Orúkọ Ọlọ́run Ló Yí Ìgbésí Ayé Mi Padà!
Orúkọ Ọlọ́run Ló Yí Ìgbésí Ayé Mi Padà!
GẸ́GẸ́ BÍ SANDY YAZZIE TSOSIE ṢE SỌ Ọ́
ÈMI àtàwọn àbúrò mi sá sábẹ́ bẹ́ẹ̀dì, a ń rẹ́rìn-ín a sì ń fọwọ́ gbún ara wa báa ti ń sá fáwọn ẹlẹ́sìn Mormon tó ń kanlẹ̀kùn ilé wa. a Nígbà tí mo jàjà dá wọn lóhùn, mo sọ̀rọ̀ lọ́nà ọ̀yájú sí wọn pé Navajo pọ́ńbélé ni wá a ò sì fẹ́ kí wọ́n sọ ohunkóhun fún wa nípa ìsìn àwọn aláwọ̀ funfun.
Àwọn òbí wa ti lọ sọ́jà láti ra àwọn ohun táa nílò. Ó sì dìrọ̀lẹ́ kí wọ́n tó dé. Nígbà tí wọ́n dé wọ́n gbọ́ pé mo ti hùwà ọ̀yájú sáwọn ẹlẹ́sìn Mormon tó wálé wa. Wọ́n bá mi wí gan-an pé mi ò gbọ́dọ̀ rí ẹnikẹ́ni fín mọ́ láé. Wọ́n kọ́ wa láti fọ̀wọ̀ wọ àwọn èèyàn ká sì ní inú rere. Mo rántí ọjọ́ kan tí àlejò tí a kò retí dé. Àwọn òbí mi ti se oúnjẹ tán níta. Ni wọ́n bá ní kí àlejò yìí kọ́kọ́ jẹun, ẹ̀yìn náà làwá ṣẹ̀ṣẹ̀ wá jẹun.
Gbígbé Lágbègbè Àdádó
Howell Mesa, ní Arizona là ń gbé, kìlómítà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ni ibẹ̀ sí apá àríwá ìwọ̀ oòrùn Àdádó Íńdíà, ibẹ̀ sì jìnnà gan-an sáwọn ìlú ńláńlá táwọn èèyàn kúnnú wọn bìbà. Èyí jẹ́ ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, níbi táwọn àrímáleèlọ aṣálẹ̀ wà, táwọn òkìtì òkúta pupa kan sì wà nínú wọn káàkiri. Ojú ilẹ̀ ibẹ̀ kò bára mu, àwọn ibì kan ga, àwọn mìíràn sì lọọlẹ̀. A lè tibẹ̀ rí àwọn àgùntàn wa tó ń jẹko ní kìlómítà mẹ́jọ sílé. Mo mà fẹ́ràn bí ìgbèríko yìí ṣe parọ́rọ́ o, ibi táa bí mi sí rèé!
Nígbà tí mo wà nílé ẹ̀kọ́ gíga, mo sún mọ́ àwọn ìbátan mi kan tí wọ́n ń gbárùkù ti Ẹgbẹ́ Àwọn Àmẹ́ríńdíà gan-an. b Mo máa ń yangàn pé mo jẹ́ Àmẹ́ríńdíà mo sì máa ń sọ ohun tó jẹ́ èrò mi jáde nípa àwọn aláwọ̀ funfun nítorí ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún tí wọ́n fi ni wá lára, èyí tó dá mi lójú pé Ẹ̀ka Ilé Iṣẹ́ Àwọn Íńdíà ló fà á. Àmọ́ mi ò jẹ́ kí ìkórìíra mi hàn sójútáyé bíi tàwọn ìbátan mi. Inú mi lọ́hùn-ún ló wà. Ìyẹn ló mú kí n kórìíra ẹnikẹ́ni tó bá ṣáà ti ní Bíbélì lọ́wọ́.
