Ewu Wo Ló Wà Nínú Kí Àwọn Èwe Máa Dájọ́ Àjọròde?
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Ewu Wo Ló Wà Nínú Kí Àwọn Èwe Máa Dájọ́ Àjọròde?
“Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn ọmọkùnrin kan níléèwé ń sọ fún mi pé ká jọ máa dájọ́ àjọròde tàbí káwọn fi mí ṣe ọ̀rẹ́bìnrin àwọn.”—Becky, ọmọ ọdún mọ́kànlá. a
“Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ọmọ iléèwé wa ló lẹ́ni tí wọ́n ń fẹ́. Ká sòótọ́, kò tún jẹ́ nǹkan tuntun mọ́ pé kí àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin jọ máa fẹnu kora wọn lẹ́nu ní ọ̀dẹ̀dẹ̀ iléèwé.”—Liana, akẹ́kọ̀ọ́ kan níléèwé gíga.
Ọ̀PỌ̀ ọ̀dọ́ máa ń bẹ̀rẹ̀ sí í ní ọ̀rẹ́kùnrin tàbí ọ̀rẹ́bìnrin nígbà tí wọ́n ṣì kéré gan-an. Àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn máa ń gbé àṣà yìí lárugẹ bí ẹni pé ohun tó bójú mu ni, bí ẹni pé eré lásán ni tí kò sí nǹkan kan tó burú ńbẹ̀. Oneyda, ọmọ ọdún méjìlá sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo àwọn ọmọ iléèwé ló ní ọ̀rẹ́kùnrin tàbí ọ̀rẹ́bìnrin.” Ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin kan tó ń jẹ́ Jenifer sọ pé: “Mo mọ àwọn ọmọ tí wọn ò ju ọmọ ọdún mẹ́sàn-án lọ tí wọ́n ti ní ọ̀rẹ́kùnrin.” Ó fi kún un pé: “Ọmọ ọdún mọ́kànlá ṣì ni mí tó ti dà bíi pé kí èmi náà máa bá ọkùnrin jáde.”
Ìyẹn fi yéni pé, tóò bá lẹ́nì kan tí ò ń fẹ́, o lè dà bí ẹni tí kò bẹ́gbẹ́ mu. Kódà gan-an, wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé sùẹ̀gbẹ̀ ni ẹ́, kí wọ́n máa fi ẹ́ ṣẹ̀sín nítorí pé o ò ṣe bí i tiwọn. Nítorí Jenifer mọ̀ pé òún ṣì kéré jù láti ní ọ̀rẹ́kùnrin, kò gbà fún àwọn ọmọkùnrin tí wọ́n ń sọ fún un pé káwọn jọ máa jáde. Kí ni wọ́n ṣe? Jenifer sọ pé: “Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ wọ́n sì ń sọ ọ́ káàkiri.” Kò sẹ́ni tó dùn mọ́ pé kí wọ́n máa fi òun ṣe yẹ̀yẹ́. Àmọ́ ṣé ó yẹ kó o bẹ̀rẹ̀ sí í dájọ́ àjọròde nítorí pé àwọn kan ń ṣe bẹ́ẹ̀? Kí tiẹ̀ ló túmọ̀ sí láti dájọ́ àjọròde? Ète wo ló sì wà fún?
Kí Ló Ń Jẹ́ Dídájọ́ Àjọròde?
Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló máa ń sọ gbólóhùn náà pé ‘A ò fẹ́ra wa o, ọ̀rẹ́ lásán ni wá’ bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí tó pọ̀ jù nínú àkókò wọn ni wọ́n ń lò pẹ̀lú ẹnì kan tó jẹ́ ẹ̀yà kejì. Àmọ́ orúkọ yòówù kí o pè é—ì báà jẹ́ dídájọ́ àjọròde, jíjọ lọ síbì kan, tàbí kẹ́ ẹ kàn jọ máa wá ara yín lọ lásán—tí ọ̀dọ́mọkùnrin kan àti ọ̀dọ́mọbìnrin kan bá ṣáà ti lè yan ara wọn láàyò tí wọ́n sì jọ ń lo àkókò pa pọ̀, ìyẹn ti kúrò ní ọ̀rọ̀ ọ̀rẹ́ lásán. Kì í sì í ṣe ẹni téèyàn rí sójú nìkan lèèyàn ń bá dájọ́ àjọròde. Jíjọ sọ̀rọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, lórí tẹlifóònù, nípasẹ̀ lẹ́tà, tàbí nípa fífi lẹ́tà ránṣẹ́ lórí kọ̀ǹpútà, ọmọ ìyá dídájọ́ àjọròde ni gbogbo wọn.
