Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọjọ́ Lọjọ́ Tí Ilé Gogoro Méjì Wó Ní Amẹ́ríkà

Ọjọ́ Lọjọ́ Tí Ilé Gogoro Méjì Wó Ní Amẹ́ríkà

Ọjọ́ Lọjọ́ Tí Ilé Gogoro Méjì Wó Ní Amẹ́ríkà

Ọ̀ KẸ́ àìmọye èèyàn lágbàáyé kò jẹ́ gbàgbé ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé nílùú New York, àtèyí tó ṣẹlẹ̀ nílùú Washington, D.C., àti ti ìlú Pennsylvania ní September 11, 2001. Ibo lo wà nígbà tó o gbọ́ pé àwọn apániláyà ti kọ lu ilé ìtajà tó tóbi jù lọ lágbàáyé, èyí tá a mọ̀ sí World Trade Center nílùú New York àti orílé-iṣẹ́ tó ń rí sọ́ràn ààbò, ìyẹn Pentagon nílùú Washington?

Ọ̀rọ̀ ọ̀hún tó jọ bí àlá, tó ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́, tí ọ̀pọ̀ ẹ̀mí sì ṣòfò ti mú káwọn èèyàn mọ̀ pé ó yẹ káwọn wa ibì kan fìdí lé káwọn sì tún inú àwọn rò.

Ẹ̀kọ́ wo la ti rí kọ́ nípa àwọn ohun tó yẹ ká fi sí ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wa àti nípa àwọn ohun tá a yàn láàyò? Báwo làwọn ìṣẹ̀lẹ̀ apanilẹ́kún wọ̀nyẹn ṣe jẹ́ ká wá túbọ̀ rí àwọn ànímọ́ dáadáa tí èèyàn ní, ìyẹn ìfara-ẹni-rúbọ, àánú, ìfaradà àti àìmọtara-ẹni-nìkan? Àpilẹ̀kọ yìí àti èyí tó tẹ̀ lé e yóò dáhùn ìbéèrè tá a béèrè kẹ́yìn yìí.

Àwọn Tó Yè Bọ́ Sọ Ohun Tójú Wọn Rí

Ní wéré tí àjálù ìlú New York náà ṣẹlẹ̀ ni ọkọ̀ ojú irin kò ti ṣiṣẹ́ mọ́, eré tete sì ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn sá kúrò nílùú Manhattan, ọ̀pọ̀ wọn ló sì sọdá lórí afárá Brooklyn àti Manhattan. Rekete ni wọ́n ń wo orílé-iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lára àwọn tí wọ́n ń wá ibi ìsádi láti ibi tí àjálù náà ti ṣẹlẹ̀ sì forí lé ibẹ̀.

Alisha (tó wà lápá ọ̀tún), ọmọbìnrin kan tí ìyá rẹ̀ jẹ́ Ẹlẹ́rìí wà lára àwọn tó kọ́kọ́ débẹ̀. Ńṣe ni eruku àti eérú bo ara rẹ̀ látòkèdélẹ̀. a Ó sọ pé: “Nígbà tí mo wà nínú ọkọ̀ ojú irin tí mo ń wọ̀ lọ síbi iṣẹ́, mo rí i tí èéfín ń jáde láti Ilé Ìtajà Tó Tóbi Jù Lọ Lágbàáyé (World Trade Center). Nígbà tí mo dé ibi tí àjálù náà ti ṣẹlẹ̀, àfọ́kù gíláàsì wà nílẹ̀ káàkiri, èmi fúnra mi rí i pé ìṣẹ̀lẹ̀ láabi rèé lóòótọ́. Ńṣe làwọn èèyàn ń sá kolobá kolobà, àwọn ọlọ́pàá sì ń kó àwọn èèyàn kúrò ní àgbègbè náà. Bí ojú ogun níbẹ̀ ṣe rí.

