O Lè Rí Ìrànwọ́
O Lè Rí Ìrànwọ́
ỌKÙNRIN ara Switzerland kan tó jẹ́ ẹni ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n kó oògùn oorun, oníhóró mọ́kàndínláàádọ́ta, ó di wì nínú kọ́ọ̀pù. Ó wa bi ara rẹ̀ pé: ‘Ṣé kí n kó o mì àbí kí n máà kó o mì.’ Ìyàwó rẹ̀ àtàwọn ọmọ rẹ̀ ti fi í sílẹ̀, ó sì wà nínú ìbànújẹ́ ọkàn tó pabanbarì. Àmọ́ lẹ́yìn tó da oògùn ọ̀hún jẹ tán ló bá figbe bọnu pé: ‘Rárá o. Mi ò fẹ́ kú mọ́!’ Ọlọ́run bá a ṣé e, kò kú, ẹnu ara rẹ̀ ló sì fi ṣàlàyé ohun tójú rẹ̀ rí. Gbogbo ìgbà kọ́ ni ìgbìyànjú láti gbẹ̀mí ara ẹni máa ń yọrí sí ikú.
Nípa ti àwọn ọ̀dọ́langba tó máa ń gbìyànjú láti pa ara wọn, Alex Crosby tó wà ní Ibùdó Tó Ń Káwọ́ Àrùn Tó sì Ń Dènà Rẹ̀ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Tó o bá kàn tiẹ̀ lè dá wọn dúró fún wákàtí díẹ̀ kí wọ́n tó ṣe é, o lè gbà ẹ̀mí wọ́n là. Tó o bá wá nǹkan ṣe, ọ̀pọ̀ ni o lè gbà sílẹ̀ kó tó di pé wọ́n para wọn. O lè dá ẹ̀mí wọn sí.”
Nígbà tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Hisashi Kurosawa ń ṣiṣẹ́ ní Ibùdó Ọ̀ràn Pàjáwìrì àti Ìgbẹ̀mílà ní Kọ́lẹ́ẹ̀jì Ìṣègùn ti Japan, ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn èèyàn tó ti fẹ́ gbẹ̀mí ara wọn tẹ́lẹ̀ ló ràn lọ́wọ́ tí wọ́n fi nífẹ̀ẹ́ láti tún wà láàyè lẹ́ẹ̀kan sí i. Ó dájú pé, téèyàn bá lo ọ̀nà èyíkéyìí tó mọ̀ láti fi dí wọn lọ́wọ́, ọ̀pọ̀ ẹ̀mí la lè gbà là. Irú ìrànlọ́wọ́ wo ni wọ́n nílò?
Àwọn Ohun Tó Fà Á Ni Kí O Bójú Tó
Gẹ́gẹ́ báa ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, àwọn tó ń ṣèwádìí sọ pé ìdá àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tó gbẹ̀mí ara wọn ló ní ìdààmú ọpọlọ tàbí kó jẹ́ pé wọ́n ń lo oògùn olóró. Èyí ló mú Eve K. Mościcki tó wà ní Ibùdó Ẹ̀kọ́ Ìlera Ọpọlọ ti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Ìrètí tó ga jù lọ fún dídènà ìfọwọ́-ara-ẹni-gbẹ̀mí-ara-ẹni láàárín onírúurú èèyàn ni pé kí á dènà ìṣòro inú ọpọlọ àti ti oògùn olóró.”
Ohun tó wá báni nínú jẹ ni pé, ọ̀pọ̀ àwọn tó ní ìṣòro yìí ni kì í wá ìrànwọ́. Kí nìdí? Yoshitomo Takahashi, tó wà ní Ilé Ẹ̀kọ́ Àrùn Ọpọlọ ti Ìlú Tokyo àti Àgbègbè Rẹ̀ sọ pé: “Ojú burúkú ni wọ́n máa ń fi wo irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ láwùjọ.” Ó fi kún un pé èyí ló fà á tó fi jẹ́ pé, kódà, àwọn tó ń fura pé nǹkan kan ń yọ wọ́n lẹ́nu kì í tètè wá ìtọ́jú.
