Ìrànwọ́ fún Àwọn Obìnrin Tí Ọkọ Wọn Ń Lù
Ìrànwọ́ fún Àwọn Obìnrin Tí Ọkọ Wọn Ń Lù
KÍ LA lè ṣe láti ran àwọn obìnrin tí ọkọ wọn ń lù lọ́wọ́? Lákọ̀ọ́kọ́, èèyàn gbọ́dọ̀ mọ ohun tójú wọn ń rí. Lọ́pọ̀ ìgbà, ọṣẹ́ tí ọkọ wọn ti ṣe wọ́n kọjá ti ara lásán. Wọ́n máa ń dẹ́rù ba àwọn obìnrin wọ̀nyí tí wọ́n á sì fẹnu ṣáátá wọn lọ́pọ̀ ìgbà, kí irú àwọn obìnrin bẹ́ẹ̀ lè rò pé àwọn kò já mọ́ nǹkankan pé àwọn ò sì ní olùrànlọ́wọ́.
Wo ti Roxana, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́. Nígbà míì, ọ̀rọ̀ ẹnu lọkọ rẹ̀ máa fi ń ṣe ohun ìjà. Roxana sọ pé: “Orúkọ tí kò yẹ ọmọ èèyàn ló máa ń pè mí. Ó máa ń sọ pé: ‘Ààbọ̀ ẹ̀kọ́ ló ń yọ ẹ lẹ́nu. Bá a bá yọwọ́ tèmi, ṣé o lè dá tọ́jú àwọn ọmọ ni? Ọ̀lẹ afàjò ni ọ́, ìyá lásán. Ṣé o rò pé ìjọba á jẹ́ kó o kó àwọn ọmọ tira bó o bá kọ̀ mí sílẹ̀ ni?’”
Ńṣe ni ọkọ Roxana máa ń fúnka mọ́ owó kí ó sáà lè jẹ́ òun nìkan lọ̀gá. Kò gbà kí ìyàwó rẹ̀ lo ọkọ̀ wọn, ìṣẹ́jú ìṣẹ́jú ló sì máa ń tẹlifóònù ìyàwó rẹ̀ nínú ilé kó lè mọ ohun tíyẹn ń ṣe. Tí obìnrin yìí bá sọ pé ohun báyìí ló dára lójú òun pẹ́nrẹ́n, ńṣe lọkọ rẹ̀ máa gbaná jẹ. Nítorí náà, Roxana kì í tiẹ̀ gbin pínkín pé báyìí ni nǹkan ṣe rí lára òun.
Gẹ́gẹ́ bá a ti lè rí i, ìṣòro ńlá gbáà ni ọ̀ràn fífi ìyà jẹ ìyàwó ẹni o. Láti ran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́, o ní láti tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí wọn. Rántí pé ó máa ń nira gan-an lọ́pọ̀ ìgbà fún ẹni tójú rẹ̀ ń rí màbo yìí láti sọ gbogbo ohun tójú rẹ̀ ń rí. Ohun tí ìwọ gbọ́dọ̀ ní lọ́kàn láti ṣe ni pé kó o fún irú obìnrin bẹ́ẹ̀ lókun tí á fi kojú ìṣòro náà díẹ̀díẹ̀.