“Mo sáré lọ sínú ilé kan tó wà nítòsí láti forí pa mọ́ síbẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni mo gbọ́ ariwo ńlá bí ọkọ̀ òfuurufú kejì ṣe kọlu ilé gogoro kejì tó wà lápá gúúsù. Áà, ìran ọ̀hún kò ṣeé ṣàlàyé, ńṣe ni èéfín kún ibi gbogbo bámúbámú. Wọ́n ní ká kúrò ní àgbègbè eléwu náà. Wọ́n fi ọkọ̀ ojú omi gbé mi sọdá omi East River sí Brooklyn. Nígbà tí mo sọdá sódì kejì, mo gbójú sókè mo sì rí àkọlé gàdàgbà náà, ‘WATCHTOWER.’ Orílé-iṣẹ́ ẹ̀sìn màmá mi nìyí kẹ̀! Kíá ni mo kẹ́sẹ̀ sọ́nà, ó di ibẹ̀. Mo mọ̀ pé kò sí ibòmíràn tí mo ti lè rí àbójútó bí èyí tí màá rí níbẹ̀. Ibẹ̀ ni mo ti tún ara mi ṣe tí mo sì wá tẹ àwọn òbí mi láago.”

Wendell (tó wà lápá ọ̀tún) jẹ́ òṣìṣẹ́ tó máa ń dúró sẹ́nu géètì Òtẹ́ẹ̀lì Marriott tó wà láàárín ilé gogoro méjèèjì náà. Ó sọ pé: “Ẹnu iṣẹ́ ni mo wà nígbà tí jàǹbá àkọ́kọ́ ṣẹlẹ̀. Mo rí i tí onírúurú pàǹtí ń rọ́ lulẹ̀ wìì látòkè. Mo wo ojú pópó, mo sì rí ọkùnrin kan tí iná ń jó làùlàù lára rẹ̀. Mo gbọn ẹ̀wù mi ya mo sì sáré lọ sọ́dọ̀ ọkùnrin yìí láti bá a pa iná tó ń jó lára rẹ̀. Ẹnì kan tó ń kọjá lọ tún pẹ̀lú mi láti ràn án lọ́wọ́. Gbogbo aṣọ ọ̀gbẹ́ni náà ló jóná mọ́ ọn lára. Bàtà àti ìbọ̀sẹ̀ tó wọ̀ nìkan ni kò jóná. Ìgbà yẹn làwọn panápaná dé wọ́n sì gbé e láti lọ tọ́jú rẹ̀.

“Kò pẹ́ lẹ́yìn èyí, Bryant Gumbel, tó wà ní ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n CBS tẹlifóònù mi láti gbọ́ ohun tí mo rí níbi ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún. Bí wọ́n ṣe gbé mi jáde lórí tẹlifíṣọ̀n yìí ló jẹ́ káwọn ìdílé mi ní Virgin Islands rí mi tí wọ́n sì mọ̀ pé mi ò tíì kú.”

Ọkùnrin fìrìgbọ̀n ni Donald, ó ga níwọ̀n sẹ̀ǹtímítà márùn-ún dín nígba [195]. Ibùdó Ìdókòwò Àgbáyé ló ti ń ṣiṣẹ́. Látorí àjà kọkànlélọ́gbọ̀n tó wà lọ́jọ́ náà ló ti ń wo Ilé Gogoro Méjì náà àti Òtẹ́ẹ̀lì Marriott lọ́ọ̀ọ́kán. Ó sọ pé: “Ohun ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ tí mo rí dẹ́rù bà mí, ó sì kó jìnnìjìnnì bá mi. Àwọn èèyàn ń já bọ́ láti ojú fèrèsé ilé gogoro tó wà lápá àríwá, táwọn mìíràn sì ń bẹ́ látòkè. Ara mi kò gbà á, kíá ni mo bẹ́sẹ̀ mi sọ̀rọ̀ tí mo sá jáde kúrò nínú ilé tí mo wà.”

Ìrírí mìíràn ni ti ìyá kan tó ti lé ní ọgọ́ta ọdún àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjì táwọn náà ti lé ní ogójì ọdún. Ruth àti àbúrò rẹ̀ obìnrin Joni ń gbé lọ́dọ̀ ìyá wọn, tó ń jẹ́ Janice, ní òtẹ́ẹ̀lì kan tí kò jìnnà sí Ilé Gogoro Méjì náà. Ruth, tó ń ṣiṣẹ́ nọ́ọ̀sì sọ ohun tó ṣẹlẹ̀: “Mò ń wẹ̀ lọ́wọ́ nílé ìwẹ̀. Lójijì ni mo gbọ́ tí màmá mi àti àbúrò mi pariwo pé kí n jáde nílé ìwẹ̀. Àjà kẹrìndínlógún là ń gbé, wọ́n sì ń rí i bí àwọn pàǹtí tó ń já bọ́ ṣe ń gba ojú fèrèsé kọjá. Kódà, màmá mi kófìrí ọkùnrin kan níbi òrùlé tó wà nítòsí wa, ńṣe ló dà bíi pé wọ́n jù ú láti ibì kan.