Àmọ́ ṣá, àwọn kan wà, tí wọn kò jẹ́ jẹ́ kí ìtìjú di àrùn sí àwọn lára. Gbangba báyìí ni Hiroshi Ogawa, ìlúmọ̀ọ́ká olùpolówó orí tẹlifíṣọ̀n kan, tó tiẹ̀ ti ń gbé eré tiẹ̀ gan-an jáde ní Japan fún ọdún mẹ́tàdínlógún ti sọ pé, òún ní ìsoríkọ́ àti pé díẹ̀ ló kù kóun gbẹ̀mí ara òun. Ogawa sọ pé: “Ìdààmú ọkàn kò yàtọ̀ sí àìsàn kan tó máa ń yọ ọpọlọ lẹ́nu.” Ó ṣàlàyé pé kò sẹ́ni tí kò lè ṣẹlẹ̀ sí, ṣùgbọ́n ó ṣeé ṣe láti bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.
Wá Ẹnì Kan Bá Sọ̀rọ̀
Béla Buda, òṣìṣẹ́ ètò ìlera ní Hungary tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ níṣàájú sọ pé: “Nígbà tẹ́nì kan bá ń dá nìkan kojú ìṣòro rẹ̀, ńṣe lá máa wò ó pé kò sí ẹni tí ìṣòro rẹ̀ tó tòun àti pé kò sí ọ̀nà àbáyọ.” Ńṣe ni ọrọ̀ yìí tẹnu mọ́ ọgbọ́n tó wà nínú òwe àtijọ́ inú Bíbélì náà pé: “Ẹni tí ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ yóò máa wá ìyánhànhàn onímọtara-ẹni-nìkan; gbogbo ọgbọ́n gbígbéṣẹ́ ni yóò ta kété sí.”—Òwe 18:1.
Fetí sí ọ̀rọ̀ ọgbọ́n yẹn o. Máà dá nìkan kojú ìṣòro rẹ. Wá ẹni tó o lè fọkàn tán tí wàá lè sọ gbogbo tinú ẹ fún. Àmọ́, o lè wá sọ pé, ‘ṣùgbọ́n mi ò lẹ́nì kankan tí mo lè finú hàn.’ Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń lérò bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Naoki Sato tó jẹ́ ọ̀gá nínú ọ̀ràn ìlera ọpọlọ ti sọ. Sato sọ pé àwọn èèyàn náà lè máà sọ tinú wọn jáde fún ẹnikẹ́ni torí wọn kì í fẹ́ kí ẹnì kankan mọ ibi tí wọ́n kù sí.
Ibo wá lẹnì kan lè yíjú sí láti rí ẹni tó máa tẹ́tí gbọ́ ọ? Níbi púpọ̀, ó lè wá ìrànwọ́ àwọn àjọ tó ń dènà ìfọwọ́-ara-ẹni-para-ẹni tàbí kó tẹ àwọn tó máa ń ran ẹni tó bá níṣòro lọ́wọ́ láago tàbí kẹ̀ kó wá dókítà gidi tó mọ̀ nípa àwọn ìṣòro tó ní í ṣe pẹ̀lú àròdùn ọkàn. Àmọ́ àwọn ògbógi kan tún sọ ohun mìíràn tó lè ṣèrànwọ́—ìyẹn ni ìsìn. Ọ̀nà wo nìyẹn fi lè ṣèrànwọ́?
