Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìrètí Ń Bẹ fún Àwọn Tó Lárùn Oríkèé-Ara-Ríro

Ìrètí Ń Bẹ fún Àwọn Tó Lárùn Oríkèé-Ara-Ríro

Ìrètí Ń Bẹ fún Àwọn Tó Lárùn Oríkèé-Ara-Ríro

DÓKÍTÀ Fatima Mili sọ pé “àrùn oríkèé-ara-ríro kì í pa èèyàn bí àrùn ọkàn tàbí àrùn jẹjẹrẹ, àmọ́ ohun tó ń sọ ìgbésí ayé èèyàn dà kò dáa rárá.” Àrùn oríkèé-ara-ríro lè nípa lórí gbogbo ìgbésí ayé ẹnì kan. Kí tiẹ̀ ni díẹ̀ lára àwọn ìṣòro tó ń kojú àwọn tó ní àrùn oríkèé-ara-ríro? Ṣé ó lè ṣeé ṣe fún wọn láti fara dà á?

Katia, a ẹni ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n láti Ítálì sọ pé: “Látìgbà tí wọ́n ti ṣàyẹ̀wò pé mo ní àrùn oríkèé-ara-ríro nígbà tí mo wà lọ́mọ ogún ọdún ni gbogbo ìgbésí ayé mi ti yí padà. Mi ò lè ṣiṣẹ́ mọ́ bẹ́ẹ̀ ni mo tún fi iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún sílẹ̀ nítorí ìrora náà.” Gbogbo àwọn tó ní àrùn oríkèé-ara-ríro ló máa ń jẹ ìrora. Alan, ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́ta ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ pé: “Gbogbo ìgbà ni ibì kan á ṣáà máa dùn ẹ lára, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó lè má fi bẹ́ẹ̀ pọ̀.” Ìṣòro mìíràn tún ni kó máa rẹni. Sarah, ẹni ọdún mọ́kànlélógún sọ pé: “Ká tiẹ̀ ní o lè fara da ìrora àti wíwú tó ń wú, rírẹ̀ tá á máa rẹ̀ ọ́ kọjá àfaradà.”

Ẹ̀dùn Ọkàn

Gẹ́gẹ́ bí Setsuko, ẹni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́ta ní Japan ṣe sọ, bí ìrora lílekoko kan bá ń bá ọ fà á lójoojúmọ́, ó lè “sọ ọ́ dìdàkudà ní ti ìmọ̀lára àti ọpọlọ.” Àní, àtimú pẹ́ńsù nílẹ̀ tàbí dídi tẹlifóònù mú lè di wàhálà! Kazumi, ẹni ọdún mẹ́tàdínláàádọ́ta kérora pé: “Kódà mi ò lè ṣe àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tọ́mọdé lè ṣe.” Janice, ẹni ọgọ́ta ọdún tí kò lè dúró dáadáa tí ò sì lè rìn dáadáa mọ́ sọ pé: “Ó máa ń bà mí nínú jẹ́ nítorí pé mi ò lè ṣe àwọn nǹkan tí mo máa ń ṣe tẹ́lẹ̀ mọ́.”

Àìlèṣe àwọn nǹkan téèyàn ń ṣe tẹ́lẹ̀ yìí lè mú kí gbogbo nǹkan sú èèyàn kólúwarẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí í ní èròkerò nípa ara rẹ̀. Gaku, ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sọ pé: “Bí mi ò ṣe lè nípìn-ín kíkún nínú iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere tàbí ṣe àwọn iṣẹ́ inú ìjọ mú kí n máa lérò pé mi ò wúlò páàpáà.” Francesca, tí àrùn oríkèé-ara-ríro ti ń bá jà látìgbà tó ti wà lọ́mọ ọdún méjì sọ pé ńṣe “lòun túbọ̀ ń nímọ̀lára pé kò sí ìrètí kankan fún òun.” Irú àìnírètí bẹ́ẹ̀ lè nípa tí kò dára lórí ipò tẹ̀mí èèyàn. Joyce, tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Gúúsù Áfíríkà sọ pé ńṣe lòun bẹ̀rẹ̀ sí pa àwọn ìpàdé Kristẹni jẹ. Ó sọ pé: “Kò tiẹ̀ wù mí láti rí ẹnikẹ́ni sójú.”

