Orúkọ Ọlọ́run Dá Àríyànjiyàn Sílẹ̀
Orúkọ Ọlọ́run Dá Àríyànjiyàn Sílẹ̀
LÁTỌWỌ́ ÒǸKỌ̀WÉ JÍ! NÍ NETHERLANDS
ÀWỌN kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń tú Bíbélì sí èdè Dutch ti dá àríyànjiyàn sílẹ̀ láàárín àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ àtàwọn èèyàn gbáàtúù. Kí ló fà á? Ìpinnu tí wọ́n ṣe pé Heer, tó túmọ̀ sí Olúwa, làwọ́n máa fún orúkọ Ọlọ́run, ló fà á.
Ní December 1998, ọ̀sẹ̀ díẹ̀ péré lẹ́yìn táwọn olùtumọ̀ náà gbé díẹ̀ lára iṣẹ́ wọn jáde, làwọn obìnrin kan láti àjọ tí wọ́n ń pè ní Kerk en Wereld (Ṣọ́ọ̀ṣì àti Ayé) ti Pùròtẹ́sítáǹtì bá bẹ̀rẹ̀ sí kọ lẹ́tà láti fi ẹ̀hónú wọn hàn. Kí nìdí? Wọ́n sọ pé “ẹ̀yà akọ nìkan” ni ọ̀rọ̀ náà “Olúwa” wà fún. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà táwọn ẹgbẹ́ mìíràn, ìyẹn Kátólíìkì àti Pùròtẹ́sítáǹtì fi dara pọ̀ mọ́ àwọn tó ń fi ẹ̀hónú hàn náà. Nígbà tó di February 1999, àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ti dara pọ̀ mọ́ wọn, wọ́n sọ pé ohun táwọn fara mọ́ ni pé kí wọ́n yí lẹ́tà Hébérù mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run sí YHWH. Kò pẹ́ sígbà yìí táwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀, àwọn olùtumọ̀, àtàwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn fi pàdé ní Amsterdam láti jíròrò ọ̀rọ̀ ọ̀hún. Ní òpin ìjíròrò náà, wọ́n ní kí gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ dìbò lórí bí wọ́n bá ṣe fẹ́ kí wọ́n kọ orúkọ náà.
Lábẹ́ àkòrí náà “Nítorí Ọlọ́run, Ẹ Má Ṣe Jẹ́ Ká Bára Wa Jà Nítorí Orúkọ Ọlọ́run,” ìwé ìròyìn Nieuwsblad van het Noorden sọ nípa àbájáde rẹ̀ pé: “Èèyàn bíi méje péré ló fara mọ́ orúkọ náà OLÚWA. Àwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ dìbò fún ọ̀pọ̀ lára àwọn orúkọ mìíràn tó kù o, àwọn bí: Orúkọ náà, (ẹnì kan péré), Ẹni náà, (èèyàn mẹ́ta), Aláàánú, (èèyàn mẹ́fà), Ẹni tí kò ṣe é Dárúkọ, (èèyàn méje), Ọba Alààyè, (èèyàn mẹ́wàá), àti Ọba Ayérayé, (èèyàn mẹ́ẹ̀ẹ́dógún). Orúkọ tó jáwé olúborí ni . . . YHWH!” Ní March 15, 2001, Ìgbìmọ̀ Tó Ń Bójú Tó títúmọ̀ Bíbélì tuntun náà sọ pé HEER (OLÚWA) làwọn máa lò fún orúkọ Ọlọ́run àmọ́ àwọn á kọ ọ́ ní lẹ́tà kéékèèké.
Àìfohùnṣọ̀kan yìí fi hàn pé láìka ti pé àríyànjiyàn wà lórí ọ̀nà tó yẹ kí wọ́n gbà kọ orúkọ Ọlọ́run lédè Dutch, àwọn ọ̀mọ̀wé gbà pé Ọlọ́run ní orúkọ kan. Lédè Hébérù, lẹ́tà mẹ́rin ló dúró fún orúkọ náà, àwọn ni: יהוה, tàbí YHWH. Báwo làwọn Bíbélì mìíràn ní èdè Dutch, ì báà jẹ́ látijọ́ tàbí lọ́jọ́ òní ṣe túmọ̀ YHWH?
Ọkùnrin ará Netherlands kan tó ń jẹ́ Nicolaas Goetzee, tẹ Bíbélì ẹ̀dà Staten, tí ìjọba fọwọ́ sí jáde ní 1762. Ohun tó kọ sí ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ni pé: “Fún àwọn ìdí pàtàkì tá a mọ̀ dáadáa, àwa náà kò túmọ̀ JÈHÓFÀ tó jẹ́ Orúkọ Ọlọ́run.” Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ mìíràn tí wọ́n tún jẹ́ ọmọ Netherlands, àwọn bí Ọ̀jọ̀gbọ́n Nicolaas Beets àti Petrus Augustus de Genestet pàápàá ti lo orúkọ náà, Jèhófà.
Ó dùn mọ́ni pé, léraléra ni Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun a lo orúkọ náà, Jèhófà. Àfikún àlàyé tó wà lẹ́yìn Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ní èdè Dutch kà pé “orúkọ náà ‘Jèhófà’ ni Bíbélì náà lò nítorí pé láti ọdún gbọ́nhan làwọn èèyàn ti mọ̀ ọ́n. Síwájú sí i, kò jẹ́ kí . . . lẹ́tà mẹ́rin YHWH, tó dúró fún orúkọ náà pa rẹ́ rárá.” Nípa báyìí, Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ti ran àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn lọ́wọ́ láti mọ ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa orúkọ Ọlọ́run.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló tẹ̀ ẹ́ jáde.