Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣọ́ọ̀ṣì Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì—Ibi Ìyapa Ni

Ṣọ́ọ̀ṣì Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì—Ibi Ìyapa Ni

Ṣọ́ọ̀ṣì Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì—Ibi Ìyapa Ni

LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ILẸ̀ GẸ̀Ẹ́SÌ

ÌPÀDÉ Àpérò Lambeth ẹlẹ́ẹ̀kẹtàlá ti Ṣọ́ọ̀ṣì Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì wáyé ní Canterbury lọ́dún 1998, ní gbàgede kàtídírà wọn tó ti pé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún tí wọ́n ti kọ́ ọ. Nígbà tí Bíṣọ́ọ̀bù William E. Swing ń sọ̀rọ̀ níbi àpérò náà, ó sọ gbólóhùn tó fakíki yìí pé: “Ìsìn gbọ́dọ̀ jáwọ́ nínú jíjẹ́ orísun wàhálà kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í pèsè ọ̀nà àbáyọ. Kò lè sí àlàáfíà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè láé àfi táwọn ìsìn bá ní àlàáfíà láàárín ara wọn.”

Ìpínyà tó wà láàárín àwọn ìsìn kì í ṣe kékeré o, bẹ́ẹ̀ náà ló sì ṣe wà láàárín àwọn ọmọ ìjọ àtàwọn àlùfáà tí wọ́n jọ wà nínú ìsìn kan náà. Bíṣọ́ọ̀bù kan kọ̀ láti wá sí ìpàdé yìí, èyí tí wọ́n ti máa ń ṣe ní gbogbo ọdún mẹ́wàá mẹ́wàá láti ọdún 1948, nítorí pé àwọn bíṣọ́ọ̀bù obìnrin wà níbẹ̀. Díẹ̀ lára àwọn tó wà níbẹ̀ sì kọ̀ láti jíròrò Bíbélì pẹ̀lú àwọn obìnrin wọ̀nyí.

Nígbà tó jẹ́ pé ọ̀ràn kí wọ́n máa fi obìnrin joyè lohun tí wọ́n fi gbogbo àpérò wọn ti ọdún 1988 gbọ́, ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ lolórí kókó àríyànjiyàn wọn lọ́dún 1998. Lópin gbogbo rẹ̀, àwọn bíṣọ́ọ̀bù ọ̀hún panu pọ̀ pé, ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ “kò bá Ìwé Mímọ́ mu.” Kí ló mú wọn ṣe ìpinnu yẹn?

Ọ̀kan lára ohun tó fà á lè jẹ́ pé, àwọn ìjọ Áńgílíkà kò fẹ́ kí nǹkan kan ba àjọṣe àwọn àti Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì jẹ́ rárá. Wọ́n sì mọ̀ pé tí àwọ́n bá ṣì ń fàyè gba “ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ láàárín àwọn àlùfáà,” ìsìn méjèèjì yìí kò ní lè jọ máa fikùnlukùn mọ́. Ìdí mìíràn tó tún lè wà lẹ́yìn ìpinnu wọn náà lè jẹ́ nítorí ìbẹ̀rù àwọn ẹlẹ́sìn Ìsìláàmù. Gẹ́gẹ́ bí ohun táwọn bíṣọ́ọ̀bù tó wá láti ilẹ̀ Áfíríkà sọ, bí wọ́n bá lọ ṣe ìpinnu kan tó fàyè gba kí àwọn àlùfáà máa lọ́wọ́ sí ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ pẹ́nrẹ́n, a jẹ́ pé “iṣẹ́ ìjíhìnrere Kristi ti dópin” láwọn orílẹ̀-èdè ẹlẹ́sìn Ìsìláàmù nìyẹn.