Ẹni tí àrùn yìí bá ń ṣe tún lè máa ṣàníyàn gan-an nípa ọjọ́ iwájú, ìyẹn ìbẹ̀rù pé òun lè máà lè rìn mọ́ tá á sì wá di kí àwọn èèyàn máa tọ́jú òun, ìbẹ̀rù pé ó lè máà sí ẹnikẹ́ni tó máa bójú tó òun, ìbẹ̀rù pé òun lè ṣubú kí egungun òun sì kán, ìbẹ̀rù pé òun lè máà lè pèsè fún ìdílé òun. Yoko, ẹni ọdún méjìléláàádọ́ta sọ pé: “Nígbà tí mo bá rí i tí oríkèé ara mi ń bà jẹ́, mo máa ń bẹ̀rù gan-an pé ó tún máa pọ̀ sí i.”

Ẹ̀dùn ọkàn lè bá àwọn mẹ́ńbà ìdílé náà, nítorí pé ojoojúmọ́ ni wọ́n á máa rí i bí ẹni tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ṣe ń jẹ̀rora. Ó tiẹ̀ lè dá wàhálà sílẹ̀ nínú ìgbéyàwó àwọn mìíràn pàápàá. Obìnrin kan ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Denise sọ pé: “Lẹ́yìn ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tá a ti fẹ́ra wa, ọkọ mi sọ lọ́jọ́ kan pé, ‘Mi ò lè fara da àrùn oríkèé-ara-ríro tó ń bá ọ jà yìí mọ́ o!’ Ló bá filé sílẹ̀ fún èmi nìkan àti ọmọbìnrin wa ọlọ́dún márùn-ún.”

Nítorí náà, àtàwọn tí àrùn oríkèé-ara-ríro ń ṣe àtàwọn èèyàn wọn ni nǹkan ò rọgbọ fún. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ṣì ń fara dà á! Ẹ jẹ́ ká wo báwọn kan ṣe ń ṣe é.

Mọ̀wọ̀n Araàrẹ

Bí àrùn oríkèé-ara-ríro bá ń yọ ọ́ lẹ́nu, rí i pé o ń fún ara rẹ nísinmi dáadáa nítorí pé ó lè mú kí àárẹ̀ dín kù. Àmọ́ èyí kò wá túmọ̀ sí pé kí o má ṣe àwọn ìgbòkègbodò tó yẹ ní ṣíṣe mọ́ o. Timothy ṣàlàyé pé: “O ò gbọ́dọ̀ dara nù rárá nítorí tó o bá jẹ́ kí àrùn oríkèé-ara-ríro dọ̀gá mọ́ ẹ lọ́wọ́, wàá kàn wà lójú kan ni tí wàá máa jẹ̀rora.” Oníṣègùn àrùn làkúrègbé náà William Ginsburg, ti Ilé Ìwòsàn Mayo sọ pé: “Ìyàtọ̀ fífarasin kan wà láàárín kéèyàn máa ṣiṣẹ́ jù àti kéèyàn má ṣíṣẹ tó. Nígbà mìíràn, èèyàn ní láti rán àwọn tí àìsàn náà ń ṣe létí pé kí wọ́n má gbà gbé pé àìsàn ń ṣe wọ́n o.”

Èyí lè kan pé kí o yí èrò rẹ padà nípa ohun tí agbára rẹ gbé. Daphne, tó wà ní Gúúsù Áfíríkà sọ pé: “Mi ò tan ara mi jẹ láti máa ronú pé mi ò lágbára láti ṣe àwọn ohun kan mọ́; ó kàn jẹ́ pé lẹ́sọ̀lẹ́sọ̀ ni mò ń ṣe wọ́n ni. Dípò tí mi ò bá fi máa ṣàníyàn tàbí kí gbogbo nǹkan sú mi, ńṣe ni mo máa ń ṣe wọ́n wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́.”

Ó tún dára kéèyàn mọ àwọn ohun èlò tó lè ran èèyàn lọ́wọ́ téèyàn lè máa lò, bóyá kó o bá dókítà rẹ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Keiko sọ pé: “A ti ṣe ohun èlò kan sílé wa tó máa ń gbé mi gun orí àwọn àtẹ̀gùn ilé. Àwọn ohun tá a fi ń ṣí ilẹ̀kùn máa ń ṣe ọrùn ọwọ́ mi léṣe, èyí ló mú ká yọ wọ́n kúrò. Ní báyìí, mo lè fi orí mi ti gbogbo ilẹ̀kùn ilé wa láti ṣí wọn. A ti rọ àwọn irin gọngọ síbi omi ẹ̀rọ kí n bàa lè ṣe àwọn iṣẹ́ ilé pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́.” Gail, tí àrun oríkèé-ara-ríro ń ṣe náà sọ pé: “Irin tí mo fi sídìí kọ́kọ́rọ́ ilé mi àti ti ọkọ̀ mi gùn gan-an, èyí sì mú kó túbọ̀ rọrùn fún mi láti lò wọ́n. Kóòmù tí wọ́n ṣe pọ̀ mọ́ búrọ́ọ̀ṣì irun ni mò ń lò, ó sì gùn débi pé mo lè yí i sí èyíkéyìí tí mo bá fẹ́ ẹ́ lò níbẹ̀.”

