Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kàtídírà—Ọwọ̀n Ìrántí fún Ọlọ́run Ni àbí fún Èèyàn?

Kàtídírà—Ọwọ̀n Ìrántí fún Ọlọ́run Ni àbí fún Èèyàn?

Kàtídírà—Ọwọ̀n Ìrántí fún Ọlọ́run Ni àbí fún Èèyàn?

LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN Jí! NÍ ILẸ̀ FARANSÉ

NǸKAN kan tó dà bí àjíǹde ṣẹlẹ̀ ní ìlú Moscow. Kàtídírà ìjọ Kristi Olùgbàlà, tí Stalin wó lulẹ̀ lọ́dún 1931 ni wọ́n ti kọ́ padà báyìí o, tí àwọn òrùlé rẹ̀ rìbìtì-rìbìtì olómi góòlù sì ń dán yanran lójú òfuurufú Rọ́ṣíà. Ní ìlú Évry, tó wà nítòsí Paris, àwọn òṣìṣẹ́ ti parí àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tó kù lára kàtídírà kan ṣoṣo tí wọ́n fi gbogbo ọ̀rúndún ogún kọ́ ní ilẹ̀ Faransé. Èyí kò ju ọdún díẹ̀ lọ lẹ́yìn tí wọ́n ya kàtídírà Almudena sí mímọ́ ní ìlú Madrid. Bákan náà sì lọ̀rọ̀ rí ní New York City, kàtídírà kan ńbẹ tí wọ́n ń pè ní Jòhánù Mímọ́ Látọ̀run Wá. Nítorí pé ó ti lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún tí wọ́n ti ń kọ́ ọ tí wọn ò sì tíì kọ́ ọ tán, Kàtídírà Jòhánù Mímọ́ Àkọ́ọ̀kọ́tán làwọn èèyàn máa ń pè é. Síbẹ̀, ọ̀kan ló jẹ́ nínú àwọn kàtídírà tó tóbi jù lọ lágbàáyé, nítorí pé fífẹ̀ rẹ̀ ju ẹgbẹ̀rún mọ́kànlá mítà lọ níbùú lóròó.

Káàkiri làwọn kàtídírà jìmàwòjimawo wà ní gbogbo ìlú táwọn ẹlẹ́sìn Kristi pọ̀ sí. Lójú àwọn tó gba ẹ̀sìn lójú méjèèjì, àmì ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run ló jẹ́. Àwọn tó jẹ́ kèfèrí pàápàá lè máa wò wọ́n pé iṣẹ́ ọ̀nà tó fakíki tàbí ọnà ìkọ́lé téèyàn ń fi ṣèran wò ni wọ́n jẹ́. Síbẹ̀, àwọn ilé títóbi jìmàwòjimawo, tí wọ́n run iyebíye owó lé lórí yìí gbé àwọn ìbéèrè pàtàkì kan dìde: Kí nìdí tí wọ́n fi kọ́ wọn àti báwo ni wọ́n ṣe kọ́ wọn? Kí ni wọ́n wà fún gan-an?

Kí Ló Ń Jẹ́ Kàtídírà?

Lẹ́yìn tí Kristi kú, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣètò ara wọn sí ìjọ-ìjọ, inú ilé àdáni sì lọ̀pọ̀ wọn ti ń pàdé. (Fílémónì 2) Fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún ni “àwọn àgbà ọkùnrin” tí wọ́n jẹ́ ẹni tẹ̀mí fi ń bójú tó àwọn ìjọ yìí. (Ìṣe 20:17, 28; Hébérù 13:17) Àmọ́ lẹ́yìn táwọn àpọ́sítélì kú tán, ìsìn Kristẹni di nǹkan míì. (Ìṣe 20:29, 30) Kò pẹ́ kò jìnnà, àwọn alàgbà kan bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra wọn ga ju àwọn tó kù lọ wọ́n sì sọ ara wọn di bíṣọ́ọ̀bù tó ń bójú tó ìjọ, èyí sì lohun tí Jésù ti kìlọ̀ tẹ́lẹ̀ pé kò gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀. (Mátíù 23:9-12) Ọ̀rọ̀ náà “ṣọ́ọ̀ṣì,” tó jẹ́ pé àwọn Kristẹni fúnra wọn ló dúró fún tún wá di orúkọ tí wọ́n ń pe ibi tí wọ́n ti ń jọ́sìn, ìyẹn ilé náà fúnra rẹ̀. Kò pẹ́ táwọn bíṣọ́ọ̀bù kan fi bẹ̀rẹ̀ sí í wá bí wọ́n ṣe máa ní àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó máa bá ipò tí wọ́n wà mu. Bí wọ́n ṣe wá ọ̀rọ̀ míì tí wọ́n á fi máa pe àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó jẹ́ ti bíṣọ́ọ̀bù nìyẹn, wọ́n pè é ní kàtídírà.