Wọ́n Rí Ìrànlọ́wọ́ Tí Wọ́n Nílò Gbà
Marin, tó jẹ́ aláìlera tó ń gbé ní Bulgaria, ti wò ó pé kò sí ohun tó kù mọ́ ju kí òun para òun lọ. Lọ́jọ́ kan, ó ṣèèṣì rí ìwé ìròyìn ẹlẹ́sìn náà, Ilé Ìṣọ́, tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde. Ó tẹ́wọ́ gba ìkésíni tó wà nínú ìwé ìròyìn náà pé kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ òun. Marin sọ ohun tó jẹ́ àbájáde rẹ̀ pé: “Mo kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ wọn pé ìwàláàyè jẹ́ ẹ̀bùn kan látọ̀dọ̀ Baba wa ọ̀run àti pé a kò ní ẹ̀tọ́ láti ṣera wa léṣe tàbí ká fọwọ́ ara wa gbẹ̀mí ara wa. Fún ìdí yẹn, mo pa èrò tí mo ní lọ́kàn tẹ́lẹ̀ láti pa ara mi tì mo sì tún padà nífẹ̀ẹ́ láti wà láàyè!” Marin tún rí ìtìlẹ́yìn onífẹ̀ẹ́ nínú ìjọ Kristẹni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìlera èèyàn ṣì ni síbẹ̀, ó sọ pé: “Ìgbésí ayé mi tí kún fún ayọ̀ báyìí, ó sì tòrò minimini, mo ní ọ̀pọ̀ nǹkan tó gbádùn mọ́ni tí mo lè ṣe—kódà wọ́n pọ̀ débi pé mi ò lè ṣe wọ́n tán! Ọpẹ́lọpẹ́ Jèhófà àti àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ ló mú kí gbogbo èyí ṣeé ṣe.”
Ọkùnrin ará Switzerland tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ náà rí ìrànwọ́ gbà lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lọ́jọ́ òní, ó máa ń sọ nípa “inú rere tí ìdílé Kristẹni kan fi hàn” tí wọ́n gbà á sínú ilé wọn. Ó fi kún un pé: “Fún ọ̀pọ̀ ọjọ́ lẹ́yìn náà làwọn mẹ́ńbà ìjọ [àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà] fi ń ké sí mi lọ́kọ̀ọ̀kan láti wá máa jẹun nílé wọn. Kì í ṣe bí wọ́n ṣe ṣaájò mi nìkan lohun tó ṣèrànwọ́, àmọ́ bí mo ṣe ń rí ẹni bá sọ̀rọ̀.”
Ẹ̀kọ́ tí ọkùnrin yìí kọ́ nínú Bíbélì tún fún un níṣìírí gan-an ni, àgàgà nígbà tó wá mọ̀ nípa ìfẹ́ tí Ọlọ́run òtítọ́ náà, Jèhófà, ní fún aráyé. (Jòhánù 3:16) Ní ti tòótọ́, Jèhófà Ọlọ́run á tẹ́tí sí ọ nígbà tó o bá ‘tú ọkàn-àyà rẹ jáde’ fún un. (Sáàmù 62:8) “Ojú rẹ̀ ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé,” kì í ṣe láti wá àṣìṣe àwọn èèyàn, ṣùgbọ́n “láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.” (2 Kíróníkà 16:9) Jèhófà fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé: “Má fòyà, nítorí mo wà pẹ̀lú rẹ. Má wò yí ká, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Dájúdájú, èmi yóò fi okun fún ọ. Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ti tòótọ́. Èmi yóò fi ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi dì ọ́ mú ṣinṣin ní ti tòótọ́.”—Aísáyà 41:10.
Nígbà tí Ọkùnrin ará Switzerland náà ń sọ nípa ìlérí tí Ọlọ́run ṣe nípa ayé tuntun, ó sọ pé: “Ìrànlọ́wọ́ tí èyí ṣe nínú sísọ ìṣòro mi di fífúyẹ́ kò kéré.” Ìrètí yìí, èyí tí a ṣàpèjúwe rẹ̀ pé ó jẹ́ “ìdákọ̀ró fún ọkàn,” ní í ṣe pẹ̀lú ìlérí ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.—Hébérù 6:19; Sáàmù 37:10, 11, 29.
