Ìtìlẹ́yìn àti Àánú Láti Ibi Gbogbo
Ìtìlẹ́yìn àti Àánú Láti Ibi Gbogbo
ÀWỌN olùyọ̀ǹda-ara-ẹni wá láti àgbègbè mìíràn ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà àti láti orílẹ̀-èdè mìíràn. Ọ̀kan lára wọn ni Tom (nínú fọ́tò tó wà lókè), ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n, òṣìṣẹ́ panápaná ni láti Ottawa ní Kánádà. Ó sọ fún Jí! pé: “Mo rí ohun tó ṣẹlẹ̀ lórí tẹlifíṣọ̀n mo sì fẹ́ láti wá ṣe àtìlẹ́yìn fún àwọn òṣìṣẹ́ panápaná ẹlẹgbẹ́ mi ní ìlú New York. Mo débẹ̀ lọ́jọ́ Friday mo sì lọ síbi tí ìjábá náà ti ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ Sátidé láti lọ ràn wọ́n lọ́wọ́. Wọn fi mí sára àwọn tó ń fi ṣọ́bìrì kó pàǹtírí, a sì ń fi korobá kó àwọn pàǹtírí náà jáde díẹ̀díẹ̀.
“A rọra ń yẹ àwọn pàǹtírí náà wò, a ń kó wọn díẹ̀díẹ̀, a sì ń wá àwọn ohun èlò tá a lè fi dá àwọn panápaná tó ṣòfò ẹ̀mí náà mọ̀. Mo rí irin kan tí wọ́n fi ń ṣí ilẹ̀kùn, mo sì tún rí àwọn irin tí wọ́n fi ń so páìpù pọ̀. Iṣẹ́ àfìṣọ́raṣe gbáà ni. Wákàtí méjì gbáko ló gba àwa olùyọ̀ǹda-ara-ẹni àádọ́ta láti kó pàǹtírí kúnnú ọkọ̀ akódọ̀tí kan ṣoṣo.
“Ní Monday, September 17, a rí yọ lára òkú àwọn òṣìṣẹ́ panápaná tí wọ́n sáré lọ síbi ilé tí jàǹbá ti ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ Tuesday tó kọjá. Mi ò lè gbàgbé ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn láé, gbogbo àwọn agbẹ̀mílà ni wọ́n dáwọ́ iṣẹ́ dúró, wọ́n bọ́ ate àti akoto tí wọ́n dé sórí, wọ́n sì dúró wámúwámú, èyí jẹ́ àmì ọ̀wọ̀ fún àwọn akẹgbẹ́ wa tó ṣòfò ẹ̀mí.
“Bí mo ṣe dúró tí mo ń wo ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà ti ṣẹlẹ̀, mo túbọ̀ rí i pé ohun ẹlẹgẹ́ ni ìwàláàyè èèyàn jẹ́ láyé tá a wà yìí. Ó mú kí n ronú nípa ìgbésí ayé mi, iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ mi àti ìdílé mi. Láìka bí iṣẹ́ mi ṣe léwu nínú tó sí, èrè púpọ̀ wà nínú rẹ̀, nítorí pé mo lè ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ kí n sì tún gba ẹ̀mí là.”
Àwọn Ẹlẹ́rìí Pèsè Ìrànwọ́ Tó Gbéṣẹ́
Ní ọjọ́ àkọ́kọ́ àti ọjọ́ kejì ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà, nǹkan bí àádọ́rin èèyàn ló sá lọ sí orílé-iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n pèsè aṣọ àti ibi ibùwọ̀ fún àwọn tí wọ́n pàdánù ẹrù àti ibùwọ̀ wọn ní òtẹ́ẹ̀lì. Wọ́n fún wọn lóúnjẹ. Kódà, àwọn alàgbà Kristẹni tó nírìírí fún wọn lóhun tó jọ pé ó ṣe pàtàkì jù, ìyẹn ni ìtùnú.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún kó àwọn ohun èlò táwọn tó ń gbẹ̀mí là nílò ránṣẹ́ sí wọn níbi tí ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà ti wáyé. Wọ́n tún gbé ọkọ̀ sílẹ̀ fún ẹ̀ka panápaná kí wọ́n lè fi gbé àwọn òṣìṣẹ́ panápaná lọ síbi ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún. Ricardo (tó wà lókè, lápá ọ̀tún), ẹni ọdún mọ́kàndínlógójì tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí, tó sì tún jẹ́ òṣìṣẹ́ ìmọ́tótó àyíká àti ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn mìíràn kò gbẹ́yìn, ojoojúmọ́ ni wọ́n ń kó òbítíbitì pàǹtírí dànù. Ó sọ fún Jí! pé: “Ibi ìṣẹ̀lẹ̀ náà kò rọgbọ rárá, àgàgà fáwọn òṣìṣẹ́ panápaná tí wọ́n ń wá òkú àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn. Mo rí i tí wọ́n hú òṣìṣẹ́ panápaná