Ọ̀rọ̀ yìí wá látinú ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà kathedra, ó túmọ̀ sí “ìjókòó.” Bí kàtídírà ṣe di ìtẹ́ àwọn bíṣọ́ọ̀bù nìyẹn o, èyí tó ń ṣàpẹẹrẹ bí agbára wọn ṣe tó láyé. Àtinú kàtídírà yìí làwọn bíṣọ́ọ̀bù ti máa ń ṣàbójútó àgbègbè tó wà níkàáwọ́ wọn.

“Ìgbà Tí Kàtídírà Ti Wà”

Ní ọdún 325 Sànmánì Tiwa, Ìgbìmọ̀ Niséà fọwọ́ sí kí àwọn bíṣọ́ọ̀bù máa wà láwọn ìlú ńláńlá. Nítorí pé Ìjọba Róòmù wà lẹ́yìn àwọn bíṣọ́ọ̀bù, ni wọ́n bá gba ẹ̀bùn ilẹ̀ lọ rabidun lọ́wọ́ àwọn aláṣẹ. Ọ̀pọ̀ ilé ìjọsìn àwọn kèfèrí ni wọ́n tún fi sábẹ́ àkóso ara wọn. Nígbà tí Ìjọba Róòmù wó, ètò ṣọ́ọ̀ṣì kò wó, ńṣe ló ń gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ sí i tó sì di àràbà ńlá ní Sànmánì Ojú Dúdú. Kò pẹ́ kò jìnnà, sànmánì yẹn di ohun tí òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Faransé náà, Georges Duby pè ní “Sànmánì Kàtídírà.”

Láàárín ọ̀rúndún keje sí ìkẹrìnlá, iye àwọn èèyàn tó wà ní Yúróòpù pọ̀ sí i ní ìlọ́po mẹ́ta. Àwọn ìlú ńlá ló jàǹfààní jù nínú bí àwọn èèyàn ṣe pọ̀ sí i yìí. Bẹ́ẹ̀ làwọn ìlú tó lọ́rọ̀ gan-an táwọn bíṣọ́ọ̀bù sì wà nínú wọn di ibi tó bọ́ sí i gẹ́ẹ́ láti kọ́ àwọn kàtídírà gìrìwò-gìrìwò sí. Kí nìdí? Ìdí ni pé kìkì ibi tí owó bá ti ń rọ̀ bí òjò nìkan ni kíkọ́ àwọn ilé àrágbáyamúyamù bẹ́ẹ̀ ti lè ṣeé ṣe!

Ohun mìíràn tó tún bu epo síná kíkọ́ àwọn kàtídírà yìí ni ìjọsìn Màríà Wúńdíá àti ti àwọn ẹni mímọ́ mìíràn, èyí tó gbòde kan nígbà yẹn. Kò tíì sígbà kan tí ìjọsìn yìí gbayì tó gbẹ̀yẹ tó ti ọ̀rúndún kọkànlá àti ìkejìlá. Làwọn bíṣọ́ọ̀bù bá bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ ìjọsìn yìí lójú, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí àwọn kàtídírà wọn gbajúmọ̀ sí i. Àkókò yìí ni àkọlé náà, Notre-Dame (Ìyálóde Wa) bẹ̀rẹ̀ sí í hàn lára àwọn kàtídírà káàkiri ilẹ̀ Faransé. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Kátólíìkì náà, Théo, sọ pé: “Ìlú wo lẹ́ máa de tí wọn ò ti ní ya ṣọ́ọ̀ṣì àtàwọn kàtídírà sí mímọ́ fún Màríà Wúńdíá?” Ìyẹn náà ló mú wọn ya kàtídírà Saint-Étienne ti ìlú Paris sí mímọ́ fún Notre-Dame. Ní gbogbo àríwá Yúróòpù, kò sí kàtídírà náà tó gbayì tó Notre-Dame, tó wà nílùú Chartres ní ilẹ̀ Faransé. Ìwé The Horizon Book of Great Cathedrals sọ pé: “Kò sí àwòrán kankan, kódà àwòrán Kristi Alára kò gba ọkàn àti ìgbésí ayé àwọn tó ń kọ́ kàtídírà kan tó àwòrán Màríà Wúńdíá.”

