà ní èbúté ọkọ̀ òkun tó wà látayébáyé tí òkìtì gígùn kan sì pààlà sáàárín rẹ̀ àti
Òkun Íńdíà. Òkìtì tó ń fani mọ́ra yìí ga ju àádọ́rùn-ún mítà lọ, koríko sì hù sórí rẹ̀. Ojoojúmọ́ làwọn ọkọ̀ òkun ràgàjì-ràgàjì máa ń forí lé èbúté yìí. Ìwé Discovery Guide to Southern Africa ṣàlàyé pé, ìlú Durban ló ní “èbúté ọkọ̀ òkun tó tóbi jù tó sì kún jù ní gbogbo Áfíríkà, òun ló wà ní ipò kẹsàn-án lágbàáyé.” Àwọn tó ń lọ fún ìsinmi máa ń fẹ́ lọ sáwọn etíkun ìlú Durban kí wọ́n sì gbádùn omi rẹ̀ tó ń lọ́ wọ́ọ́wọ́. Àwọn ibi tó dára wà téèyàn ti lè fi pátákó sáré lórí omi, ọkàn àwọn tó ń lúwẹ̀ẹ́ sì balẹ̀ nítorí àwọ̀n tí wọ́n fi dáàbò bò wọ́n kúrò lọ́wọ́ ẹja ekurá.Ìdí mìíràn tún wà táwọn tó nífẹ̀ẹ́ nínú Bíbélì fi fẹ́ràn ìlú náà. Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí nígbà yẹn kọ́ ọ́fíìsì ẹ̀ka síbẹ̀ lọ́dún 1910. Nígbà tó di oṣù April 1914, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe àpéjọpọ̀ àgbègbè wọn àkọ́kọ́ ní Áfíríkà ní Durban. Nǹkan bí àádọ́ta èèyàn ló pésẹ̀ síbẹ̀, àwọn tó wá láti ibi tó jìnnà ní Gúúsù Áfíríkà sì wà lára wọn. Ní àpéjọpọ̀ àgbègbè mánigbàgbé náà, àwọn mẹ́rìndínlógún tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ di olùjọ́sìn ló ṣèrìbọmi. Iye tó pọ̀ lára àwọn tó wà níbẹ̀ ló jẹ́ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n ṣe olóòótọ́ títí wọ́n fi kú, lára wọn ni William W. Johnston, tó jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láti bójú tó ọ́fíìsì ẹ̀ka kan ní Áfíríkà.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣètò ọ̀pọ̀ àpéjọpọ̀ àgbègbè mìíràn ní ìlú Durban láti ọdún 1914 wá. Ní December 2000, nǹkan bí ẹgbàá méje, òjìlélẹ́gbẹ̀rin àti mẹ́jọ [14,848] ló pésẹ̀ sí àpéjọpọ̀ àgbègbè “Àwọn Olùṣe Ohun Tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Wí” méjì tí wọ́n ṣe ní ìlú náà, àwọn ẹni tuntun tó jẹ́ àádọ́rin lé rúgba àti mẹ́jọ [278] ló ṣèrìbọmi. Gbé ìdílé kan lára ọ̀pọ̀ àwọn ará Íńdíà tó pésẹ̀ síbẹ̀ yẹ̀ wò. Ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn, ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Somashini sọ òtítọ́ Bíbélì fún bàbá rẹ̀ tó ń jẹ́ Alan. Alan ṣẹ̀ṣẹ̀ ń fi ọtí àmupara sílẹ̀ ni, ó sì ń wá bó ṣe máa mọ ète ìgbésí ayé. Somashini, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ta péré nígbà náà mú ìwé kan tó rí nílé aládùúgbò wọn kan wá fún bàbá rẹ̀. Àkọlé ìwé náà, True Peace and Security—How Can You Find It?, fa Alan mọ́ra lójú ẹsẹ̀. Ó fẹ́ràn ohun tó kà ó sì bẹ̀rẹ̀ sí dara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nítorí nǹkan tó ti kọ́ nínú Bíbélì, Alan lọ forúkọ ìgbéyàwó rẹ̀ sílẹ̀ lábẹ́ òfin. Láìpẹ́, ìyàwó rẹ̀ Rani, náà fìfẹ́ hàn ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí ìpàdé pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lákòókò náà, ọ̀dọ̀ àwọn òbí Rani tí wọ́n ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì Kirisẹ́ńdọ̀mù ni tọkọtaya náà ń gbé. Àwọn òbí náà fárígá pé tọkọtaya náà gbọ́dọ̀ jáwọ́ nídìí ìsìn tuntun tí wọ́n ń ṣe, wọ́n sì sọ fún wọn pé: “Nínú kí ẹ má ṣe Ajẹ́rìí mọ́ tàbí kẹ́ẹ jáde kúrò nílé wa, ẹ mú kan!”
Alan àti Rani sọ pé àwọn máa jáde bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣòro gan-an láti rílé. Àwọn ọ̀rẹ́ wọn tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá wọn wá ilé tó dára láti máa gbé. Ní 1992, Alan àti Rani di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà tí wọ́n ṣe ìrìbọmi. Wọn bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀ síwájú, lónìí, Alan ń sìn bí alàgbà nínú ìjọ Kristẹni.
Ó lé ní àádọ́ta ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ìlú Durban àti àgbègbè rẹ̀. Àwọn Zulu ló pọ̀ jù nínú wọn. Àmọ́ ṣá o, àwọn ìjọ kan wà tó ní àwọn èèyàn tó jẹ́ Zulu, Íńdíà, àtàwọn tó wá láti ilẹ̀ Yúróòpù, àgàgà àwọn ìjọ tó sún mọ́ àárín gbùngbùn ìlú náà. Tóo bá ṣèbẹ̀wò sí ọ̀kan lára àwọn ìpàdé wọ̀nyí, wàá rí pé tiwọ́n kọjá kìkì pé àṣà Ìlà Oòrùn wọnú ara pẹ̀lú ti Ìwọ̀ Oòrùn ayé. Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kóo rí i kí Ẹlẹ́rìí ọmọ Áfíríkà kan tó rú sáṣọ máa darí ìpàdé, ó sì lè jẹ́ Ẹlẹ́rìí ará Íńdíà tàbí Ẹlẹ́rìí tó wá láti Yúróòpù. Àmọ́ ohun kan dájú: Wàá fi ojú rẹ kòrókòró rí ẹ̀rí pé Bíbélì ní agbára láti so àwọn ènìyàn láti onírúurú orílẹ̀-èdè pa pọ̀ kí wọ́n sì jẹ́ ọ̀rẹ́ títí ayé.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Alan, Rani, àtàwọn ọmọ wọn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Àwọn ìpàdé ìjọ máa ń so gbogbo èèyàn onírúurú ẹ̀yà pa pọ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Gbọ̀ngàn ìlú Durban
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 21]
Àwọn fọ́tò: Pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Gonsul Pillay