kan jáde lóòyẹ̀. Òṣìṣẹ́ panápaná mìíràn kú nígbà tí ẹnì kan já bọ́ lé e lórí. Ẹkún lọ̀pọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ panápaná ń sun ràì. Mo jókòó mo sì bú sẹ́kún. Kò sẹ́ni tó hùwà akin tó àwọn ènìyàn wọ̀nyí lọ́jọ́ tá a wí yìí.”“Ìgbà àti Ìṣẹ̀lẹ̀ Tí A Kò Rí Tẹ́lẹ̀”
Ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló ṣòfò ẹ̀mí nínú àjálù náà. Ó kéré tán, àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́rìnlá wà lára wọn, wọ́n wà níbi tí ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà ti ṣẹlẹ̀ gan-an tàbí lẹ́bàá ibẹ̀. Joyce Cummings, ẹni ọdún márùnlélọ́gọ́ta, tó jẹ́ ọmọ Trinidad, lọ ṣètọ́jú eyín rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ilé Ìtajà Tó Tóbi Jù Lọ Lágbàáyé náà (World Trade Center) lọ́jọ́ yẹn. Ó mà ṣe o, ìgbà yẹn gan-an ni àjálù náà ṣẹlẹ̀. Èéfín ló hàn án léèmọ̀ tí wọ́n sì sáré gbé e lọ sí ilé ìwòsàn tó wà nítòsí. Àmọ́ ẹ̀pa kò bóró mọ́. Ó wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọ́n ń jìyà àtúbọ̀tán “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀” ni. (Oníwàásù 9:11) Gbogbo èèyàn ló mọ̀ ọ́n sí ajíhìnrere tó nítara.
Ilé iṣẹ́ okòwò kan tó wà ní àjà kẹrìnlélọ́gọ́rin ilé gogoro ti apá gúúsù ni Calvin Dawson (wo àpótí) ti ń ṣiṣẹ́. Ó wà ní ọ́fíìsì rẹ̀ ó sì fojú ara rẹ̀ rí i nígbà tí ọkọ̀ òfuurufú kọ lu ilé gogoro ti apá àríwá. Ọ̀gá Calvin kò sí ní ọ́fíìsì, àmọ́ ó tẹ̀ Calvin láago láti béèrè ohun tó ṣẹlẹ̀. Ohun tí ọ̀gá Calvin sọ nìyí: “Calvin ń gbìyànjú láti sọ ohun tó rí fún mi. Ó sọ pé, ‘Àwọn èèyàn ń fò látòkè!’ Ni mo bá sọ fún un pé kó ké sí àwọn èèyàn tó kù kí gbogbo wọn sì sá jáde kúrò nínú ọ́fíìsì náà.” Àmọ́ Calvin ò ríbi jáde. Lẹ́yìn náà lọ̀gá Calvin wá sọ pé: “Ká mú tẹ̀gàn kúrò, Calvin dára léèyàn, gbogbo wa la fẹ́ràn rẹ̀, títí kan àwa kan tí ìsìn kò jẹ́ nǹkankan lójú wa. Gbogbo wa ni ìfọkànsin Ọlọ́run tó ní àti bó ṣe ń ṣe dáadáa sáwọn èèyàn máa ń wú lórí lọ́pọ̀lọpọ̀.”
Ẹlẹ́rìí mìíràn tó ṣòfò ẹ̀mí nínú àjálù náà ni James Amato (nísàlẹ̀ pátápátá lójú ewé 10). Ọ̀gá ni nílé iṣẹ́ panápaná nílùú New York, ó sì ti bímọ mẹ́rin. Àwọn tó mọ̀ ọ́n nígbà ayé rẹ̀ sọ pé ó láyà débi pé “ó máa ń wọnú ilé tíná ti ń jó
kódà káwọn mìíràn tiẹ̀ máa sá sẹ́yìn.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti kú, wọ́n sọ ọ́ dọ̀gá àgbà níbi iṣẹ́ rẹ̀.Ẹlẹ́rìí mìíràn tó tún jẹ́ òṣìṣẹ́ panápaná, tó sì ti ṣiṣẹ́ náà fún ọdún méje ni George DiPasquale. Melissa lorúkọ ìyàwó rẹ̀, wọ́n sì ní ọmọbìnrin ọlọ́dún méjì kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Georgia Rose. Nígbà ayé rẹ̀, alàgbà ni nínú ìjọ Staten Island ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ó sì wà ní àjà kẹwàá ilé gogoro ti apá gúúsù nígbà tó wó lulẹ̀. Ibi tóun náà ti ń gbẹ̀mí àwọn ẹlòmíràn là ló ti dolóògbé.