Ìwàláàyè Rẹ Jẹ Àwọn Mìíràn Lógún
Lóòótọ́, o lè máa kojú àwọn ìṣòro tó lè mú kí o máa rò pé o ò lẹ́nì kan àti pé ikú rẹ kò ná ẹnikẹ́ni ní ohunkóhun. Àmọ́, má gbàgbé pé: Ìyàtọ̀ ńlá ló wà láàárín kéèyàn ronú pé ńṣe lòún nìkan wà àti nínìkan wà lóòótọ́. Lásìkò tí kíkọ Bíbélì ń lọ lọ́wọ́, wòlíì Èlíjà bá ara rẹ̀ nínú ipò kan tó kó o sí ìbànújẹ́ gan-an. Ó sọ fún Jèhófà pé: ‘Wọ́n ti fi idà pa àwọn wòlíì rẹ, tí ó fi jẹ́ pé èmi nìkan ṣoṣo ni ó ṣẹ́ kù.’ Bẹ́ẹ̀ ni, bí ẹni pé Èlíjà nìkan ló ṣẹ́ kù ló rí lára rẹ̀, ó sì nídìí. Àwọn wòlíì ẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n ti pa kì í ṣe kékeré. Ikú ń rọ̀ dẹ̀dẹ̀ lórí òun náà, ó sì ń sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ̀. Àmọ́ ṣe òótọ́ ni pé òun nìkan ló kù? Rárá o. Jèhófà jẹ́ kó mọ̀ pé, ó ṣì ku nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje àwọn èèyàn tó jẹ́ adúróṣinṣin, tó jẹ́ pé, bíi tiẹ̀, wọ́n ń fi ìṣòtítọ́ sapá láti sin Ọlọ́run òtítọ́ làwọn àkókò tó kún fún ẹ̀rù yẹn. (1 Àwọn Ọba 19:1-18) Ìwọ náà ń kọ́? Ṣé ó lè jẹ́ pé o ò dá wà bó o ṣe rò pé o dá wà?
Àwọn èèyàn tó bìkítà nípa rẹ wà. O lè ronú nípa àwọn òbí rẹ, ọkọ rẹ, ìyàwó rẹ, àwọn ọmọ rẹ, àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Kò tán síbẹ̀ o. Nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, o lè rí àwọn Kristẹni tí wọ́n dàgbà dénú tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ lọ́kàn, tí wọ́n á fara balẹ̀ tẹ́tí gbọ́ ọ, tí wọ́n á gbàdúrà pẹ̀lú rẹ tí wọ́n á sì tún gbàdúrà fún ọ. (Jákọ́bù 5:14, 15) Kódà, ká tiẹ̀ wá ní gbogbo èèyàn aláìpé já ọ kulẹ̀, Ẹnì kan wà tí kò ní fi ọ́ sílẹ̀ láé. Ọba Dáfídì ìgbàanì sọ pé: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé baba mi àti ìyá mi fi mí sílẹ̀, àní Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò tẹ́wọ́ gbà mí.” (Sáàmù 27:10) Dájúdájú, Jèhófà ‘bìkítà fún ọ.’ (1 Pétérù 5:7) Má fìgbà kankan gbàgbé láé pé o ṣeyebíye lójú Jèhófà.
Ìwàláàyè jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Òótọ́ ni pé, ìgbà mìíràn wà tí ìgbésí ayé lè dà bí ìnira, tí kò ní jọ ẹ̀bùn níbì kankan. Rò ó wò ná, báwo ló ṣe máa rí lára rẹ ká ní o fún ẹnì kan ní ẹ̀bùn ṣíṣeyebíye kan, kẹ́ni yẹn wá sọ ọ́ nù láìtiẹ̀ tíì lò ó rárá? Àwa èèyàn aláìpé kò tíì bẹ̀rẹ̀ sí í lo ẹ̀bùn ìwàláàyè rárá ni ká sọ. Kódà gan-an, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé irú ìgbésí ayé tá a ń gbé lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí kì í ṣe ‘ìgbésí ayé tòótọ́’ lójú Ọlọ́run. (1 Tímótì 6:19) Ó dájú pé, láìpẹ́ sí àkókò yìí, ìgbésí ayé wa máa lójú ju báyìí lọ, yóò nítumọ̀, yóò si kún fún ayọ̀. Báwo?
Bíbélì sọ pé: ‘[Ọlọ́run] yóò nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.’ (Ìṣípayá 21:3, 4) Fojú inú wo bí ìgbésí ayé rẹ á ṣe rí nígbà táwọn ọ̀rọ̀ yẹn bá nímùúṣẹ. Fara balẹ̀ ronú nípa rẹ̀. Gbìyànjú láti fọkàn rẹ yàwòrán rẹ̀ ní kíkún, pẹ̀lú àrímáleèlọ ẹwà. Àwòrán yìí kì í ṣe àlá lásán o. Bó o ti ń ṣàṣàrò lórí ọ̀nà tí Jèhófà gbà bá àwọn èèyàn rẹ̀ lò láwọn àkókò tó kọjá, ìgbọ́kànlé tó o ní nínú rẹ̀ á pọ̀ sí i, àwòrán tó o fọkàn yà yẹn á sì túbọ̀ wá jẹ́ òótọ́ sí ọ.—Sáàmù 136:1-26.