Ìtìlẹ́yìn Ìdílé Jẹ́ “Orísun Okun” Kan

Carla, tó wà ní ilẹ̀ Brazil sọ pé: “Ìtìlẹ́yìn ọkọ mi ti ṣe gudugudu méje fún mi. Bó ṣe máa ń tẹ̀ lé mi lọ sọ́dọ̀ dókítà máa ń fi mí lọ́kàn balẹ̀. A jọ ń fetí ara wa gbọ́ bí àrùn náà ṣe máa nípa lórí mi ni, àwọn àmì rẹ̀ àti irú ìtọ́jú tí mo máa gbà. Inú mi dùn nítorí pé ó lóye ìrora tí mo ń rún mọ́ra.” Òdodo ọ̀rọ̀, àwọn èèyàn tó bá mọ ibi tí agbára ọkọ tàbí aya wọn mọ tí wọ́n sì ń fẹ́ láti lóye ipò tí wọ́n wà dáadáa máa ń jẹ́ orísun okun àti ìtìlẹ́yìn ńláǹlà.

Fún àpẹẹrẹ, Bette bẹ̀rẹ̀ sí ṣe iṣẹ́ àwọn tó ń tọ́jú ilé nígbà tí àrùn ọkọ rẹ̀ kò jẹ́ kó lè ṣe iṣẹ́ kọ́lékọ́lé tó ń ṣe tẹ́lẹ̀ mọ́. Ọkọ Kazumi máa ń bójú tó ìyàwó rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ló tún máa ń ṣe àwọn iṣẹ́ ilé tí kò lè ṣe. Kò tán síbẹ̀ o, ó tún kọ́ àwọn ọmọ wọn láti ṣe àwọn iṣẹ́ tí agbára wọn bá ká. Kazumi sọ pé: “Orísun okun ni ọkọ mi jẹ́. Ká ní kì í ṣe ti bó ṣe ń ràn mí lọ́wọ́ ni, àìlera mi ì bá burú ju báyìí lọ gan-an.”

Obìnrin kan ní Ọsirélíà tó ń jẹ́ Carol, ṣe kìlọ̀kìlọ̀ pé: “Ṣọ́ra kó o má ṣe ṣiṣẹ́ kọjá agbára rẹ. Mo tètè máa ń lérò pé mi ò tóótun nígbà tí mi ò bá lè ṣe àwọn nǹkan tí ìdílé mi ń ṣe.” Tí ìdílé bá fi òye àti ìgbatẹnirò ṣètìlẹ́yìn, ó lè jẹ́ orísun ńláǹlà fún ẹni tára rẹ̀ kò yá.

Ìrànlọ́wọ́ Nípa Tẹ̀mí

Katia sọ pé: “Bí irú àìsàn báyìí bá ń ṣe ẹnì kan, ohun tó máa wà lọ́kàn onítọ̀hún ni pé àwọn èèyàn kò mọ iná tó ń jó òun lábẹ́ aṣọ. Èyí ló mú kó ṣe pàtàkì láti yíjú sí Jèhófà Ọlọ́run, ká sì mọ̀ pé ó lóye ohun tó ń ṣe wá nípa tara àti pé ó mọ ẹ̀dùn ọkàn wa. (Sáàmù 31:7) Àjọṣe tó dán mọ́rán tí mo ní pẹ̀lú rẹ̀ ló fọkàn mi balẹ̀ tí mo fi ń fara da àìsàn tó ń bá mi jà láìbọ́hùn.” Lọ́nà tó bá a mu, Bíbélì pe Jèhófà ní, “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo, ẹni tí ń tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa.”—2 Kọ́ríńtì 1:3, 4.

Fún ìdí yìí, àdúrà jẹ́ orísun ìtùnú ńláǹlà fún ẹnì tí àìsàn tí kì í lọ bọ̀rọ̀ bá ń ṣe. Kazumi sọ pé: “Láàárín àwọn òru gígùn wọ̀nyẹn tí ìrora kì í jẹ́ kí n lè sùn, pẹ̀lú omijé ni mo máa ń ro gbogbo ohun tó wà lọ́kàn mi fún Jèhófà. Mo máa ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé kó fún mi lókun láti fara da ìrora náà kó sì fún mi ní òye láti kojú gbogbo ìṣòro mi. Jèhófà dáhùn àwọn àdúrà mi o.” Bákan náà ni Francesca rí àtìlẹ́yìn onífẹ̀ẹ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ó sọ pé: “Ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Fílípì 4:13, ti ṣẹ sí mi lára pé: ‘Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.’”

Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jèhófà Ọlọ́run máa ń lo ìjọ Kristẹni láti pèsè àtìlẹ́yìn. Fún àpẹẹrẹ, Gail sọ nípa ìrànlọ́wọ́ tóun gbà látọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó wà nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí òun wà. Ó sọ pé: “Ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn sí mi ni kò jẹ́ kí n soríkọ́.” Bákan náà, nígbà tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ Keiko pé, “Ǹjẹ́ o lè ronú kan ohun kan tó o fẹ́ràn nínú ìgbésí ayé rẹ?” ó dáhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, ìfẹ́ àti ìbánikẹ́dùn tí tàgbàtèwe nínú ìjọ fi hàn sí mi ni!”

Àwọn alábòójútó nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò kẹ̀rẹ̀ nínú ṣíṣe irú àtìlẹ́yìn bẹ́ẹ̀. Setsuko sọ pé: “Mi ò lè ṣàlàyé bára ẹni tí àrùn ń bá jà ṣe máa ń yá tó táwọn alàgbà bá tẹ́tí sí i tí wọ́n sì tún tù ú nínú.” Àmọ́ ṣá o, gẹ́gẹ́ bí Daniel tóun náà ní àrùn oríkèé-ara-ríro ṣe sọ, “bá a bá gba àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa láyè láti ràn wá lọ́wọ́ ni wọ́n tó lè ṣe bẹ́ẹ̀.” Ìdí rèé tó fi ṣe kókó pé kí àwọn tí àrùn náà ń ṣe má ṣe máa fi àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn sílẹ̀, kí wọ́n máa sa gbogbo ipá wọn láti wá sáwọn ìpàdé ìjọ. (Hébérù 10:24, 25) Ibẹ̀ ni wọ́n ti lè rí ìṣírí nípa tẹ̀mí tí wọ́n nílò láti fara dà á.

Ìrora Máa Dópin

Àwọn tí àrùn oríkèé-ara-ríro ń ṣe ń dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn onímọ̀ ìṣègùn fún gudugudu méje tí wọ́n ṣe títí di báyìí. Síbẹ̀, ìtọ́jú tó tiẹ̀ dára jù lọ pàápàá kò dà bíi kí àrùn ọ̀hún lọ pátápátá. Ní paríparí rẹ̀, àwọn tó ní àrùn yìí lè rí ìtùnú tó ga jù lọ bí wọ́n bá tẹ́wọ́ gba ìlérí ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣe. b (Aísáyà 33:24; Ìṣípayá 21:3, 4) Nínú ayé yẹn, ‘àwọn tó yarọ á gun òkè bí akọ àgbọ̀nrín.’ (Aísáyà 35:6) Àrùn oríkèé-ara-ríro àtàwọn àrùn mìíràn tó ń ṣe ẹ̀dá ènìyàn máa di àwátì! Ìdí rèé tí Peter tí oríkèé egungun ẹ̀yìn ń dà láàmú fi sọ pé: “Mo nírètí tó ń fi mí lọ́kàn balẹ̀ pé mo máa bọ́ lọ́wọ́ àrùn tó ń pọ́n mi lójú yìí.” Bákan náà ni obìnrin Kristẹni kan tó ń jẹ́ Giulian sọ pé: “Bí ọjọ́ kan bá kọjá, mo máa ń kà á sí pé mo ti ṣẹ́gun, pé ìrora tí màá jẹ tí òpin á fi dé ti dín ọjọ́ kan!” Òtítọ́ ni o, àkókò tí àrùn oríkèé-ara-ríro àti gbogbo ìrora yóò dópin ti sún mọ́lé!

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.

b Tó o bá fẹ́ kí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá ṣàlàyé àwọn ìlérí Bíbélì fún ọ, kàn sí ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ tàbí kó o kọ̀wé sí àwọn tó ṣe ìwé yìí.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ọ̀pọ̀ jaburata àwọn ohun èèlò ló wà tó lè mú káwọn tí àrùn yìí ń bá jà lè ṣe àwọn nǹkan

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

A lè rí ìtìlẹ́yìn onífẹ̀ẹ́ ní àwọn ìpàdé Kristẹni