Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ló Dé Táwọn Ọkùnrin Kan Fi Máa Ń Lu Ìyàwó Wọn?

Kí Ló Dé Táwọn Ọkùnrin Kan Fi Máa Ń Lu Ìyàwó Wọn?

Kí Ló Dé Táwọn Ọkùnrin Kan Fi Máa Ń Lu Ìyàwó Wọn?

ÀWỌN ògbógi kan sọ pé ó ṣeé ṣe kí iye àwọn obìnrin táwọn ọkọ wọn ń pa ju iye àwọn obìnrin tó ń kú nípasẹ̀ gbogbo nǹkan tó ń ṣekú pa obìnrin láyé yìí. Onírúurú ìwádìí làwọn èèyàn ti ṣe nítorí àtifòpin sí ìwà kí ọkùnrin máa lu ìyàwó rẹ̀. Irú ọkùnrin wo ló tiẹ̀ máa ń lu ìyàwó rẹ̀? Báwo ni wọ́n ṣe tọ́ ọ dàgbà? Ṣé kìígbọ́-kìígbà ni nígbà tí wọ́n ń fẹ́ra sọ́nà? Tí àwọn dókítà afìṣemọ̀rònú bá ń bá ẹni tó ń lu ìyàwó rẹ̀ yìí sọ̀rọ̀ nípa ìwà ipá náà, ṣé ó máa ń tẹ́wọ́ gba ìmọ̀ràn náà?

Ohun kan táwọn ògbógi ti kíyè sí ni pé àwọn ọkọ tó ń lu ìyàwó wọn kò rí bákan náà. Àwọn kan wà tó jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni wọ́n máa ń hùwà ipá yìí. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ kì í lo àwọn ohun ìjà kò sì sí lákọọ́lẹ̀ rẹ̀ pé ó ń lu ìyàwó rẹ̀ léraléra. Kì í ṣe àṣà irú ẹni yìí láti máa hùwà ipá àmọ́ ipò àyíká àti àwùjọ tó wà ló mú kó máa ṣe bẹ́ẹ̀. Ibẹ̀ sì ni ọkùnrin mìíràn wà tó jẹ́ pé lílu ìyàwó rẹ̀ ní àlùpa-mókùú ti di mọ́ọ́lí sí i lára. Gbogbo ìgbà ló máa ń hùwà yìí, kò sì jẹ́ ronú rárá pé nǹkan tóun ń ṣe kù díẹ̀ káàtó.

Àmọ́ ṣá, pé oríṣiríṣi làwọn ọkùnrin tó ń lu ìyàwó wọn yìí kò túmọ̀ sí pé àwọn ọ̀nà kan wà tí wọ́n ń gbà ṣe é tí kò burú o. Ká sòótọ́, líluni lọ́nà èyíkéyìí lè fa ọgbẹ́, kódà ó lè fa ikú pàápàá. Nítorí náà, ti pé ọkùnrin kan kì í hùwà jàgídíjàgan yìí ní gbogbo ìgbà tàbí pé tiẹ̀ kò burú tó ti ẹlòmíràn kò fi hàn pé ìwà náà dára. Ní ti gidi, kò sóhun tó ń jẹ́ líluni “lọ́nà tó dára.” Nígbà náà, kí ló lè wá mú kí ọkùnrin kan máa lu obìnrin tó jẹ́jẹ̀ẹ́ pé òun á ṣìkẹ́ títí ọjọ́ ayé òun?

