Bí A Ṣe Lè Dín Ewu Inú Oúnjẹ Kù
Bí A Ṣe Lè Dín Ewu Inú Oúnjẹ Kù
ṢÉ OÚNJẸ lè ṣèèyàn ní jàǹbá ni? Àwọn ìwádìí kan lè mú kó o gbà bẹ́ẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Ìlera Àgbáyé ṣe sọ, nǹkan bí àádóje mílíọ̀nù àwọn èèyàn tó wà ní Àgbègbè Tí Àjọ Ìlera Àgbáyé Ń Bójú Tó ni Yúróòpù ni àìsàn tí oúnjẹ ń fà ń yọ lẹ́nu lọ́dọọdún. Ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nìkan, ó ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún èèyàn lọ tí wọ́n jẹ oúnjẹ burúkú ní 1998, èyí tó sì fa ikú nǹkan bí igba èèyàn. Wọn fojú bù ú pé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́rìndínlọ́gọ́rin èèyàn ló ń kó àìsàn látinú oúnjẹ lọ́dọọdún, ọ̀kẹ́ mẹ́rìndínlógún ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [325,000] lára wọn ni wọ́n á dá dúró sílé ìwòsàn, tí ẹgbẹ̀rún márùn-ún á sì gbẹ́mìí mì níkẹyìn.
Kò lè rọrùn rárá láti mọ bí ọ̀ràn náà ti rí ní gbogbo ayé. Àmọ́, Àjọ Ìlera Àgbáyé ròyìn pé ní 1998, nǹkan bíi mílíọ̀nù méjì àti ọ̀kẹ́ mẹ́wàá [2,200,000] èèyàn ni àìsàn ìgbẹ́ gbuuru pa, mílíọ̀nù
kan àti ogójì ọ̀kẹ́ [1,800,000] lára wọn ló sì jẹ́ àwọn ọmọ kéékèèké. Ìròyìn náà sọ pé: “Èyí tó pọ̀ jù nínú wọn ló jẹ́ pé tí wọ́n bá wádìí rẹ̀, oúnjẹ àti omi tó lẹ́gbin nínú ló fà á.”Iye yẹn lè dún bí iye tó pọ̀ rẹpẹtẹ létí. Àmọ́ ṣé ó yẹ kí ìròyìn tí wọ́n ń gbé jáde kó jìnnìjìnnì bá ẹ nípa bí oúnjẹ rẹ kò ṣe ní ṣe ọ́ ní jàǹbá? Kò dájú. Tún wo àpẹẹrẹ mìíràn. Ní Ọsirélíà, nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́rin àti ọ̀kẹ́ mẹ́wàá [4,200,000] èèyàn ló ń kó àìsàn látinú oúnjẹ lọ́dọọdún, ìyẹn sì jẹ́ nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mọ́kànlá àtààbọ̀ [11,500] lójoojúmọ́! Iye yẹn lè dún bí iye kan tó pọ̀ jàáǹtìrẹrẹ. Àmọ́ tún gba ọ̀nà mìíràn wò ó ná. Iye ìgbà táwọn ara Ọsirélíà ń jẹun lọ́dún kan ń lọ sí bíi bílíọ̀nù lọ́nà ogún ìgbà; nínú gbogbo rẹ̀, èyí tó lè yọrí sí àìsàn kò tó nǹkan kan rárá. Ká sọ ọ́ lọ́nà míì, ewu tó wà nínú oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ kéré gan-an ni.
Síbẹ̀ ewu ńbẹ, èyí sì gba ìrònú gidi. Kí ló ń mú kí oúnjẹ máa fa àìsàn, kí la sì lè ṣe láti dín ewu náà kù?