Èyí kàn jẹ́ méjì péré lára ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn òṣìṣẹ́ panápaná, àwọn ọlọ́pàá, àtàwọn agbẹ̀mílà tí wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn nígbà tí wọ́n ń gbìyànjú láti gba ẹ̀mí àwọn èèyàn là. Ìgboyà àwọn èèyàn wọ̀nyí tó ohun téèyàn ń ṣe sàdáńkátà fún. Olórí Ìlú New York, Rudolph Giuliani, sọ lẹ́yìn náà fún àwùjọ àwọn òṣìṣẹ́ panápaná kan tí wọ́n gbé ga lẹ́nu iṣẹ́ pé: “Bẹ́ ẹ ṣe yọ̀ǹda ara yín láìbẹ̀rù, lákòókò tó le koko yìí jẹ́ ìwúrí fún gbogbo wa. . . . Kò tún . . . sí àpẹẹrẹ ìgboyà tó tayọ ti Ilé Iṣẹ́ Panápaná Ìlú New York.”
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tí Ń Tuni Nínú
Láwọn ọjọ́ tó tẹ̀ lé ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà, nǹkan bí ọ̀kẹ́ márùnlélógójì [900,000] àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ni wọ́n ṣakitiyan gidigidi láti tu àwọn tó ní ẹ̀dùn ọkàn nínú. Ìfẹ́ tí wọ́n ní fún àwọn aládùúgbò wọn sún wọn láti tu àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ nínú. (Mátíù 22:39) Bákan náà, nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn, wọ́n tún jẹ́ káwọn èèyàn mọ ìrètí kan ṣoṣo tó wà fún ẹ̀dá èèyàn tó bára wọn nínú wàhálà.—2 Pétérù 3:13.
Pẹ̀lú ẹ̀mí ìbákẹ́dùn làwọn Ẹlẹ́rìí náà fi ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. Ohun tí wọ́n ní lọ́kàn láti ṣe ni pé kí wọ́n tu àwọn èèyàn nínú látinú Ìwé Mímọ́ kí wọ́n sì fara wé àpẹẹrẹ Kristi tó ń tuni lára. Ó sọ pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú, èmi yóò sì tù yín lára. Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni èmi, ẹ ó sì rí ìtura fún ọkàn yín. Nítorí àjàgà mi jẹ́ ti inú rere, ẹrù mi sì fúyẹ́.”—Mátíù 11:28-30.
Wọ́n gba àwùjọ àwọn alàgbà láti ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Manhattan láyè láti dé ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà ti ṣẹlẹ̀ láti lọ bá àwọn agbẹ̀mílà tó wà níbẹ̀ sọ̀rọ̀ kí wọ́n sì tù wọ́n nínú. Àwọn èèyàn náà mọrírì ohun tí wọ́n ṣe yìí gan-an ni. Àwọn òjíṣẹ́ wọ̀nyí sọ pé: “Ńṣe ni omi ń bọ́ lójú àwọn èèyàn wọ̀nyí bá a ṣe ń ka ìwé mímọ́ fún wọn.” Àwọn agbẹ̀mílà kan ń sinmi nínú ọkọ̀ ojú omi kan létíkun. “Ńṣe ni wọ́n ń ká ṣíóṣíó, wọ́n dorí kodò nítorí ohun tí wọ́n fojú rí kọjá agbára wọn. A jókòó tì wọ́n á sì jíròrò ẹsẹ Bíbélì pẹ̀lú wọn. Àwọn ọkùnrin náà dúpẹ́ gidigidi fún wíwá tá a wá, wọ́n sọ pé àwọn nílò ìtùnú náà gan-an ni.”
Ó ń ṣe àwọn èèyàn táwọn Ẹlẹ́rìí bá sọ̀rọ̀ lẹ́yìn àjálù náà bíi kí wọ́n rí ohun kan kà, a sì pín ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìwé pẹlẹbẹ fún wọn lọ́fẹ̀ẹ́. Lára wọn ni ìwé pẹlẹbẹ Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, Will There Ever Be a World Without War? àti Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi? Bákan náà, a fún àwọn ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ inú ìtẹ̀jáde Jí! méjì ní àfiyèsí àrà ọ̀tọ̀: “The New Look of Terrorism” (May 22, 2001) àti “Coping With Post-traumatic Stress” (August 22, 2001). Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn Ẹlẹ́rìí máa ń ṣàlàyé nípa ìrètí àjíǹde tó wà nínú Bíbélì. (Jòhánù 5:28, 29; Ìṣe 24:15) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ni ọ̀rọ̀ ìtùnú yìí dé ọ̀dọ̀ wọn.