“A Máa Kọ́ Kàtídírà Kan Tá Á Tóbi Débi Pé . . . ”

Kí ló fà á ná tí ọ̀pọ̀ lára àwọn ilé yìí fi tóbi ràgàjìràgàjì bẹ́ẹ̀? Àtìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kẹrin ni wọ́n ti ń kọ́ àwọn kàtídírà tó ń gbalẹ̀ kan. Irú rẹ̀ wà nílùú Trier, lórílẹ̀-èdè Jámánì àti ní ìlú Geneva lórílẹ̀-èdè Switzerland, láìka ti pé ẹ̀tahóró làwọn tó ń jọ́sìn níbẹ̀ sí. Ní ọ̀rúndún kọkànlá, bí wọ́n bá kó gbogbo èèyàn tó ń gbé ìlú Speyer lórílẹ̀-èdè Jámánì sínú kàtídírà tó wà níbẹ̀, wọn ò kún un. Ìyẹn ló mú ìwé The Horizon Book of Great Cathedrals parí ọ̀rọ̀ pé, “títóbi táwọn [kàtídírà] tóbi tí wọ́n sì runwó lé wọn lórí fi hàn pé, àwọn ohun tó mú wọn kọ́ ọ kò jẹ mọ́ ti ìsìn rárá.” Lára rẹ̀ ní “ìgbéraga tó ń yọ àwọn bíṣọ́ọ̀bù àtàwọn olórí ilé àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé lẹ́nu, tó jẹ́ pé abẹ́ àkóso wọn ni kíkọ́ àwọn ilé náà wà.”

Ní ọ̀rúndún kejìlá àti ìkẹtàlá, àwọn kàtídírà máa ń gùn tó ọgọ́rùn-ún mítà níbùú àti lóròó, tó jẹ́ pé bí wọ́n ṣe gùn tó náà ni wọ́n ṣe ń ga tó. Àwọn kan tí kò lẹ́lẹ́gbẹ́ ni kàtídírà ìlú Winchester ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, tó gùn ní mítà mọ́kàndínláàádọ́sàn-án níbùú lóròó, àti Kàtídírà ìlú Milan ní Ítálì tó jẹ́ mítà márùnlélógóje níbùú àti lóròó. Òṣìṣẹ́ ṣọ́ọ̀ṣì ilẹ̀ Sípéènì kan sọ ní ìlú Seville lọ́dún 1402 pé: “A máa kọ́ kàtídírà kan táá tóbi débi pé, tá a bá parí rẹ̀, àwọn tó bá rí i á rò pé a ya wèrè ni.” Lóòótọ́, kàtídírà ìlú Seville yìí la gbọ́ pé ó tóbi ṣìkejì lágbàáyé, tí òrùlé rẹ̀ nìkan sì wọ mítà mẹ́tàléláàádọ́ta. Òrùlé tí wọ́n kọ́ sórí kàtídírà ìlú Strasbourg ní ilẹ̀ Faransé nìkan ga tó mítà méjìlélógóje, ìwọ̀n kan náà pẹ̀lú ilé ológójì àjà. Ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, òrùlé gogoro orí kàtídírà Gothic Münster ní ìlú Ulm, ilẹ̀ Jámánì ga tó mítà mọ́kànlélọ́gọ́jọ, èyí tó mú kó jẹ́ ilé gogoro tí wọ́n fi òkúta kọ́ tó tíì ga jù lọ lágbàáyé. Òpìtàn Pierre du Colombier sọ gbangba pé: “Kò sí ohun kan tí ìjọsìn ń béèrè lọ́wọ́ wa tó ṣètìlẹ́yìn fún kíkọ́ àwọn ilé ràgàjìràgàjì tí àṣejù ti wọ̀ yìí.”