Èrò mi ni pé Bíbélì ló jẹ́ káwọn òyìnbó aláwọ̀ funfun wá gba ilẹ̀ wa àtàwọn ẹ̀tọ́ wa àti òmìnira táa ní láti ṣe ìsìn tó bá wù wá! Mo tiẹ̀ ṣarúmọjẹ ọ̀nà tí bàbá mi ń gbà buwọ́ lùwé kí n má bàa kópa nínú ayẹyẹ àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì àti tàwọn Kátólíìkì nígbà tí wọ́n fi ọ̀ranyàn mú wa lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì lákòókò tí mo wà ní ilé ẹ̀kọ́. Ńṣe làwọn ilé ẹ̀kọ́ wọ̀nyẹn fẹ́ ká gbàgbé gbogbo àṣà ìbílẹ̀ Íńdíà pátápátá. Wọn ò tiẹ̀ jẹ́ ká sọ èdè wa rárá ni!
A nífẹ̀ẹ́ sí ìṣẹ̀dá àti àyíká lọ́pọ̀lọpọ̀. Àràárọ̀ la máa c Bí wọ́n ṣe kọ́ mi gan-an nìyí láti ṣe ìsìn lọ́nà tàwọn Navajo, pẹ̀lú inú dídùn ni mo sì fi máa ń ṣe é. Ìgbàgbọ́ táwọn Kirisẹ́ńdọ̀mù ní pé èèyàn á lọ sọ́run kò tiẹ̀ wù mí páàpáà, bẹ́ẹ̀ ni mi ò gbà pé èèyàn ń joró nínú iná lọ́run àpáàdì. Gbígbé lórí ilẹ̀ ayé lohun tó wà lọ́kàn mi.
ń kọjú sí ìhà ìlà oòrùn, a máa ń gbàdúrà, á óò sì fọ́n lẹ́bú àgbàdo mímọ́ táa fi máa ń ṣàdúrà káàkiri.Lákòókò ìsinmi, mo máa ń gbádùn àjọṣe tímọ́tímọ́ tí ìdílé mi ní. Iṣẹ́ mi ojoojúmọ́ ni kí n mú kí ahéré táa ń gbé wà ní mímọ́ tónítóní, kí n hunṣọ, kí n sì tọ́jú àwọn àgùntàn wa. Ọjọ́ ti pẹ́ táwa Navajo ti ń ṣètọ́jú àgùntàn. Gbogbo ìgbà tí mo bá ń tún ahéré táa ń gbé ṣe (wo fọ́tò tó wà nísàlẹ̀), ni mo máa ń rí ìwé pupa kékeré kan tó ní Sáàmù àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé “Májẹ̀mú Tuntun” nínú. Mo kàn máa ń fẹsẹ̀ gbá a síbí sọ́hùn-ún ni, mi ò fìgbà kan rí ronú nípa ohun tó lè wà nínú rẹ̀ àti ìtumọ̀ rẹ̀. Àmọ́ mi ò sọ ọ́ nù ṣá o.
Ẹ̀tàn àti Ìjákulẹ̀ Gbáà Ni Ìgbéyàwó Jẹ́ fún Mi
Lẹ́yìn tí mo jáde ilé ẹ̀kọ́ gíga, mo ronú pé kí n lọ sí ilé ẹ̀kọ́ ẹ̀kọ́ṣẹ́ ọwọ́ ní Albuquerque, New Mexico. Àmọ́ mi ò tíì lọ tí mo fi pàdé ẹni tó di ọkọ mi. Mo padà sí àgbègbè àdádó táa ń gbé, láti lọ́kọ. Àwọn òbí mi ti ṣègbéyàwó fún ọ̀pọ̀ ọdún. Mo sì fẹ́ ṣe bíi tiwọn, lèmi náà bá ṣègbéyàwó. Mo fẹ́ràn títọ́jú ilé, mo sì gbádùn bí ìdílé wa ṣe rí, àgàgà ìgbà táa bí ọmọkùnrin wa, Lionel. Ilé ayọ̀ àti ẹ̀rín ni ilé wa, àfìgbà tó di ọjọ́ kan tí mo gbọ́ ìròyìn abani-lọ́kàn-jẹ́ kan!
