Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ta Ni Yóò Bọ́ Aráyé?

Ta Ni Yóò Bọ́ Aráyé?

Ta Ni Yóò Bọ́ Aráyé?

ṢÉ ỌMỌ aráyé lè bẹ̀rẹ̀ sí í dáàbò bo oríṣiríṣi ohun ọ̀gbìn dípò pípa wọ́n run? Ìyẹn ń béèrè fún “ìyípadà ńláǹlà” níbàámu pẹ̀lú ohun tí John Tuxill, onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ohun alààyè sọ. Ó fi kún un pé, irú ìyípadà bẹ́ẹ̀ “kò dájú pé ó lè ṣeé ṣe láìjẹ́ pé àwọn èèyàn bá mọ àwọn àǹfààní tó wà nínú gbígbin onírúurú ohun ọ̀gbìn, kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ láti yí bí wọ́n ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀ padà, kí wọ́n sì múra tán láti gbìyànjú àwọn ọ̀nà tuntun mìíràn.”

Ó ṣòro fáwọn kan láti gbà gbọ́ pé irú àwọn ìyípadà ńlá bẹ́ẹ̀ máa ṣẹlẹ̀. Àwọn kan ò sì fara mọ́ ibi tí Tuxill parí ọ̀rọ̀ sí. Àwọn onímọ̀ nípa àyíká kan ronú pé àwọn èèyàn kò tíì fi bẹ́ẹ̀ lóye àǹfààní tó wà nínú gbígbin oríṣiríṣi ohun ọ̀gbìn tàbí pé bóyá àwọn ẹgbẹ́ wọn gan-an ló ń gbé e lárugẹ ju bó ṣe yẹ lọ. Síbẹ̀, pẹ̀lú bí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe ń jiyàn ọ̀rọ̀ yìí, ó tọ́ ó sì yẹ pé kí wọ́n fiyè sí ìkìlọ̀ tó ń ró gbọnmọgbọnmọ látọ̀dọ̀ àwọn ògbógi tó mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí. Kì í ṣe bí oríṣiríṣi ohun ọ̀gbìn ṣe ń pòórá nìkan lohun tó ń ká wọn lára, àmọ́ ẹ̀mí ìwọra àti àìronú nípa ọjọ́ iwájú tó wà nídìí ọ̀ràn ọ̀hún. Kíyè sí àwọn gbólóhùn wọ̀nyí tó wá látọ̀dọ̀ àwọn akọ̀wé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

“Lóhun tí kò ju ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn àgbẹ̀ tó wà káàkiri ayé ló ń fúnra wọn mójú tó àwọn ohun ọ̀gbìn wọn. . . . Lónìí, èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ohun ọ̀gbìn náà ti bọ́ sọ́wọ́ àwọn iléeṣẹ́ àgbáyé, wọ́n ti yí wọn padà, wọ́n sọ wọ́n lórúkọ wọn, wọ́n sì sọ pé ọgbọ́n orí àwọn ló wà lẹ́yìn gbogbo ẹ̀. . . . Nítorí àǹfààní ojú ẹsẹ̀, àwọn èèyàn ń fi ìmọ̀ ẹ̀rọ ṣe ìpalára fún àbùdá àwọn ohun alààyè, èyí tó lè wá wúlò gidigidi lọ́jọ́ iwájú fún ìdáàbòbò àwọn àbùdá náà kúrò lọ́wọ́ àwọn àrùn tàbí kòkòrò tó lè máà ṣeé pa bọ̀rọ̀.”—Jeremy Rifkin, òǹkọ̀wé onímọ̀ sáyẹ́ǹsì.

“Ohun táwọn ilé iṣẹ́ oníròyìn ń gbé jáde tí wọ́n sì ń tẹnu mọ́ léraléra ni pé, ohun tó ṣe pàtàkì jù ni ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́jà àgbáyé, ṣíṣe òwò níbikíbi láìsí ìdíwọ́ àti ọrọ̀ ajé àgbáyé. Nígbà tó bá jẹ́ pé ọrọ̀ àti àǹfààní àwọn iléeṣẹ́ ńláńlá lohun tó jẹ àwọn tó ń gbé ìròyìn jáde lógún, a jẹ́ pé ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú ọrọ̀ ajé jẹ́ ìgbàgbọ́ gbà-á-bẹ́ẹ̀-bẹ́ẹ̀, kò sì fi bẹ́ẹ̀ sẹ́ni tó ń wádìí ẹ̀ wò.”—Onímọ̀ nípa àbùdá, David Suzuki.

