Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Bí Àlá Ló Máa Ń Rí Lójú Mi Nígbà Míì!”

“Bí Àlá Ló Máa Ń Rí Lójú Mi Nígbà Míì!”

“Bí Àlá Ló Máa Ń Rí Lójú Mi Nígbà Míì!”

Lourdes ń wo bí ìlú ṣe rí lọ láti ojú fèrèsé ilé rẹ̀, ó fọwọ́ bo ẹnu rẹ̀ tó ń gbọ̀n pẹ̀pẹ̀. Ọmọ orílẹ̀-èdè Látìn-Amẹ́ríkà ni, ó lé ní ogún ọdún tó fi jẹ palaba ìyà lọ́wọ́ ọkọ rẹ̀ Alfredo, tó jẹ́ oníwà ipá. Alfredo mà yí padà o. Síbẹ̀, ẹnu Lourdes kò lè sọ ohun tójú rẹ̀ kàn àti palaba ìyà tó fara dà.

Lourdes fohùn jẹ́jẹ́ sọ pé: “Ọ̀sẹ̀ méjì péré lẹ́yìn tá a fẹ́ra wa lọ̀rọ̀ náà bẹ̀rẹ̀. Ìgbà kan wà tó fi ẹ̀ṣẹ́ yọ eyín mi méjì. Lákòókò mìíràn, ó ju ẹ̀ṣẹ́ sí mi, àmọ́ mo yẹ̀ ẹ́, ó sì fọwọ́ gbá àpótí aṣọ dá lu. Àmọ́ àwọn orúkọ burúkú tó máa ń pè mí ló dùn mí jù. Ó máa ń pè mí ní ‘akídanidání’ ó sì máa ń hùwà sí mi bí ẹni pé mi ò tiẹ̀ ní ọpọlọ. Mo fẹ́ kó jáde, àmọ́ báwo ni mo ṣe lè kó jáde pẹ̀lú ọmọ mẹ́ta?”

Alfredo rọra gbé ọwọ́ lé èjìká Lourdes. Ó sì sọ pé: “Ọ̀gá kan tó mọṣẹ́ dunjú ni mí. Ńṣe ló dà bí ẹni pé wọ́n fi ìwọ̀sí lọ̀ mí nígbà tí ilé ẹjọ́ ní kí n wá, tó sì pa á láṣẹ fún mi pé mi ò gbọ́dọ̀ tún lu ìyàwó mi mọ́. Mo gbìyànjú láti yí padà, àmọ́ kò pẹ́ tí mo tún bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun kan náà.”

Báwo ni nǹkan ṣe wá yí padà? Lourdes, tára rẹ̀ ti wá balẹ̀ báyìí ṣàlàyé pé: “Obìnrin kan tó wà nílé ìtajà ní òpópó wa jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó sọ pé òun á ràn mí lọ́wọ́ láti lóye Bíbélì. Mo kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà Ọlọ́run kò fọ̀rọ̀ àwọn obìnrin ṣeré rárá. Mo bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Alfredo kọ́kọ́ gbaná jẹ nítorí èyí. Ìrírí tuntun ló jẹ́ fún mi láti wà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Kàyéfì gbáà ló jẹ́ fún mi láti mọ̀ pé mo lè dá ní ìgbàgbọ́ tèmi, kí n sọ ọ́ jáde bó bá ṣe wù mí, kí n tiẹ̀ tún fi kọ́ àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú. Mo wá rí i pé Ọlọ́run kà mí sí. Èyí fún mi ní ìgboyà.

“Ìyípadà kan ṣẹlẹ̀ tí mi ò lè gbàgbé láé. Alfredo ṣì ń lọ sí Máàsì Kátólíìkì ní ọjọọjọ́ Sunday, ó sì yarí nítorí ohun tí mò ń ṣe pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Mo tẹjú mọ́ ọn, mo sì fohùn pẹ̀lẹ́ sọ pé: ‘Alfredo, ohun tó o ń rò kọ́ lèmi ń rò o.’ Kò mà gbá mi lẹ́ṣẹ̀ẹ́ o! Kò pẹ́ sígbà yẹn ni mo ṣe ìrìbọmi, kò sì tí ì tún lù mí fún odindi ọdún márùn-ún láti ìgbà yẹn.”

Àmọ́ kékeré ni ìyípadà ti mo ṣì rí. Alfredo ṣàlàyé pé: “Lẹ́yìn nǹkan bí ọdún mẹ́ta tí Lourdes ṣèrìbọmi, ẹnì kan tá a jọ ń ṣiṣẹ́ tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pè mí wálé rẹ̀, ó sì ṣàlàyé àwọn nǹkan tó fà mí lọ́kàn mọ́ra fún mi látinú Bíbélì. Mo bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ rẹ̀ láìsọ fún ìyàwó mi. Láìpẹ́, mo bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀ lé Lourdes lọ sáwọn ìpàdé. Èyí tó pọ̀ lára àwọn àsọyé tí mo gbọ́ níbẹ̀ ló dá lórí ìgbésí ayé ìdílé, èyí sì máa ń mú kí ojú tì mí lọ́pọ̀ ìgbà.”

Ó ya Alfredo lẹ́nu láti rí bí àwọn tó wà nínú ìjọ, tó fi dórí àwọn ọkùnrin ṣe ń gbálẹ̀ lẹ́yìn ìpàdé. Tó bá lọ kí wọn nílé, ó máa ń rí bí àwọn ọkọ ṣe máa ń bá ìyàwó wọn fọ abọ́. Àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ yìí jẹ́ kí Alfredo rí i béèyàn ṣe ń fi ìfẹ́ tòótọ́ hàn.

Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni Alfredo ṣèrìbọmi, ní báyìí, òun àti ìyàwó rẹ̀ ń sìn bí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Lourdes sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń bá mi palẹ̀ tábìlì mọ́ lẹ́yìn oúnjẹ ó sì máa ń bá mi tẹ́ bẹ́ẹ̀dì. Ó máa ń yìn mí pé mo mọ oúnjẹ sè, ó sì máa ń fún mi láyè láti sọ ohun tó bá wù mí, bí irú orin tí mo fẹ́ gbọ́ tàbí irú àwọn ohun wo ni màá fẹ́ kí á rà sílé. Tẹ́lẹ̀, Alfredo kò jẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀! Láìpẹ́ yìí, ó ra òdòdó fún mi fún ìgbà àkọ́kọ́. Bí àlá ló máa ń rí lójú mi nígbà míì!”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

“Mo wá rí i pé Ọlọ́run kà mí sí. Èyí ló fún mi ní ìgboyà”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ó ya Alfredo lẹ́nu láti rí i bí àwọn ará inú ìjọ, títí kan àwọn ọkùnrin, ṣe ń gbálẹ̀ lẹ́yìn ìpàdé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ó rí i bí àwọn ọkọ ṣe ń bá àwọn ìyàwó wọn fọ àwo

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

“Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ó ra òdòdó fún mi fún ìgbà àkọ́kọ́”