Ọkọ mi ní ìyàwó mìíràn síta! Ìwà àìṣòótọ́ tó hù yìí ló tú ìgbéyàwó wa ká. Ìbànújẹ́ bá mi mo sì kórìíra ọkọ mi burúkú burúkú. Ó ṣe mí bíi pé kí n gbẹ̀san! Àmọ́ ní gbogbo àkókò yánpọnyánrin nípa ta ló máa mú ọmọ sọ́dọ̀ àti ọ̀ràn ìtìlẹ́yìn nípa ìṣúnná owó nígbà táa bá kọra wa sílẹ̀, inú mi kàn ń bà jẹ́ ni, ó wá dà bíi pé mi ò já mọ́ nǹkankan mọ́ tí kò sì sí ìrètí. Mo máa ń sáré ọ̀pọ̀ kìlómítà láti fi tu ara mi nínú. Gbogbo ìgbà ni mo ń sunkún àsun-ùn-dákẹ́ mi ò sì lè jẹun. Ó wá dà bíi pé mi ò lálábàárò.
Nígbà tó yá, mo bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ ọkùnrin kan tóun náà níṣòro ìgbéyàwó bíi tèmi. Àwa méjèèjì la ní ìbànújẹ́ ọkàn. Ó fìfẹ́ hàn sí mi ó sì fún mi ní ìtìlẹ́yìn tí mo nílò. Gbogbo ohun tó wà nínú mi pátá àti èrò mi nípa ìgbésí ayé ni mo rò fún un. Ó fara balẹ̀ gbọ́ mi, èyí sì jẹ́ kí n gbà pé ó ṣèèyàn. A ṣètò láti ṣègbéyàwó.
Lẹ́yìn náà ni mo rí i pé aláìṣòótọ́ lòun náà! Mo fòpin sí àjọṣe wa bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí ṣòro gan-an ó sì dùn mí púpọ̀. Ayé sú mi, ìbànújẹ́ sì dorí mi kodò. Inú wá ń bí mi gan-an, mo di ẹlẹ́mìí ìgbẹ̀san, mo sì fẹ́ para mi. Ìgbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni mo gbìyànjú láti gbẹ̀mí ara mi. Ó ṣáà ń dà bí ẹni pé kí n kú ni.
Ìgbà Àkọ́kọ́ Tí Mo Mọ Díẹ̀ Nípa Ọlọ́run Tòótọ́
Pòròpòrò lomi máa ń dà lójú mi tí mo bá ń gbàdúrà sí Ọlọ́run bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò mọ̀ ọ́n. Síbẹ̀, mo gbà gbọ́ pé Ẹni Gíga Jù Lọ kan wà tó ṣẹ̀dá àgbáálá ayé tó kàmàmà yìí. Àtiwọ̀ oòrùn tó máa ń jojú ní gbèsè ru mí lọ́kàn sókè mo sì ronú lórí bí Ẹni tí mi ò mọ̀ rí yẹn ṣe jẹ́ àgbàyanu tó, tó fi gbà wá láyè láti gbádùn àwọn ohun àrà wọ̀nyí. Mo bẹ̀rẹ̀ sí nífẹ̀ẹ́ ẹni yẹn bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò mọ̀ ọ́n. Mo wá ń sọ fún un pé: “Ọlọ́run, tó bá jẹ́ lóòótọ́ lo wà, ràn mí lọ́wọ́, tọ́ mi sọ́nà, wáá fayọ̀ sáyé mi.”
