Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wíwo Ayé

Wíwo Ayé

Wíwo Ayé

Fífi Ìrì Dídì Múlé Tutù

Ìwé ìròyìn Asahi Evening News ti ilẹ̀ Japan sọ pé wọ́n ti ń lo ìrì dídì báyìí o, bí ọ̀nà tuntun láti mú ilé tutù lásìkò ooru. Àkókò ẹ̀ẹ̀rùn ìlú Bibai ní Hokkaido, lápá àríwá ilẹ̀ Japan kì í gùn lọ títí ó sì máa ń gbóná girigiri, àmọ́ ìrì dídì tó máa ń dà sílẹ̀ nígbà òtútù máa ń pọ̀ gan-an. Dípò kí àwọn òṣìṣẹ́ kó àwọn ìrì dídì yìí dà nù, ńṣe ni wọ́n máa ń tọ́jú wọn pa mọ́. Ìwé ìròyìn náà sọ pé tó bá wá di ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn, “wọ́n á ṣí atẹ́gùn sáwọn ibi tí wọ́n kó ìrì dídì náà jọ pelemọ sí, lẹ́yìn náà ni wọ́n á wá tú wọn jáde bí atẹ́gùn tútù, tó dà bí èyí tí wọ́n máa ń lò fún ẹ̀rọ amú-omi-tutù.” Wọ́n tún máa ń lo afẹ́fẹ́ tútù rinrin yìí láti mú àwọn ilé tí wọ́n ṣe ẹ̀rọ amúlétutù tó ń lo ìrì dídì sínú wọn tutù. Àǹfààní kan tó tún wà níbẹ̀ ni pé àwọn ilé tí wọ́n máa ń kó àwọn ìrì dídì náà sí máa ń tutù gan-an, èyí sì máa ń jẹ́ kí afẹ́fẹ́ mọ́ tónítóní torí pé ó máa ń fa ekuru àti òórùn kúrò nínú afẹ́fẹ́.

Ikọ́ Ẹ̀gbẹ Aṣekúpani Tí Kò Gbóògùn

Ìwé ìròyìn ìlú Johannesburg náà, Star sọ pé: “Ikọ́ ẹ̀gbẹ kan tó ń ṣekú pani tí kì í sì í gbóògùn, èyí tó túbọ̀ ń gbalẹ̀ sí i báyìí lè run odindi ìdílé kan tán o. Tá a bá fi máa rí ọdún díẹ̀ si, yóò gbapò ọ̀pọ̀ ìkọ́ ẹgbẹ́ tó ń ṣe àwọn èèyàn lọ́wọ́lọ́wọ́ ní Gúúsù Áfíríkà. Gẹ́gẹ́ bí Ẹgbẹ́ Tó Ń Rí Sí Ìṣòro Ikọ́ Ẹ̀gbẹ Jákèjádò Gúúsù Áfíríkà ti sọ, àwọn tí ikọ́ ẹ̀gbẹ ń bá fínra lè kó irú ikọ́ ẹ̀gbẹ yìí tí wọ́n bá dáwọ́ oògùn tí wọ́n ń lò dúró ṣáájú ìgbà tó yẹ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ tàbí tí wọn ò lò ó bí wọ́n ṣe ní kí wọ́n lò ó. Wọ́n á sì tipa bẹ́ẹ̀ kó ikọ́ ẹ̀gbẹ tó túbọ̀ ń ṣekú pani yìí ran àwọn èèyàn tí wọn ò ní àrùn ikọ́ ẹ̀gbẹ tẹ́lẹ̀. Ìtọ́jú tó wà fún ikọ́ ẹ̀gbẹ tí kì í gbóògùn bọ̀rọ̀ yìí fi ìlọ́po ogún wọ́n ju ìtọ́jú ikọ́ ẹ̀gbẹ lásán, kì í gbéṣẹ́ tó o, ìdajì àwọn tó ní i ló sì máa ń kú. Ìròyìn náà sọ pé, ìṣòro ọ̀rọ̀ ikọ́ ẹ̀gbẹ tó ń bá orílẹ̀-èdè Gúúsù Áfíríkà fínra “ti wá ń di ohun tí apá kò fẹ́ ẹ́ ká mọ́ o, láìka ti ìtọ́jú àrùn ikọ́ ẹ̀gbẹ́ tó ti di ọ̀fẹ́ sí, tó sì wà káàkiri.” Ìdá méjì nínú mẹ́ta àwọn èèyàn tó ń gbébẹ̀ ló ti ní ikọ́ ẹ̀gbẹ tí kò tíì fojú hàn, tó jẹ́ pé pẹ̀lú ìrọ̀rùn ni kòkòrò àrùn Éèdì lè fi fẹjú ẹ̀ síta.