Ó Yẹ Kó Mú Wa Tún Inú Ara Wa Rò
Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ láabi bí èyí tó ṣẹlẹ̀ ní Ìlú New York yìí yẹ kó mú wa tún inú ara wa rò nípa ohun tá à ń fi ìgbésí ayé wa ṣe. Ṣé àwọn nǹkan tara wa nìkan là ń fayé wa lé kiri, àbí à ń sapá láti mú kí ayọ̀ àwọn ẹlòmíràn pọ̀ sí i? Wòlíì Míkà béèrè pé: ‘Kí ni ohun tí Jèhófà ń béèrè láti ọ̀dọ̀ rẹ bí kò ṣe pé kí o ṣe ìdájọ́ òdodo, kí o sì nífẹ̀ẹ́ inú rere, kí o sì jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run rẹ rìn?’ (Míkà 6:8) Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ á sún wa láti lọ sínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ká lè mọ ìrètí tòótọ́ tó wà fún àwọn tó ti kú ká sì tún mọ̀ pé láìpẹ́, Ọlọ́run á sọ ilẹ̀ ayé di Párádísè. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa àwọn ìlérí inú Bíbélì, a rọ̀ ọ́ pé kí o kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àdúgbò rẹ..—Aísáyà 65:17, 21-25; Ìṣípayá 21:1-4.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
ÀDÚRÀ TÍ TATIANA GBÀ
Ìyàwó olóògbé Calvin Dawson, ìyẹn Lena, sọ fún Jí! nípa àdúrà tí ọmọbìnrin rẹ̀ ọlọ́dún méje gbà ní ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn tó mọ̀ pé bàbá òun ò ní padà wálé mọ́. Lena ti gbàdúrà rẹ̀ tán, Tatiana wá béèrè pé, “Mọ́mì, ṣé mo lè gbàdúrà?” Ìyá rẹ̀ ní kó ṣe bẹ́ẹ̀. Tatiana bá tẹnu bọ àdúrà, ó ní: “Jèhófà, Bàbá wa ọ̀run, a dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ fún oúnjẹ yìí àti fún ìwàláàyè wa tòní. A bẹ̀bẹ̀ pé kí ẹ̀mí rẹ wà pẹ̀lú mi àti Mọ́mì ká lè ní okun. A tún bẹ̀bẹ̀ pé kí ẹ̀mí rẹ wà pẹ̀lú Dádì, kára rẹ̀ lè le dáadáa nígbà tó bá máa padà wálé. Tó bá sì dé, kó ṣèèyàn, kó lókun, kó láyọ̀ kára rẹ̀ sì le, ká sì tún rí i lẹ́ẹ̀kan sí i. Ní orúkọ Jésù . . . jọ̀wọ́, má gbàgbé láti fún Mọ́mì lókun o. Àmín.”
Kò dá Lena lójú bóyá Tatiana lóye ohun tó ti ṣẹlẹ̀, ó sọ pé: “Àdúrà rẹ dára gan-an ni Tiana. Àmọ́, olólùfẹ́, ǹjẹ́ o mọ̀ pé Dádì kò ní wálé mọ́?” Lójú ẹsẹ̀, ojú Tatiana ti kọ́rẹ́ lọ́wọ́. Ó sọ pé: “Ṣé pé kò ní wálé mọ́?” Ìyá rẹ̀ ní “Kò ní wálé mọ́. Mo rò pé mo ti sọ fún ọ ni. Mo rò pé mo ti sọ fún ọ pé Dádì kò ní wálé mọ́ ni.” Tatiana sọ pé: “Ṣùgbọ́n, ẹ máa ń sọ fún mi pé ó máa padà wálé nínú ayé tuntun kẹ̀!” Nígbà tí Lena wá lóye ohun tí ọmọ rẹ̀ ní lọ́kàn, ó sọ pé: “Tatiana, dákun, máà bínú. Èmi ni mo ṣì ọ́ lóye. Mo rò pé ńṣe lo sọ pé Dádì ń bọ̀ wálé lọ́la.” Lena wá sọ pé: “Inú mi dùn gan-an pé ó gbà gbọ́ pé ayé tuntun ń bọ̀ lóòótọ́.”