Ní gbogbo àkókò yìí, ọkàn ìdílé mi ò balẹ̀, àgàgà bàbá mi. Àwọn òbí mi lọ gba àwọn babaláwo láti wò mí sàn. Bàbá mi sọ pé ojúlówó oníṣègùn kò jẹ́ béèrè owó lọ́wọ́ rẹ láé, ohun tó bá sì sọ ló máa ṣe. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo lọ́wọ́ nínú ààtò ẹ̀sìn Ọ̀nà Ìbùkún Àwọn Navajo, láti múnú àwọn òbí mi dùn.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ ni mo lò nínú ahéré lémi nìkan, àfi rédíò kan tó tún wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀dì mi. Ńṣe ninú ń bí mi bí mo ti ń gbọ́ tí àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì kan ń gégùn-ún nítorí pé mi ò gbà gbọ́ nínú Jésù. Ṣe ni inú mi ń ru gùdù! Kò tún sóhun tó kàn mí kan ẹ̀sìn àwọn aláwọ̀ funfun mọ́ àti tèmi gan-an pàápàá! Mo pinnu lọ́kàn mi pé màá wá Ọlọ́run lọ́nà tó bá ti wù mí.
Nígbà tí mo dá wà nínú ahéré yẹn, mo tún ṣàkíyèsí ìwé pupa náà lẹ́ẹ̀kan sí i. Mo wá rí i pé apá kan Bíbélì ni. Nígbà tí mo ka Sáàmù, mo rí ìjìyà Ọba Dáfídì àti ìsoríkọ́ tó bá a, èyí sì tù mí nínú. (Sáàmù 38:1-22; 51:1-19) Ṣùgbọ́n nítorí pé mo máa ń ronú pé mo sàn ju àwọn aláwọ̀ funfun lọ, kíákíá ni mo mú ọkàn mi kúrò nínú gbogbo nǹkan tí mo kà. Mo ní mi ò jẹ́ gba ẹ̀sìn àwọn aláwọ̀ funfun.
Pẹ̀lú bí ìbànújẹ́ ṣe dorí mi kodò, mo tiraka láti tọ́jú ọmọ mi. Ó wá di orísun ìṣírí fún mi. Mo bẹ̀rẹ̀ sí wo àwọn ètò ìsìn tó ń gbàdúrà tí wọ́n máa ń fi hàn lórí tẹlifíṣọ̀n. Ni mo bá ki tẹlifóònù mọ́lẹ̀ mo sì tẹ nọ́ńbà kan tí mo rò pé mo ti lè rí ìrànlọ́wọ́ gbà. Tìbínú-tìbínú ni mo fi gbé fóònù jù sílẹ̀ nígbà tí wọ́n sọ fún mi pé mo gbọ́dọ̀ ṣèlérí pé màá san àádọ́ta tàbí ọgọ́rùn-ún dọ́là!
Ìgbẹ́jọ́ kóòtù nípa ìkọ̀sílẹ̀ wa kó ìrònú bá mi gan-an, pàápàá bó ṣe jẹ́ pé irọ́ ni ọkọ mi kàn ń pa kùrà fún adájọ́ tó ń gbọ́ ẹjọ́ náà. Ó pẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìkọ̀sílẹ̀ wa tó forí tì síbì kan nítorí wàhálà lórí ẹni tó máa mú ọmọ wa tira nínú àwa méjèèjì. Àmọ́ ọ̀dọ̀ mi ló já sí. Tìfẹ́tìfẹ́ ni bàbá mi fi tì mí lẹ́yìn gbágbáágbá lákòókò ìgbẹ́jọ́ náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò pariwo rẹ̀ síta. Ó mọ̀ pé ibi tọ́ràn náà bọ́ sí lára mi kò dáa.
