Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Bóyá Ó Máa Yí Padà Lọ́tẹ̀ Yìí”

“Bóyá Ó Máa Yí Padà Lọ́tẹ̀ Yìí”

“Bóyá Ó Máa Yí Padà Lọ́tẹ̀ Yìí”

ARA Roxana a yá mọ́ èèyàn, arẹwà obìnrin ni, ó sì lọ́mọ mẹ́rin, oníṣègùn iṣẹ́ abẹ tó gbayì gan-an lọkọ rẹ̀ ní Gúúsù Amẹ́ríkà. Obìnrin yìí sọ pé: “Àwọn obìnrin fẹ́ràn ọkọ mi gan-an, àwọn ọkùnrin pẹ̀lú sì gba tiẹ̀.” Àmọ́ ohun kan ba ọkọ Roxana jẹ́, ohun táwọn ọ̀rẹ́ wọn tímọ́tímọ́ pàápàá kò mọ̀. “Kìnnìún ni lọ́dẹ̀dẹ̀. Òjòwú pọ́ńbélé sì ni.”

Àìbalẹ̀ ọkàn hàn lójú Roxana bó ṣe ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ. “Kò ju ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan lọ tá a ṣègbéyàwó ni ìṣòro náà bẹ̀rẹ̀. Àwọn àbúrò mi ọkùnrin àti ìyá mi wá kí wa, a jọ ṣeré tá a sì gbádùn ara wa dáadáa. Àmọ́ nígbà tí wọ́n lọ tán, tìbínú-tìbínú lọkọ mi fi jù mí lu àga ìjókòó, ìbínú ti ru bò ó lójú. Bí àlá lọ̀rọ̀ ọ̀hún ṣe rí lójú mi.”

Ó mà ṣe o, bí wàhálà Roxana ṣe bẹ̀rẹ̀ wẹ́rẹ́ nìyẹn o, fún ọ̀pọ̀ ọdún lọkọ rẹ̀ ti lù ú léraléra nílù bàrà. Ńṣe ni Roxana máa ń jìyà ní àjẹ-ǹjẹ-tún-jẹ. Ọkọ rẹ̀ á nà án, lẹ́yìn náà láá wá bẹ̀ ẹ́ gan-an pé òun ò tún ní ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́ láé. Ó máa ń tọwọ́ ọmọ rẹ̀ baṣọ fún ìgbà díẹ̀. Àmọ́ bó bá ṣe sàà, wàhálà ọ̀hún á tún bẹ̀rẹ̀. Roxana sọ pé: “Ohun tí mo máa ń rò ni pé bóyá ó máa yí padà lọ́tẹ̀ yìí. Kódà bí mo bá sá kúrò nílé pàápàá, màá tún padà lọ bá a.”

Ohun tó máa ń já Roxana láyà ni pé ọjọ́ kan á jọ́kan tí ìwà ipá ọkọ rẹ̀ yìí á tún burú jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ó sọ pé: “Ó ti sọ ọ́ rí pé òun á pa èmi àtàwọn ọmọ, àtòun fúnra rẹ̀. Ó ti gbé sáàsì sí mi lọ́fun rí. Ó tiẹ̀ ti fẹ́ fìbọn pa mí rí, ó gbé e sí etí mi, ó sì yin ìbọn náà! Ọlá pé kò sí ọta nínú rẹ̀ ni mo jẹ, àmọ́ jìnnìjìnnì ọ̀hún fẹ́rẹ̀ẹ́ pa mí.”

Mẹ́nu Mọ́ Làwọn Obìnrin Ń Fi Ọ̀rọ̀ Náà Ṣe

Bíi ti Roxana, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn obìnrin kárí ayé ní ń jẹ dẹndẹ ìyà lọ́wọ́ àwọn ọkùnrin tí kò láàánú lójú. b Ọ̀pọ̀ wọn kò jẹ́ sọ iná tó ń jó wọn lábẹ́ aṣọ síta. Èrò wọn ni pé bí wọ́n bá fẹjọ́ sun àwọn tí ọkọ wọn bẹ̀rù, kò sóhun tó máa tìdí ẹ̀ yọ. Ó ṣe tán, ọ̀pọ̀ àwọn aṣeniléṣe ọkọ bẹ́ẹ̀ ló ti sọ pé irọ́ ni ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n, bíi kí wọ́n sọ pé, “Nǹkan ti tètè máa ń bí ìyàwó mi nínú jù,” tàbí “Ó ti máa ń fi kún ọ̀rọ̀ ju bó ṣe yẹ lọ.”

