Báwo Ni Mo Ṣe Lè Dẹ́kun Dídààmú Kọjá Ààlà?
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Báwo Ni Mo Ṣe Lè Dẹ́kun Dídààmú Kọjá Ààlà?
“Lára ohun tó lè kó ìdààmú bá ọ̀dọ́ kan jù lọ ni àníyàn nípa ọjọ́ ọ̀la. Wàá bẹ̀rẹ̀ sí ṣàníyàn nípa ara rẹ. Ṣé kí n filé sílẹ̀ ni? Àbí kí n lọ síléèwé? Ṣé kí n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ni? Àbí kí n lọ ṣègbéyàwó? Ilẹ̀ á wá kún rẹ́kẹrẹ̀kẹ fún ohun púpọ̀ láti yàn, débi pé ẹ̀rù á tiẹ̀ máa bà ẹ́.”—Shane, ọmọ ogún ọdún.
ṢÉ O máa ń dààmú púpọ̀? Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló ń ṣe bẹ́ẹ̀, oríṣiríṣi nǹkan ló sì ń fà á. Ìròyìn kan tí wọ́n tẹ̀ jáde láti tọ́ àwọn òbí sọ́nà sọ pé: “Ìwádìí tí wọ́n ṣe jákèjádò ayé nípa àwọn ọ̀dọ́langba tọ́jọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí méjìdínlógún ní orílẹ̀-èdè mọ́kànlélógójì, fi hàn pé bí àwọn ọ̀dọ́langba òde òní ṣe máa rí iṣẹ́ tó dára ṣe lolórí àníyàn wọn.” Èyí tó tẹ̀ lé e ni dídààmú nípa ìlera àwọn òbí wọn. Bákan náà ni ìbẹ̀rù pé kéèyàn wọn kan má lọ kú kò gbẹ́yìn nínú ohun tí wọ́n sọ.
Ìwádìí tí Ẹ̀ka Ètò Ẹ̀kọ́ kan ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ṣe fi hàn pé ìṣòro gidi ni “ìrònú gbígba máàkì púpọ̀” jẹ́ fún àwọn ọ̀dọ́ lórílẹ̀-èdè ọ̀hún. Ìwádìí kan náà tún fi hàn pé ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ lọ̀rọ̀ wọn ò yàtọ̀ sí ti Shane (táa fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ níbẹ̀rẹ̀). Ọ̀dọ́ mìíràn tó ń jẹ́ Ashley sọ pé: “Ọkàn mi ò balẹ̀ lórí bí ọjọ́ iwájú mi ṣe máa rí.”
Síbẹ̀, ohun tó ń kó ìdààmú ọkàn bá àwọn ọ̀dọ́ mìíràn ni àìsí ààbò. Níbàámu pẹ̀lú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní 1996, nǹkan bí ìdajì lára àwọn ọ̀dọ́ ilẹ̀ Amẹ́ríkà ló gbà pé ńṣe ni ìwà ipá ilé ẹ̀kọ́ wọn túbọ̀ ń gogò sí i. Ó lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ (ìpín mẹ́tàdínlógójì nínú ọgọ́rùn-ún) àwọn ọ̀dọ́langba tó sọ pé àwọn mọ ẹnì kan tí ọta ìbọn ti bà rí!
Síbẹ̀, kì í ṣe gbogbo ìdààmú ló ń kó ìjayà báni bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló jẹ́ pé olórí ìṣòro wọn kò ju bí wọ́n ṣe máa bẹ́gbẹ́ mu lọ. Ìròyìn orí kọ̀ǹpútà kan tí wọ́n darí rẹ̀ sáwọn òbí sọ pé: “Àwọn ọ̀dọ́langba máa ń ṣàníyàn nípa níní ọ̀rẹ́kùnrin tàbí níní ọ̀rẹ́bìnrin, àmọ́ èyí tó jẹ́ olórí àníyàn wọn ni àìní ọ̀rẹ́ rárá.” Ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó ń jẹ́ Meagan dárò pé: “Báwo lèèyàn ṣe lè wàpa kó sì bẹ́gbẹ́ mu ná? Mo fẹ́ láwọn ọ̀rẹ́ o.” Ohun kan náà ló wà lọ́kàn Natanael ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tó jẹ́ Kristẹni nígbà tó sọ pé: “Àwọn ọmọ iléèwé máa ń ṣàníyàn nípa ìmúra wọn. Wọ́n máa ń ṣàníyàn nípa bí wọ́n ṣe ń rìn, bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀, àti bí wọ́n ṣe rí lójú àwọn ẹlòmíràn. Ẹ̀rù máa ń bà wọ́n pé kí wọ́n má lọ pè wọ́n ní sùẹ̀gbẹ̀.”