Ipa Tí Ìdílé Tí Wọ́n Ti Wá Ń Kó

Kò yani lẹ́nu pé inú ìdílé oníjàgídíjàgan ni wọ́n ti tọ́ lára àwọn ọkùnrin tó máa ń lu ìyàwó wọn yìí dàgbà. Michael Groetsch, tó ti fi ohun tó lé ní ogún ọdún ṣèwádìí nípa báwọn ọkùnrin ṣe ń han ìyàwó wọn léèmọ̀ kọ̀wé pé: “Inú ìdílé tó dà bí ‘ojú ogun’ ni wọ́n ti tọ́ ọ̀pọ̀ àwọn ọkùnrin tó ń lu ìyàwó wọn dàgbà. Àyíká burúkú tí kò ti sóhun tó ‘burú’ nínú kéèyàn gbèrò ibi tàbí hùwà ibi ni wọ́n ti ṣe èwe, ibẹ̀ ni wọ́n sì ti dàgbà.” Ògbóǹtagí kan sọ pé, ọkùnrin tí wọ́n bá tọ́ dàgbà nírú àyíká bẹ́ẹ̀ “lè ti kékeré bẹ̀rẹ̀ sí ní irú ìkórìíra tí bàbá rẹ̀ ní fún àwọn obìnrin. Ohun tí ọmọ yẹn á kọ́ ni pé ọkùnrin ló gbọ́dọ̀ máa darí àwọn obìnrin, àti pé ọ̀nà tí ipò orí yẹn fi lè dọ́wọ́ rẹ̀ ni pé kó máa dẹ́rù bà wọ́n, kó máa hàn wọ́n léèmọ̀, kó sì máa yẹ̀yẹ́ wọn. Lọ́wọ́ kan náà, á tún kọ́ pé ọ̀nà kan ṣoṣo tí inú bàbá òun fi lè dùn sí òun ni kóun máa hùwà bó ṣe ń hùwà.”

Bíbélì sọ ọ́ ní kedere pé ìwà òbí lè ní ipa lórí ọmọ gan-an, yálà ipa tó dára tàbí èyí tí kò dára. (Òwe 22:6; Kólósè 3:21) Lóòótọ́, bí wọ́n ṣe tọ́ èèyàn dàgbà kò torí ẹ̀ sọ pé kéèyàn máa lu ìyàwó rẹ̀, àmọ́ ó lè ṣèrànwọ́ láti jẹ́ ká lóye ibi tí ìwà ipá yìí ti ṣẹ̀ wá.

Àṣà Ìbílẹ̀ Ní Ipa Tó Ń Kó

Ní àwọn ilẹ̀ kan kò sóhun tó burú nínú kéèyàn na obìnrin, déédéé ló ṣe. Ìròyìn kan látọ̀dọ̀ Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sọ pé: “Láwọn àgbègbè tó pọ̀, ọwọ́ dan-in dan-in ni wọ́n fi ń mú ẹ̀tọ́ tí ọkọ ní láti lu ìyàwó rẹ̀ tàbí kó fayé sú u.”

Àní láwọn ilẹ̀ tí wọn ò ti fara mọ́ irú ìwàkiwà bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ làwọn tó ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe bẹ́ẹ̀ láyè ara wọn. Èrò àwọn ọkùnrin kan nípa ọ̀ràn yìí bani lẹ́rù. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Weekly Mail and Guardian ti Gúúsù Áfíríkà ti sọ, ìwádìí kan tí wọ́n ṣe níbi Ìyawọlẹ̀ Omi Cape fi hàn pé ọ̀pọ̀ àwọn ọkùnrin tó sọ pé àwọn kì í lu ìyàwó àwọn sọ pé kò sóhun tó burú nínú kéèyàn gbá ìyàwó rẹ̀ lẹ́ṣẹ̀ẹ́, ìyẹn kò sì túmọ̀ sí ìwà ipá.

Ní tòótọ́, àtìgbà ọmọdé lèrò tó lòdì bẹ́ẹ̀ ti ń bẹ̀rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ìwádìí kan fi hàn pé ìdá márùndínlọ́gọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọkùnrin ọlọ́dún mọ́kànlá sí méjìlá ló sọ pé bí inú bá ń bí ọkùnrin, ó lè kó ẹ̀ṣẹ́ bo obìnrin.