Láàárín ọ̀rúndún kejìlá sí ìkẹtàlá, àwọn onígbọ̀wọ́ kàtídírà tún lo ohun mìíràn tí ‘kò bá ìsìn tan rárá,’ ìyẹn ni ìfẹ́ ìlú ẹni. Encyclopædia Britannica sọ pé: “Ńṣe làwọn ìlú máa ń bára wọn díje láti kọ́ kàtídírà tó ga lọ́lá jù.” Àwọn alága ìlú, àwọn aláṣẹ àtàwọn ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ wá sọ kàtídírà di àmì tó ń fi bí ìlú wọn ṣe tó hàn.

Bó Ṣe Ń Jẹ Owó Láyé Ọjọ́un Ló Ń Jẹ Owó Lóde Òní

Òǹkọ̀wé kan fi kàtídírà kíkọ́ wé “àgbààná.” Ibo ni wọ́n ti ń rí owó ná sórí àwọn ilé yìí lásìkò yẹn, nígbà tó jẹ́ pé iye tí wọ́n ń fi bójú tó wọn lásìkò yìí gan-an kò kéré? Nígbà míì, àwọn àlùfáà máa ń ná owó ara wọn, irú bíi Maurice de Sully tó wà ní Paris. Nígbà míì, àwọn alákòóso òṣèlú ló máa ń gbé bùkátà náà, irú bí Ọba James Aragon Kìíní. Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, owó tó ń wá láti àgbègbè tí bíṣọ́ọ̀bù kọ̀ọ̀kan wà ni wọ́n fi ń kọ́ àwọn kàtídírà náà. Owó orí tí wọ́n ń san nígbà ayé Ojú Dúdú àti owó tó ń wá látinú àwọn dúkìá tún wà lára owó yìí. Kódà, ẹgbẹ̀rún méjì ilẹ̀ ni Bíṣọ́ọ̀bù ìlú Bologna ní Ítálì nìkan ní! Èyí kò mọ́ owó tó ń wọlé fún wọn látọ̀dọ̀ àwọn ọmọ ìjọ o, ìyẹn owó ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ àtèyí táwọn èèyàn fi bẹ̀bẹ̀ fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ní ìlú Rouen, ilẹ̀ Faransé, àwọn tó bá ra ẹ̀tọ́ láti máa jẹ wàrà tó wá láti ara ẹran lásìkò ààwẹ̀ Lẹ́ǹtì máa ń san owó Ilé Gogoro Butter tó jẹ́ ti kàtídírà náà.

Àwọn kan wà tí wọ́n máa ń dáwó rẹpẹtẹ ní ṣọ́ọ̀ṣì, wọ́n sì máa ń buyì fún wọn nípa yíya àwòrán wọn sára àwọn fèrèsé onígíláàsì tàbí kí wọ́n ya ère wọn. Ó hàn kedere pé, wọ́n ti gbàgbé ìlànà tó sọ pé kí àwọn Kristẹni má fi ẹ̀bùn wọn ṣe àṣehàn. (Mátíù 6:2) Nítorí pé iye tí wọ́n ń ná sábà máa ń kọjá iye tí wọ́n fojú bù, owó gbọ́dọ̀ máa ya wọlé ni ní gbogbo ìgbà ṣáá. Abájọ tí ìtara láti rí owó fi máa ń tì wọ́n láti bù ju iye tí wọ́n nílò lọ àti láti lu jìbìtì. Bí àpẹẹrẹ, bí wọ́n bá fi ẹ̀sùn àdámọ̀ kan ẹnì kan, ńṣe ni wọ́n á gbẹ́sẹ̀ lé nǹkan ìní ẹni náà. Èyí ló jẹ́ kí wọ́n máa gba nǹkan ìní àwọn tí wọ́n sábà máa ń pè ní aládàámọ̀, irú bí ìjọ Cathar, èyí sì jẹ́ kí wọ́n rí owó láti kọ́ àwọn ṣọ́ọ̀ṣì bíi mélòó kan. a