Ìbéèrè tó wà níbẹ̀ ni pé, Báwo tiẹ̀ ni lílo
àkókò púpọ̀ pẹ̀lú ẹnì kan ṣoṣo gíro tó jẹ́ ẹ̀yà kejì ṣe léwu tó?Àwọn Ewu Tó Wà Nínú Dídájọ́ Àjọròde
Nínú Òwe 30:19, Bíbélì pé nǹkan kan ní “ọ̀nà abarapá ọkùnrin pẹ̀lú omidan.” Gbólóhùn yìí fi hàn pé, ó ní bí àjọṣe tó máa ń wà láàárín ọkùnrin àti obìnrin ṣe sábà máa ń rí. Tí àwọn méjèèjì bá ti dàgbà tó tí wọ́n sì ń ṣègbọràn sí ọ̀nà ìwà rere tí Ọlọ́run là sílẹ̀, dídájọ́ àjọròde a jálẹ̀ sí ìfẹ́, á sì wá yọrí sí ìgbéyàwó tó lọ́lá nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Ó ṣe tán, ńṣe ni Ọlọ́run dá ọkùnrin àti obìnrin lọ́nà tí wọ́n á fi wu ara wọn. Àmọ́ ká ní o ò tíì tó ẹni tó ń ṣègbéyàwó ńkọ́? Bó o bá lọ ń dájọ́ àjọròde nígbà tó o ṣì kéré, kòtò wàhálà lo ń gbẹ́ sílẹ̀ fúnra rẹ yẹn o.
Kí nìdí? Torí pé, tó o bá bẹ̀rẹ̀ sí lo ọ̀pọ̀ àkókò pẹ̀lú ẹnì kan tó jẹ́ ẹ̀yà kejì, kò sí tàbí ṣùgbọ́n pé ìfẹ́ onítọ̀hún á bẹ̀rẹ̀ sí kó sí ẹ lórí. Kó o tó mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀, á ti máa ṣe ẹ́ bí i pé kó o ṣáà máa rí onítọ̀hún. Àkókò tí ẹ ò bá jọ wà pa pọ̀ báyìí, ńṣe ni wàá máa ronú nípa rẹ̀ ṣáá. Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, ọ̀kan láàárín ẹ̀yin méjèèjì ló máa ní irú ìmọ̀lára yẹn tí ìbànújẹ́ á sì bá ẹnì kan. Ká tiẹ̀ wá ní ẹ̀yin méjèèjì lẹ jọ nífẹ̀ẹ́ ara yín, ìjákulẹ̀ àti ìbànújẹ́ náà ló ṣì máa kẹ́yìn rẹ̀ nígbà tí ẹnì kan tàbí ẹnì kejì kò bá tíì dàgbà dénú tó tàbí lọ́jọ́ lórí tó láti ṣègbéyàwó. Ká sòótọ́, ibo ni irú àjọṣe yẹn máa sìn yín dé ná? Òwe Bíbélì kan sọ pé: “Ṣé ọkùnrin kan lè wa iná jọ sí oókan àyà rẹ̀, síbẹ̀síbẹ̀ kí ẹ̀wù rẹ̀ gan-an má sì jóná?”—Òwe 6:27.
Gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Nina yẹ̀ wò. Ó sọ pé: “Mo pàdé ọ̀dọ́mọkùnrin kan lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ọ̀pọ̀ wákàtí la fi máa ń sọ̀rọ̀ lójoojúmọ́ lórí ibi tí wọ́n ti máa ń fọ̀rọ̀ wérọ̀ lórí kọ̀ǹpútà. Ńṣe ni ọkàn mi á máa fà sí i ṣáá, orí rẹ̀ sì ni gbogbo ìgbésí ayé mi dá lé. Àjọṣe yìí kò gùn lọ títí o. Nígbà tó wá sópin, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìsoríkọ́ tó lékenkà. Lẹ́yìn náà, ó pè mí ó sì sọ fún mi pé ńṣe ni òun máa pa ara òun fún pé a túká. Ìyẹn túbọ̀ wá dá kún ìsoríkọ́ tí mo ní.” Nígbà ti Nina wo gbogbo rẹ̀ látòkèdélẹ̀, ohun tó sọ ni pé: “Àṣedànù gbáà ló jẹ́! Ó ti pé ọdún méjì báyìí tí àjọṣe yẹn ti forí ṣánpọ́n, síbẹ̀ ìbànújẹ́ ṣì dórí mi kodò.” Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé Nina ti kéré jù láti ní irú àjọṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ẹnì kan.
Ó yẹ ká fiyè sí i pé, nígbà tí Bíbélì sọ nípa “ọ̀nà abarapá ọkùnrin pẹ̀lú omidan,” ó lè jẹ́ ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ ló ń sọ. Láyé òde òní, ìbálòpọ̀ ló sábà máa ń kẹ́yìn dídájọ́ àjọròde. Ó lè máà sí èrò tó burú kankan lọ́kàn yín níbẹ̀rẹ̀, ẹ kàn lè máa di ara yín lọ́wọ́ mú lásán. Ó lè jẹ́ pé gbígbára yín mú tàbí fífẹnu kora yín lẹ́rẹ̀kẹ́ ló máa tẹ̀ lé e. Ìyẹn yàtọ̀ sí ti àwọn tó ti dàgbà o, tí wọ́n ti ní àdéhùn tó nípọn láàárín ara wọn tí wọ́n sì ń fi irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn síra wọn. Àmọ́ nígbà tẹ́ni méjì kan kò bá tíì tó láti ṣègbéyàwó, irú ìwà bẹ́ẹ̀ kò lóhun méjì tó máa yọrí sí ju pé kí ọkàn wọn máa fà sí ìbálòpọ̀ láìyẹ. Fífi irú “ìfẹ́ni” bẹ́ẹ̀ hàn lè bẹ̀rẹ̀ sí lágbára sí i, kó sì di èyí tí kò tọ́ tàbí aláìmọ́. Ó tiẹ̀ lè yọrí sí àwọn ìwà tó jẹ mọ́ àgbèrè. b