Ìgbà Àkọ́kọ́ Tí Mo Pàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí
Mo pinnu pé màá fi ara mi lọ́kàn balẹ̀ bí mo ti ń gbé ìgbésí ayé mi. Lọ́jọ́ kan, mo rí i táwọn Navajo kan ń bá àwọn aládùúgbò mi sọ̀rọ̀. Ni mo bá ń fọgbọọgbọ́n yọjú wò wọ́n. Iṣẹ́ ilé-dé-ilé ni àwọn àlejò wọ̀nyí ń ṣe. Wọ́n dé ilé tèmi náà. Sandra, tó jẹ́ Navajo sọ pé òun jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Orúkọ náà Jèhófà ló ta mí kìjí. Mo ní: “Ta ló ń jẹ́ Jèhófà? Ẹ̀sìn rẹ yìí ẹ̀sìn tuntun ni. Kí ló dé tí wọn ò kọ́ mi ní orúkọ Ọlọ́run ní ṣọ́ọ̀ṣì mi?”
Ó fẹ̀sọ̀ ṣí Bíbélì rẹ̀ sí Sáàmù 83:18, tó kà pé: “Kí àwọn ènìyàn lè mọ̀ pé ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” Ó ṣàlàyé fún mi pé Ọlọ́run ní orúkọ kan àti pé Ọmọkùnrin rẹ̀, Jésù Kristi, jẹ́ ẹlẹ́rìí fún Jèhófà. Ó sọ pé òun máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà àti Jésù ó sì fún mi ní ìwé Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye. d Inú mi dùn gan-an, mo sì sọ pé: “Kò burú. Màá fẹ́ dán ẹ̀sìn tuntun yìí wò!”
Kíákíá ni mo ka ìwé náà tán. Àwọn nǹkan tó wà nínú rẹ̀ ṣàjèjì sí mi wọ́n sì yàtọ̀. Ó ṣàlàyé pé ìgbésí ayé ní ète, àti pé ohun tí mo nílò rèé láti tún lè nífẹ̀ẹ́ sí ìgbésí ayé padà. Mo bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, inú mi sì dùn pé púpọ̀ lára àwọn ìbéèrè mi ni mo rí ìdáhùn sí látinú Bíbélì. Gbogbo ohun tí mo kẹ́kọ̀ọ́ pátá ni mo gbà gbọ́. Ó lọ́gbọ́n nínú, ó sì ní láti jẹ́ òtítọ́!
Mo bẹ̀rẹ̀ sí fi òtítọ́ inú Bíbélì kọ́ Lionel nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́fà. A jọ máa ń gbàdúrà pọ̀. A máa ń gbara wa níyànjú pé Jèhófà bìkítà nípa wa, pé ó yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé e. Gbogbo nǹkan máa ń fẹ́ pin mí lẹ́mìí nígbà mìíràn.
Àmọ́, ọwọ́ rẹ̀ kéékèèké tó fi máa ń gbá mi mọ́ra, pẹ̀lú ọ̀rọ̀ afúnninírètí tó máa ń sọ pé, “Ẹ má sunkún mọ́, Mọ́mì, Jèhófà á tọ́jú wa,” máa ń tù mí lára gan-an ni. Kódà, ó tù mí nínú gan-an ó sì mú kí n pinnu pé dandan mi ò ní jáwọ́ kíka Bíbélì! Gbogbo ìgbà ni mo ń gbàdúrà fún ìtọ́sọ́nà.Ipa Táwọn Ìpàdé Kristẹni Kó
Ìmọrírì táa ni fún Jèhófà sún wa láti rìnrìn àjò òjìlérúgba [240] kìlómítà ní àlọ àtàbọ̀ láti lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ìlú Tuba. Ẹ̀ẹ̀méjì lọ́sẹ̀ la máa ń lọ nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, a sì máa ń wà níbẹ̀ látàárọ̀ ṣúlẹ̀ lọ́jọ́ Sunday lásìkò òtútù nítorí ojú ọjọ́ tí kò bára dé. Nígbà kan tí ọkọ̀ wa bà jẹ́, ńṣe la bẹ àwọn onímọ́tò tó ń kọjá lọ pé kí wọ́n dákun gbé wa dé Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ìrìn àjò náà ń mú kó rẹ èèyàn gan-an, àmọ́ ọ̀rọ̀ tí Lionel ti sọ pé a ò gbọ́dọ̀ pa ìpàdé jẹ àyàfi táa bá ń ṣàìsàn tó le gan-an ti jẹ́ kí n fi sọ́kàn pé ó ṣe pàtàkì láti má ṣe máa fi ọwọ́ dẹngbẹrẹ mú ìtọ́ni nípa tẹ̀mí tó ń wá látọ̀dọ̀ Jèhófà.
