Màmá Àtàwọn Ọmọbìnrin Rẹ̀ Mẹ́wàá
Màmá Àtàwọn Ọmọbìnrin Rẹ̀ Mẹ́wàá
GẸ́GẸ́ BÍ ESTHER LOZANO ṢE SỌ Ọ́
ÌLÚ Bitlis ní Turkey ni wọ́n ti bí Màmá àti Bàbá, ará Àméníà sì làwọn òbí wọn. Níbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún tó kọjá, nígbà tí wọ́n ń pa àwọn ará Àméníà bí ẹní pẹran, bàbá wa sá kúrò ní Turkey lọ sí Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Ọmọ nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ni nígbà yẹn. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni Sophia, màmá wa tọ̀ ọ́ lọ lẹ́ni ọdún méjìlá.
Ó jọ pé ńṣe ni òbí àwọn méjèèjì jọ fọwọ́ sí i pé kí màmá wa lọ sí Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà láti lọ fẹ́ bàbá wa, Aram Vartanian. Sophia kò tíì tó lọ́kọ nígbà tó dé sílùú Fresno ní California, ló bá ń gbé lọ́dọ̀ ẹni tó ń bọ̀ wá di ìyá ọkọ rẹ̀ títí tó fi dàgbà tó ẹni tí ń lọ́kọ.
Ọkùnrin làwọn òbí wa fi ṣe àkọ́bí, wọ́n sì sọ ọ́ ní Antranig, àmọ́ ó yí orúkọ yẹn padà sí Barney nígbà tó yá. August 6, 1914 ni wọ́n bí i. Obìnrin ni wọ́n fi gbogbo ọmọ wọn mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí wọ́n bí lẹ́yìn náà bí. Bàbá wa di Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe máa ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn, nígbà tí Shield Toutjian wá sí ìlú Fresno tó sì sọ àsọyé kan fún àwọn tó jẹ́ ará Àméníà ní 1924. Látìgbà náà ni gbogbo ìdílé wa pátá ti ń lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni.
Ní 1931, a kó lọ sí ìlú Oakland ní California, a sì ń dára pọ̀ mọ́ ìjọ tó wà níbẹ̀. Barney fi ìdúróṣinṣin sin Jèhófà ní ìlú Napa, ní California, títí tó fi
kú ní 1941. Èmi ni ọmọbìnrin kẹta tí wọ́n bí lé Barney mo sì fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ mi hàn sí Jèhófà ní 1935. Lẹ́yìn ọdún karùndínlọ́gọ́rin tí Agnes, arábìnrin wa ti ń lọ sí ìpàdé, ẹnu àìpẹ́ yìí ló ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi! Gbogbo àwa arábìnrin rẹ̀ la pésẹ̀ síbẹ̀, inú wa sì dùn gan-an ni pé ẹni kan tó ṣẹ́ kù lára àwa ọmọbìnrin mẹ́wàá náà ti ṣèrìbọmi báyìí.Ó bà wá nínú jẹ́ pé Màmá kò sí níbẹ̀. Ọdún kan ṣáájú ìgbà yẹn ló kú lẹ́ni ọgọ́rùn-ún ọdún ó lé ọjọ́ méjì. Ìwé ìròyìn ilẹ̀ California náà, Hayward News, ti May 14, 1996 gbé ìròyìn ikú rẹ̀. Ó sọ pé “ó ṣe iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni fún àwọn ará àdúgbò gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nípa kíkọ́ . . . àwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì lẹ́kọ̀ọ́ fún ọdún mẹ́rìnléláàádọ́ta.” Àpilẹ̀kọ náà tún ṣàyọlò ọ̀rọ̀ tí Elizabeth arábìnrin wa sọ pé: “Gbogbo ìgbà ni èèyàn lè lọ sí ilé rẹ̀, kò sì sígbà tí èèyàn délé rẹ̀ tí kò rí nǹkan jẹ . . . Ó máa ń sọ pé, ‘Ẹ wọlé kẹ́ ẹ mu kọfí díẹ̀,’ tó o bá sì wá lọ rìn sígbà tó ti ṣe ìpápánu rẹ̀ tó gbayì tán, a jẹ́ pé o mọ̀ ọ́n rìn gan-an.”
Ẹni ọdún márùnlélọ́gọ́rin ni Gladys, arábìnrin wa tó dàgbà jù, tí ẹni tó kéré jù sì jẹ́ ọdún mẹ́rìndínláàádọ́rin. Gbogbo wa jẹ́ Ẹlẹ́rìí tó ń ṣe déédéé. Mẹ́ta nínú wa jẹ́ míṣọ́nnárì lẹ́yìn táa kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Watchtower Bible School of Gilead. Elizabeth tó ń gbé báyìí ní Newport Beach, ní California lọ sí kíláàsì kẹtàlá iléèwé náà ó sì sìn ní ìlú Callao, Peru, fún ọdún márùn-ún. Ruth lọ sí kíláàsì karùndínlógójì. Òun àti ọkọ rẹ̀, Alvin Stauffer, jẹ́ míṣọ́nnárì ní Ọsirélíà fún ọdún márùn-ún. Kíláàsì kẹrin ti Gilead lèmi lọ, nígbà tó sì di 1947, wọ́n yàn mí sí ìlú Mẹ́síkò, níbi tí mo ti fẹ́ Rodolfo Lozano lọ́dún 1955. a Àwa méjèèjì ń sìn ní Mẹ́síkò látìgbà náà wá.
Àwa arábìnrin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá kún fún ọpẹ́ gidigidi pé ara wa le. Ìyẹn jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti máa báa lọ láti sin Jèhófà pẹ̀lú gbogbo èrò inú wa, ọkàn wa, àti okun wa níwọ̀n ìgbà tí Jèhófà bá ṣì fẹ́ ẹ bẹ́ẹ̀, nísinsìnyí àti títí lọ gbére nínú ayé tuntun rẹ̀.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a O lè rí ìrírí rẹ̀ nínú ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ January 1, 2001.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Agnes, nígbà tó ṣèrìbọmi, 1997
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Elizabeth, ní ọjọ́ tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Gilead, 1949
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Esther (lápá ọ̀tún) ní ọ́fíìsì ẹ̀ka ní Mẹ́síkò, 1950
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Ruth àti Alvin Stauffer ń sìn bí ìránṣẹ́ ilẹ̀ òkèèrè ní ọ́fíìsì ẹ̀ka ní Mẹ́síkò, 1987