1 Kọ́ríńtì 6:13, 18; 1 Tẹsalóníkà 4:3) Yíyàgò fún dídájọ́ àjọròde ní rèwerèwe ló máa jẹ́ kó o lè pa àṣẹ yìí mọ́.
Ìbànújẹ́ ló máa ń tẹ̀yìn àgbèrè jáde. Àwọn kan tó ń ṣe é máa ń kó àrùn tí ìbálòpọ̀ ń fà. Àwọn mìíràn kì í níyì lójú ara wọn mọ́, ẹ̀rí ọkàn wọn kì í sì í jẹ́ kí wọ́n gbádùn. Àwọn ọmọbìnrin mìíràn tí wọ́n ṣì kéré máa ń rí oyún he. Abájọ tí Bíbélì fi pa àṣẹ yìí pé: “Sá fún àgbèrè”! (Ìgbà Tó Yẹ Kéèyàn Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Dájọ́ Àjọròde
Èyí kò wá túmọ̀ sí pé o ò ní tó ẹni tó ń dájọ́ àjọròde mọ́ láéláé o. Àmọ́ tó bá jẹ́ ọ̀dọ́langba ṣì ni ọ́, ó jọ pé àkókò kan tí Bíbélì pè ní “ìgbà ìtanná òdòdó èwe” lo ṣì wà. (1 Kọ́ríńtì 7:36) Ńṣe lo ṣẹ̀sẹ̀ ń dàgbà di irú ọkùnrin tàbí obìnrin tí wà á jẹ́ nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Láàárín àkókò yìí, o ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dàgbà ni, nípa tara, ti èrò ìmọ̀lára, àti ti ìbálòpọ̀. Àkókò yìí ni àwọn ìmọ̀lára rẹ, títí kan ìfẹ́ rẹ láti ní ìbálòpọ̀ máa lágbára ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Àmọ́ o, àwọn ìmọ̀lára yẹn tún lè yí padà bìrí. Ìdí nìyẹn tí ọ̀rọ̀ ìfẹ́ tó máa ń wà láàárín àwọn ọ̀dọ́langba kì í fi í tọ́jọ́ rárá. Ọ̀dọ́mọbìnrin kan sọ pé: “Tí mo bá ń bá ẹnì kan ròde, kì í ju ọ̀sẹ̀ kán lọ, tí àá sì fòpin sí i lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e.”
Ó hàn kedere pé, kò bọ́gbọ́n mu láti máa dájọ́ àjọròde nígbà “ìtànná òdòdó èwe.” Ohun tó dára jù lọ ni pé kó o ní sùúrù títí dìgbà tí wàá lóye ara rẹ dáadáa, tí wàá mọ àwọn ohun tó wù ọ́ àtèyí tí kò wù ọ́, àtàwọn ohun tó o fẹ́ fi ìgbésí ayé rẹ ṣe. Bákan náà, o gbọ́dọ̀ dàgbà tó ẹni tí ń gbé àwọn ẹrù iṣẹ́ ìdílé. Fún àpẹẹrẹ, Jèhófà retí pé kí ọkọ pèsè fún ìdílé rẹ̀, nípa ti ara àti nípa tẹ̀mí. Ìwọ ọkùnrin tó o jẹ́ ọ̀dọ́langba, ṣé o ti múra tán láti wá iṣẹ́ rí kó o sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé bùkátà obìnrin kan àti, bóyá tàwọn ọmọ pẹ̀lú? Ṣé wà á lè ràn wọ́n lọ́wọ́ tí wọ́n á fi lè máa bá a lọ ní jíjẹ́ ẹni tẹ̀mí? Tó bá sì jẹ́ ọ̀dọ́bìnrin ni ọ́ ńkọ́? A béèrè lọ́wọ́ aya láti nífẹ̀ẹ́ ọkọ̀ rẹ̀ kó sì tẹrí ba fún un; ó gbọ́dọ̀ gbárùkù ti àwọn ìpinnu tó bá ṣe. Ṣé lóòótọ́ lo ti múra tán láti máa ṣe bẹ́ẹ̀ láìjáwọ́? Bákan náà, ṣe o ti múra tán láti máa tọ́jú ilé, tí wàá máa pèsè oúnjẹ, tí wàá sì máa tọ́jú àwọn ọmọ?—Éfésù 5:22-25, 28-31; 1 Tímótì 5:8.
Bí àpẹẹrẹ: Ní ìlú òyìnbó, ó máa ń wu àwọn ọ̀dọ́ gan-an láti wa mọ́tò àwọn òbí wọn. Àmọ́ kí ni ọ̀dọ́ kan gbọ́dọ̀ ṣe kó tó di ẹni tí wọ́n fún láyè láti ṣe bẹ́ẹ̀? Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, o gbọ́dọ̀ gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí wàá sì ṣe ìdánwò kí wọ́n tó lè fún ẹ ní ìwé àṣẹ. Kí nìdí? Nítorí pé ẹrù iṣẹ́ ńlá ni wíwakọ̀ jẹ́. Tó o bá ń wakọ̀, ọwọ́ rẹ ni ẹ̀mí rẹ àti tàwọn mìíràn tó wà nínú ọkọ̀ wà. Tóò, ìgbéyàwó náà kì í ṣe ẹrù iṣẹ́ kékeré o! Bí o sì ti jẹ́ ọ̀dọ́langba, o lè má tíì tó ẹni tó ń ṣègbéyàwó rárá. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, á bọ́gbọ́n mu pé kó o yẹra fún ìdẹwò náà láti bẹ̀rẹ̀ sí í dájọ́ àjọròde, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ohun tó wà fún ni láti wá ẹni téèyàn máa fẹ́. Ká kúkú sọ ọ́ lọ́nà tó rọrùn: Tóò bá tíì tó ẹni tó ń ṣègbéyàwó, o ò gbọ́dọ̀ dájọ́ àjọròde.