Àwọn Ohun Tó Ń Fa Àìsàn Nínú Oúnjẹ
Ìwé ìròyìn Emerging Infectious Diseases sọ pé ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àìsàn lèèyàn lè kó látinú oúnjẹ, àti pé àwọn àìsàn náà lé ní ọgọ́rùn-ún méjì. Àmọ́ àwọn ohun tó ń fa àwọn àìsàn wọ̀nyí kò tó nǹkan rárá. Gẹ́gẹ́ bí dókítà Iain Swadling, ọ̀gá tó ń rí sí Ètò àti Ìsọfúnni Nípa Oúnjẹ Lágbàáyé
ṣe sọ, nǹkan bí ìdá àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo àwọn àìsàn tí oúnjẹ ń fà ló jẹ́ pé ẹ̀yà àwọn kòkòrò tín-tìn-tín tó ń fà wọ́n “kò pé mẹ́rìnlélógún.” Báwo ni onírúurú àwọn ohun tó ń fa àìsàn—ìyẹn àwọn fáírọ́ọ̀sì, bakitéríà, àfòmọ́, àtàwọn májèlé lóríṣiríṣi ṣe ń ráyè dénú oúnjẹ?Dókítà Swadling dárúkọ márùn-ún lára àwọn ọ̀nà tó wọ́pọ̀ jù lọ tí oúnjẹ fi máa ń di èyí tó lè fa àìsàn: “Síse èèlò oúnjẹ tó ti bà jẹ́; kí ẹni tó lárùn tàbí tó ń ṣàìsàn máa se oúnjẹ; àìsí ọ̀nà tó bójú mu láti tọ́jú oúnjẹ pa mọ́ àti síse oúnjẹ sílẹ̀ tipẹ́ kó tó di pé èèyàn ṣẹ̀ṣẹ̀ wá jẹ ẹ́; kí kòkòrò ara oúnjẹ kan ran òmíràn níbi téèyàn ti ń sè é; kí oúnjẹ má jinná tàbí kó máà gbóná dáadáa nígbà téèyàn ń tún un gbé kaná.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ohun tí wọ́n kà sílẹ̀ yìí lè dà bí èyí tó ń kó ìdààmú báni, ohun kan wà nínú wọn tó dùn mọ́ni láti gbọ́. Ọ̀pọ̀ ohun tó ń fa àìsàn látinú oúnjẹ yìí ló ṣeé yẹra fún. Láti mọ ohun tó o lè ṣe láti rí i dájú pé oúnjẹ rẹ kò ní ṣe ọ́ ní jàǹbá, wo àpótí tó wà ní ojú ewé 18 àti 19.
Bó O Ṣe Lè Ṣe Ìpinnu Tó Dára
Nítorí onírúurú ewu àti àníyàn tó ti dìde nípa ọ̀ràn oúnjẹ, àwọn kan lónìí ti wá pinnu pé èròjà oúnjẹ tó ṣì tutù yọ̀yọ̀ làwọn á máa rà, pé àwọn á máa sè é fúnra àwọn, òun làwọn á sì máa jẹ. Tí irú ìpinnu yẹn bá wu ìwọ náà, wá ọjà tàbí àwọn ibi tí wọ́n ti ń ta àwọn nǹkan tí kò tíì pẹ́ nílẹ̀ tí wọ́n ò sì tíì po nǹkan mọ́ ládùúgbò rẹ. Ìwé kan tó ń tọ́ àwọn òǹrajà sọ́nà sọ pé: “Ọ̀pọ̀ òǹrajà máa ń lọ pàdé àwọn ọlọ́jà, bóyá láwọn ọjà tí wọ́n ń ná lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ [níbi tí wọ́n ti ń ta nǹkan tútù yọ̀yọ̀] tàbí níbi tí wọ́n ti ń ṣe àwọn oúnjẹ náà jáde—kí wọ́n bàa lè rí àwọn nǹkan náà rà nígbà tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde kí wọ́n sì lè rí i bí wọ́n ṣe ń ṣe é àti ibi tó ti ń jáde wá.” Irú àṣà yìí lè ṣèrànwọ́ nígbà téèyàn bá fẹ́ ra àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ẹran.
Bákan náà, ríra àwọn nǹkan tó jẹ́ tiwa-n-tiwa
lásìkò tí wọ́n máa ń jáde lọ́pọ̀ rẹpẹtẹ lóko tún lè ṣèrànwọ́ púpọ̀, níwọ̀n bó ti lè jẹ́ pé àwọn ló máa ṣara lóore jù lọ. Àmọ́ gbọ́ o, tó bá jẹ́ irú ìlànà yẹn lo fẹ́ gùn lé, kì í ṣe gbogbo ìgbà ni wàá máa rí àwọn nǹkan bí èso àti ẹ̀fọ́ lọ́pọ̀ yanturu bẹ́ẹ̀ tọ́dún á fi yí po.Ṣé wàá kúkú yíjú sí àwọn oúnjẹ tí wọn ò fi ajílẹ̀ àti ìmọ̀ ẹ̀rọ gbìn? Ìwọ lo ni ìpinnu yẹn. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló nífẹ̀ẹ́ àwọn oúnjẹ tí wọn ò fi nǹkan kan gbìn, ó sì dájú pé ohun tó sún àwọn kan sí i kò ṣẹ̀yìn bí wọn ò ṣe ní ìgbẹ́kẹ̀lé mọ́ nínú ìmọ̀ ẹ̀rọ tuntun tí àwọn iléeṣẹ́ tó ń ṣe oúnjẹ ń lò. Ṣùgbọ́n gbogbo èèyàn kọ́ ló gbà pé àwọn oúnjẹ tí wọ́n gbìn láìlo ìmọ̀ ẹ̀rọ kò lè ṣèèyàn ní jàǹbá.