Ńṣe lomi máa ń dà lójú mi nínú ìpàdé táa bá ń kọ orin Ìjọba tó sọ pé a máa wà láàyè títí láé láìsí pákáǹleke nínú ìgbésí ayé. Mo rí ìtùnú àti ìṣírí gbà lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n mọ aájò àlejò ṣe gan-an ni, wọ́n á pè wá sílé wọn ká lè bá wọn jẹ oúnjẹ ọ̀sán àti ìpápánu, a tún máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé pẹ̀lú wọn. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ wa wọ́n sì tẹ́tí sí wa. Ipa táwọn alàgbà kó kò kéré, wọ́n máa ń fi ọ̀ràn wa ro ara wọn wò wọ́n sì túbọ̀ jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà Ọlọ́run kò fi wá sílẹ̀. Inú mi dùn gan-an pé mo rí àwọn ọ̀rẹ́ gidi. Wọ́n tù mí lára púpọ̀púpọ̀, kódà, wọ́n bá mi sunkún nígbà tí mo ronú pé ẹ̀mí mi kò fẹ́ gbé e mọ́.—Mátíù 11:28-30.
Ìpinnu Pàtàkì Méjì
Àkókò tọ́kàn mi ti wá balẹ̀ sórí àwọn ìpèsè Jèhófà ni ẹni tí mo ń fẹ́ tẹ́lẹ̀ dé pé ká parí ìjà. Mi ò lè sọ pé rárá nítorí mo ṣì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. A ṣètò láti ṣe ìgbéyàwó. Èrò mi ni pé òtítọ́ á yí i padà. Ìyẹn ni àṣìṣe tó burú jù lọ tí mo ṣe láyé mi! Inú mi ò dùn rárá. Ẹ̀rí ọkàn mi ń dà mí láàmú gidi gan-an. Sí ìyàlẹ́nu mi, kò fẹ́ràn òtítọ́ rárá.
Mo finú han alàgbà kan. Ó bá mi fọ̀rọ̀ jomitoro ọ̀rọ̀ nínú Ìwé Mímọ́, ó sì gbàdúrà pẹ̀lú mi lórí ìpinnu tí mo ṣe. Mo wá fi sọ́kàn pé Jèhófà nìkan ni kò lè bà mí nínú jẹ́ tàbí kó fìyà jẹ mí, àwọn èèyàn aláìpé lè ṣe bẹ́ẹ̀ bó ti wù ká pọ́n wọn lé tó. Àní, mo wá rí i pé kò sí ààbò nínú ìgbéyàwó téèyàn kò ṣe lábẹ́ òfin. Ni mo bá ṣe ìpinnu. Kò rọrùn rárá ó sì kó ìdààmú bá mi láti fòpin sí àjọṣe náà. Ó di dandan kí n fi gbogbo ọkàn mi gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé màá níṣòro ìṣúnná owó.
Mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà mo sì pinnu láti sìn ín. Ní May 19, 1984, mo fàmì ìyàsímímọ́ ìgbésí ayé mi fún Jèhófà Ọlọ́run hàn nípa ṣíṣe ìrìbọmi. Ọmọ mi náà, ìyẹn Lionel, ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ti ṣèrìbọmi. Ìdílé mi àti ọkọ mi tẹ́lẹ̀ ṣe inúnibíni sí wa gan-an, àmọ́ a ò yéé gbára lé Jèhófà. Kò sì já wa kulẹ̀. Lẹ́yìn ọdún mọ́kànlá gbáko, àwọn òbí mi fọwọ́ wọ́nú wọ́n sì fi wá sílẹ̀ jẹ́ẹ́.