Àwọn obìnrin mìíràn tí ọkọ wọn ń lù ní láti kàn sí ìjọba fún ìrànlọ́wọ́. Nígbà mìíràn, bọ́ràn bá di ti ìjọba, bóyá táwọn ọlọ́pàá tiẹ̀ wá dá
sí ọ̀ràn náà, ìyẹn lè jẹ́ kí ọkùnrin náà rí i pé ìwà tóun ń hù kò dára páàpáà. Bó ti wù kó rí, òótọ́ ni pé gbogbo kùrùkẹrẹ tí ọkùnrin náà ń ṣe pé òun fẹ́ yí padà lè wọ̀ ṣin-in bí atẹ́gùn bá ti fẹ́ sí ọ̀ràn náà.Ṣé ó yẹ kí ìyàwó tí ọkọ rẹ̀ ń fìyà jẹ kó kúrò lọ́dọ̀ ọkọ rẹ̀? Bíbélì kò fi ọ̀rọ̀ pé kí ọkọ àti aya fi ara wọn sílẹ̀ ṣe ṣeréṣeré o. Àmọ́ ṣá, kò fi dandan lé e pé ìyàwó tí ọkọ rẹ̀ ń lù tó tiẹ̀ fẹ́ gbẹ̀mí rẹ̀ pàápàá gbọ́dọ̀ jókòó sọ́dọ̀ irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀. Kristẹni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ ọ́ pé: “Bí ó bá lọ ní ti gidi, kí ó wà láìlọ́kọ, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ kí ó parí aáwọ̀ pẹ̀lú ọkọ rẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 7:10-16) Ìgbà tí Bíbélì kò kúkú fòfin dè é pé ọkọ àti aya kò lè pínyà bọ́ràn bá di kàráǹgídá, ìpinnu yòówù kí obìnrin kan ṣe bọ́ràn bá rí báyìí jẹ́ ti ara ẹni. (Gálátíà 6:5) Ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ fúngun mọ́ obìnrin kan pe kí ó kó kúrò lọ́dọ̀ ọkọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ sọ pé kí obìnrin kan dúró sọ́dọ̀ ọkọ rẹ̀ tí ìlera rẹ̀, ìwàláàyè rẹ̀, àti ipò tẹ̀mí obìnrin náà bá wà nínú ewu.
Ǹjẹ́ Àwọn Tó Ń Lu Ìyàwó Wọn Lè Yí Padà?
Títàpá sí ìlànà inú Bíbélì ni àṣà kí ọkùnrin máa lu ìyàwó rẹ̀. A kà á nínú ìwé Éfésù 4:29, 31, pé: “Kí àsọjáde jíjẹrà má ti ẹnu yín jáde . . . Kí ẹ mú gbogbo ìwà kíkorò onínú burúkú àti ìbínú àti ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò lọ́dọ̀ yín pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ìwà búburú.”
Kò sí ọkọ tó máa sọ pé òun ń tẹ̀ lé Kristi táá lè fi gbogbo ẹnu sọ pé òun fẹ́ràn ìyàwó òun tó bá ń fìyà jẹ ẹ́. Kí ló máa jẹ́ àǹfààní gbogbo iṣẹ́ rere mìíràn tó bá ń ṣe nígbà tó jẹ́ pé ó ń fojú ìyàwó rẹ̀ rí màbo? “Aluni” kò tóótun fún àǹfààní àkànṣe èyíkéyìí nínú ìjọ Kristẹni. (1 Tímótì 3:3; 1 Kọ́ríńtì 13:1-3) Àní, ẹnikẹ́ni tó bá sọ pé Kristẹni lòun, tó sì ń bínú ní gbogbo ìgbà láìronúpìwàdà, lè di ẹni tá a yọ kúrò nínú ìjọ Kristẹni.—Gálátíà 5:19-21; 2 Jòhánù 9, 10.
Ǹjẹ́ àwọn ọkùnrin tí wọ́n burú lè yí ìwà wọn padà? Àwọn kan ti ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ bó ti sábàá máa ń rí, ọkùnrin kan tó ń fìyà jẹ ìyàwó rẹ̀ kò lè yí padà àyàfi (1) tó bá gbà pé nǹkan tóun ń ṣe kò dára, (2) tó bá wù ú láti yí padà, àti (3) tó bá wá ìrànlọ́wọ́. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti rí i pé Bíbélì lágbára gan-an láti yí èèyàn padà. Ọ̀pọ̀ àwọn tó fìfẹ́ hàn tí wọ́n sì ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn ló ti wá nífẹ̀ẹ́ láti mú inú Ọlọ́run dùn. Àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yìí kọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run pé “dájúdájú, ọkàn Rẹ̀ kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.” (Sáàmù 11:5) Lóòótọ́, kì í kàn án ṣe pé kí ẹni tó ń lu ìyàwó rẹ̀ tẹ́lẹ̀ máà lù ú mọ́ ló túmọ̀ sí pé ó ti yí padà. Ó tún kan pé kí gbogbo ohun tó ń rò tó sì ń ṣe sí ìyàwó rẹ̀ yí padà.