Ó lè gba àkókò díẹ̀ kí ìfẹ́ rẹ láti wà láàyè tó padà dọ̀tun. Máà dẹ́kun gbígbàdúrà sí “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo, ẹni tí ń tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa.” (2 Kọ́ríńtì 1:3, 4; Róòmù 12:12; 1 Tẹsalóníkà 5:17) Jèhófà á fún ẹ ní okun tó o nílò. Á jẹ́ kó o mọ̀ pé kò sóhun tó dùn tó kí o wà láàyè.—Aísáyà 40:29.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Ǹjẹ́ O Lè Ran Ẹnì Kan Tó Fẹ́ Para Rẹ̀ Lọ́wọ́?
Kí ló yẹ kó o ṣe tẹ́nì kan bá sọ létí rẹ pé òun fẹ́ pa ara òun? Ibùdó Tó Ń Káwọ́ Àrùn Tó sì Ń Dènà Rẹ̀ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà dámọ̀ràn pé, “Tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa.” Fún un láyè láti ṣàlàyé bí nǹkan náà ṣe rí lára rẹ̀ gan-an. Àmọ́ ṣá o, lọ́pọ̀ ìgbà, ẹni tó fẹ́ gbẹ̀mí ara rẹ̀ kì í dá sí ẹnì kankan kò sì ní í sọ fún ẹ. Jẹ́ kó mọ̀ pé lóòótọ́ lo gbà pé ara ń ni í tàbí pé kò nírètí mọ́.
Tó o bá rọra fọgbọ́n sọ àwọn ìyípadà pàtàkì kan tó o ti kíyè sí nínú ìṣesí rẹ̀ fún un, ó lè sún un láti sọ tinú rẹ̀ jáde.
Bó o ti ń tẹ́tí gbọ́ ọ, máa fi ọ̀rọ̀ náà rora rẹ wò. Ibùdó tó Ń Káwọ́ Àrùn Tó sì Ń Dènà Rẹ̀ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Ó ṣe pàtàkì kó o tẹnu mọ́ ọn pé ìwàláàyè ẹni náà jẹ ọ́ lógún, pé ó tún jẹ àwọn mìíràn lógún pẹ̀lú.” Jẹ́ kó mọ bí ikú rẹ̀ ṣe máa kó ìdààmú bá ìwọ àtàwọn mìíràn tó. Ran ẹni náà lọ́wọ́ láti mọ̀ pé Ẹlẹ́dàá rẹ̀ bìkítà nípa rẹ̀.—1 Pétérù 5:7.
Àwọn ògbógi tún dámọ̀ràn pípalẹ̀ ohunkóhun tí ẹni náà lè lò láti fi gbẹ̀mí ara rẹ̀ mọ́ kúrò nílẹ̀—àgàgà ìbọn. Tí ọ̀rọ̀ náà bá ti kúrò ní kékeré, o lè gba ẹni náà nímọ̀ràn pé kó lọ rí dókítà. Tó bá sì le ju, kò sóhun méjì tí wàá ṣe ju pé kí ìwọ alára pe àwọn onítọ̀ọ́jú pàjáwìrì.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 21]
‘Ṣé Ọlọ́run Á Dárí Jì Mí fún Níní Irú Èrò Yẹn?’
Kíkẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ran ọ̀pọ̀ lọ́wọ́ láti borí èrò tí wọ́n ní tẹ́lẹ̀ láti pa ara wọn. Síbẹ̀, kò sẹ́ni tí àwọn ohun tí ń kó ìbànújẹ́ báni ní ìgbésí ayé yọ sílẹ̀ lóde òní. Ẹ̀rí ọkàn àwọn Kristẹni kan tí wọ́n ti ronú láti para wọn tẹ́lẹ̀ sábà máa ń dààmú wọn, tí á sì máa dá wọn lẹ́bi fún níní irú èrò yẹn. Ńṣe ni dídára wọn lẹ́bi á wulẹ̀ tún dá kún ìṣòro wọn. Nítorí náà, ọ̀nà wo ni wọ́n lè gbà kojú irú èrò bẹ́ẹ̀?
