Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ló Burú Nínú Kéèyàn Gbẹ̀san?

Kí Ló Burú Nínú Kéèyàn Gbẹ̀san?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Kí Ló Burú Nínú Kéèyàn Gbẹ̀san?

“Ó fìwọ̀sí lọ̀ mí.”—Conneel, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, ẹ̀sùn ìpànìyàn ló gbé e dẹ́wọ̀n.

Andrew, ọmọ ọdún mẹ́rìnlá tó pa olùkọ́ kan níbi ijó níléèwé sọ pé òún kórìíra àwọn olùkọ́ àtàwọn òbí òun, inú sì máa ń bí òun nítorí pé àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin kò gba tòun.

“ÌWÀ tí ń ṣekú pani” ni ìwé ìròyìn Time pè é. Ọ̀dọ́ kan tínú ń bí yọ́ gbé ìbọn kan lọ síléèwé ó sì ṣíná bo àwọn olùkọ́ àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ aburú báwọ̀nyí ti bẹ̀rẹ̀ sí í dà bí èyí tó ń wọ́pọ̀ gan-an ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà débi tí ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n kan fi pe àṣà náà ní “ìwà ipá tó le kú.”

A dúpẹ́ pé, àṣà yíyìnbọn níléèwé kò tíì fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀. Àmọ́ síbẹ̀ náà, àwọn ìwà ọ̀daràn ẹnu àìpẹ́ yìí tí ìbínú fà fi bí àwọn ọ̀dọ́ kan ṣe ya oníbìínú èèyàn tó hàn. Kí lohun tó dà bí ẹni pé ó ń súnná sí ìbínú fùfù yìí? Kò sírọ́ ńbẹ̀ pé ìwà ìrẹ́jẹ tàbí lílo ipò ẹni nílòkulò táwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí ń fojú winá rẹ̀ látọ̀dọ̀ àwọn tó lágbára jù wọ́n lọ ló ń fa ìbínú wọn. Ohun tó sì ń múnú bí àwọn mìíràn kò ṣẹ̀yìn bí àwọn ẹgbẹ́ wọn ṣe máa ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ nígbà gbogbo. Ọ̀dọ́mọkùnrin ọlọ́dún méjìlá kan tó yìnbọn pa ọmọ kíláàsì rẹ̀ kan, tó sì tún yìnbọn para rẹ̀ lẹ́yìn náà ni wọ́n ti máa ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ pé ó sanra jù.

A ò jiyàn rẹ̀ pé, èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ọ̀dọ́ ni kò jẹ́ ronú láé láti lọ́wọ́ nínú irú ìwà ipá tó gogò bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, kì í rọrùn láti kojú ìrora tó máa ń jẹ yọ nígbà tí wọ́n bá tani nù nítorí ìran ẹni, tí wọ́n ń hùwà ìkà síni, tàbí tí wọ́n ń fini ṣe yẹ̀yẹ́ lọ́nà tí ń bani nínú jẹ́. Nígbà tí Ben ronú padà sígbà tó wà níléèwé, ó sọ pé: “Èmi ni mo kúrú jù nínú àwọn ọmọ tá a jọ jẹ́ ẹgbẹ́. Nítorí pé ńṣe ni mo tún máa ń fá orí mi kodoro, gbogbo ìgbà làwọn ọmọ tó kù máa ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ tí wọ́n á sì máa gbá mi lórí pẹ̀ẹ́pẹ̀ẹ́. Èyí máa ń bí mi nínú gan-an ni. Ohun tó tún wá mú ọ̀rọ̀ ọ̀hún burú sí i ni pé, tí mo bá lọ fẹjọ́ wọn sun àwọn ọ̀gá wa, wọn kì í dá mi lóhùn. Ìyẹn á tún mú kínú bí mi sí i!” Ben fi kún un pé: “Nǹkan kan ṣoṣo tí kò jẹ́ kí n yìn àwọn ẹni yẹn níbọn ni pé ọwọ́ mi ò tẹ ìbọn.”

Irú ojú wo ló yẹ kó o fi wo àwọn ọ̀dọ́ tó máa ń wá bí wọ́n á ṣe gbẹ̀san lára àwọn tó ṣẹ̀ wọ́n? Kí ló sì yẹ kó o ṣe ká ni ìwọ gan-gan ni wọ́n fìyà jẹ? Láti rí ìdáhùn, gbé ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ yẹ̀ wò.

Ìkóra-Ẹni-Níjàánu Kì Í Ṣe Àmì Àìlera O!