Ṣe Ewu Wà Nínú Kéèyàn Jẹ́ Ẹni Ọdún Mọ́kàndínláàádọ́ta?

Ìwé ìròyìn Asahi Shimbun kìlọ̀ pé, ‘ẹ ṣọ́ra o, ẹ̀yin ẹni ọdún mọ́kàndínláàádọ́ta.’ Àwọn ọkùnrin tó wà lọ́jọ́ orí yìí tí wọ́n ń mú ní Japan fún ẹ̀sùn ìpànìyàn tàbí nítorí pé wọ́n gbìyànjú láti ṣe bẹ́ẹ̀ pọ̀ ju àwọn tó jẹ́ ọmọ ọjọ́ orí mìíràn tí wọ́n ń mú lọ. Àwọn ọlọ́dún mọ́kàndínláàádọ́ta yìí ló tún pọ̀ jù nínú àwọn tó máa ń dá ọgbẹ́ síni lára. Ẹ̀yìn wọn ló kan àwọn ọlọ́dún mẹ́tàdínláàádọ́ta, tí àwọn ọlọ́dún méjìdínláàádọ́ta tẹ̀ lé wọn, kó tó wá kan àwọn ọlọ́dún márùndínláàádọ́ta. Kí ló dé tó jẹ́ àárín ọjọ́ orí yìí ni wọ́n pọ̀ sí? Oníṣègùn ọpọlọ kan ní Tokyo sọ pé, àwọn ọkùnrin tó ń sún mọ́ àádọ́ta ọdún ti wà ní apá tó le koko jù lọ nínú ìgbésí ayé. Ó sọ pé: “Àwọn ọmọ wọn á ti wà ní àyè ara wọn, wọ́n ní àwọn òbí àgbà láti bójú tó bẹ́ẹ̀ sì ni àjọṣe àwọn àti ìyàwó wọn kì í dán mọ́rán mọ́. Wọ́n ti dé ipò kan tí wọn kì í lè fi bẹ́ẹ̀ ṣàkóso ohun tó ń sún wọn ṣe nǹkan mọ́, àwọn kan sì lè dìídì hùwà míì tí wọ́n mọ̀ pé ó léwu nínú.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn náà ti sọ, owó ẹ̀yáwó ìkọ́lé, owó ẹ̀kọ́, wàhálà ibi iṣẹ́, ìdádúró lẹ́nu iṣẹ́ àti kí iṣẹ́ má lọ déédéé tún máa ń fa àìfararọ nínú ìgbésí ayé àwọn ọkùnrin tó ti ń sún mọ́ àádọ́ta ọdún.

Ṣé Pé Ìmọ̀ Iṣẹ́ Ẹ̀rọ Ń Fa Gbígbàgbé Nǹkan?

Ìwé ìròyìn The Sunday Times ti London sọ pé, ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà, irú bí ẹ̀rọ pélébé tí wọ́n máa ń fi ìsọfúnni pa mọ́ sínú rẹ̀ àti lílo kọ̀ǹpútà láti mọ ọ̀nà tó yá jù lọ síbi téèyàn ń lọ, ni àwọn dókítà kan ní Japan, Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, àti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í dá lẹ́bi fún bí àwọn èèyàn ṣe ń gbàgbé nǹkan lọ́nà tó bùáyà. Àwọn dókítà yìí sọ pé àwọn nǹkan èèlò ìgbàlódé ti yọrí sí ṣíṣàìlo ọpọlọ tó láti yanjú àwọn ìṣòro, èyí tó ń fa káwọn òṣìṣẹ́ má lè rántí orúkọ, ohun tí wọ́n kọ sílẹ̀, àtàwọn àdéhùn tí wọ́n ní, ó tún kan àwọn èèyàn tó wà láàárín ogún ọdún sí ọgbọ̀n ọdún ó lé. Dókítà David Cantor ti Ilé Ẹ̀kọ́ Nípa Ìrònú Òun Ìhùwà ní Atlanta, Georgia, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ògbóǹkangí ló gbà pé àpọ̀jù ìsọfúnni ti ń mú kó ṣòro fún àwọn èèyàn kan láti lè gba ìsọfúnni tuntun sórí . . . Àwọn èèyàn yìí máa ń gbàgbé nǹkan nítorí ọkàn wọn kò pa pọ̀ débi tí wọ́n á ríbi gba ìsọfúnni ọ̀hún sí ọpọlọ.” Dókítà Takashi Tsukiyama ní Tokyo sọ pé àwọn ìṣòro yìí “kò ní nǹkankan ṣe pẹ̀lú ọjọ́ orí o, àmọ́ ó ní í ṣe pẹ̀lú bó o ṣe ń gbé ìgbésí ayé [rẹ], irú bíi kó o máà máa lo ọpọlọ rẹ tó bó ṣe yẹ.”