Òǹkọ̀wé Kenny Ausubel nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní Seeds of Change—The Living Treasure, tọ́ka sí àgàbàgebè tó wà láwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà, táwọn “ìjọba wọn àtàwọn oríṣiríṣi àjọ máa ń pariwo pé ewu ń rọ̀ dẹ̀dẹ̀ káàkiri ayé nítorí píparun tí àbùdá tó jẹ́ ‘ogún gbogbo’ ẹ̀dá ń pa run.” Ó sọ pé àwọn gan-an ló túbọ̀ ń dá kún bí onírúurú àwọn ohun alààyè ṣe ń pòórá nípa gbígbé ọ̀nà iṣẹ́ àgbẹ̀ òde òní àti àṣà gbígbin oríṣi irè oko kan ṣoṣo lárugẹ.

Bóyá ìbẹ̀rù àwọn onímọ̀ nípa àyíká yìí tọ̀nà tàbí kò tọ̀nà, ó lè má ṣeé ṣe fún ẹ láti fọkàn balẹ̀ pé kò ní séwu fún ayé yìí lọ́jọ́ iwájú. Báwo lẹ̀mí ayé ọ̀hún ṣe máa gùn tó pẹ̀lú bí ojúkòkòrò kò ṣe jẹ́ kọ́mọ aráyé gbádùn yìí? Bí ọ̀pọ̀ ṣe ń wá ìdáhùn lójú méjèèjì, ìrètí wọn ni pé ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ló máa kó wa yọ.

Ṣé Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì àti Ìmọ̀ Iṣẹ́ Ẹ̀rọ Lè Kó Wa Yọ?

Ẹgbẹ́ Aláyélúwà ti Edinburgh láìpẹ́ yìí ti bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀rù pé àwọn ìtẹ̀síwájú tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ń yára kánkán ó sì díjú débi pé, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì wà nínú ewu ṣíṣàì ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òye ohun tó máa tìdí àwọn ìtẹ̀síwájú náà yọ. David Suzuki kọ̀wé pé: “Ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ń fún wa ní òye bín-ń-tín nípa ayé wa, èyí tí wọ́n ṣà níbí ṣà lọ́hùn-ún. A fẹ́rẹ̀ẹ́ máà mọ dòò nípa àwọn ohun tó para pọ̀ mú kí ìwàláàyè ṣeé ṣe lórí Ilẹ̀ Ayé, ká má ṣẹ̀sẹ̀ wá sọ ti bí wọ́n ṣe so kọ́ra tí wọ́n sì gbára léra wọn.”

Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Science ti ṣàlàyé “kò sí ọ̀kankan tó dá èèyàn lójú nínú ewu àti àǹfààní tó wà nínú Àwọn Ohun Alààyè Tí Wọ́n Ti Yí Àbùdá Wọn Padà tàbí pé bóyá gbogbo ibi ni wọ́n ti tẹ́wọ́ gbà á. . . . Òye wa láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sáwọn ọ̀wọ́ irúgbìn tí wọ́n ṣí nípò padà kò tó nǹkan rárá, títí kan Àwọn Ohun Alààyè Tí Wọ́n Ti Yí Àbùdá Wọn Padà.”

Ká sòótọ́, ojú méjì ni ọ̀pọ̀ “ìtẹ̀síwájú” ní. Wọ́n ní dáadáa díẹ̀, àmọ́ wọ́n tún fi hàn pé ọgbọ́n kù fún ọmọ aráyé, ọ̀pọ̀ ìgbà sì ni ojúkòkòrò wọn ń fara hàn. (Jeremáyà 10:23) Fún àpẹẹrẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ètò kébimápàlú pèsè oúnjẹ rẹpẹtẹ tí kò sì jẹ́ kí ebi pa ọ̀pọ̀ èèyàn kú, ó tún dá kún pípàdánù níní onírúurú ohun ọ̀gbìn. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé lílo àwọn oògùn apakòkòrò àtàwọn ọ̀nà ìgbàṣe iṣẹ́ ọ̀gbìn tó ń náni lówó gegere ni ètò náà gbé lárugẹ, Dókítà Mae-Wan Ho kọ̀wé pé: “Àwọn oríṣiríṣi àjọ tó ń fi nǹkan ọ̀gbìn ṣòwò àtàwọn ọ̀tọ̀kùlú tó wà láwọn Orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà ló ṣe láǹfààní nígbẹ̀yìngbẹ́yín, àwọn mẹ̀kúnnù ló sì forí fá a.” Ìwà yìí kò dáwọ́ dúró rárá bí iṣẹ́ àgbẹ̀ tí wọ́n gbé karí ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ àti ti ohun alààyè ṣe túbọ̀ ń di òwò tó ń búrẹ́kẹ́ tó sì ń lágbára sí i, tó sì ń tì wá lọ sí ọjọ́ iwájú kan tó jẹ́ pé láìsí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì a kò ní rí oúnjẹ jẹ.

