Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Lílò Tí Ọlọ́run Ń Lo Agbára Rẹ̀ Láti Pa Àwọn Ẹni Ibi Run Tọ̀nà?

Ṣé Lílò Tí Ọlọ́run Ń Lo Agbára Rẹ̀ Láti Pa Àwọn Ẹni Ibi Run Tọ̀nà?

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ṣé Lílò Tí Ọlọ́run Ń Lo Agbára Rẹ̀ Láti Pa Àwọn Ẹni Ibi Run Tọ̀nà?

ÀTÌGBÀDÉGBÀ nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn làwọn èèyàn ti máa ń fi agbára wọn pa àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn nípakúpa. Àwọn kan fojú díwọ̀n rẹ̀ pé, nǹkan bí àádọ́sàn-án [170] mílíọ̀nù àwọn èèyàn ni àwọn ìjọba tó ń ṣàkóso lé wọn lórí ṣekú pa ní ọ̀rúndún ogún. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ ọ́ gan-an ló rí pé ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.—Oníwàásù 8:9.

Nítorí pé ènìyàn ń lo agbára rẹ̀ nílòkulò yìí, àwọn kan lè bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé kí ló dé tí Ọlọ́run náà máa ń fi agbára rẹ̀ pa àwọn ọ̀tá rẹ̀ run. Ṣé kì í ṣe Ọlọ́run ló pàṣẹ fáwọn Júù pé kí wọ́n kọ lu àwọn ará Kénáánì tó wà ní Ilẹ̀ Ìlérí kí wọ́n sì pa wọ́n run ni? (Diutarónómì 20:16, 17) Àbí Ọlọ́run kọ́ ló fúnra rẹ̀ sọ pé òun máa fọ́ àwọn ìjọba tó ń ta kò òun túútúú, òun á sì fòpin sí wọ́n? (Dáníẹ́lì 2:44) Àwọn èèyàn olóòótọ́ kan ti ṣe kàyéfì pé bóyá gbogbo ìgbà kọ́ ni lílò tí Ọlọ́run ń lo agbára rẹ̀ láti pa àwọn ẹni ibi run tọ̀nà.

Ṣíṣi Agbára Lò

Ó yẹ ká mọ̀ pé lílo agbára ṣe pàtàkì nínú ìjọba. Ìjọba yẹ̀bùyẹ́bù ni ìjọba tí kò bá lè mú káwọn èèyàn tẹ̀ lé àwọn òfin rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, èèyàn mélòó ló máa sọ pé òun ò fẹ́ ààbò àwọn ọlọ́pàá nítorí tí ó gbọ́ pé wọ́n máa ń ṣe èèyàn níṣekúṣe? Tàbí èèyàn tí orí rẹ̀ pé wo ló máa sọ pé kò sídìí fún gbígbé òfin ró láwùjọ ẹ̀dá?

Mohandas Gandhi, táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹni mowó pé ó kórìíra ìwà ipá gan-an, sọ nígbà kan pé: “Ká ní ẹnì kan ya wèrè tó sì bẹ̀rẹ̀ sí já ṣòòròṣò káàkiri tòun ti idà lọ́wọ́, tó ń pa ẹnikẹ́ni tó bá rí tí kò sì sẹ́ni tó lè sún mọ́ ọn. Gbogbo ará ìlú ni á máa gbóṣùbà fún ẹni tó ba lè mú wèrè yìí balẹ̀ tí wọ́n á sì máa ka irú ẹni bẹ́ẹ̀ sí ẹnì iyì òun ẹ̀yẹ.” Ẹ ò rí nǹkan, Gandhi fúnra rẹ̀ rí i pé àwọn ọ̀ràn kan wà nínú èyí tó ti yẹ kéèyàn lo agbára.

Ó hàn fún aráyé rí pé lílo agbára ṣe kókó kí àwùjọ ba lè rójú kí ó sì ní àlàáfíà. Níbi gbogbo, bí àwọn èèyàn bá fárígá pé àwọn ò fẹ́ kí ẹnì kan ló agbára lórí àwọn, ó dájú pé àṣìlò agbára ni wọ́n ń sọ.—Oníwàásù 4:1-3.

“Gbogbo Ọ̀nà Rẹ̀ Jẹ́ Ìdájọ́ Òdodo”

A kò rí ẹ̀rí rẹ̀ nínú ìtàn pé Ọlọ́run lo agbára rẹ̀ nílòkulò rí. Kì í ṣàkóso bóofẹ́-bóokọ̀ lé àwọn ènìyàn lórí. Ó fẹ́ kí ìfẹ́ tá a ní láti jọ́sìn rẹ̀ wá látinú wa. (1 Jòhánù 4:18, 19) Kódà, bí ọ̀nà tó bẹ́tọ̀ọ́ mu mìíràn bá wà tí Ọlọ́run lè lò láti ṣe ohun kan, kò jẹ́ lo ipá. (Jeremáyà 18:7, 8; 26:3, 13; Ìsíkíẹ́lì 18:32; 33:11) Bó bá sì wá fẹ́ lo agbára rẹ̀, ó kọ́kọ́ máa ń ṣe ìkìlọ̀ ṣáájú àkókò káwọn tó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ lè ṣàtúnṣe. (Ámósì 3:7; Mátíù 24:14) Ǹjẹ́ tí Ọlọ́run bá jẹ́ òǹrorò àti aláṣẹ bóofẹ́-bóokọ̀, ṣe ó máa ṣe gbogbo ìkìlọ̀ wọ̀nyẹn?