Mo fẹ́ràn wọn gan-an, ohun tí mo sì fẹ́ ni pé káwọn náà kọ́ nípa Jèhófà kí wọ́n bàa lè láyọ̀ pẹ̀lú. Bàbá mi tó ti ronú nígbà kan rí pé ìsoríkọ́ á mú kí n gbẹ̀mí ara mi wà lẹ́yìn mi gbágbáágbá. Inú rẹ̀ dùn gan-an pé mi ò banú jẹ́ mọ́. Mo wá rí i pé gbígbàdúrà sí Jèhófà, lílọ sípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àti fífi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò ṣe kókó láti mú kí ìdààmú ọkàn lọ.
Ìrètí Ọjọ́ Iwájú
Mo ń retí ìgbà tí gbogbo ìjìyà, àìpé, àìṣòótọ́, àti ìkórìíra máa lọ tèfètèfè. Mo ń fojú inú
wo bí koríko, igi peach àti apricot tó wà ní ilẹ̀ Navajo ṣe máa hù lọ súà. Mo ń fojú inú wo bí ìdùnnú náà á ṣe tó nígbà tí oríṣiríṣi ẹ̀yà bá ń lo omi odò àti òjò láti sọ ibi tí wọ́n ń gbé, tó gbẹ táútáú tẹ́lẹ̀ di ibi ọgbà ẹlẹ́wà. Mo ń wo bó ṣe máa rí nígbà táwa àtàwọn Hopi aládùúgbò wa, àtàwọn ẹ̀yà mìíràn kò tún ní fìjà pẹẹ́ta bíi ti àìpẹ́ yìí mọ́, àmọ́ tí a óò jọ máa ṣe wọléwọ̀de. Mo wá rí i báyìí bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ń so gbogbo ẹ̀yà, èdè, àti àwùjọ pa pọ̀. Nígbà àjíǹde lọ́jọ́ iwájú, mo máa rí àwọn ìdílé àtàwọn ọ̀rẹ́, tí wọ́n á tún wà pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn èèyàn wọn tó ti kú tẹ́lẹ̀. Àkókò ayọ̀ ńláǹlà ló máa jẹ́, tí wọ́n á sì máa gbé títí láé. Mi ò rò pé a lè rí ẹnì kan tí kò ní fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa àǹfààní tó gadabú yìí.Mímú Iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run Gbòòrò ní Ilẹ̀ Àwọn Navajo
Inú mi dùn gan-an láti rí Gbọ̀ngàn Ìjọba kan ní Ìlú Tuba àti láti wo bí ìjọ mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ṣe ń gbòòrò sí i lágbègbè àdádó Navajo àti Hopi e—ìjọ Chinle, Kayenta, Ìlú Tuba, àti Keams Canyon. Ìgbà àkọ́kọ́ pàá tí mo ṣiṣẹ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ní 1983, mo ń rò ó lọ́kàn pé ọjọ́ kan á ṣáà jọ́kan tí wọ́n á fi èdè Navajo darí ilé ẹ̀kọ́ náà. Bẹ́ẹ̀ gan-an ló sì wá rí. Láti ọdún 1998 ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí fi èdè Navajo darí ilé ẹ̀kọ́ náà.
Sísọ fún àwọn ẹlòmíràn pé Ọlọ́run ní orúkọ kan ti mú àwọn ìbùkún tó pọ̀ wá. Ẹnu mi kò gba ìròyìn nípa bó ṣe rí lára mi nígbà tí mo bá kà á fáwọn èèyàn tí mo sì ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó ń fún ìgbàgbọ́ lókun fún àwọn èèyàn ní èdè ìbílẹ̀ wa gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ, Nihookáá’gi Hooláágóó liná Bahózhoóodoo! (Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!), Ha’át’fíísh éí God Nihá yee Hool’a’? (Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?), àti èyí tó dé gbẹ̀yìn náà, Ni Éí God Bik’is Dííleelgo Át’é! (Ìwọ́ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!) Mo dúpẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye fún ṣíṣagbátẹrù iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yìí kí gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti èdè lè jàǹfààní, tó fi dórí àwọn Àmẹ́ríńdíà, ìyẹn àwọn Diné.—Mátíù 24:45-47.