Ìṣòro Jẹ́ Apá Kan Ìgbésí Ayé
Ì bá dára gan-an ni ká ní èèyàn kì í ní ìṣòro rárá. Ṣùgbọ́n ohun tí Bíbélì sọ ni pé: “Ènìyàn, tí obìnrin bí, ọlọ́jọ́ kúkúrú ni, ó sì kún fún ṣìbáṣìbo.” (Jóòbù 14:1) Ìdí nìyẹn tí ìṣòro àtàwọn wàhálà tó ń bá a rìn fi jẹ́ apá kan ìgbésí ayé wa. Àmọ́ tóo bá jẹ́ kí ìdààmú àti àníyàn máa ṣàkóso ìrònú rẹ, o lè ṣera rẹ léṣe. Bíbélì kìlọ̀ pé: “Àníyàn ṣíṣe nínú ọkàn-àyà ènìyàn ni yóò mú un tẹ̀ ba.”—Òwe 12:25.
Ọ̀nà kan tóo fi lè yàgò fún wíwulẹ̀ máa ṣàníyàn láìnídìí ni pé kóo ṣọ́ bóo ṣe ń hùwà. Ana tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ kíláàsì mi lẹ̀rù máa ń bà pé káwọn má lọ lóyún tàbí kó àrùn tí ìbálòpọ̀ ń fà.” Ṣùgbọ́n irú àwọn ìdààmú ọkàn bẹ́ẹ̀ kò ní kàn ọ́ tóo bá ń pa àwọn ìlànà ìwà rere inú Bíbélì mọ́. (Gálátíà 6:7) Síbẹ̀, kì í ṣe gbogbo ìṣòro rẹ ló máa hàn kedere tàbí ṣeé yanjú lọ́wọ́ kan bẹ́ẹ̀ yẹn. Báwo wá lo ṣe lè fòpin sí dídààmú kọjá bó ṣe yẹ?
“Fọgbọ́n Ṣe É”
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń jẹ́ kí ìdààmú ọkàn sọ wọ́n di nǹkan míì. Àmọ́ àpilẹ̀kọ kan tó jáde nínú ìwé ìròyìn àwọn ọ̀dọ́langba kan dámọ̀ràn pé èèyàn lè “fọgbọ́n ṣe é” nípa wíwá nǹkan gidi ṣe sí ìdààmú náà! Bíbélì ní ọ̀pọ̀ ìlànà tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Gbé Òwe 21:5 yẹ̀ wò tó sọ pé: “Dájúdájú, àwọn ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní.” Fún àpẹẹrẹ, ká sọ pé o fẹ́ gbàlejò àwọn ọ̀rẹ́ díẹ̀ látinú ìjọ. Tóo bá wéwèé rẹ̀ dáadáa, o ò ní fi bẹ́ẹ̀ dààmú. Béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé, ‘Àwọn wo gan-an ni màá fẹ́ láti pè? Ìgbà wo ni màá fẹ́ kí wọ́n dé? Ìgbà wo ni màá fẹ́ kí wọ́n lọ? Báwo ni màá ṣe fẹ́ kí nǹkan àlejò wọn pọ̀ tó? Àwọn nǹkan wo ni mo lè fi dá wọn lára yá tí gbogbo wọn á sì gbádùn rẹ̀?’ Bóo bá ṣe gbé àwọn nǹkan yẹ̀ wò dáadáa tó ni àpèjẹ rẹ máa fi yọrí sí rere tó.
Àmọ́ o lè fọwọ́ ara rẹ fa wàhálà nípa fífẹ ohun tóo fẹ́ ṣe lójú. Jésù Kristi fún obìnrin kan tó lọ kóra ẹ̀ sí wàhálà kọjá bó ṣe yẹ nígbà tó ń ṣètọ́jú àlejò rẹ̀ ní ìmọ̀ràn yìí pé: “Nǹkan díẹ̀ tàbí ẹyọ kan ṣoṣo ni a nílò.” (Lúùkù 10:42) Torí náà, bi ara rẹ léèrè pé, ‘Kí ni nǹkan náà gan-an tó ṣe pàtàkì láti mú kí àpèjọ yìí yọrí sí rere?’ Ṣíṣe é níwọ̀ntúnwọ̀nsì lè ṣèrànwọ́ láti dín àníyàn rẹ kù.