Fífi tí Ọlọ́run ń fi agbára rẹ̀ pa àwọn ẹni búburú kò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú lílò tí ẹ̀dá ènìyàn ti lo agbára wọn nílòkulò. Mósè sọ nípa Jèhófà pé: “Gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo. Ọlọ́run ìṣòtítọ́, ẹni tí kò sí àìṣèdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ rẹ̀.” (Diutarónómì 32:4) Ìjọba Ọlọ́run kò dà bíi ti ẹ̀dá ènìyàn tí kò lójú àánú, tó jẹ́ pé ẹni tó bá lágbára àtiṣèjọba ló ń ṣe é. Ní gbogbo ibi tó ti lo agbára rẹ̀ ló ti lò ó pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀ pípé, ọgbọ́n àti àìṣègbè.—Sáàmù 111:2, 3, 7; Mátíù 23:37.

Fún àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí Ọlọ́run ti fi ọ̀pọ̀ ọdún kìlọ̀ fún àwọn èèyàn búburú ló tó fi Ìkún Omi pa wọ́n dànù. Ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ ì bá ti lo àǹfààní ààbò ọkọ̀ Nóà, ì bá má sì kú. Ìwọ̀nba èèyàn mẹ́jọ péré ló ṣe bẹ́ẹ̀. (1 Pétérù 3:19, 20; 2 Pétérù 2:5) Nígbà ayé Jóṣúà, Ísírẹ́lì mú ìdájọ́ Ọlọ́run ṣẹ sórí àwọn ará Kénáánì tí wọ́n ti ya ìyàkuyà, Ọlọ́run sì ti kéde ìdájọ́ ní ohun tó lé ní irínwó ọdún ṣáájú! (Jẹ́nẹ́sísì 15:13-21) Ní gbogbo àkókò yẹn, àwọn ará Kénáánì kò lè sọ pé àwọn ò rí ẹ̀rí lílágbára tó fi hàn pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì làwọn èèyàn tí Ọlọ́run yàn. (Jóṣúà 2:9-21; 9:24-27) Síbẹ̀, kò sí ẹnì kankan ní ilẹ̀ Kénáánì yàtọ̀ sáwọn ará Gíbéónì tó bẹ̀bẹ̀ fún àánú tàbí tó lo àǹfààní tí wọ́n ní láti wá àlàáfíà. Dípò ìyẹn, ńṣe làwọn ọmọ Kénáánì kó agídí borí, tí wọ́n sé ọkàn wọn le sí Ọlọ́run.—Jóṣúà 11:19, 20.

Àṣẹ Ń Bẹ Lọ́wọ́ Ọlọ́run

Bá a bá fẹ́ lóye bí Ọlọ́run ṣe ń lo agbára rẹ̀, a gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn òtítọ́ tó jẹ́ ìpìlẹ̀ nípa bá a ṣe jẹ́ sí Ọlọ́run. Wòlíì Aísáyà fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ sọ pé: “Àwa ni amọ̀, ìwọ sì ni Ẹni tí ó mọ wá.” (Aísáyà 64:8) Ó ṣe kedere pé Ọlọ́run lè lo agbára rẹ̀ lọ́nà tó bá wù ú nítorí pé òun ni Ẹlẹ́dàá láyé lọ́run. Bá a bá ti gbà pé Ọlọ́run lè lo àṣẹ rẹ̀ bó bá ṣe wù ú, àwa náà á lè sọ bíi ti Sólómọ́nì pé: “Ọ̀rọ̀ ọba ni agbára àkóso; ta sì ni ó lè sọ fún un pé: ‘Kí ni ìwọ ń ṣe?’”—Oníwàásù 8:4; Róòmù 9:20, 21.

Nítorí pé Ọlọ́run ni Aṣẹ̀dá, tí agbára tó ju agbára lọ sì ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀, ó lè sọ pé kí ìwàláàyè wà lórí ilẹ̀ ayé tàbí kó máà sí. Àní, ẹ̀dá èèyàn kò lẹ́mìí rẹ̀ láti ṣe gbọ́ńkú-gbọ́ńkú sí Ọlọ́run pé kí ló dé tó fi lo agbára rẹ̀ bó ṣe lò ó. Ẹ̀dá ènìyàn gbọ́dọ̀ kọ́ láti mú èrò rẹ̀ bá ti Ọlọ́run mu. Jèhófà béèrè pé: “Kì í ha ṣe àwọn ọ̀nà tiyín ni kò gún?”—Ìsíkíẹ́lì 18:29; Aísáyà 45:9.

Ànímọ́ ìdájọ́ òdodo tí Jèhófà ní àti ìfẹ́ tó fi hàn sí àwọn ènìyàn ló máa mú kó pa gbogbo àwọn tó ń lo agbára wọn nílòkulò tí wọ́n sì ń tẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìkejì wọn lójú run lórí ilẹ̀ ayé. Lílo agbára náà lọ́nà yìí ló máa mú kí ipò tó dára wà lórí ilẹ̀ ayé fún gbogbo ẹ̀dá ènìyàn tó fẹ́ràn àlàáfíà. (Sáàmù 37:10, 11; Náhúmù 1:9) Èyí á jẹ́ ká gbà pé ìjọba Ọlọ́run ń ṣe ohun tó tọ́, a ó sì máa dá a láre títí láé.—Ìṣípayá 22:12-15.