“Ìṣòro Ńlá Kan     Tó Kan Gbogbo Èèyàn”

Níbàámu pẹ̀lú ìṣirò tí ìjọba ṣe, ìfọwọ́-ara-ẹni-para-ẹni ló wà ní ipò kẹjọ lára ohun tó ń fa ikú àwọn ará Amẹ́ríkà jù lọ. Ó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n [30,000] àwọn ará Amẹ́ríkà tó ń fọwọ́ ara wọn para wọn lọ́dún, tí ọ̀kẹ́ méjìlélọ́gbọ̀n ó lé ẹgbàárùn-ún [650,000] sì máa ń gbìyànjú láti ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́dọọdún. Ilé iṣẹ́ ìròyìn Reuters sọ pé, táwọn èèyàn bá fi pa ẹni méjì péré, àwọn tó ti máa fọwọ́ ara wọn para wọn á ti ju mẹ́ta lọ. Àwọn àjọ gbogbo gbòò àti ti aládàáni ti tọ́ka sí ìfọwọ́-ara-ẹni-para-ẹni pé ó jẹ́ “ìṣòro ńlá kan tó kan gbogbo èèyàn.” David Satcher, oníṣègùn àgbà fún Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Ṣàṣà èèyàn ni ọ̀ràn ìbànújẹ́ ìfọwọ́-ara-ẹni-para-ẹni kì í kàn jálẹ̀ gbogbo ìgbésí ayé wọn.” Reuters sọ pé, lára àwọn nǹkan tó máa ń fa ìfọwọ́-ara-ẹni-para-ẹni ni “ìsoríkọ́, àìsírètí, àìlólùrànlọ́wọ́ àti ìmukúmu ọtí àti lílo oògùn olóró.”

Àìní Ìmọ̀ Bíbélì

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àtọjọ́ táláyé ti dáyé ni wọ́n ti ń fọ̀wọ̀ wọ Bíbélì ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ìwádìí kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí fi hàn pé kìkì ìdá mẹ́rìndínlógún péré nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tó pera wọn ní Kristẹni níbẹ̀ lo sọ pé àwọn máa ń ka Bíbélì lójoojúmọ́. Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tó fara hàn nínú The Sun Herald ti Biloxi, Mississippi, Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ṣe sọ, ìwádìí mìíràn fi hàn pé kìkì èèyàn méjì nínú mẹ́wàá ló lè dárúkọ ẹni tó sọ Ìwàásù Lórí Òkè. Láfikún sí i, àwọn tí wọn béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ wọn náà kò lè sọ ju mẹ́ta sí mẹ́rin lọ nínú Òfin Mẹ́wàá.

Omi Ọsàn Àjàrà àti Egbòogi

Fífi omi ọsàn àjàrà lo egbòogi lè dá kún “àwọn ìṣòro tó máa ń jẹ yọ nínú egbòogi, ó sì lè [fa] ìṣòro tí kì í ṣe kékeré nígbà míì” ni ohun tí ìwé ìròyìn UC Berkeley Wellness Letter sọ. Àwọn egbòogi tó máa ń nípa lórí wọn jù ni àwọn tó ń dín èròjà cholesterol inú ara kù, ti ẹ̀jẹ̀ ríru tá a mọ̀ sí agbógunti káṣíọ̀mù, àti irú àwọn egbòogi amárarọni kan. Àmọ́ ohun tó dùn mọ́ni ni pé gbogbo èèyàn kọ́ ni àlòpọ̀ náà máa ń yọ lẹ́nu, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe gbogbo omi ọsàn àjàrà ló ń fa wàhálà náà. Ìwé ìròyìn Wellness Letter ọ̀hún sọ pé: “Tó o bá ń lo oògùn kan lọ́wọ́ tó o sì ń mu omi ọsàn àjàrà, béèrè lọ́wọ́ dókítà rẹ nípa ohun tó ṣeé ṣe kí ó fà.”

Ṣé O Máa Ń Rántí Nǹkan Bí I Ti Erin?