Láti lè ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu lórí ọ̀rọ̀ yìí, o nílò ohun tí Bíbélì pè ní “ìmọ̀ àti agbára láti ronú.” (Òwe 1:4) Nígbà náà, ohun tó bọ́gbọ́n mu tó o lè ṣe ni pé, kó o wá ìmọ̀ àti ìrírí lọ́dọ̀ ẹnì kan tó dàgbà jù ọ́ lọ. Àwọn òbí tí wọ́n jẹ́ Kristẹni ló máa lè ràn ọ́ lọ́wọ́ lọ́nà tó dára jù láti jẹ́ kó o mọ̀ bóyá lóòótọ́ lo ti tó ẹni tí ń ṣègbéyàwó. O sì tún lè gba ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn mẹ́ńbà ìjọ Kristẹni tí wọ́n dàgbà dénú. Táwọn òbí rẹ bá ní kó o máà tíì dájọ́ àjọròde, á dára kó o gbọ́ tiwọn. Ìfẹ́ wọn ni pé kí wọ́n ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè “taari ìyọnu àjálù kúrò.”—Oníwàásù 11:10.
Tí wọ́n bá rí i pé o ò tíì tó ẹni tí ń dájọ́ àjọròde, wọ́n lè dábàá pé ní báyìí ná, dípò tó fi jẹ́ pé orí ẹnì kan ṣoṣo gíro ni wàá kó gbogbo ìrònú rẹ lé, kó o ní àwọn ọ̀rẹ́ tó pọ̀ sí i. Bíbá àtọmọdé àtàgbà, àpọ́n àti ẹni tó ti gbéyàwó kẹ́gbẹ́, títí kan àwọn tó jẹ́ ojúgbà rẹ, á jẹ́ kí ìṣesí rẹ dára sí i á sì jẹ́ kó o túbọ̀ mọ ohun tí ìgbésí ayé àti ìgbéyàwó jẹ́ lóòótọ́.
Dídúró di ìgbà tí wàá tó ẹni tí ń ṣègbéyàwó kò ní rọrùn. Àmọ́ ohun tó dára jù lọ láti ṣe nìyẹn o. Nípa “lílo ìgbà ìtanná òdòdó èwe” láti dàgbà di àgbàlagbà tó dáńgájíá tó sì mọ ohun tó ń ṣe, ọ̀pọ̀ ìṣòro ni wàá bì sọ nù. Wàá fún ara rẹ lákòókò láti dàgbà di ẹni tó lè kápá àwọn wàhálà àti ẹrù iṣẹ́ ìgbéyàwó. Wàá tún fún ara rẹ lásìkò tó tó láti dàgbà di ẹni tẹ̀mí. Nípa bẹ́ẹ̀, nígbà tó o bá wá tó ẹni tí ń dájọ́ àjọròde, àwọn mìíràn á lè rí i pé lóòótọ́ lo yẹ lẹ́ni téèyàn ń fẹ́ láti mọ̀.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.
b Inú ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, por·neiʹa ni àgbèrè ti wá. Ó jẹ́ ìṣekúṣe tí wọ́n ń fi àwọn ẹ̀yà ìbímọ ṣe láàárín àwọn ẹni tí kò ṣègbéyàwó. Èyí kan fífi ọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ẹnì kan àti ìbálòpọ̀ àgbẹnuṣe.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Wàhálà ló sábà máa ń kẹ́yìn kí àwọn èwe máa fìfