Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Òfo ni Àyẹ̀wò Ọ̀hún Já Sí’

‘Òfo ni Àyẹ̀wò Ọ̀hún Já Sí’

‘Òfo ni Àyẹ̀wò Ọ̀hún Já Sí’

LÁYÉ òde òní tí ayé ti lu jára, àwọn kan sọ pé ńṣe ni àlàfo tó wà láàárín àwọn ọlọ́rọ̀ àti tálákà túbọ̀ ń fẹ̀ sí i. Nígbà tí ẹgbẹ́ kan tó ń jà fẹ́tọ̀ọ́ àwọn èèyàn kárí ayé ń sọ̀rọ̀ nípa akitiyan láti mú ètò ọrọ̀ ajé ṣọ̀kan kárí ayé, ó sọ pé: “Lẹ́yìn àádọ́ta ọdún tá a ti ń gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò, kò tí ì lójú. Dípò tí ì bá fi ṣe ètò ọrọ̀ ajé gbogbo mùtúmùwà láǹfààní, ó ti fẹ́ fa ìṣẹ̀lẹ̀ aburú fún gbogbo ayé, rìgbòrìyẹ̀ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà tí kò sírú rẹ̀ rí la ń rí, ètò ọrọ̀ ajé ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ti dorí kodò, ipò òṣì ńbẹ, ebi, àìrí ilẹ̀ lò, ìṣòro ṣíṣí kúrò ní orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn náà wà, a sì ti sọ àwùjọ dìdàkudà. A ò ṣì sọ bí a bá sọ pé òfo ni àyẹ̀wò ọ̀hún já sí.”

Kí ló dé? Kò sọ́gbọ́n kó máà sí ìpalára, tó bá jẹ́ pé àwọn nǹkan onímọtara-ẹni-nìkan lèèyàn ń lépa. George Soros, tó jẹ́ ọ̀gá kan níbi ìdókòwò sọ pé: “Ètò ọrọ̀ ajé níbi gbogbo lágbàáyé ti sọ gbogbo nǹkan, tó fi dórí ẹ̀dá ènìyàn àti àwọn ẹ̀dá mìíràn di ohun téèyàn kàn lè rà tàbí kéèyàn kàn lù tà.” Àìpé ẹ̀dá náà kò tún gbẹ́yìn o. Láti fi hàn pé òun fara mọ́ èrò onímọ̀ ọgbọ́n orí náà Karl Popper, Soros sọ pé: “Òye tá a ní kò gbòòrò tó bó ti yẹ rárá; ọwọ́ wa ò sì lè tó ògidì òtítọ́ àti ọgbọ́n tí àwùjọ nílò.”

Ètò ọrọ̀ ajé tí kò bára dé kì í ṣohun tuntun. Ọ̀rúndún mẹ́jọ ṣáájú kí Kristi tó ó wá sáyé, òǹkọ̀wé Bíbélì kan sọ̀rọ̀ nípa àwọn “tí ó ń lu àwọn ẹni rírẹlẹ̀ ní jìbìtì, tí ó ń ni àwọn òtòṣì lára.” (Ámósì 4:1) Nígbà tí ọ̀gbẹ́ni kan láyé ọjọ́un kíyè sí irú ìṣègbè kan náà, ló mú kó kọ ọ́ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3,000] ọdún sẹ́yìn pé: “Ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.”—Oníwàásù 8:9.

Kí wá lojútùú báyìí? Ǹjẹ́ ẹ̀dá ènìyàn lè gbáwọ́ jọ pọ̀ láti yanjú àìbáradé ètò ọrọ̀ ajé tó ti di ńlá yìí? Soros sọ pé: “Àwọn àjọ tó ń dáàbò bo òmìnira kálukú, ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, ààbò àyíká tàbí tó ń gbé àìṣègbè láwùjọ lárugẹ tá a ní kò pọ̀ tó, ká máà tíì mẹ́nu kan èyí tó máa pa àlàáfíà mọ́. Ọ̀pọ̀ àwọn àjọ tá a ní ló jẹ́ tàwọn ẹgbẹ́ òṣèlú, ire tara wọn ni wọ́n sì kọ́kọ́ máa ń dù kó tó kan tàwọn gbáàtúù. Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè kò sì lágbára láti ṣe àwọn ohun tó fi ṣáájú nínú ìwé tó fi ṣàlàyé ète rẹ̀.”

Ṣó wá yẹ ká sọ̀rètí nù ni? Rárá o. Ìjọba òdodo mà ti wà nítòsí! Òun gan-an ni Jésù fi ṣe ẹṣin ọ̀rọ̀ ìwàásù rẹ̀. Ó pè é ní “ìjọba Ọlọ́run,” ó sì kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti gbàdúrà fún un. (Lúùkù 11:2; 21:31) A ti gbé Ìjọba Ọlọ́run kalẹ̀ ní ọ̀run, ó sì máa tó mú gbogbo ìṣègbè tó wà lórí ilẹ̀ ayé yìí kúrò. (Ìṣípayá 11:15, 18) Ìjọba Ọlọ́run kò ní jẹ́ ìṣàkóso tí a fi ń ṣe ìdánrawò bóyá á lè gbéṣẹ́, ńṣe ló máa wà títí láé. (Dáníẹ́lì 2:44) Ó máa yanjú ìṣòro ipò òṣì àti ìnilára, wọn ò ní sí mọ́ títí láé. Ìfojúsọ́nà tó ga lọ́lá mà lèyí jẹ́ fún àwọn òtòṣì àtàwọn tí a ń ni lára o, àní fún gbogbo ènìyàn pàápàá!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Ètò ọrọ̀ ajé kárí ayé kò tíì yanjú ìṣòro àwọn òtòṣì, ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù ni kò sí omi ẹ̀rọ nínú ilé wọn tí wọ́n ò sì ní iná mànàmáná