Àwọn olùwádìí tó ń ṣiṣẹ́ ní Ọgbà Ẹranko Amboseli ní Kẹ́ńyà ti ṣàwárí pé ọ̀kan lára àwọn ohun tó máa ń dáàbò bo agbo àwọn erin ni agbára tí abo erin tó dàgbà jù lọ láàárín wọn ní láti rántí nǹkan. Ìwé ìròyìn Science News sọ pé: “Àwọn tó dàgbà jù nínú àwọn ìyá erin ńlá, ìyẹn àwọn abo tó ti tó ọdún márùndínlọ́gọ́ta ó kéré tán, máa ń mọ ìyàtọ̀ láàárín ẹni tó jẹ́ àjèjì tàbí tó jẹ́ ọ̀rẹ́ . . . ju àwọn ọlọ́dún márùndínlógójì lọ fíìfíì.” Nípa rírántí àwọn ohùn tí wọ́n ti gbọ́ rí, tàbí àwọn ohùn abẹ́nú kan, àwọn tó dàgbà jù nínú àwọn ìyá ńlá náà máa ń dá ohùn tó ṣàjèjì mọ̀ tí wọ́n á sì kó gbogbo àwùjọ náà pa pọ̀ síbi tí jàǹbá kò ti ní ṣe wọ́n. Ìròyìn náà sọ pé, “abo erin kan lè fi ohùn dá àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ tó tó nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mọ̀.” Nípa bẹ́ẹ̀, nígbà táwọn tó ń pa ẹranko láìgbàṣẹ bá pa àgbà erin kan, ìsọfúnni ńlá ni gbogbo agbo náà pàdánù yẹn.

Ohun Tó Ń Ṣekú Pààyàn Jù

“Ọtí líle ń ṣekú pa ẹgbẹ̀rún márùnléláàádọ́ta ọ̀dọ́ lọ́dún” lohun tí ìwé ìròyìn Le Figaro ti ilẹ̀ Faransé sọ. Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Ìlera Àgbáyé ṣe sọ, ọtí líle ló ń ṣekú pa àwọn ọkùnrin ọlọ́dún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí mọ́kàndínlọ́gbọ̀n jù ní Yúróòpù, ó sì jẹ́ kókó kan nínú ohun tó ń fa ìdá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo ikú tó ń ṣẹlẹ̀. Ìwé ìròyìn ọ̀hún sọ pé àwọn ikú tí “àmujù ọtí, jàǹbá ojú pópó, ìfọwọ́-ara-ẹni-para-ẹni, àti ìpànìyàn ń fà” wà lára èyí. Ìṣòro ọ̀hún tiẹ̀ wá bògìrì láwọn orílẹ̀-èdè kan ní ìhà Ìlà Oòrùn Yúróòpù, níbi tó jẹ́ pé “ìdá kan nínú mẹ́ta àwọn ọkùnrin tó jẹ́ ọ̀dọ́ ló ti dájú pé wọ́n máa kú láìtọ́jọ́ nítorí mímu ọtí líle lámujù.” Níbi àpérò kan tó wáyé ní ìlú Stockholm, lórílẹ̀-èdè Sweden, Dókítà Gro Harlem Brundtland, olùdarí àgbà fún Àjọ Ìlera Àgbáyé, bẹnu àtẹ́ lu bí àwọn tó ń ṣe ọtí líle jáde ṣe ń dà á sọ́jà wìtìwìtì, èyí tó túbọ̀ ń mú kó ṣòro gan-an fún àwọn ọ̀dọ́ láti ní “èrò tó tọ́ tó sì bójú mu nípa ọtí líle.”

Bó O Ṣe Lè Láyọ̀

Níbàámu pẹ̀lú ìwádìí tuntun kan táwọn onímọ̀ nípa ìrònú òun ìhùwà ṣe, “owó rẹpẹtẹ ní báńkì kọ́ ni àṣírí gbígbé ìgbésí ayé ìfọ̀kànbalẹ̀. Ká sòótọ́, kéèyàn lọ́rọ̀, kó gbajúmọ̀ kó sì gbayì láwùjọ jìnnà fíìfíì sí rírí ìtẹ́lọ́rùn.” Kennon Sheldon ti Yunifásítì Missouri-Columbia, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Nínú àṣà àwọn aláwọ̀ funfun, ọ̀pọ̀ ìpolówó ọjà máa ń mú ká ní èrò pé a gbọ́dọ̀ rẹwà, ká gbajúmọ̀, ká sì lówó rẹpẹtẹ. Ó lè mú ọjà wọn yá lóòótọ́, àmọ́ àwọn tí wọ́n fi ìpolówó ọjà tàn jẹ́ yìí kò láyọ̀ ju àwọn ẹlòmíràn lọ.” Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwé ìròyìn The Independent ti London sọ, ìwádìí kan tí wọ́n ṣe láàárín àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Yunifásítì tí wọ́n jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin fi hàn pé, “bíbuyì kúnra ẹni” àti “níní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn” lohun tó ṣe pàtàkì jù lọ tó ń mú wọn láyọ̀. Wọn ò tiẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ kan owó pé òun ló ń mú èèyàn láyọ̀. Ìwé ìròyìn náà sọ pé, èrò táwọn èèyàn ní tẹ́lẹ̀ pé “‘àwọn tó ń rò pé owó kò lè fúnni láyọ̀ kò mọ àǹfààní tí owó ní’ ti di ọ̀rọ̀ àná.”