“Kíá mo ti wọṣọ, a sì sá jáde. Igbe là ń gbọ́ lọ́tùn-ún lósì. A bọ́ sójú pópó. À ń gbọ́ táwọn nǹkan ń bú gbàù, gbàù, bẹ́ẹ̀ là ń rí i tí iná ń sọ kẹ̀ù. Wọ́n ní ká yára forí lé apá gúúsù ní Battery Park, níbi tí Ọkọ̀ Ojú Omi tó ń ná Staten Island wà. Bá a ṣe ń lọ, la ò bá rí Màmá mọ́, bẹ́ẹ̀ sì rèé ikọ́ fée ń yọ ọ́ lẹ́nu gan-an. Báwo ló ṣe máa yè bọ́ nínú adúrú èéfín, eérú àti ekuru yìí? Odidi ọgbọ̀n ìṣẹ́jú la fi wá a kiri tá ò sì rí i. Àmọ́, àyà wa kò fi bẹ́ẹ̀ já nítorí ẹni tó dáńgájíá ni màmá ó sì mọ bó ṣe lè tọ́jú ara rẹ̀.

“Nígbà tó yá, wọ́n sọ pé ká lọ gba orí Afárá Brooklyn ká sì gbabẹ̀ sọdá sí òdìkejì. Ńṣe lara wa rọlẹ̀ wọ̀ọ̀ nígbà tá a sọdá afárá náà tá a sì rí àkọlé gàdàgbà náà ‘WATCHTOWER’! A mọ̀ pé kò séwu mọ́.

“Wọ́n tọ́jú wa wọ́n sì fún wa nílé. Wọ́n tún fún wa láṣọ, nítorí pé kìkì aṣọ tó wà lára wa nìkan la ní. Àmọ́ ibo ni Màmá wà? Gbogbo òru la fi ń wá a kiri ilé ìwòsàn, àmọ́ pàbó ni gbogbo rẹ̀ já sí. Ní nǹkan bí aago mọ́kànlá ààbọ̀ òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, a rí ìsọfúnni kan gbà. Màmá wà ní ọ̀dẹ̀dẹ̀ àjà tó wà nísàlẹ̀! Kí ló ti ṣẹlẹ̀ sí i?”

Janice, ìyẹn màmá fúnra rẹ̀, gbẹ́nu lé ọ̀rọ̀: “Bá a ṣe sá kúrò nínú òtẹ́ẹ̀lì náà, mo rí obìnrin arúgbó kan tó jẹ́ ọ̀rẹ́ mi, tó ṣì wà nínú ilé nígbà táwa sáré jáde. Mo fẹ́ wọlé padà láti gbé e jáde. Àmọ́ ewu gidi ni. Ibi tí ọ̀rọ̀ ti di bóòlọ-o-yà-fún-mi yìí lèmi àtàwọn ọmọ mi ti ya ara wa. Àmọ́ ṣá, ẹ̀rù kò bà mí jù, nítorí orí wọn pé dáadáa, nọ́ọ̀sì tó mòye sì ni Ruth.

“Ibikíbi tí mo bá kọjú sí ni mo ti ń rí àwọn èèyàn tó nílò ìrànlọ́wọ́, àgàgà àwọn ògo wẹẹrẹ àtàwọn ìkókó. Mo ran àwọn tí mo lè ràn lọ́wọ́ lọ́wọ́. Mo lọ ràn wọ́n lọ́wọ́ níbi tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn tó fara pa. Mo ń bá àwọn ọlọ́pàá àtàwọn panápaná fomi fọ iwájú àti ọwọ́ wọn tí màjàlà àti eruku kún bámúbámú. Ibẹ̀ ni mo wà títí aago mẹ́ta ìdájí. Mo wá wọ ọkọ̀ ojú omi tó gbẹ̀yìn lọ sí Staten Island. Mo ronú pé ó ṣeé ṣe káwọn ọmọ mi ti lọ wábi forí pa mọ́ sí níbẹ̀. Àmọ́ mi ò rí wọn níbẹ̀.

“Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, mo ní kí n lọ wọ ọkọ̀ ojú omi àkọ́kọ́ lọ sí Manhattan, àmọ́ wọn ò jẹ́ kí n wọ̀ ọ́ nítorí mi ò sí lára àwọn òṣìṣẹ́ tó ń lọ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ níbi tí àjálù ti ṣẹlẹ̀. Bí mo ṣe tajú kán, ni mo rí ọ̀kan lára àwọn ọlọ́pàá tí mo ti ràn lọ́wọ́ tẹ́lẹ̀. Mo bá ké sí i pé: ‘John! Mo fẹ́ padà sí Manhattan.’ Ó dáhùn pé: ‘Wá máa bá mi lọ.’

“Nígbà tí mo dé Manhattan, mo padà sí Òtẹ́ẹ̀lì Marriott. Pé bóyá mo ṣì lè ráyè ran ọ̀rẹ́ mi arúgbó náà lọ́wọ́. Àyè rẹ̀ kò yọ! Òtẹ́ẹ̀lì náà ti di àlàpà. Àárín ìgboro sì dá páropáro, kò ku ẹnì kan ṣoṣo níbẹ̀ mọ́. Àwọn ọlọ́pàá àtàwọn òṣìṣẹ́ panápaná nìkan ló wà ńbẹ̀, ìbànújẹ́ sì ti dorí wọn kodò.

“Mo tún ta mọ́ra, ó di ibi Afárá Brooklyn. Bí mo ṣe sún mọ́ òpin afárá náà, mo rí àkọlé kan tí mo ti máa ń rí tẹ́lẹ̀, ìyẹn ‘WATCHTOWER.’ Mo ní bóyá màá rí àwọn ọmọ mi níbẹ̀. Mó kúkú rí wọn níbẹ̀, wọ́n wá sí ọ̀dẹ̀dẹ̀ wá kí mi. Bá a ṣe ń gbára wa mú ni omijé ń jáde lójú wa!

“Ó yà mí lẹ́nu pé pẹ̀lú gbogbo èéfín, ekuru àti eérú náà, ikọ́ fée mi kò dà mí láàmú pínrín. Àdúrà ni mò ń gbà ṣáá, nítorí ńṣe ni mo fẹ́ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, kì í ṣe pé kí n di ẹrù ìnira sí wọn lọ́rùn.”

“Kò Mà Síbi Tó Lè Balẹ̀ Sí Níbí!”

Rachel, obìnrin kan tó lé lọ́mọ ogun ọdún sọ fún akọ̀ròyìn Jí! pé: “Mò ń rìn lọ lójú pópó ládùúgbò mi lápá ìsàlẹ̀ Manhattan nígbà tí mo gbọ́ ariwo ọkọ̀ òfuurufú lókè. Ariwo náà pọ̀ gan-an tí mo fi gbójú sókè. Ó yà mí lẹ́nu nígbà tí mo rí ọkọ̀ òfuurufú gìrìwò náà tó ń já bọ̀ wálẹ̀. Bó ṣe ń yara fò bọ̀ wálẹ̀ yìí ṣe mí ní kàyéfì. Kò mà síbi tó lè balẹ̀ sí níbí! Àbí ọkọ̀ náà ti yarí mọ́ ẹni tó ń wà á lọ́wọ́ ni. Bẹ́ẹ̀ ni mo gbọ́ tí obìnrin kan figbe ta, ‘Àfi gbòò tí ọkọ̀ òfuurufú yìí kọlu ilé náà!’ Ńṣe ni iná ńlá sọ kẹ̀ù látinú ilé gogoro ti apá àríwá. Mo rí ihò ńlá tí ọkọ̀ òfuurufú yìí dá sí ara ilé náà.

“Mi ò rí irú nǹkan ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ bẹ́ẹ̀ rí láyé mi. Ńṣe ló dà bí àlá. Mo kàn dúró ni tí mo la ẹnu sílẹ̀. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni ọkọ̀ òfuurufú mìíràn tún kọlu ilé gogoro kejì, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ilé gogoro méjèèjì dà wó lulẹ̀. Jìnnìjìnnì bò mí. Ohun tó ṣẹlẹ̀ náà ju ẹ̀mí mi lọ!”