Ká má déènà pẹnu, ló bá di kí ṣọ́ọ̀ṣì máa pariwo owó ṣáá, kí owó lè máa wọlé. Òdìkejì ọ̀rọ̀ làwọn òpìtàn kan sọ pé, owó táwọn èèyàn ń dá láti kọ́ àwọn ilé yìí wá látọkàn wọn. Òpìtàn Henry Kraus sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ ìsìn gan-an nígbà ayé Ojú Dúdú, ṣọ́ọ̀ṣì kíkọ́ kì í ṣe ohun tó wà lórí ẹ̀mí wọn.” Ọ̀pọ̀ àwọn òpìtàn tipa bẹ́ẹ̀ bẹnu àtẹ́ lu àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì fún ìná àpà wọn. Ìwé The Horizon Book of Great Cathedrals sọ pé: “Owó tí àwọn àlùfáà ì bá fi bọ́ àwọn tí ebi ń pa kú lọ . . . tàbí kí wọ́n fi tún àwọn ọsibítù àtàwọn ilé ẹ̀kọ́ ṣe, ṣọ́ọ̀ṣì ni wọ́n fi ń kọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, a lè sọ pé àwọn kàtídírà dá kún gbígba ẹgbàágbèje ẹ̀mí èèyàn.”

Bí Wọ́n Ṣe Kọ́ Wọn

Àwọn kàtídírà fi bí èèyàn ṣe ní ọpọlọ tó hàn. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ pé ìwọ̀nba ìmọ̀ ẹ̀rọ tó wà láyé ọjọ́un ni wọ́n lò láti kọ́ irú àwọn ilé kíkàmàmà bẹ́ẹ̀. Ńṣe ni wọ́n á kọ́kọ́ ya àwòrán ilé náà ní kíkún. Níbi tí wọ́n ti ń fọ́ òkúta, wọ́n ní àwọn bátànì tí wọ́n ń lò láti rí i pé àwọn nǹkan tí wọ́n máa fi bu ẹwà kún ilé náà dọ́gba délẹ̀ àti pé àwọn búlọ́ọ̀kù olókùúta náà bára mu rẹ́gí. Wọ́n máa ń fi tìṣọ́ratìṣọ́ra ṣe àmì sí àwọn búlọ́ọ̀kù náà láti mọ apá ibi tí ọ̀kọ̀ọ̀kan máa wà lára ilé náà. Kíkó wọn kúrò máa ń falẹ̀ gan-an ni ó sì máa ń gbówó lórí, àmọ́ láìka gbogbo èyí sí, gẹ́gẹ́ bí ohun tí òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Faransé náà Jean Gimpel sọ, ‘láàárín ọdún 1050 sí 1350, òkúta tí ilẹ̀ Faransé fọ́ láti kọ́lé ju ti gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì ìgbàanì lọ.’

Téèyàn bá wá dé ibí tí ilé kíkọ́ náà ti ń lọ lọ́wọ́, itú táwọn òṣìṣẹ́ ń pa kò kéré rárá. Wọ́n ń lo irinṣẹ́ agbóhunròkè ti ayé ìgbà náà, ìyẹn àwọn ohun tó ń gbé nǹkan tó wúwo lọ sókè. Ìlànà ìṣirò táwọn onímọ̀ ẹ̀rọ ń lò lóde òní kò tíì dáyé nígbà yẹn. Ohun tí ọkàn àwọn kọ́lékọ́lé bá ní kí wọ́n ṣe àti ìrírí tí wọ́n ti ní tẹ́lẹ̀ ni wọ́n máa ń tẹ̀ lé. Abájọ tí ọ̀pọ̀ aburú fi ṣẹlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1248, òrùlé gogoro tí wọ́n ṣe sórí kàtídírà ìlú Beauvais ní ilẹ̀ Faransé ti tóbi jù, ló bá ya lulẹ̀. Àmọ́ nígbà tí wọ́n wá jágbọ́n àwọn nǹkan bí irin ṣóńṣó, irin abẹ́ òrùlé, àtàwọn ìgbátí òrùlé, èyí jẹ́ kí àwọn kọ́lékọ́lé náà lè túbọ̀ gbé àwọn nǹkan ribiribi ṣe.

