Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

(A lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí, a sì kọ àwọn ìdáhùn náà ní kíkún sí ojú ìwé 23. Fún àfikún ìsọfúnni, wo ìtẹ̀jáde “Insight on the Scriptures,” tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.)

1. Gẹ́gẹ́ bí Pétérù ṣe sọ, ànímọ́ wo ni ẹnì kan gbọ́dọ̀ ní kó tó lè rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run gbà? (1 Pétérù 5:5)

2. Lẹ́yìn tí Símírì, ọba karùn-ún ní Ísírẹ́lì ti ṣàkóso fún ọjọ́ méje, àwọn ọkùnrin méjì wo ló du ìtẹ́ láàárín ọdún mẹ́rin tí ogun abẹ́lé fi jà? (1 Àwọn Ọba 16:21)

3. Kí ló kó ìjayà bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọn ò fi wọ Ilẹ̀ Ìlérí? (Númérì 13:28, 31-33; Diutarónómì 1:28)

4. Èwo ló pọ̀ jù nínú ìdíwọ̀n táwọn Hébérù ń lò fún ẹrù àtowó? (Ẹ́sírà 8:26)

5. Kí ni Fẹ́líìsì fi ṣe bojúbojú tó fi ránṣẹ́ pe Pọ́ọ̀lù, àmọ́ kí ló ń wá ní ti gidi? (Ìṣe 24:24-26)

6. Orúkọ wo ni Jésù pe ara rẹ̀ àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀? (Mátíù 5:14; Jòhánù 8:12)

7. Orúkọ wo ló tọ́ sí Jésù nìkan ṣoṣo àmọ́ tí kò tọ́ sí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀? (Mátíù 23:10)

8. Ọ̀rọ̀ wo ni Jákọ́bù lò láti tọ́ka sí lílépa ipò ọlá, òkìkí, àti agbára? (Jákọ́bù 4:1)

9. Òkúta ìkọ́lé wo ni a lò jù ní ààfin àwọn ará Páṣíà tó wà ní Ṣúṣánì? (Ẹ́sítérì 1:6)

10. Gẹ́gẹ́ bí Jòhánù ti sọ, àwọn ohun ayé mẹ́ta wo ni “kò pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Baba”? (1 Jòhánù 2:16)

11. Nínú àwọn ìhámọ́ra tẹ̀mí ti Kristẹni tí Pọ́ọ̀lù tò lẹ́sẹẹsẹ, èwo níbẹ̀ ló dúró fún ìgbàlà? (Éfésù 6:17)

12. Ta la mọ̀ tó máa ń bọlá fún ọmọ rẹ̀ ju Jèhófà lọ? (1 Sámúẹ́lì 2:27-29)

13. Èwo ni lẹ́tà karùn-ún nínú ááfábẹ́ẹ̀tì Hébérù? (Sáàmù 111:3)

14. Oṣù wo nínú kàlẹ́ńdà àwọn Júù ni Sólómọ́nì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ tẹ́ńpìlì? (1 Àwọn Ọba 6:1)

15. Wòlíì tó jẹ́ Kristẹni wo ló sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa fàṣẹ ọba mú Pọ́ọ̀lù ní Jerúsálẹ́mù? (Ìṣe 21:10, 11)

Ìdáhùn Sáwọn Ìbéèrè

1. “Ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú,” tàbí ìwà ìrẹ̀lẹ̀

2. Tíbínì àti Ómírì

3. Bí àwọn tó ń gbé ibẹ̀ ṣe “tóbi lọ́nà àrà ọ̀tọ̀” tí wọ́n sì lágbára

4. Tálẹ́ǹtì

5. Láti gbọ́ nípa “èrò ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jésù”; àbẹ̀tẹ́lẹ̀

6. “Ìmọ́lẹ̀ ayé”

7. Aṣáájú

8. “Adùn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara”

9. Òkúta mábílì

10. “Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara,” “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú,” àti “fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími”

11. Àṣíborí

12. Àlùfáà Àgbà Élì

13. Híì’

14. Sífì

15. Ágábù