Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ló Ṣe Yẹ Káwọn Òbí Máa Bá Àwọn Ọmọ Wọn Wí?

Báwo Ló Ṣe Yẹ Káwọn Òbí Máa Bá Àwọn Ọmọ Wọn Wí?

Báwo Ló Ṣe Yẹ Káwọn Òbí Máa Bá Àwọn Ọmọ Wọn Wí?

Ìwé ìròyìn National Post ti Kánádà sọ pé “ohun tó ń fa ìṣòro ni bí àwọn òbí ṣe máa ń kan sáárá sáwọn ọmọ ṣáá láìka ohun yòówù kí wọ́n ṣe sí.” Àwọn òbí kan rò pé irú ìwà yìí máa ń jẹ́ káwọn ọmọ wọn mọ̀ pé àwọn gbayì. Àmọ́ ṣá, gẹ́gẹ́ bí afìṣemọ̀rònú Roy Baumeister ṣe sọ, “kò sóhun tó burú nínú kéèyàn nímọ̀lára pé òun gbayì tó bá jẹ́ nítorí àṣeyọrí kan tó ṣe ni, àmọ́ àwọn òbí gbọ́dọ̀ gbájú mọ́ kíkọ́ àwọn ọmọ láti lè kóra wọn níjàánu.”

Ìpalára ńlá ni òbí tó bá ń bẹ̀rù àtibá ọmọ rẹ̀ wí, bí ọmọdé náà bá ṣe ohun tí kò tọ́, ń ṣe fún ọmọ náà o. Ó ṣe tán, ìtọ́sọ́nà ni ìbáwí jẹ́. Nípa bẹ́ẹ̀, ń ṣe ló ń kọ́ ọmọ kan tó ti hùwà tí kò dáa láti má ṣe ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́. Lóòótọ́, àwọn òbí gbọ́dọ̀ ṣọ́ra láti má ṣe jẹ́ kí ìbáwí náà le koko jù kí wọ́n sì rí i dájú pé àṣìṣe tí ọmọ kan ṣe gan-an ni wọ́n bá a wí fún. (Jeremáyà 46:28) Wọ́n gbọ́dọ̀ rí i dájú pé ìbáwí náà kò kọjá ààlà. Bíbélì sọ pé: “Ẹ̀yin baba, ẹ má ṣe máa dá àwọn ọmọ yín lágara, kí wọ́n má bàa soríkodò.”—Kólósè 3:21.

Nínú Bíbélì, léraléra ni a so ìbáwí pọ̀ mó ìfẹ́ àti ìwàtútù, a kò so ó pọ̀ mọ́ ìbínú àti ìwà òǹrorò. Olùgbani-nímọ̀ràn tó mọṣẹ́ dáadáa gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni “pẹ̀lẹ́ sí gbogbo ènìyàn, . . . tí ń kó ara rẹ̀ ní ìjánu lábẹ́ ibi, kí ó máa fún àwọn tí kò ní ìtẹ̀sí ọkàn rere ní ìtọ́ni pẹ̀lú ìwà tútù.” (2 Tímótì 2:24, 25) Nítorí náà, ìbáwí látọ̀dọ̀ àwọn òbí kò kàn gbọ́dọ̀ jẹ́ láti fi bí ọ̀ràn ṣe dùn wọ́n tó hàn. Bíbélì kò fọwọ́ sí pé káwọn òbí bá ọmọ wọn wí lọ́nà tó máa ṣèpalára fún wọn.

Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn káàkiri àgbáyé ló ti jàǹfààní nínú ìwé olójú ìwé 192 náà, Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. Lára àwọn àkòrí tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ nínú rẹ̀ ni: “Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Ìgbà Ọmọdé Jòjòló” àti “Ran Ọ̀dọ́langba Rẹ Lọ́wọ́ Láti Ṣàṣeyọrí.” O lè béèrè fún ẹ̀dà kan nípa kíkàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí, kí o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó yẹ lára èyí tí a tò sí ojú ìwé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí. Wà á rí àwọn àbá tó ṣe sàn-án tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti yanjú ìṣòro tá á sì mú kí ìgbésí ayé ìdílé rẹ lárinrin gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá ti fẹ́ kó rí.

□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.