Ó dára láti mọ̀ pé àwọn ọkùnrin àti obìnrin olóòótọ́ kan wà lásìkò tí kíkọ Bíbélì ń lọ lọ́wọ́, tí wọ́n ní ìrònú tó gbòdì gan-an nípa ìgbésí ayé. Ìṣòro kan nínú ìdílé kó Rèbékà, aya Ísákì baba ńlá náà sí ìbànújẹ́ nígbà kan débi tó fi sọ pé: “Mo ti wá fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ìgbésí ayé tèmi yìí.” (Jẹ́nẹ́sísì 27:46) Jóòbù, tó pàdánù àwọn ọmọ rẹ̀, àlááfíà rẹ̀, ọrọ̀ rẹ̀, àti ipò rẹ̀ láwùjọ, sọ pé: “Dájúdájú, ọkàn mi kórìíra ìgbésí ayé mi tẹ̀gbintẹ̀gbin.” (Jóòbù 10:1) Mósè ké pe Ọlọ́run nígbà kan rí pé: “Jọ̀wọ́ kúkú pa mí dànù.” (Númérì 11:15) Èlíjà, tó jẹ́ wòlíì Ọlọ́run sọ nígbà kan pé: “Ó tó gẹ́ẹ́! Wàyí o, Jèhófà, gba ọkàn mi kúrò.” (1 Àwọn Ọba 19:4) Bẹ́ẹ̀ sì ni wòlíì Jónà sọ léraléra pé: “Kí n kú dànù sàn ju kí n wà láàyè.”—Jónà 4:8.
Ǹjẹ́ Jèhófà bínú sí àwọn èèyàn náà pé nǹkan rí báyìí lára wọn? Ó tì o. Àní ó tiẹ̀ tún pa àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ mọ́ sínú Bíbélì. Ṣùgbọ́n ó ṣe pàtàkì láti kíyè sí i pé, kò sí ọ̀kankan nínú àwọn olóòótọ́ wọ̀nyí tó jẹ́ kí bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára wọn sún wọn lọ gbẹ̀mí ara wọn. Jèhófà kà wọ́n sí; ó fẹ́ kí wọ́n wà láàyè. Ohun kan tó jẹ́ òótọ́ ni pé, ìwàláàyè àwọn ènìyàn búburú pàápàá jẹ Ọlọ́run lógún. Ó pàrọwà sí wọn pé kí wọ́n yí ọ̀nà wọn padà kí wọ́n sì “máa wà láàyè nìṣó.” (Ìsíkíẹ́lì 33:11) Mélòómélòó wá ló fẹ́ kí àwọn tó tún ń ṣàníyàn láti rí ojú rere rẹ̀ wà láàyè!
Ọlọ́run ti pèsè ẹbọ ìràpadà Ọmọ rẹ̀, ìjọ Kristẹni, Bíbélì, àti àǹfààní láti gbàdúrà. Ọ̀nà láti bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ yìí, ìyẹn nípasẹ̀ àdúrà, kì í dí nígbà kankan. Ọlọ́run lè tẹ́tí sí gbogbo àwọn tó bá tọ̀ ọ́ wá, tí wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti òótọ́ inú. “Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a sún mọ́ ìtẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí pẹ̀lú òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ, kí a lè rí àánú gbà, kí a sì rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún ìrànlọ́wọ́ ní àkókò tí ó tọ́.”—Hébérù 4:16.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 22]
Ṣé O Ní Ẹnì Kan Tó Ti Fọwọ́ Ara Rẹ̀ Para Rẹ̀?