“Bó Jẹ́ Kí N Lúwẹ̀ẹ́ Ni, Màá Lúwẹ̀ẹ́”

Denise, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún ṣẹ̀ṣẹ̀ dé sí ilé ìwé rẹ̀ ni, èyí tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ibùdó Ìṣepàṣípààrọ̀ Okòwò ní Amẹ́ríkà tó jẹ́ ilé kẹta sí Ilé Ìtajà Tó Tóbi Jù Lọ Lágbàáyé ti apá gúúsù. “Aago mẹ́sàn-án àárọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ kọjá ni. Mo mọ̀ pé nǹkan kan ti ṣẹlẹ̀, àmọ́ mi ò mọ ohun náà ní pàtó. Mo wà ní àjà kọkànlá ilé ìwé náà, níbi tí wọ́n ti ń kọ́ mi ní ẹ̀kọ́ nípa ìtàn. Gbogbo àwa akẹ́kọ̀ọ́ làyà wa ń já. Olùkọ́ wa sáà fẹ́ ṣe ìdánwò fún wa. Àwa sì fẹ́ jáde ká máa lọ sílé.

“Ilé ìwé wa mì jìgìjìgì bí ọkọ̀ òfuurufú kejì ṣe kọlu ilé gogoro kejì ní ìhà gúúsù. Síbẹ̀, a ò tíì mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀. Mo kàn ṣàdédé gbọ́ lórí rédíò asọ̀rọ̀gbèsì tíṣà wa pé: ‘Ọkọ̀ òfuurufú méjì ti kọlu Ilé Gogoro Méjèèjì o!’ Mo ń rò ó nínú ara mi pé ‘Kò bọ́gbọ́n mu kéèyàn ṣì tún jókòó sílé ìwé o. Àwọn apániláyà ló ń ṣiṣẹ́ yìí o, Ibùdó Ìṣepàṣípààrọ̀ Okòwò ló sì máa kàn lẹ́yìn èyí.’ La bá jáde.

“A sáré lọ sí Battery Park. Mo bojú wẹ̀yìn pé kí n tiẹ̀ wo nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀. Mo rí i pé ilé gogoro tó wà níhà gúúsù fẹ́ dà wó. Mo ń rò ó pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé ló máa wó o nítorí àwọn ilé gogoro gogoro tó ń dà wó yìí. Mi ò lè mí dáadáa, nítorí eérú àti eruku ti dí imú àti ọ̀nà ọ̀fun mi. Mo sáré lọ síbi odò East River, mo sì ń sọ lọ́kàn mi pé, ‘Bó jẹ́ kí n lúwẹ̀ẹ́ ni, màá lúwẹ̀ẹ́.’ Bí mo ṣe ń sá, ni mo ń gbàdúrà sí Jèhófà pé kó dáàbò bò mí o.

“Nígbà tó yá, wọ́n fi mí sínú ọkọ̀ ojú omi kan tó gbé mi lọ sí New Jersey. Ó lé ní wákàtí márùn-ún tí màmá mi fi wá mi kiri kó tó rí mi, àmọ́ ọpẹ́ ni pé kò sóhun tó ṣe mí!”

“Ṣé Ọjọ́ Tí Màá Ráyé Mọ Rèé?”

Joshua, ẹni ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n, tó wá láti ìlú Princeton, ní New Jersey, ń kọ́ àwọn kan níwèé ní àjà ogójì nínú ilé gogoro ti ìhà àríwá. Ó sọ pé: “Lójijì ni nǹkan ọ̀hún dún gbàù bíi bọ́ǹbù. Ibi gbogbo mì jìgìjìgì, mo sì sọ pé, ‘Rárá, ilẹ̀ ló sẹ̀.’ Mo wòta, ohun àràmàǹdà gbáà ni mo rí, èéfín àti pàǹtírí ló bo gbogbo ara ilé náà. Mo sọ fún àwọn tí mo ń kọ́ pé, ‘Ó yá, gbogbo yín, ẹ fi gbogbo ẹrù yín sílẹ̀. Ẹ jẹ́ ká lọ!’

“A bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀ kalẹ̀ látorí àjà náà, èéfín gba ibi gbogbo kan, omi sì ń tú jáde látinú ẹ̀rọ omi. A ò jẹ́ kí ìpayà mú wa. Mo bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà pé kó sáà jẹ́ ọ̀nà tó tọ́ la gbà ká má lọ ko iná lọ́nà.

“Bí mo ṣe ń sáré sọ̀ kalẹ̀, mo ń rò ó lọ́kàn pé, ‘Ṣé ọjọ́ tí màá ráyé mọ rèé?’ Mo sáà ń gbàdúrà sí Jèhófà, ara mi sì wá rọlẹ̀ pẹ̀sẹ̀. Irú ìbàlẹ̀ ọkàn bẹ́ẹ̀ kò tíì bá mi rí. Mi ò ní gbà gbé rẹ̀ títí ayé.