Ohun Tí Ò Dáa Kò Dáa

Àwọn ohun tá a sọ lókè yìí lè jẹ́ ká lóye nǹkan tó ń mú káwọn ọkùnrin kan máa lu ìyàwó wọn, àmọ́ àwọn nǹkan wọ̀nyẹn ò sọ pé ó dára láti lu ìyàwó ẹni. Ká kúkú sọ ojú abẹ níkòó, ẹ̀ṣẹ̀ ńlá gbáà ni lílu ìyàwó ẹni jẹ́ lójú Ọlọ́run. A kà á nínú Bíbélì tó jẹ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ó yẹ kí àwọn ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnra wọn. Ẹni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀, nítorí pé kò sí ènìyàn kankan tí ó jẹ́ kórìíra ara òun fúnra rẹ̀; ṣùgbọ́n a máa bọ́ ọ, a sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti ń ṣe sí ìjọ.”—Éfésù 5:28, 29.

Ó ti pẹ́ tí Bíbélì ti sọ ọ́ pé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò àwọn nǹkan yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa di “afìyàjẹni, aláìnífẹ̀ẹ́, àti òǹrorò.” (2 Tímótì 3:1-3; The New English Bible) Bí àṣà kí ọkùnrin máa lu ìyàwó rẹ̀ ṣe ń gbèèràn káàkiri yìí jẹ́ ohun mìíràn tó fi hàn pé àkókò tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí sọ gan-an la wà yìí. Àmọ́ kí la lè ṣe láti ran àwọn tó ń jẹ irú ìyà yìí lọ́wọ́? Ǹjẹ́ ìrètí wà pé àwọn ọkùnrin tó ń lu ìyàwó wọn lè yí padà?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]

“Ẹnì kan tó lu ìyàwó rẹ̀ kò yàtọ̀ sí ọkùnrin arúfin kan tó da ẹ̀ṣẹ́ bo ẹni tí kò mọ̀ rí.”—When Men Batter Women

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

Kí Ọkọ Máa Lu Aya Ó Ti Di Ìṣòro Kárí Ayé

Lílù tí àwọn ọkùnrin onígbèéraga ń lu àwọn ìyàwó wọn ti di ìṣòro tó kárí ayé o, àwọn ìròyìn tó wà nísàlẹ̀ yìí fi èyí hàn.

Íjíbítì: Ìwádìí olóṣù mẹ́ta tí wọ́n ṣe ní Alẹkisáńdíríà fi hàn pé ìwà ipá nínú ilé lohun tó ń dá ọgbẹ́ sára àwọn obìnrin jù lọ. Òun ló ń mú ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdá ọgbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo àwọn obìnrin lọ sí ilé ìtọ́jú ọgbẹ́.—Résumé 5 of the Fourth World Conference on Women.

Thailand: Ní àgbègbè tó tóbi jù lọ ní ìlú Bangkok, ìdá àádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún àwọn obìnrin tó wà nílé ọkọ lọkọ wọn máa ń lù déédéé.—Pacific Institute for Women’s Health.

Hong Kong: “Iye àwọn obìnrin tó sọ pé ọkọ wọn ti lù wọ́n rí ti fi iye tó lé ní ìpín ogójì nínú ọgọ́rùn-ún lọ sókè lẹ́nu ọdún tó kọjá.”—South China Morning Post, July 21, 2000.

Japan: Iye àwọn obìnrin tó ń wá ibi tí wọ́n máa sá lọ ti lọ sókè látorí nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún lọ́dún 1995 sí ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́fà àtààbọ̀ lọ́dún 1998. “Nǹkan bí ìdá kan nínú mẹ́ta wọn sọ pé ìwà ipá ọkọ wọn ló jẹ́ káwọn máa wá ibi táwọn máa sá lọ.”—The Japan Times, September 10, 2000.

Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì: “Láàárín ìṣẹ́jú àáyá mẹ́fà péré, wọ́n á fipá ba ẹnì kan lòpọ̀, wọ́n á lu ẹnì kan tàbí gún un lọ́bẹ nínú ilé kan nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.” Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn kan látọ̀dọ̀ àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ṣe sọ, “àwọn ọlọ́pàá ń gba ìpè ọgọ́rùn-ún dín légbèje [1,300] lójoojúmọ́ látọ̀dọ̀ àwọn tá a ń fìyà jẹ nínú ilé, iye ìpè bẹ́ẹ̀ sì ju ọ̀kẹ́ méjìdínlọ́gbọ̀n ó lé ẹgbàárùn-ún [570,000] lọ lọ́dún. Ìdá mọ́kànlélọ́gọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún ló jẹ́ àwọn obìnrin táwọn ọkùnrin ń hàn léèmọ̀.”—The Times, October 25, 2000.