Ọjọ́ pẹ́ tí ìwà ká máa fìyà jẹni àti ká máa rẹ́ni jẹ ti bẹ̀rẹ̀. Ìmọ̀ràn tí òǹkọ̀wé Bíbélì kan fúnni nìyí: “Jáwọ́ nínú ìbínú, kí o sì fi ìhónú sílẹ̀; má ṣe gbaná jẹ kìkì láti ṣe ibi.” (Sáàmù 37:8) Lọ́pọ̀ ìgbà, ìbínú máa ń ní í ṣe pẹ̀lú àìní ìkóra-ẹni-níjàánu, téèyàn á fara ya láìro ohunkóhun tó lè tìdí rẹ̀ yọ. ‘Gbígbaná jẹ’ lè mú kéèyàn fa ìbínú yọ! Kí ló lè tìdí rẹ̀ yọ?

Wo àpẹẹrẹ Kéènì àti Ébẹ́lì nínú Bíbélì. ‘Ìbínú Kéènì gbóná gidigidi’ sí Ébẹ́lì arákùnrin rẹ̀. Nítorí bẹ́ẹ̀, “nígbà tí wọ́n wà nínú pápá, Kéènì bẹ̀rẹ̀ sí fipá kọlu Ébẹ́lì arákùnrin rẹ̀, ó sì pa á.” (Jẹ́nẹ́sísì 4:5, 8) Àpẹẹrẹ ẹlòmíràn tí kò kó ìbínú rẹ̀ níjàánu ni Sọ́ọ̀lù Ọba. Nítorí pé ó ń jowú àṣeyọrí tí Dáfídì ọ̀dọ́ ṣe lójú ogun, ńṣe ló dìídì ju ọ̀kọ̀ fún un, kì í ṣe sí Dáfídì nìkan o, ó tún jù ú fún Jónátánì, ọmọ tirẹ̀ gan-gan!—1 Sámúẹ́lì 18:11; 19:10; 20:30-34.

Lóòótọ́, àwọn ìgbà míì wà tó yẹ kéèyàn bínú. Àmọ́ síbẹ̀ náà, inú téèyàn bí lórí ẹ̀tọ́ lè yọrí sí wàhálà téèyàn ò bá ṣàkóso rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, ó dájú pé Síméónì àti Léfì jàre fún bí wọ́n ṣe bínú sí Ṣékémù nígbà tí wọ́n gbọ́ pé ó fipá bá Dínà arábìnrin wọn sùn. Àmọ́ dípò kí wọ́n fiyè dénú, wọ́n jẹ́ kí inú wọn ru láti hùwà ipá, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ lẹ́yìn náà ti fi hàn, pé: “Ṣé ó yẹ kí ẹnikẹ́ni hùwà sí arábìnrin wa bí ẹni pé kárùwà ni?” (Jẹ́nẹ́sísì 34:31) Nígbà tí ìbínú wọn ru dé góńgó, ni wọ́n bá “mú idà wọn, wọ́n sì yọ́ lọ sí ìlú ńlá náà, wọ́n sì pa olúkúlùkù ọkùnrin” tó ń gbé abúlé tí Ṣékémù ń gbé. Ìbínú wọn tún ran àwọn mìíràn nítorí pé “ìyókù àwọn ọmọkùnrin Jékọ́bù” dara pọ̀ nínú ìjà tó mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀mí lọ náà. (Jẹ́nẹ́sísì 34:25-27) Àní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Jékọ́bù tó jẹ́ bàbá Síméónì àti Léfì fi wọ́n bú fún ṣíṣàì bomi sùúrù mu.—Jẹ́nẹ́sísì 49:5-7.

A rí ohun pàtàkì kan kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí: Ìbínú fùfù kì í ṣe àmì okun ṣùgbọ́n ó jẹ́ àmì àìlera. Òwe 16:32 sọ pé: “Ẹni tí ó lọ́ra láti bínú sàn ju alágbára ńlá, ẹni tí ó sì ń ṣàkóso ẹ̀mí rẹ̀ sàn ju ẹni tí ó kó ìlú ńlá.”