“Nígbà tá a jàjà kúrò nínú ilé náà, àwọn ọlọ́pàá ti ń kó àwọn èèyàn kúrò níbẹ̀. Mo gbójú sókè mo sì rí i pé wọ́n ti dáhò sára ilé gogoro méjèèjì. Mérìíyìírí gbáà ni.

“Ohun ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ mìíràn tún ṣẹlẹ̀, ńṣe ni ibi gbogbo pa rọ́rọ́ bí ìgbà tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn bá ṣíwọ́ mímí. Ó wá dà bí ẹni pé ohunkóhun ò dún pẹ́nkẹ́n ní ìlú New York. Lẹ́yìn èyí la bẹ̀rẹ̀ sí gbúròó igbe lọ́tùn-ún lósì. Ni ilé gogoro ti apá gúúsù bá bẹ̀rẹ̀ sí í dà wó! Èéfín ń sọ kùlà, eérú àti ekuru sì ń bù wá sápá ọ̀dọ̀ wa. Ńṣe ló dà bí àwọn nǹkan tí kò lè ṣẹlẹ̀ lójú ayé tá a máa ń rí nínú sinimá. Àmọ́ eléyìí ṣẹlẹ̀ gan-gan. Ìgbà tí gbogbo eruku yìí dé ibi tá a wà, agbára káká la fi ń mí.

“Mo sá lọ sórí Afárá Manhattan, ibẹ̀ ni mo ti bojú wẹ̀yìn tí mo sì rí i tí ilé gogoro ti apá àríwá àti òpó tẹlifíṣọ̀n gàgàrà tó wà lórí rẹ̀ ń wó lulẹ̀. Bí mo ṣe ń sọdá lórí afárá náà ni mò ń gbàdúrà kí n lè dé Bẹ́tẹ́lì, ìyẹn orílé-iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Látọjọ́ tí mo ti ń lọ síbẹ̀, mi ò tíì láyọ̀ tó ti ọjọ́ náà rí. Àkọlé gàdàgbà kan sì wà lára ògiri ilé ìtẹ̀wé náà tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn lè rí lójoojúmọ́ tó sọ pé, ‘Máa Ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Bíbélì Mímọ́ Lójoojúmọ́’! Mo sọ lọ́kàn ara mi pé, ‘Mo ti fẹ́rẹ̀ẹ́ débẹ̀. Kí n sáà tẹsẹ̀ mọ́rìn.’

“Bí mo ṣe ń ronú lórí àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ yìí ti jẹ́ kí n túbọ̀ mọ̀ lọ́kàn mi pé, mo ní láti fara balẹ̀ láti mọ àwọn ohun tó yẹ kí n kọ́kọ́ ṣe, ìyẹn ni pé, mo gbọ́dọ̀ fi àwọn ohun tó yẹ kó gba ipò iwájú nígbèésí ayé ṣíwájú.”

“Mo Rí I Táwọn ÈèyànŃ Bẹ́ Sílẹ̀ Látorí Ilé Gogoro Náà”

Jessica, ọmọ ọdún méjìlélógún, rí ohun tó ṣẹlẹ̀ bó ṣe bọ́ sílẹ̀ látinú ọkọ̀ ojú irin kan láàárín ìgboro. “Bí mo ṣe wòkè ni mo rí i tí eérú, pàǹtírí àti irin ń já bọ̀ wálẹ̀. Ọ̀pọ̀ èèyàn tò sídìí fóònù tó máa ń wà káàkiri ìgboro, inú sì ń bí wọn nítorí kò tètè kàn wọ́n. Mo gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún mi ní sùúrù. Bẹ́ẹ̀ la tún gbọ́ tí nǹkan kan tún bú gbàù lẹ́ẹ̀kejì. Irin àti àkúfọ́ ìgò ǹ já bọ́ látòkè. Mo gbọ́ táwọn èèyàn ń pariwo, ‘Ọkọ̀ òfuurufú mìíràn tún ni o!’