Nígbà tí ẹnì kan bá fọwọ́ ara rẹ̀ para rẹ̀, ìrònú tó máa ń kó ẹbí àti ọ̀rẹ́ sí kì í ṣe kékeré rárá. Ọ̀pọ̀ ló máa ń dá ara wọn lẹ́bi fún ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà. Wọ́n á máa sọ àwọn nǹkan bíi: ‘Ká ní mi ò kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ bọ̀rọ̀ lọ́jọ́ yẹn,’ ‘Ká ní mi ò sọ́ ọ̀rọ̀ tí mo sọ lásìkò yẹn ni,’ ‘Ká ní mo mọ̀ kí n ti ṣe nǹkankan láti ràn án lọ́wọ́.’ Wọ́n á wá máa kìka àbámọ̀ bọnu pé, ‘Ká ní mo ti ṣegbá ni, ká ní mo ti ṣàwo ni, èèyàn mi yìí ì bá máà kú.’ Àmọ́, ṣé ó bójú mu kó o máa dá ara rẹ lẹ́bi nítorí ẹni tó fọwọ́ ara rẹ̀ para rẹ̀?
Rántí o, ìgbà tí ìfọwọ́-ara-ẹni-para-ẹni bá ti ṣẹlẹ̀ tán lèèyàn ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ń ronú nípa àwọn àmì tó rí. Kó tóó ṣẹlẹ̀, kì í rọrùn láti rí àwọn àmì yẹn. Bíbélì sọ pé: “Àyà mọ ikorò ara rẹ̀; ko si alejo kan tii ṣe alábapin ayọ̀ rẹ̀.” (Òwe 14:10, Bibeli Yoruba Atọ́ka) Nígbà mìíràn, kò tiẹ̀ ṣeé ṣe rárá ni láti mọ ohun tí ẹlòmíràn ń rò tàbí tó ń bá yí. Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tó ń gbèrò àti pa ara wọn ni kì í lè ṣàlàyé ohun tó wà nínú wọn lọ́hùn-ún fún àwọn ẹlòmíràn, kódà fáwọn ẹbí wọn tó sún mọ́ wọn jù lọ pàápàá.
Ìwé kan tó ń jẹ́ Giving Sorrow Words sọ nípa àwọn àmì tó lè fi hàn pé ẹnì kan fẹ́ láti pa ara rẹ̀, ó sọ pé: “Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, kì í fìgbà gbogbo rọrùn láti mọ irú àwọn àmì bẹ́ẹ̀.” Ìwé yìí kan náà tún sọ pé, ká tiẹ̀ ní o rí àwọn àmì kan, ìyẹn kò fi dandan túmọ̀ sí pé o lè dá ìpara ẹni náà dúró kó má ṣẹlẹ̀. Dípò tí wàá fi máa dára rẹ lóró, o lè rí ìtùnú nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí ọlọgbọ́n ọba Sólómọ́nì sọ pé: “Àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá.” (Oníwàásù 9:5) Èèyàn rẹ yìí ò sí níbì kankan tó ti ń joró nínú iná ọ̀run àpáàdì. Bẹ́ẹ̀ sì ni ìdààmú àti ẹ̀dùn ọkàn tó kó wàhálà bá ọpọlọ rẹ̀, èyí tó mú kó lọ fọwọ́ ara rẹ̀ pa ara rẹ̀ ti dópin. Kò sí nínú ìrora rárá; ńṣe ló ń sinmi.
Ohun tó máa dára jù lọ báyìí ni pé kó o gbájú mọ́ àlááfíà àwọn tó kù láàyè àti ti ìwọ fúnra rẹ̀. Sólómọ́nì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Gbogbo ohun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, fi agbára rẹ ṣe é” nígbà tó o ṣì wà láàyè. (Oníwàásù 9:10) Fọkàn balẹ̀ pé ìrètí ìwàláàyè ọjọ́ iwájú àwọn tó pa ara wọn wà lọ́wọ́ Jèhófà, “Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.”—2 Kọ́ríńtì 1:3. a
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wàá rí èrò tó tọ́ nípa ìrètí ọjọ́ iwájú tó wà fáwọn tó fọwọ́ ara wọn pa ara wọn nínú àpilẹ̀kọ náà “Oju Ìwoye Bíbélì: Ipara Ẹni—Ajinde Nkọ?” nínú ìtẹ̀jáde Jí! ti March 8, 1991.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Wá ẹnì kan bá sọ̀rọ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Ìwàláàyè rẹ̀ ṣe pàtàkì lójú àwọn ẹlòmíràn