Kíkọ́ àwọn ilé yìí máa ń gbà tó ogójì ọdún (bí i ti Salisbury, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì) sí ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún. Àwọn kan wà, irú bí àwọn kàtídírà ti ìlú Beauvais àti Strasbourg ní ilẹ̀ Faransé, tí wọn ò tíì parí wọn dòní.

“Wọn Ò Mọ Ohun Tó Yẹ Kí Wọ́n Kọ́kọ́ Mú Ṣe”

Àtìbẹ̀rẹ̀ làwọn ‘ilé wọ̀nyí, tó lẹ́wà, tó sì ń kówó mì,’ gẹ́gẹ́ bí Póòpù Honorius Kẹta ṣe pè wọ́n, ti ń fa arukutu. Àwọn àlùfáà kan láwọn ò fara mọ́ kíkọ́ àwọn ilé yìí àti arabaríbí owó tó ń gbé mì. Pierre le Chantre, bíṣọ́ọ̀bù Notre-Dame de Paris ní ọ̀rúndún kẹtàlá kéde pé: “Nǹkan ẹ̀ṣẹ̀ ni láti máa kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì bá a ṣe ń kọ́ ọ lónìí.”

Kódà títí dòní làwọn èèyàn ṣì ń sọ̀rọ̀ lòdì sí kàtídírà tó wà ní ìlú Évry, ká kàn dárúkọ ẹyọ kan yẹn. Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn inú ìwé ìròyìn Le Monde ti ilẹ̀ Faransé ṣe sọ, ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé ńṣe ni àwọn kàtídírà fi àwọn àlùfáà hàn bí ẹni tí “kò mọ ohun tó yẹ kí wọ́n kọ́kọ́ mú ṣe” àti pé “èèyàn àti iṣẹ́ ìhìn rere ló yẹ kí wọ́n ná owó lé lórí dípò tí wọ́n fi ń ná an sórí òkúta àti ọ̀ṣọ́.”

Kò sí àní-àní pé àwọn tó kọ́ àwọn ilé ràgàjìràgàjì yìí nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run lóòótọ́. Ó dájú pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ní “ìtara fún Ọlọ́run” ṣùgbọ́n “kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye.” (Róòmù 10:2) Jésù Kristi kò sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ rí pé kí wọ́n kọ́ àwọn ilé ìjọsìn àwòṣífìlà. Ó rọ àwọn olùjọsìn tòótọ́ láti “jọ́sìn ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” (Jòhánù 4:21-24) Láìka ẹwà wọn sí, àwọn kàtídírà gìrìwògiriwo tí àwọn ẹlẹ́sìn Krisiti ń kọ́ yìí, tako ìlànà yìí. Wọ́n lè jẹ́ ọwọ̀n ìrántí fún àwọn tó kọ́ wọn o, àmọ́ wọn kò mú ògo bá Ọlọ́run.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo àpilẹ̀kọ náà, ‘Àwọn Cathar—Kristian Ajẹ́rìíkú Ha Ni Wọ́n Bí?’ nínú ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ September 1, 1995, ojú ìwé 27 sí 30 tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Kàtídírà ìlú Santiago de Compostela, ní Sípéènì

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Òkè Pátápátá: Fèrèsé onígíláàsì Notre-Dame, ìlú Chartres, ní ilẹ̀ Faransé tí wọ́n lo bátànì òdòdó róòsì fún

Òkè: Àwòrán afọ́kùúta kan, Notre-Dame, nílùú Paris

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Kàtídírà Notre-Dame ti ọ̀rúndún kejìlá, nílùú Paris

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Bí kàtídírà Notre-Dame ṣe rí nínú, Amiens. Òun ni ilé ìjọsìn tó tóbi jù lọ ní ilẹ̀ Faransé, pẹ̀lú àwọn òrùlé ṣóńṣó rẹ̀ tó ga ní mítà mẹ́tàlélógójì