Nǹkan mìíràn tó tún lè máa kó ẹ sí ìṣòro ni bóo ṣe lè ní ààbò níléèwé. Ó lè má fi bẹ́ẹ̀ sí ohun tóo lè ṣe láti yí ipò nǹkan padà níbẹ̀. Ṣùgbọ́n, o lè gbé àwọn ìgbésẹ̀ tó bọ́gbọ́n mu láti dáàbò bo ara rẹ. Òwe 22:3 sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́.” Yíyẹra fún gbogbo àgbègbè tó léwu—kì í ṣe kìkìdá àwọn ibi àdádó, àmọ́ títí kan àwọn àgbègbè téèyàn kì í fi bẹ́ẹ̀ sí, táwọn jàǹdùkú máa ń kóra jọ sí—ti tó láti dín ṣíṣe tí ó ṣeé ṣe kóo bá ara rẹ nínú ìjọ̀ngbọ̀n kù.
Iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tún lè jẹ́ nǹkan míì tó ń kó ìdààmú bá ọ. Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àṣetiléwá ṣíṣe pàtàkì lè wà nílẹ̀ jàńtìrẹrẹ fún ẹ láti ṣe tí ẹ̀rù sì ń bà ẹ́ pé o ò ní parí gbogbo wọn lásìkò. Ìlànà tó wà nínú Fílípì 1:10 wúlò, ó sọ pé: “Wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.” Bẹ́ẹ̀ ni, kọ́ béèyàn ṣe ń mọ ohun tó kọ́kọ́ yẹ ní ṣíṣe! Fojú wo èwo ló jẹ́ kánjúkánjú jù lọ, kóo sì kọ́kọ́ ṣèyẹn. Lẹ́yìn náà, bọ́ sórí òmíràn. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, wọn ò ní já ẹ láyà mọ́.
Béèrè fún Ìmọ̀ràn
Nígbà tí Aaron wà lọ́dọ̀ọ́, ìrònú bó ṣe máa yege ìdánwò àṣekágbá rẹ̀ níléèwé kó ìdààmú bá a gan-an débi pé àyà bẹ̀rẹ̀ sí í dùn ún. Ó sọ pé: “Mo sọ fún àwọn òbí mi nípa rẹ̀, wọ́n sì mú mi lọ sọ́dọ̀ dókítà. Kíá ló ti rí i pé kò sóhun tó ṣe ọkàn mi, ó sì ṣàlàyé nípa bí àníyàn ṣe lè ṣàkóbá fún ara èèyàn. Lẹ́yìn náà làwọn òbí mi wá jẹ́ kí n mọ̀ pé mo ti ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti gbára dì fún ìdánwò náà àti pé ará mi ló kù tí mo gbọ́dọ̀ mójú tó. Bí àníyàn mi ṣe fò lọ nìyẹn, àyà tó ń dùn mí wábi gbà, mo sì ṣe dáadáa nínú ìdánwò tí mo ṣe.”
Òwe 12:25, táa yọ lò lára rẹ̀ níṣàájú sọ lápapọ̀ pé: “Àníyàn ṣíṣe nínú ọkàn-àyà ènìyàn ni yóò mú un tẹ̀ ba, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere ní ń mú un yọ̀.” Àyàfi tóo bá sọ “àníyàn” rẹ jáde nìkan lo fi lè gbọ́ “ọ̀rọ̀ rere” tó máa fún ẹ níṣìírí!
Tí ìdààmú bá bá ọ, máà gbé e sọ́kàn o.Lákọ̀ọ́kọ́, o lè bá àwọn òbí rẹ jíròrò rẹ̀; ó ṣeé ṣe gan-an pé kí wọ́n ní àwọn ìmọ̀ràn díẹ̀ fún ẹ. Àwọn mìíràn tó tún lè fún ọ níṣìírí ni àwọn tó dàgbà dénú nípa tẹ̀mí nínú ìjọ Kristẹni tóo ń dara pọ̀ mọ́. Janelle tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sọ pé: “Ẹ̀rù àtilọ síléèwé gíga bà mí, gbogbo nǹkan tí màá dojú kọ níbẹ̀ sì ń dáyà já mi—bí oògùn líle, ìbálòpọ̀, àti ìwà ipá—àfìgbà tí mo tóó bá alàgbà kan nínú ìjọ sọ ọ́. Ó fún mi ní ọ̀pọ̀ ìmọ̀ràn tó ṣiṣẹ́. Kíá lara mi yá gágá nítorí mo wá rí i pé apá mi á ká ọ̀ràn náà.”
Má Máa Fònídónìí Fọ̀ladọ́la
Àwọn nǹkan kan wà tó yẹ ká ṣe nígbà míì, àmọ́ tí a kì í já kúnra nítorí pé kì í ṣe nǹkan tó gbádùn mọ́ wa láti ṣe. Fún àpẹẹrẹ, Shevone ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún ní gbólóhùn asọ̀ pẹ̀lú Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan. Ó mọ̀ pé ó yẹ kí òun bá ẹni náà jíròrò rẹ̀, àmọ́ bó ṣe ń fònídónìí ló ń fọ̀ladọ́la. Ó jẹ́wọ́ pé: “Bí mo ṣe ń gbé e tì, bẹ́ẹ̀ ló túbọ̀ ń kó ìdààmú bá mi.” Ni Shevone bá rántí ọ̀rọ̀ Jésù ní Mátíù 5:23, 24, èyí tó rọ àwọn Kristẹni láti yanjú irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀ ní wéré-wéré. Shevone sọ pé: “Ìgbà tí mo jàjà ṣe bẹ́ẹ̀ ni mo tó lálàáfíà.”
