Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ènìyàn Ti Fìyà Jẹ Ènìyàn Ẹlẹgbẹ́ Rẹ̀

Ènìyàn Ti Fìyà Jẹ Ènìyàn Ẹlẹgbẹ́ Rẹ̀

Ènìyàn Ti Fìyà Jẹ Ènìyàn Ẹlẹgbẹ́ Rẹ̀

Ìtàn ti fi hàn pé òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ tó wà nínú Oníwàásù 8:9, pé: “Ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.” Tàbí gẹ́gẹ́ bí Catholic Jerusalem Bible ṣe sọ, “ènìyàn ti fìyà jẹ ènìyàn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ sí ìpalára rẹ̀.” Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn ni wọ́n ń rẹ́ jẹ lónìí, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ bẹ́ẹ̀ lọ̀ràn rí lábẹ́ gbogbo onírúurú ìjọba tó ti ṣàkóso lé ènìyàn lórí. Ọ̀rọ̀ tí igbákejì akọ̀wé fún Àwọn Ará Íńdíà ní Ẹ̀ka Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Abẹ́lé Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ níbi ayẹyẹ ọdún karùnléláàádọ́sàn-án [175] tí wọ́n dá Ọ́fíìsì Tó Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Àwọn Ará Íńdíà sílẹ̀, ló ránni létí ìjìyà náà.

Ó sọ pé “àkókò tó yẹ ká sọ òkodoro ọ̀rọ̀ rèé, tó yẹ ká ronú pìwà dà ohun tá a ṣe,” kì í ṣe àkókò láti dáwọ̀ọ́ ìdùnnú. Ó sọ pe ohun tí àjọ náà kọ́kọ́ ṣe láwọn ọdún 1830 ni pé wọ́n lé àwọn ẹ̀yà tó wà ní ìhà gúúsù ìlà oòrùn, ìyẹn àwọn ẹ̀yà Cherokee, Creek, Choctaw, Chickasaw, àti ẹ̀yà Seminole, kúrò lórí ilẹ̀ wọn. “Wọ́n lo ìhalẹ̀mọ́ni àti ẹ̀tàn fún wọn, wọ́n sì sọ pé káwọn ẹ̀yà yìí fẹsẹ̀ lásán rin ìrìn ẹgbẹ̀jọ [1,600] kìlómítà gba ìhà ìwọ̀ oòrùn, bí wọ́n ti ń rin Ipa Ọ̀nà Omijé náà lọ ni wọ́n ń sin àwọn arúgbó, àwọn ọmọdé àtàwọn tára wọn ò fi bẹ́ẹ̀ dá tí wọ́n ń kú lójú ọ̀nà sínú àwọn kòtò tí wọ́n ń sáré gbẹ́.”

Ó sọ ọ́ síwájú pé: “Síbẹ̀, lákòókò ọ̀làjú tá a wà yìí, ó yẹ ká mọ̀ pé mímọ̀ọ́mọ̀ tan àrùn kálẹ̀, pípa agbo ẹfọ̀n, fífi ọtí onímájèlé ṣe àwọn èèyàn léṣe, àti pípa àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé ti yọrí sí jàǹbá tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tá ò kàn lè sọ pé wàhálà tó bẹ́ sílẹ̀ láàárín àwọn ará Íńdíà àtàwọn aláwọ̀ funfun ló fà á.” a Ó tún sọ pé: “Àjọ yìí kò tiẹ̀ fẹ́ rí ohunkóhun tó bá ti jẹ́ ti àwọn ará Íńdíà sójú rárá. Ó ní wọn ò gbọ́dọ̀ sọ àwọn èdè ìbílẹ̀ Íńdíà . . . ó sì dójú ti àwọn ará Íńdíà gan-an. Èyí tó burú jù ńbẹ̀ ni pé, Ilé Iṣẹ́ Tó Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Àwọn Ará Íńdíà tún hu ìwà àìdáa yìí sí àwọn ọmọ tó wà lábẹ́ àbójútó wọn, tí wọ́n ń gbé ní ilé ẹ̀kọ́ tó ní ibùgbé. Ilé iṣẹ́ náà tún ṣe àwọn ọmọ wọ̀nyí léṣe nípa tara, ti ìmọ̀lára, ti ìrònú òun ìhùwà, àti nípa tẹ̀mí.”

Ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ẹ jẹ́ ká bẹ̀rẹ̀ nípa kíkẹ́dùn gidigidi fún ohun tí àjọ yìí ti ṣe sẹ́yìn. . . . A ò tún gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ nínú kíkó ẹrù àwọn ará Íńdíà mọ́ láé. . . . A ò tún ní kọ lu ìsìn yín, èdè yín, àwọn ààtò ìsìn yín, tàbí èyíkéyìí nínú àṣà ìbílẹ̀ yín mọ́ láé.” Ó wá sọ ohun kan tó gbàfiyèsí pé: “A gbọ́dọ̀ pawọ́ pọ̀ nu omijé ìran méje tó ti kọjá nù. A gbọ́dọ̀ pawọ́ pọ̀ wo ọkàn wa tó ti gbọgbẹ́ sàn.”—Vital Speeches of the Day, October 1, 2000.

Ìjọba Ọlọ́run ni ojútùú tòótọ́ kan ṣoṣo tó máa wà pẹ́ títí láti yanjú ìwà àìdáa tí ènìyàn ń hù sí ènìyàn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tó máa mú ìdájọ́ òdodo wá fún gbogbo ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ló tún máa “nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:3, 4.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìtàn àwọn Àmẹ́ríńdíà fi hàn pé àwọn ẹ̀yà yìí pàápàá máa ń bára wọn jà, èyí ló mú kí ìjà “lórí ilẹ̀, ẹṣin àti màlúù máa wáyé ní gbogbo ìgbà.”—The People Called Apache.

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 31]

Àwọn ará Íńdíà: Àwòrán tá a gbé ka fọ́tò tí Edward S. Curtis yà; Àwòrán Ilẹ̀: Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.; Ilé àwọn ará Íńdíà: Leslie’s