“Mo gbójú sókè, ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ lohun tí mo rí, àwọn èèyàn ń bẹ́ sílẹ̀ látòkè pátápátá níbi tí èéfín àti iná ti bú jáde. Mo ṣì lè finú wo bó ṣe ṣẹlẹ̀, ìyẹn ti ọkùnrin àti obìnrin kan. Wọ́n di fèrèsé mú fúngbà díẹ̀. Nígbà to yá ó di dandan kí wọ́n jáwọ́ lára fèrèsé, bí wọ́n ṣe ń já bọ̀ wálẹ̀ nìyẹn ṣòòròṣò. Áà, àríbanújẹ́ gbáà ni.

“Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, mo dé orí Afárá Brooklyn, ibẹ̀ ni mo ti bọ́ bàtà tó ń dẹ́rù pa mí tí mo sì sáré sọdá sí Brooklyn. Mo lọ sí ilé Watchtower, wọ́n sì bójú tó mi níbẹ̀ títí tí ara mi fi balẹ̀.

“Lálẹ́ ọjọ́ yẹn, nígbà tí mo wà nílé, mo ka àwọn àpilẹ̀kọ tó sọ nípa ‘Coping With Post-traumatic Stress,’ nínú Jí! August 22, 2001. Ìsọfúnni tó wà nínú rẹ̀ bọ́ sákòókò gan-an ni!”

Bí àjálù tó ṣẹlẹ̀ yìí ṣe rinlẹ̀ tó sún ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti ṣèrànwọ́ lọ́nà èyíkéyìí tí apá wọn ká. Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e sọ̀rọ̀ nípa èyí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn tó yè bọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí tí Jí! fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò pọ̀ gan-an, kò lè sáyè láti kọ ohun tí gbogbo wọn sọ síbí. Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ wọn ló jẹ́ ká lè ṣe àkọsílẹ̀ pípéye yìí.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

ÀWỌN IBI TÓ PA RẸ́ RÁÚRÁÚ

1 ILÉ GOGORO APÁ ÀRÍWÁ 1 Ilé Ìtajà Tó Tóbi Jù Lọ Lágbàáyé

2 ILÉ GOGORO APÁ GÚÚSÙ 2 Ilé Ìtajà Tó Tóbi Jù Lọ Lágbàáyé

3 ÒTẸ́Ẹ̀LÌ MARRIOTT 3 Ilé Ìtajà Tó Tóbi Jù Lọ Lágbàáyé

7 7 ILÉ ÌTAJÀ TÓ TÓBI JÙ LỌ LÁGBÀÁYÉ

ÀWỌN IBI TÓ BÀ JẸ́ GAN-AN

4 4 ILÉ ÌTAJÀ TÓ TÓBI JÙ LỌ LÁGBÀÁYÉ

5 5 ILÉ ÌTAJÀ TÓ TÓBI JÙ LỌ LÁGBÀÁYÉ

L ONE LIBERTY PLAZA

D BÁŃKÌ DEUTSCHE 130 Òpópónà Liberty

6 6 ILÉ IṢẸ́ ÀWỌN ÒṢÌṢẸ́ AṢỌ́BODÈ TI ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ 6 Ilé Ìtajà Tó Tóbi Jù Lọ Lágbàáyé

N S ÀRÍWÁ ÀTI GÚÚSÙ ÀWỌN AFÁRÁ TÁWỌN ẸLẸ́SẸ̀ Ń GBÀ

ÀWỌN IBI TÍ KÒ BÀ JẸ́ PÚPỌ̀

2F 2 IBÙDÓ ÌDÓKÒWÒ ÀGBÁYÉ

3F 3 IBÙDÓ ÌDÓKÒWÒ ÀGBÁYÉ

W WINTER GARDEN

[Credit Line]

Títí di October 4, 2001 3D Àwòrán-Ilẹ̀ ti Lower Manhattan látọwọ́ Urban Data Solutions, Inc.

[Àwọn àwòrán]

Òkè pátápátá: Ilé gogoro ti apá gúúsù ló kọ́kọ́ wó lulẹ̀

Lápá òkè: Àwọn kan sáré lọ sínú àwọn ilé Watchtower fún ààbò

Lápá ọ̀tún: Ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn òṣìṣẹ́ panápaná àtàwọn agbẹ̀mílà ṣiṣẹ́ àṣelàágùn níbi tí ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà ti wáyé

[Àwọn Credit Line]

Fọ́tò AP/Jerry Torrens

Fọ́tò Andrea Booher/FEMA News

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

Fọ́tọ̀ AP/Marty Lederhandler

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 4]

Fọ́tò AP/Suzanne Plunkett