Nígbà tí ìwé ìròyìn The Sunday Telegraph tún ń sọ nípa kókó mìíràn tó fa ìpínyà níbi àpérò náà, ó sọ pé: “Láwọn apá ibì kan ní Áfíríkà, olórí ohun tó jẹ́ ìṣòro àwọn míṣọ́nnárì ni ìkóbìnrinjọ.” Nígbà tí bíṣọ́ọ̀bù kan ń ṣíṣọ lójú ìṣòro líle koko yìí tó dojú kọ àwọn Áńgílíkà ní ilẹ̀ Áfíríkà, ó sọ pé: “Bí ẹnì kan bá dá owó rẹpẹtẹ sí Ṣọ́ọ̀ṣì àmọ́ tó ní ju ìyàwó kan lọ, kí làwọn bíṣọ́ọ̀bù máa ṣe?” Nígbà tí ìwé ìròyìn The Times ti ìlú London ń sọ nípa ohun tó ṣeé ṣe kó jẹ́ àbájáde ọ̀ràn tí wọ́n ń jiyàn lé lórí náà, ó sọ pé: “Ńṣe làwọn bíṣọ́ọ̀bù Áńgílíkà á ṣẹnu mẹ́rẹ́n wọn ò ní sọ nǹkankan mọ́ nípa ìkóbìnrinjọ náà.”

Fún ìgbà àkọ́kọ́, àwọn bíṣọ́ọ̀bù Áńgílíkà sọ̀rọ̀ nípa bí àjọṣe àwọn àti ẹ̀sìn Ìsìláàmù ṣe rí. Bíṣọ́ọ̀bù Kàdúná ní ilẹ̀ Nàìjíríà sọ pé: “Ìkórìíra ńláǹlà wà láàárín àwọn Kristẹni àtàwọn Mùsùlùmí ní Nàìjíríà,” ó ní, ó ti jú ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá èèyàn lọ tí ẹ̀mí wọn ti ṣòfò nítorí rògbòdìyàn ẹ̀sìn lórílẹ̀-èdè òun. Wọ́n sọ pé lílóye ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn Ìsìláàmù dáadáa nìkan ni kò ní jẹ́ kógun ẹ̀sìn bẹ́ sílẹ̀ ní Áfíríkà.

Kí ló ń bẹ lọ́jọ́ iwájú fún àádọ́rin mílíọ̀nù èèyàn káàkiri ayé tí wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà ṣọ́ọ̀ṣì Áńgílíkà gẹ́gẹ́ bí iye tí wọ́n pè wọ́n, àmọ́ tí awuyewuye ṣì ń lọ lórí iye náà? a Ipò náà kò mú orí èèyàn wú rárá o, nítorí gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn The Times ti sọ: “Kàyéfì gbáà ni àpérò ọ̀hún jẹ́ fún àwọn tó ń wòran àtàwọn tó ń kópa níbẹ̀, nítorí nígbà míì, ńṣe ni ìpàdé ọ̀hún máa dà bí ìpàdé àwọn olóṣèlú tí kò sì ní fibì kankan jọ ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹni níbi tí wọ́n ti ń gbàdúrà.”

Kò yani lẹ́nu nígbà náà, tí ìwé ìròyìn The Sunday Times fi parí ọ̀rọ̀ pé ‘gbúngbùngbún àti kèéta ni wọ́n fi ṣe ìpàdé ọ̀hún.’

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìwé ìròyìn The Times sọ pé iye yìí, ìyẹn àádọ́rin mílíọ̀nù “dún bí iye bàbàrà létí” àmọ́, “ohun tí wọn kì í sábà sọ ni pé mílíọ̀nù mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n lára iye yìí ló jẹ́ ara Ṣọ́ọ̀ṣì Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì lọ́wọ́lọ́wọ́ níbí [ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì] kò pé mílíọ̀nù kan mọ́, Áńgílíkà aláfẹnujẹ́ lásán sì ni gbogbo àwọn tó kù.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Kàtídírà ìlú Canterbury, ó ti pé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún tí wọ́n ti kọ́ ọ