A Kí I Yín Káàbọ̀ sí Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Olùkọ́ni Ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run”!
A Kí I Yín Káàbọ̀ sí Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Olùkọ́ni Ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run”!
ÀRÀÁDỌ́TA Ọ̀KẸ́ ÈNÌYÀN LÓ MÁA LỌ ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ibi táa ti máa ṣe é kárí ayé. Ní Nàìjíríà nìkan, àpéjọpọ̀ àgbègbè mẹ́rìndínlógóje [136] la ṣètò. Àkọ́kọ́ máa wáyé ní October 12 sí 14, 2001 èyí tó sì gbẹ̀yìn á jẹ́ ní January 18 sí 20, 2002. Ó ṣeé ṣe kí ọ̀kan lára àwọn àpéjọpọ̀ ọlọ́jọ́ mẹ́ta yìí, Friday sí Sunday, wáyé ní ìlú tí kò jìnnà síbi tóò ń gbé.
Ní ibi tó pọ̀ jù lọ, wọ́n máa bẹ̀rẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ní aago mẹ́sàn-án ààbọ̀ òwúrọ̀ lójoojúmọ́. Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ ìkíni káàbọ̀ ní ọjọ́ Friday la máa gbọ́ àwọn àsọyé táa gbé àkòrí wọn karí Bíbélì, “Kíkọ́ Àwọn Ẹlòmíràn Nípa Ìjọba Náà Ń Mú Èso Rere Jáde,” “‘Àwọn Ohun Ọlá Ńlá Ọlọ́run’ Ń Ru Wá Sókè Láti Ṣe Rere,’” àti “Ní Inú Dídùn Nínú Òdodo Jèhófà.” Lájorí àsọyé la máa fi parí ìtòlẹ́sẹẹsẹ òwúrọ̀, àkọlé rẹ̀ ni, “A Ti Mú Wa Gbára Dì fún Iṣẹ́ Olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.”
Lẹ́yìn àsọyé àkọ́kọ́ lọ́sàn-án táa pe àkọlé rẹ̀ ní “A Wẹ̀ Wá Mọ́ Láti Jẹ́ Èèyàn fún Iṣẹ́ Rere,” ló máa kan àpínsọ àsọyé alápá mẹ́ta tó ní àkọlé náà “Báa Ti Ń Kọ́ Àwọn Ẹlòmíràn, Ẹ Jẹ́ Ká Máa Kọ́ Ara Wa.” Ó máa sọ fún wa bó ti ṣe pàtàkì tó kéèyàn máa fi ohun tó ń wàásù ṣèwà hù èyí tó kan ìwà rere, ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àti bó ti ṣe kókó láti gbéjà ko ìsapá Èṣù láti ṣì wá lọ́nà. Àsọyé náà “Ẹ Kórìíra Àwọn Ohun Arùfẹ́-Ìṣekúṣe-Sókè Tó Ti Di Àjàkálẹ̀ Àrùn Nínú Ayé” á sì tẹ̀ lé e. Ìjíròrò ìwé Aísáyà orí 60 ló máa kásẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ náà nílẹ̀, àkọlé rẹ̀ ni “Jèhófà Fi Ìmọ́lẹ̀ Bu Ẹwà Kún Àwọn Èèyàn Rẹ̀.”
Ní ọjọ́ Saturday, àwọn àsọyé wọ̀nyí “Rírí Ìtura Lábẹ́ Àjàgà Kristi,” “Fara Wé Olùkọ́ Ńlá Náà,” àti “Ṣé O Múra Tán Láti Sin Àwọn Ẹlòmíràn?” máa ṣàlàyé ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi. Lọ́jọ́ Saturday kan náà, àwọn àpínsọ àsọyé oníwákàtí méjì gbáko yóò wà, àkọlé rẹ̀ ni “Àwọn Òjíṣẹ́ Táwọn Ẹlòmíràn Ń Tipasẹ̀ Wọn Di Onígbàgbọ́” àti “Jàǹfààní Ní Kíkún Látinú Ẹ̀kọ́ Tí Ọlọ́run Ń Kọ́ni.” Àpínsọ àsọyé ti òwúrọ̀ yóò fún wa láwọn àbá nípa sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn, nígbà tí àsọyé tọ̀sán yóò sọ̀rọ̀ lórí àwọn ọ̀nà táa fi lè túbọ̀ jàǹfààní látinú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti lílọ sáwọn ìpàdé Kristẹni. Ọ̀rọ̀ ìrìbọmi ló máa mú ìtòlẹ́sẹẹsẹ òwúrọ̀ wá sópin, lẹ́yìn náà làwọn tó bá tóótun á láǹfààní láti ṣe ìrìbọmi. Ọ̀pọ̀ yóò máa fojú sọ́nà láti gbọ́ àsọyé tó máa parí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọ̀sán Saturday, àkòrí rẹ̀ ni “Àwọn Ìpèsè Tuntun Tí Yóò Mú Wa Tẹ̀ Síwájú Nípa Tẹ̀mí.”
Àpínsọ àsọyé alápá mẹ́ta tó ṣàlàyé ìwé Málákì tó sì tún sọ bó ṣe bá àkókò táa wà yìí mu wà lára ìtòlẹ́sẹẹsẹ òwúrọ̀ Sunday. Lẹ́yìn èyí ni àá wá wo àwòkẹ́kọ̀ọ́ ìgbàanì tó dá lórí ìwà ọ̀tẹ̀ tí Kórà, Dátánì, àti Ábírámù hù sí àṣẹ tí Ọlọ́run fún Mósè. Àsọyé kan á wá tẹ̀ lé e tó máa sọ àwọn kókó tó wà nínú àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọ̀sán á ní àsọyé fún gbogbo èèyàn tó ní àkọlé náà, “Àwọn Wo Ló Ń Fi Òtítọ́ Kọ́ Gbogbo Orílẹ̀-Èdè?”
Ó dájú pé ipò tẹ̀mí rẹ á túbọ̀ dára sí i tóo bá wà níbẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà. Bóo bá fẹ́ mọ ibi àpéjọpọ̀ yìí tó sún mọ́ ọ jù lọ, kàn sí Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ tàbí kóo kọ̀wé sáwọn tó ṣe ìwé ìròyìn yìí jáde. Àdírẹ́sì gbogbo ibi tí a óò ti ṣe àpéjọpọ̀ yìí ní Nàìjíríà la tò sínú Ilé Ìṣọ́ May 1, 2001.