Nígbà tí ọkùnrin kan bá bẹ̀rẹ̀ sí í gba ìmọ̀ Ọlọ́run, á mọ̀ pé òun kò gbọ́dọ̀ wo ìyàwó òun bí ẹrú, kàkà bẹ́ẹ̀ “olùrànlọ́wọ́” ni. Á mọ̀ pé kì í ṣe ẹni tí kò ní láárí ni ṣùgbọ́n ẹni tí òun gbọ́dọ̀ fi ‘ọlá’ fún. (Jẹ́nẹ́sísì 2:18; 1 Pétérù 3:7) Á tún kọ́ láti jẹ́ oníyọ̀ọ́nú àti pé ó yẹ kóun máa fetí sí ohun tí ìyàwó òun bá ní lọ́kàn. (Jẹ́nẹ́sísì 21:12; Oníwàásù 4:1) Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe ti ran ọ̀pọ̀ tọkọtaya lọ́wọ́. Kò sáyè fún bíbúmọ́ni tàbí àkóso oníwà ìkà nínú ìdílé Kristẹni.—Éfésù 5:25, 28, 29.
“Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára.” (Hébérù 4:12) Nítorí náà, ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì lè ran àwọn lọ́kọláya lọ́wọ́ láti gbé ohun tó jẹ́ ìṣòro wọn yẹ̀ wò fínnífínní á sì tún fún wọn ní ìgboyà láti kojú rẹ̀. Ohun tó tún ju ìyẹn lọ ni pé, ìrètí tó dájú tó sì ń tuni nínú wà nínú Bíbélì, ìyẹn nípa rírí ayé kan tí kò ti ní sí ìwà ipá, níbi tí Ọba ọ̀run ti Jèhófà yóò ti máa ṣàkóso lórí gbogbo ìran ènìyàn onígbọràn. Bíbélì sọ pé: “Òun yóò dá òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè, ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ pẹ̀lú, àti ẹnì yòówù tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Yóò tún ọkàn wọn rà padà lọ́wọ́ ìnilára àti lọ́wọ́ ìwà ipá.”—Sáàmù 72:12, 14.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 12]
Kò sáyè fún bíbúmọ́ni tàbí àkóso oníwà ìkà nínú ìdílé Kristẹni
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8]
Èrò Táwọn Kan Ní Kò Tọ̀nà O
• Àwọn obìnrin táwọn ọkọ wọn máa ń lù ló ń fà á.
Ọ̀pọ̀ àwọn ọkùnrin tó ń lu ìyàwó wọn ló sọ pé kì í ṣe ẹ̀bi àwọn, pé ìyàwó àwọn ló múnú bí àwọn. Kódà àwọn ọ̀rẹ́ wọn pàápàá lè gba ohun tí ọkọ náà sọ gbọ́ pé obìnrin náà ló ya pamí-n-kú aya, pé ìyẹn ló mú kí ọkọ máa fìyà jẹ ẹ́ nígbà gbogbo. Àmọ́ ńṣe ni wọ́n ń gbé ẹ̀bi fún aláre. Ká sòótọ́, àwọn ìyàwó tí ọkọ wọn ń lù yìí máa ń forí ṣe fọrùn ṣe láti tu ọkọ wọn lójú. Yàtọ̀ síyẹn gan-an, ìwà àìdáa gbáà ni kéèyàn máa fìyà jẹ ìyàwó rẹ̀. Ìwé The Batterer—A Psychological Profile sọ pé: “Àwọn ọkùnrin tí ilé ẹjọ́ ní kí wọ́n lọ gba ìtọ́jú kí wọ́n lè ṣíwọ́ lílu ìyàwó wọn jẹ́ àwọn tí ìwà ipá ti wọ̀ lẹ́wù. Wọ́n máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ kí inú tó ń bí wọn àti ìsoríkọ́ wọn bàa lè lọ, òun ni wọ́n fi ń pa ìrònú rẹ́, òun ni wọ́n sì fi ń yanjú aáwọ̀. . . . Ọ̀pọ̀ ìgbà tiẹ̀ ni wọn kì í mọ̀ pé àwọn ni ọ̀dádá tó ń dá wàhálà sílẹ̀, wọn kì í sì í ka ìṣòro náà sí ohun bàbàrà.”
• Ọtí líle ló ń mú kí ọkùnrin máa lu ìyàwó rẹ̀.