Mo ń ṣiṣẹ́ látàárọ̀ ṣúlẹ̀ láti gbọ́ bùkátà ara mi àmọ́ mo máa ń gbádùn ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ déédéé. Mo mọrírì bí mo ṣe wà láìlọ́kọ mo sì fẹ́ sin Jèhófà láìsí ìpínyà ọkàn. Inú mi dùn ara mi sì yá gágá láti sọ fáwọn èèyàn mi àtàwọn mìíràn, àgàgà àwọn tí wọn ò nírètí pé “Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà; ó sì ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là.”—Sáàmù 34:18.
Mi ò ka Bíbélì sí ìwé àwọn aláwọ̀ funfun mọ́. Bíbélì tó jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wà fún gbogbo ẹni tó bá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ kó sì fi sílò. Bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá bẹ̀ ọ́ wò, jẹ́ kí wọ́n fi bóo ṣe lè rí ìdùnnú tòótọ́ hàn ọ́. Ìhìn rere nípa orúkọ Ọlọ́run, Jèhófà, ni wọ́n mú wá bá ọ, orúkọ tó yí ìgbésí ayé mi padà! “Aoo,’ Diyin God bízhi’ Jiihóvah wolyé.” (“Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.”)
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ìsọfúnni ní kíkún nípa ìsìn Mormon, wo Jí!, November 8, 1995.
b Ẹgbẹ́ Àwọn Àmẹ́ríńdíà jẹ́ àjọ tó ń rí sí ẹ̀tọ́ gbogbo gbòò tí Àmẹ́ríńdíà kan dá sílẹ̀ lọ́dún 1968. Òun àti Ẹ̀ka Ilé Iṣẹ́ Àwọn Íńdíà tí ìjọba sọ pé òun dá sílẹ̀ lọ́dún 1824 láti mú kí ìgbésí ayé àwọn Íńdíà sunwọ̀n sí i kì í sì í fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ ara wọn sétí rárá. Ńṣe ni ilé iṣẹ́ yìí máa ń fi àwọn ohun àlùmọ́nì inú ilẹ̀, omi, àtàwọn nǹkan mìíràn tó wà níbi àdádó náà háyà fún àwọn tí kì í ṣe ọmọ Íńdíà.—World Book Encyclopedia.
c Wọ́n ka lẹ́bú àgbàdo sóhun mímọ́ kan, wọ́n sì ń fi ṣàdúrà àti àwọn ààtò mìíràn, ó dúró fún ìwàláàyè àti ìsọdọ̀tun. Àwọn Navajo gbà gbọ́ pé béèyàn bá gba ojú ọ̀nà tí wọ́n fi lẹ́búlẹ́bú yìí wọ́n, ara onítọ̀hún á di mímọ́.—The Encyclopedia of Native American Religions.
d Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló tẹ̀ ẹ́ jáde, àmọ́ wọn ò tẹ̀ ẹ́ jáde mọ́.
e Fún ìsọfúnni síwájú sí i wo ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Amerind—Kí Ni Ìrètí Wọn fún Ọjọ́ Ọ̀la?” tó wà nínú ìtẹ̀jáde Jí! September 8, 1996.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Bí ahéré àwọn Navajo ṣe máa ń rí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Èmi àti ọmọ mi, Lionel
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Èmi àtàwọn ọ̀rẹ́ láti Rọ́ṣíà ní àpéjọpọ̀ àgbáyé ní Moscow ní 1993
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Èmi àtàwọn ìdílé mi nípa tẹ̀mí ní ìjọ Kayenta, tó wà ní Arizona