Àmọ́ kò yẹ káwọn ìṣòro wọ̀nyí kó ìbànújẹ́ bá wa o. Ní ti gidi, wọ́n wulẹ̀ ń ṣàlàyé kókó pàtàkì kan ni. Bíbélì ràn wá lọ́wọ́ láti rí i pé kò yẹ ká retí nǹkan bàbàrà látọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn aláìpé tí wọ́n ń ṣàbójútó ayé yìí ní lọ́wọ́lọ́wọ́ àtàwọn ohun tó wà nínú rẹ̀. Ní báyìí ná, àwọn àṣìṣe wọn àti àṣìlò àwọn ohun àmúṣọrọ̀ wulẹ̀ jẹ́ apá kan ipò tí ẹ̀dá ènìyàn bá ara rẹ̀ ni. Ìdí rèé tí Sáàmù 146:3 fi kìlọ̀ pé: “Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ yín lé àwọn ọ̀tọ̀kùlú, tàbí lé ọmọ ará ayé, ẹni tí ìgbàlà kò sí lọ́wọ́ rẹ̀.” Ṣùgbọ́n a lè ní ìgbọ́kànlé kíkún nínú Ọlọ́run. (Òwe 3:5, 6) Ó wù ú láti ràn wá lọ́wọ́ ó sì ní agbára láti ṣe bẹ́ẹ̀.—Aísáyà 40:25, 26.

Láìpẹ́, Ayé Yóò Di Ibi Ẹlẹ́wà, Tí Aásìkí Kúnnú Rẹ̀

Kóo tó tún ilé kan tó ti di ẹgẹrẹmìtì ṣe, ó lè pọn dandan pé kóo kọ́kọ́ palẹ̀ àwọn àwókù rẹ̀ mọ́. Bákan náà, láìpẹ́, Jèhófà Ọlọ́run yóò mú gbogbo ìwà ibi inú ayé kúrò, títí kan àwọn tó kan ayé wa, ọrọ̀ àlùmọ́nì inú rẹ̀, àtàwọn èèyàn ẹlẹgbẹ́ wọn sí ohun tí wọ́n kàn lè máa lò fún ire ara wọn àti láti di ọlọ́rọ̀ láwùjọ. (Sáàmù 37:10, 11; Ìṣípayá 11:18) Ṣùgbọ́n Jèhófà yóò dá gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tí wọ́n sì ń sapá láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ sí.—1 Jòhánù 2:15-17.

Lẹ́yìn náà, ayé yìí àti àìmọye àwọn ohun alààyè inú rẹ̀, títí kan àwọn èèyàn onígbọràn, ni ìjọba kan tí Ọlọ́run ti gbé kalẹ̀ yóò bójú tó—ìyẹn Ìjọba Mèsáyà. (Dáníẹ́lì 7:13, 14; Mátíù 6:10) Ọ̀pọ̀ yanturu ohun ọ̀gbìn ni ayé máa mú jáde lábẹ́ ìṣàkóso ọlọ́gbọ́n yẹn, kódà, á kọjá ohun táa lè fẹnu sọ! Sáàmù 72:16 sọ pé: “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.” Bẹ́ẹ̀ ni o, oúnjẹ kò tún ní jẹ́ ohun tó ń dá àríyànjiyàn àti ìṣòro sílẹ̀ mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, á máa wà, á sì pọ̀ yanturu.

Torí náà, bí sànmánì táa wà nínú rẹ̀ yìí ti túbọ̀ ń rì sínú ipò ìbànújẹ́, láìsí ìrètí àti ìdánilójú, àwọn tó gbọ́kàn wọn lé Jèhófà lè máa fojú sọ́nà fún ọjọ́ iwájú ológo kan lórí ilẹ̀ ayé níbí. Ìrètí yìí ló wà nínú “ìhìn rere ìjọba” tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fi tìdùnnú-tìdùnnú sọ fún gbogbo àwọn tó fẹ́ ayé kan tó dára jù lọ tó sì bójú mu. (Mátíù 24:14) Ọpẹ́lọpẹ́ ìrètí tó dájú yìí àti bí Ọlọ́run ṣe ń bójú tó àwọn ènìyàn rẹ̀ tó ń ṣe baba fún—èyí tó jẹ́ ká lè ‘gbé nínú ààbò, ká sì bọ́ lọ́wọ́ ìyọlẹ́nu,’ kódà lásìkò táa wà yìí pàápàá.—Òwe 1:33.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, oúnjẹ á máa wà, á sì pọ̀ yanturu

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 8]

Fọ́tò FAO/K. Dunn

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 9]

Iléeṣẹ́ Tó Ń Mójú Tó Ìrìn Àjò Afẹ́ ní Thailand