Peru: Ìpín àádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún ìwà ipá tá a fi tó àwọn ọlọ́pàá létí ló jẹ́ ti àwọn obìnrin táwọn ọkọ wọn lù.—Pacific Institute for Women’s Health.

Rọ́ṣíà: “Ní ọdún kan péré, ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá àtààbọ̀ [14,500] làwọn obìnrin ará Rọ́ṣíà táwọn ọkọ wọn ń pa, tí àwọn ẹgbàá méjìdínlọ́gbọ̀n ó lé irínwó [56,400] sì ń di amúkùn-ún tàbí kí wọ́n gbọgbẹ́ yánna-yànna nípasẹ̀ ìwà ipá inú ilé.”—The Guardian.

China: Ọ̀jọ̀gbọ́n Chen Yiyun, tó jẹ́ olùdarí Ibùdó Ọ̀ràn Ìdílé ti ìlú Jinglun, sọ pé: “Kò tíì pẹ́ tí ìṣòro yìí bẹ̀rẹ̀. Ó sì ti ń gbilẹ̀ gan-an, àgàgà láwọn ìgboro. Gbogbo bí àwọn kan ṣe lòdì sí i kò ní kó dáwọ́ dúró.”—The Guardian.

Nicaragua: “Ńṣe ni híhùwà ipá sáwọn obìnrin ní Nicaragua ń peléke sí i. Ìwádìí kan fi hàn pé lọ́dún tó kọjá nìkan, ìdá méjìléláàádọ́ta àwọn obìnrin Nicaragua ló ń jìyà nípasẹ̀ oríṣi ìwà ipá inú ilé kan tàbí òmíràn látọ̀dọ̀ àwọn ọkọ wọn.”—Ìròyìn orí rédíò BBC.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]

Àwọn Àmì Tó Ń Fi Hàn Pé Ewu Ń Bẹ

Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí tí Richard J. Gelles ṣonígbọ̀wọ́ rẹ̀ ní Yunifásítì Rhode Island, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ṣe sọ, àwọn ohun tó wà nísàlẹ̀ yìí ni àwọn nǹkan tó máa ń fa kí ọkọ máa lu ìyàwó rẹ̀ tàbí kó máa sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí i nínú ilé:

1. Ọkùnrin náà ti lọ́wọ́ nínú ìwà ipá inú ilé nígbà kan rí.

2. Ọkùnrin náà kò níṣẹ́ lọ́wọ́.

3. Ó máa ń lo oògùn olóró ní ó kéré tán ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún.

4. Nígbà tó ṣì wà lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ̀, ó máa ń rí i bí bàbá rẹ̀ ṣe máa ń lu ìyá rẹ̀.

5. Ọkùnrin àti obìnrin náà kò fẹ́ra wọn níṣu-lọ́kà; wọ́n kàn jọ ń gbé ni.

6. Tí ọkùnrin náà bá níṣẹ́ lọ́wọ́, a jẹ́ pé owó tó ń gbà kò tó nǹkan.

7. Ọkùnrin náà kò jáde ilé ẹ̀kọ́ gíga.

8. Ọjọ́ orí rẹ̀ kò ju méjìdínlógún sí ọgbọ̀n lọ.

9. Bàbá tàbí ìyá ọkùnrin náà tàbí àwọn méjèèjì ń hùwà ipá sáwọn ọmọ nílé.

10. Gbogbo owó tó ń wọlé fún un kò tó nǹkan.

11. Àṣà ìbílẹ̀ ọkùnrin náà àti ìyàwó rẹ̀ yàtọ̀ síra.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ìwà ipá nínú ilé lè nípa burúkú lórí àwọn ọmọ