Òótọ́ ni pé ìwà ipá àwọn ọkùnrin kan kúrò ní kèrémí nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í mutí. Àmọ́ ṣé ọtí líle ló wá yẹ ká bá wí? K. J. Wilson, kọ ọ́ nínú ìwé rẹ̀ When Violence Begins at Home pé: “Ọtí tí ẹni tó ń lu ìyàwó rẹ̀ mu yó á jẹ́ kó rí nǹkan parọ́ mọ́ pé òun ló jẹ́ kóun hùwà tí òun hù.” Ó tún sọ pé: “Ó dà bí ẹni pé nínú àwùjọ wa, ìwà ipá nínú ilé dùn ún gbọ́ sétí tó bá jẹ́ pé ẹni tó mutí yó ló hù ú. Obìnrin tí ọkọ rẹ̀ ń lù lè máà ka ọkọ rẹ̀ sí ẹni tó lè ṣe é léṣe, kàkà bẹ́ẹ̀ ó lè kà á sí pé ọtí ìmukúmu tó ń mu ló ń fà á.” Wilson wá sọ pé irú èrò bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ kí obìnrin kan máa fojú síbi tí ọ̀nà kò sí pé “bí ọkùnrin náà bá lè jáwọ́ ọtí mímú báyìí, kò ní hu ìwà ipá mọ́.”
Ní báyìí, ọ̀pọ̀ àwọn olùwádìí ka ọtí mímu àti lílu ìyàwó ẹni sí ohun méjì tó yàtọ̀ síra wọn. Ó ṣe tán, èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ọkùnrin tó ń lo oògùn olóró ni kì í lu ìyàwó wọn. Àwọn òǹkọ̀wée When Men Batter Women sọ pé: “Ohun tó ń jẹ́ kí lílu ìyàwó ẹni máa bá a lọ ni pé, ẹni tó ń ṣe bẹ́ẹ̀ ń lò ó láti jẹ gàba lé ìyàwó rẹ̀ lórí, láti tẹ́ ẹ, àti láti fi halẹ̀ mọ́ ọn. . . . Ẹni tó ń lu ìyàwó rẹ̀ yìí kì í fi ọtí líle àti oògùn olóró ṣeré rárá. Àmọ́ àṣìṣe ńlá gbáà ló máa jẹ́ tá a bá rò pé ọtí líle àti oògùn olóró tó ń lò ló ń fa ìwà ipá yìí.”
• Bákan náà làwọn tó ń lu ìyàwó wọn ṣe ń hùwà ipá sí gbogbo èèyàn.
Ọkùnrin tó ń lu ìyàwó rẹ̀ sábàá máa ń hùwà ọmọlúwàbí sáwọn mìíràn. Ìwà rẹ̀ á wá yàtọ̀ pátápátá. Èyí ni kì í jẹ́ káwọn ọ̀rẹ́ wọn lè gbà pé lóòótọ́ ló ń lu ìyàwó rẹ̀. Àmọ́, òtítọ́ ibẹ̀ ni pé ńṣe lẹni tó ń lu ìyàwó rẹ̀ yìí ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ láti fi jẹ gàba lórí ìyàwó rẹ̀.
• Àwọn obìnrin kì í ké gbàjarè tí ọkọ wọn bá ń lù wọ́n.
Àfàìmọ̀ ni kò ní jẹ́ pé bí àwọn èèyàn ò ṣe lóye ipò irú obìnrin bẹ́ẹ̀ ló mú kí wọ́n lérò yìí, ẹni ẹlẹ́ni tí kò síbi tó máa sá gbà. Obìnrin tí ọkọ rẹ̀ ti lù yìí lè ní àwọn ọ̀rẹ́ tó lè gbà á sọ́dọ̀ fún ọ̀sẹ̀ kan tàbí méjì, àmọ́ kí ló máa ṣe lẹ́yìn èyí? Àtiwá iṣẹ́, kó máa sanwó ilé, kó sì tún máa tọ́jú àwọn ọmọ lè di nǹkan tá á máa dà á lọ́kàn rú. Òfin sì lè má gbà á láyè láti kó àwọn ọmọ sá lọ. Àwọn kan tiẹ̀ ti sá lọ rí, àmọ́ ọkọ wọn wá wọn kàn ó sì mú wọn padà, yálà ní tipátipá tàbí lẹ́yìn tí ọkọ bẹ̀bẹ̀. Àwọn ọ̀rẹ́ tí ọ̀rọ̀ náà kò yé lè máa rò pé ńṣe ni irú àwọn obìnrin bẹ́ẹ̀ kò ké gbàjarè nítorí ìyà tí ọkọ wọn fi ń jẹ wọ́n.