Irú oúnjẹ yòówù kó o yàn láti máa jẹ, rí i pé o ń wo ohun tí o ń rà dáadáa. Ògbógi kan tí wọ́n fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ nínú ìwé ìròyìn ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ kan tó ń jẹ́ Die Zeit dárò pé: “Tó bá di ọ̀rọ̀ oúnjẹ rírà, iye owó tí wọ́n dá lé e nìkan làwọn òǹrajà máa ń wò.” Ó dára lóòótọ́ láti ṣọ́ owó ná, àmọ́ tún máa ṣàkíyèsí ohun tó o fẹ́ rà dáadáa. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì àwọn èèyàn tó ń ra oúnjẹ láwọn orílẹ̀-èdè Ìwọ Oòrùn ayé tí wọ́n fojú bù pé wọn kì í fara balẹ̀ ka ìsọfúnni tó wà lára àwọn oúnjẹ náà nípa iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe lára. Lóòótọ́, láwọn orílẹ̀-èdè kan àwọn ohun tí wọ́n máa ń kọ sára wọn kì í kún tó. Àmọ́ tó o bá fẹ́ oúnjẹ tí kò léwu nínú, ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti ṣàyẹ̀wò àwọn èròjà wọn.
Ìpinnu yòówù kó o ṣe nípa irú oúnjẹ tí o ń jẹ, o jọ pé kò sọ́gbọ́n tí o kò fi ní máa yíwọ́ padà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, tí wàá máa ṣe é bó bá ṣe gbà ní àdúgbò tí o ń gbé. Fún ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń gbé láyé lónìí, kò sọ́gbọ́n tí wọ́n lè dá tí wọ́n á fi máa rí oúnjẹ tí kò léwu nínú rárá jẹ nígbà gbogbo. Owó, àkókò àti wàhálà tó máa ná wọn á ti pọ̀ jù.
Ṣé ìyẹn wá jẹ́ kó o wò ó pé ayé tá a ń gbé yìí kò já mọ́ nǹkankan mọ́? Òótọ́ pọ́ńbélé ibẹ̀ nìyẹn. Àmọ́, ìròyìn ayọ̀ kan wà o, òun ni pé, nǹkan máa tó yí padà sí rere.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18, 19]
Àwọn Ohun Tó o Lè Ṣe
◼ Má fi nǹkan sílẹ̀ láìfọ̀. Rí i pé o ń fi ọṣẹ àti omi gbígbóná fọ ọwọ́ rẹ kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í se oúnjẹ. Fọ ọwọ́ rẹ lẹ́yìn tó o bá lo ilé ìyàgbẹ́ tán, tó o bá tọ́jú ọmọ tán (irú bíi tó o bá pààrọ̀ ìtẹ́dìí tàbí tó o bá nu imú ọmọ), àti nígbà tó o bá fọwọ́ kan ẹranko, títí kan àwọn ẹran tẹ́ ẹ̀ ń sìn nínú ilé. Fi ọṣẹ àti omi gbígbóná fọ gbogbo nǹkan tó o bá lò, bíi pátákó ìgé-nǹkan àti orí ibi tó o ti ń dáná ní gbogbo ìgbà tó o bá se oúnjẹ tán, àgàgà tó o bá se ẹran tútù, adìyẹ tàbí ẹja tútù. Ìwé ìròyìn Test dámọ̀ràn pé kí o “fi omi tó lọ́ wọ́ọ́rọ́wọ́ fọ èso àti ẹ̀fọ́” láti pa àwọn kòkòrò àti àwọn oògùn apakòkòrò tó ṣì lè ṣẹ́ kù sí wọn lára. Lọ́pọ̀ ìgbà, bíbó èèpo ara nǹkan tó o fẹ́ jẹ, bíbẹ wọ́n tàbí bíbọ̀ wọ́n nínú omi gbígbóná ni ọ̀nà tó dára jù lọ láti jẹ́ kí wọ́n mọ́. Tó bá jẹ́ ewébẹ̀ lettuce tàbí cabbage ni, ṣí gbogbo ewé ẹ̀yìn wọn dà nù.