Ìdí tí Gbígbẹ̀san Fi Jẹ́ Ìwà Òmùgọ̀

Ìdí nìyẹn tí Ìwé Mímọ́ fi fún wa ní ìmọ̀ràn yìí pé: “Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnì kankan. . . . Ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín.” (Róòmù 12:17, 19) Ọlọ́run kò nífẹ̀ẹ́ sí gbígbẹ̀san, ì báà jẹ́ nípa ṣíṣe ẹlòmíràn léṣe tàbí sísọ̀rọ̀ burúkú síni. Yàtọ̀ síyẹn, gbígbẹ̀san kò kàn tiẹ̀ bọ́gbọ́n mu ni. Ìdí kan ni pé, ńṣe ni ìwà ipá sábà máa ń bí ìwà ipá púpọ̀ sí i. (Mátíù 26:52) Ọ̀rọ̀ burúkú sì máa ń bí ọ̀rọ̀ burúkú mìíràn. Tún rántí o, pé ọ̀pọ̀ ìgbà lèèyàn kì í jàre tó bá bínú. Fún àpẹẹrẹ, báwo ló ṣe lè dá ẹ lójú pé lóòótọ́ lẹni tó ṣẹ̀ ọ́ yẹn ní ọ sínú? Ṣé ó lè jẹ́ pé ńṣe lẹni yẹn kan fi àìnírònú sọ̀rọ̀ tàbí kó jẹ́ pé ẹni jàùjàù ni? Ká tiẹ̀ wá ní ẹni náà ní nǹkan kan lọ́kàn sí ẹ, ṣe ọ̀rọ̀ ọ̀hún wá burú débi pé gbígbẹ̀san lóhun tó tọ́ láti ṣe?

Wo ohun tí Bíbélì sọ nínú Oníwàásù 7:21, 22 pé: “Má fi ọkàn-àyà rẹ sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí àwọn ènìyàn lè máa sọ, kí o má bàa gbọ́ tí ìránṣẹ́ rẹ ń pe ibi wá sórí rẹ. Nítorí ọkàn-àyà ìwọ fúnra rẹ mọ̀ dáadáa, àní ní ọ̀pọ̀ ìgbà pé ìwọ, àní ìwọ, ti pe ibi wá sórí àwọn ẹlòmíràn.” Òótọ́ ni pé inú rẹ̀ kò lè dùn tó o bá gbọ́ táwọn kan sọ ohun tí kò dára nípa rẹ. Ṣùgbọ́n Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé kò sí ọgbọ́n tíyẹn ò fi ní ṣẹlẹ̀. Ṣé kì í ṣòótọ́ ni pé àfàìmọ̀ ni ìwọ náà ò ti sọ nǹkan kan tí kò yẹ kó o sọ nípa àwọn ẹlòmíràn? Kí wá ló dé tí wàá fi gbaná jẹ nígbà tí ẹlòmíràn wá sọ nǹkan tí kò dára nípa rẹ? Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tó dára jù lọ tó o lè ṣe tẹ́nì kán bá ń fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́ ni pé kó o kàn ṣe bíi pé o kò gbọ́.

Bákan náà, kì í ṣe ohun tó bọ́gbọ́n mu láti fara ya nígbà tó bá dà bíi pé ẹnì kan ṣe ohun tí kò dára sí ọ. Ọ̀dọ́langba kan tó ń jẹ́ David rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tóun àtàwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan jọ ń gbá bọ́ọ̀lù alápẹ̀rẹ̀. Ó sọ pé: “Ẹnì kan lára àwọn ẹgbẹ́ kejì lẹ bọ́ọ̀lù mọ́ mi.” Kíá, David ti parí rẹ̀ sí pé ìkà lẹni yẹn fi ṣe, ló bá ṣe tiẹ̀ padà, ó sì lẹ bọ́ọ̀lù náà mọ́ ẹni yẹn san. David sọ pé: “Orí mi ti kanrin.” Àmọ́ kí ọ̀rọ̀ ọ̀hún tó di èyí tó burú sí i, David gbàdúrà sí Jèhófà. Ló bá bá ara rẹ̀ sọ̀rọ̀ pé, ‘Kí ni mo ń ṣe yìí kẹ̀, ṣe mo fẹ́ wá máa bá Kristẹni arákùnrin mi jà ni?’ Lẹ́yìn ìgbà náà, wọ́n tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ara wọn.

Nínú irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀ yẹn, ó bọ́gbọ́n mu láti rántí àpẹẹrẹ Jésù Kristi. “Nígbà tí a ń kẹ́gàn rẹ̀, kò bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́gàn padà. Nígbà tí ó ń jìyà, kò bẹ̀rẹ̀ sí halẹ̀ mọ́ni.” (1 Pétérù 2:23) Bẹ́ẹ̀ ni o, tínú bá ń bí ọ, dípò tí wàá fi gbaná jẹ, gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti kó ara rẹ níjàánu. Tinútinú ni ó máa ń “fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.” (Lúùkù 11:13) Dípò tí wàá fi gbẹ̀san tẹ́nì kan bá ṣẹ̀ ọ́, bóyá ohun tó ò bá kúkú ṣe ni pé kó o lọ bá ẹni yẹn kẹ́ ẹ sì jọ yanjú rẹ̀. (Mátíù 5:23, 24) Tàbí kẹ̀ ká ní ẹnì kan ń fòòró ẹ̀mí rẹ ṣáá, bóyá iléèwé lẹni tó ń fayé ni ẹ́ lára náà wà, má lọ kò ó lójú, ó lè yọrí sí wàhálà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ kó o wá bí wàá ṣe dáàbò bo ara rẹ. a

Ọ̀dọ́ Kan Tí Kò Gba Ìbínú Láyè

Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló ti fi àwọn ìlànà Bíbélì yìí sílò tí wọ́n sì ti rí àwọn àbájáde rere. Fún àpẹẹrẹ, wọ́n já Catrina fún alágbàtọ́ nígbà tó ṣì kéré gan-an. Ó sọ pé: “Mo máa ń bínú yánnayànna nítorí mi ò mọ ìdí tí màmá mi gan-gan fi já mi sílẹ̀. Ni màá bá máa fi ìkanra mọ́ màmá tó gbà mí tọ́. Nítorí ìdí tí kò ní láárí, mo rò pé tí mo bá ń ṣe nǹkan tó dùn ún, ńṣe ni mo ń yaró ohun tí màmá mi ṣe. Nípa bẹ́ẹ̀ kò sí ohun tí mi ò ṣe sí i tán, màá yan èébú sí i lára, màá jan ẹsẹ̀ mọ́lẹ̀, màá sọ̀rọ̀ sí i játijàti. Títi ilẹ̀kùn gbàmù lohun tí mo máa ń ṣe jù. Mo tún máa ń sọ fún un pé, ‘Mo kórìíra rẹ!’—inú tó ń bí mi ló jẹ́ kí ń máa ṣe gbogbo èyí. Tí mo bá wá ronú padà sẹ́yìn, ìyàlẹ́nu ló máa ń jẹ́ fún mi pé èmi náà ni mo ṣe gbogbo ìyẹn.”

Kí ló ran Catrina lọ́wọ́ láti bomi sùúrù mu? Ó fèsì pé: “Kíka Bíbélì ni! Èyí ṣe pàtàkì gan-an nítorí pé Jèhófà mọ bí nǹkan ṣe rí lára wa.” Catrina tún rí ìtùnú gbà nígbà tóun àti ìdílé rẹ̀ ka àwọn àpilẹ̀kọ kan nínú Jí! tó sọ̀rọ̀ lórí irú ìṣòro gan-an tó ń yọ ìdílé rẹ̀ lẹ́nu. b Ó sọ pé: “Ó jẹ́ kó ṣeé ṣe fún gbogbo wa láti jókòó pọ̀ ká sì lóye ara wa.”

Ìwọ náà lè kọ́ bó o ṣe lè kápá ìbínú. Táwọn kan bá ń fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́, tí wọ́n ń halẹ̀ mọ́ ọ tàbí tí wọ́n hùwà àìdáa sí ẹ, rántí ọ̀rọ̀ tó wà nínú Bíbélì ní Sáàmù 4:4 tó sọ pé: “Kí inú yín ru, ṣùgbọ́n má ṣẹ̀.” Àwọn ọ̀rọ̀ yẹn lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti yẹra fún ìbínú tó lè ba ayé èèyàn jẹ́.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún ìmọ̀ràn tó gbẹ́ṣẹ́ lórí ohun tó o lè ṣe nípa àwọn tíṣà tó máa ń ṣe ojúsàájú, àwọn tó ń fìyà jẹni níléèwé, àtàwọn tó máa ń fòòró ẹni, wo àwọn àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” tó jáde nínú àwọn ìtẹ̀jáde Jí! ti January 22, 1986; August 22, 1985 (Gẹ̀ẹ́sì); àti February 8, 1990

b Wo ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ náà, “Ìgbàṣọmọ Ayọ̀ àti Ìpèníjà Rẹ̀,” tó wà nínú ìtẹ̀jáde Jí! ti May 8, 1996.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tó dára jù lọ tó o lè ṣe tẹ́nì kán bá ń fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́ ni pé kó o kàn ṣe bíi pé o kò gbọ́