Ṣé ìwọ náà ní nǹkan kan tóò ń gbé tì, bóyá iṣẹ́ kan tó yẹ kóo ṣe àmọ́ tí kò rọrùn fún ẹ tàbí pé ó nira fún ọ láti kojú ẹnì kan? Tóò, rí i pé o mú un kúrò kíá, wàá sì rí i pé ohun tó ń kó ìdààmú bá ẹ á dín kan.
Àwọn Ìṣòro Lílekoko
Kì í ṣe gbogbo ìṣòro ló lè dùn ún yanjú bẹ́ẹ̀ yẹn. Wo ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó ń jẹ́ Abdur. Ìyá rẹ̀ ní àrùn jẹjẹrẹ, ó sì di dandan kó máa gbé bùkátà ìyá rẹ̀ àti ti àbúrò rẹ̀ ọkùnrin. Báa ṣe mọ̀, ipò tí màmá Abdur wà yìí kó ìdààmú bá a. Àmọ́ ó sọ pé: “Mo di kókó kan mú nínú ọ̀rọ̀ Jésù pé, ‘Ta ni nínú yín, nípa ṣíṣàníyàn, tí ó lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún ìwọ̀n gígùn ìwàláàyè rẹ̀?’ Dípò tí ǹ bá fi jẹ́ kí ìbànújẹ́ gbé mi mì, mo gbìyànjú láti ronú lórí ipò náà dáadáa kí n lè ṣe ìpinnu tó máa ṣàǹfààní jù lọ.”—Mátíù 6:27.
Kì í rọrùn láti fara balẹ̀ téèyàn bá bára ẹ̀ nínú ìṣòro lílekoko. Inú àwọn kan máa ń bà jẹ́ débi pé wọn ò ní bójú tó ara wọn mọ́, wọ́n á sì pa oúnjẹ tì. Àmọ́ ṣá, ìwé kan tó ń jẹ́ Helping Your Teenager Deal With Stress kìlọ̀ pé tóo bá kọ̀ láti fún ara rẹ láwọn èròjà pàtàkì tó lè ṣe é láǹfààní, ńṣe ló “máa túbọ̀ ṣòro fún ẹ láti kápá àwọn wàhálà tí másùnmáwo náà ti fà tí yóò sì túbọ̀ jẹ́ kó rọrùn fún àìsàn ńlá láti kọ lù ọ́.” Nítorí náà, bójú tó ara rẹ. Máa sinmi dáadáa kóo sì máa jẹ àwọn ohun tó máa ṣe ara rẹ lóore.
Ohun tó lè fún ọ ní ìtura tó dára jù lọ ni títẹ̀lé ìmọ̀ràn Bíbélì pé: “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró. Kì yóò jẹ́ kí olódodo ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n láé.” (Sáàmù 55:22) Shane táa fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ níbẹ̀rẹ̀ dààmú nípa ọjọ́ iwájú rẹ̀. Ó sọ pé: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí í túbọ̀ pọkàn pọ̀ sórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ète rẹ̀.” Kò pẹ́ tó fi rí i pé tí òun bá lo ìgbésí ayé òun fún iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, ọjọ́ iwájú òun á lóyin. (Ìṣípayá 4:11) Shane sọ pé: “Mo jáwọ́ ṣíṣàníyàn nípa ara mi. Mo ti wá ní ohun kan tó túbọ̀ ṣe pàtàkì láti máa ronú nípa rẹ̀.”
Torí náà, tóo bá rí i pé o ń ṣàníyàn ju bó ṣe yẹ lọ, wá ọ̀nà tó gbéṣẹ́ tí wàá fi kojú ìṣòro náà. Wá ìmọ̀ràn sọ́dọ̀ àwọn tó dàgbà dénú. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, kó gbogbo àníyàn rẹ lọ sọ́dọ̀ Jèhófà ‘nítorí ó bìkítà nípa rẹ.’ (1 Pétérù 5:7) Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, ó ṣeé ṣe kóo dẹ́kun dídààmú kọjá ààlà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Bá àwọn òbí rẹ jíròrò ohun tó ń dà ọ́ láàmú
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Bóo bá ṣe tètè yanjú àwọn ìṣòro rẹ sí, bẹ́ẹ̀ ni wàá ṣe tètè jáwọ́ nínú dídààmú