Ọ̀dọ́ Kan Tó Fi Ìsìn Rẹ̀ Yangàn
Ọ̀dọ́ Kan Tó Fi Ìsìn Rẹ̀ Yangàn
N ÍGBÀ tí Andrew wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá, wọ́n sọ fún un níléèwé pé kó ṣe iṣẹ́ kan wá láti ilé, kí iṣẹ́ náà dá lórí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀. Ó sọ pé: “Mo kọ́kọ́ ronú pé màá kọ̀rọ̀ nípa bàbá bàbá mi, ni mo bá tún ronú pé: ‘Tiẹ̀ gbọ́ ná! Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mà ni mí. Àǹfààní ńlá rèé láti sọ fún àwọn èèyàn nípa ohun tí mo gbà gbọ́!’
“Mo pe àkọlé iṣẹ́ náà ní ‘Dúró Gbọn-in,’ mo sì fi ìwé fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ kan yàwòrán inúnibíni rírorò tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dojú kọ lábẹ́ ìjọba Násì ti Jámánì. Lára àwọn àwòrán tí mo lò ni ti aṣọ tó ní àmì onígun mẹ́ta tó sì jẹ́ aláwọ̀ àlùkò àti onírúurú àwòrán àtàwọn lẹ́tà látọ̀dọ̀ ìdílé Kusserow. a Mo tún kó ẹ̀dà àwọn lẹ́tà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ sí ìjọba ilẹ̀ Jámánì síbẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn lẹ́tà náà kò dá sí ètò ìṣèlú, ṣùgbọ́n wọ́n ké gbàjarè pé ìwà àìdáa tí wọ́n ń hù sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò bọ́ sí i rárá. Mo gbé kásẹ́ẹ̀tì fídíò náà, Jehovah’s Witnesses Stand Firm Against Nazi Assault sí i, kí àwọn èèyàn lè wò ó. Mo tún kó Bíbélì, àwọn ìwé pẹlẹbẹ àtàwọn ìwé àṣàrò kúkúrú síbẹ̀.
“Wọ́n kọ́kọ́ fi àwọn ohun tá a ṣe yìí han gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ ní ilé ẹ̀kọ́. Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kejì, wọ́n ké sí àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti wá wò ó. Ọ̀pọ̀ wọn bi mí láwọn ìbéèrè nítorí wọn ò mọ̀ pé wọ́n ṣenúnibíni sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà ìjọba Násì.”
Andrew sọ pé níní ìgboyà ló jẹ́ kóun lè bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa nǹkan tóun gbà gbọ́. Ó sọ pé: “Mo mọ̀ pé àwọn kan máa fi mí ṣẹ̀sín, àmọ́ ara mi kì bá balẹ̀ ká ní mi ò sọ tẹnu mi ni. Nínú iṣẹ́ tí wọ́n ní kí n ṣe, mo sọ̀rọ̀ nípa àwọn èèyàn tó kú láti gbèjà ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú Jèhófà, èyí ló mú kí n ronú pé kò sóhun tó burú nínú kí èmi náà fara da àríwísí díẹ̀.”
Lópin gbogbo rẹ̀, inú Andrew dùn pé òun lo àǹfààní yìí láti wàásù. Ó sọ pé: “Mo ṣàlàyé púpọ̀ lórí ohun tí kò jẹ́ ká máa jagun, mo sì fún àwọn tó fìfẹ́ hàn ní Bíbélì, àwọn ìwé àtàwọn ìwé àṣàrò kúkúrú.” Ó fi kún un pé: “Kò tíì sí ìgbà kankan tí mo láyọ̀ pé mo jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ti ìgbà yẹn.”
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àmì onígun mẹ́ta aláwọ̀ àlùkò ni wọ́n fi ń dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ yàtọ̀ nínú àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́. Ìgbàgbọ́ ìdílé Kusserow gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò yingin nígbà ìjọba Násì. Wo Ilé Ìṣọ́nà March 1, 1986, ojú ìwé 10 sí 15.