◼ Máa se oúnjẹ rẹ jinná dáadáa. Tí iná tàbí ààrò tó o fi ń se oúnjẹ bá ń jó dáadáa tí oúnjẹ náà bá sì jinná wọnú dáadáa, bí o kò tilẹ̀ sè é fúngbà pípẹ́, gbogbo kòkòrò tó bá wà nínú rẹ̀ ló máa fẹ́rẹ̀ẹ́ kú tán. Adìyẹ tútù gbọ́dọ̀ pẹ́ lórí iná dáadáa ju gbogbo oúnjẹ mìíràn lọ. Tó o bá ń tún oúnjẹ gbé kaná, rí i pé ó gbóná wọnú dáadáa. Má ṣe jẹ adìyẹ tí inú rẹ̀ ṣì pọ́n rẹ́súrẹ́sú, ẹyin tí kò jinná tàbí ẹja tí kò jinná dénú, tí ò ṣeé tètè fi ṣíbí ya.
◼ Má ṣe kó èèlò oúnjẹ pọ̀ mọ́ra wọn. Rí i pé o kì í kó ẹran tútù, adìyẹ tàbí ẹja tútù mọ́ àwọn oúnjẹ mìíràn nígbà kankan, bóyá nígbà tó o bá lọ rà wọ́n lọ́jà, tó o bá ń kó wọn pa mọ́ tàbí nígbà tó o bá ń sè wọ́n. Má ṣe jẹ́ kí omi wọn máa ta tàbí kó máa ro sórí ara wọn tàbí sórí oúnjẹ mìíràn. Bákan náà, má ṣe bu oúnjẹ tó o ti sè tán sínú àwo tó o ti kọ́kọ́ fi kó ẹran, ẹja tàbí adìyẹ tútù tẹ́lẹ̀, àyàfi tó o bá ti fi omi gbígbóná àti ọṣẹ fọ̀ wọ́n.
◼ Palẹ̀ oúnjẹ mọ́ tàbí kó o gbé wọn sínú fìríìjì. Fìríìjì kì í jẹ́ kí àwọn kòkòrò àrùn tó léwu máa pọ̀ sí i, àmọ́ o, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ fìríìjì tó máa ń mú omi tutù gan-an. Ẹ̀rọ tó ń mú omi dì gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tí omi inú tòun náà máa ń dì dáadáa. Má ṣe jẹ́ kí oúnjẹ tó lè bà jẹ́ lò ju wákàtí méjì lọ nílẹ̀ kó o tó gbé e sínú fìríìjì. Tó o bá máa kọ́kọ́ bu oúnjẹ sílẹ̀ kó tó di pé o jẹ ẹ́, rí i pé o bo àwọn àwo náà kí eṣinṣin má bàa bà lé wọn lórí.
◼ Ṣọ́ra tó o bá ń ra oúnjẹ jẹ. Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan ti fi hàn, nǹkan bí ìdá ọgọ́ta sí ọgọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo àìsàn táwọn èèyàn ń kó látinú oúnjẹ ní àwọn orílẹ̀-èdè kan tó ti gòkè àgbà ló jẹ́ pé látinú àwọn oúnjẹ tí wọ́n rà jẹ ni wọ́n ti kó o. Rí i dájú pé ilé àrójẹ èyíkéyìí tó o bá yà láti jẹun kúnjú ìwọ̀n ohun tí òfin ìlera àti ti ìmọ́tótó béèrè. Sọ fún wọn pé ẹran tó jinná dáadáa lo fẹ́. Tó bá jẹ́ pé o fẹ́ gbé oúnjẹ náà dání lọ ni, rí i pé o jẹ ẹ́ láàárín wákàtí méjì sígbà tó o rà á. Tó bá ti lè kọjá àkókò yẹn, tún un gbé kaná dáadáa.
◼ Tí o bá ń ṣiyèméjì nípa oúnjẹ kan, dà á nù. Tí kò bá dá ọ lójú bóyá oúnjẹ kan ṣì dáa tàbí ó ti bà jẹ́, a dáa kó o dáàbò bo ara rẹ nípa dídà á nù. Lóòótọ́, kò dára kéèyàn máa fi oúnjẹ tó dáa ṣòfò. Síbẹ̀, tó o bá lọ kó àìsàn látinú oúnjẹ tó ti bà jẹ́, ohun tó máa ná ẹ lè ju oúnjẹ yẹn lọ.
[Credit Line]
—A rí èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn kókó yìí látinú ìwé Food Safety Tips, tí Ẹgbẹ́ Tó Ń Fi Ìmọ̀ Ẹ̀rọ Dáàbò Bo Oúnjẹ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ṣe.