Ọ̀ràn ìbànújẹ́ ló jẹ́ pé ọ̀pọ̀ obìnrin lọkàn wọn máa ń kó sókè lójoojúmọ́ nítorí ìbẹ̀rù ìgbájú-ìgbámú nínú ilé tó ti yẹ kí ọkàn wọn balẹ̀ jù lọ. Síbẹ̀, ẹni tó ń fìyà jẹ èèyàn ni wọ́n sábàá máa ń fojú àánú hàn sí lọ́pọ̀ ìgbà dípò ẹni tá a ń fìyà jẹ. Kódà, àwọn kan ò tiẹ̀ lè gbà pé ọkùnrin kan táwọn èèyàn ń ṣe sàdáńkátà fún lè máa na ìyàwó rẹ̀. Gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí obìnrin kan tó ń jẹ́ Anita yẹ̀ wò nígbà tó ké gbàjarè lórí bí ọkọ rẹ̀ táwọn èèyàn ń bọ̀wọ̀ fún ṣe ń lù ú. “Ọ̀kan lára àwọn ojúlùmọ̀ wa sọ fún mi pé: ‘Kí ló mú ẹ fẹ̀sùn kan ọ̀gbẹ́ni táwọn èèyàn ń wárí fún yìí?’ Òmíràn sọ pé ó ní láti jẹ́ pé èmi ni mò ń fín in níràn! Kódà nígbà tí àṣírí ọkọ mi tiẹ̀ wá tú pàápàá, ńṣe làwọn ọ̀rẹ́ mi kan bẹ̀rẹ̀ sí yàn mí lódì. Wọn rò pé ó yẹ kí n máa mú un mọ́ra nítorí pé ‘bẹ́ẹ̀ làwọn ọkùnrin ṣe rí.’”

Gẹ́gẹ́ bá a ṣe rí i nínú ìrírí Anita, ó ṣì ṣòro fún ọ̀pọ̀ láti gbà pé àwọn ọkùnrin kan ń han ìyàwó wọn léèmọ̀. Kí ló lè mú kí ọkùnrin kan máa hùwà òǹrorò sí obìnrin tó sọ pé òun nífẹ̀ẹ́? Báwo la ṣe lè ran àwọn tí ìyà ń jẹ yìí lọ́wọ́?

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ padà nínú ọ̀wọ́ yìí.

b A gbà pé ọ̀pọ̀ àwọn ọkùnrin náà máa ń jìyà. Àmọ́ àwọn ìwádìí fi hàn pé àwọn obìnrin ló ṣeé ṣe kí wọ́n ṣèṣe jù àti pé tiwọn ló máa ń pọ̀ jù. Fún ìdí yìí, àwọn àpilẹ̀kọ yìí dá lórí àwọn ọkọ tí ń lu àwọn aya wọn.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Ìwà Ipá Láàárín Ìdílé Ti Gbòde Kan

Gẹ́gẹ́ bí Òfin tí Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ṣe Láti Fòpin sí Híhùwà Ipá Sáwọn Obìnrin ti wí, ọ̀rọ̀ náà “ìwà ipá sáwọn obìnrin” lè túmọ̀ sí “ìwà ipá èyíkéyìí tó bá ti jẹ mọ́ ti ẹ̀yà obìnrin tó sì yọrí sí tàbí tó ṣeé ṣe kó yọrí sí ìpalára nípa ti ara, ti ìbálòpọ̀, tàbí ti ìmọ̀lára fún àwọn obìnrin, èyí kan híhalẹ̀ mọ́ wọn, fífipá mú wọn ṣe nǹkan tàbí fífi òmìnira dù wọ́n yálà ní gbangba tàbí níkọ̀kọ̀.” Irú ìwà ipá bẹ́ẹ̀ kan “ìwà ipá nípa tara, nípa ti ìbálòpọ̀ àti ti ìrònú òun ìhùwà tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé tàbí láwùjọ, tó fi dórí nína obìnrin bí ẹní máa pa á, fífi ìbálòpọ̀ fìtínà àwọn ọmọbìnrin kéékèèké, ìwà ipá tó jẹ mọ́ ọ̀ràn ìdána, fífipá bá ìyàwó ẹni lòpọ̀, dídábẹ́ fún ọmọbìnrin àtàwọn àṣà ìbílẹ̀ mìíràn tó lè ṣèpalára fún obìnrin.”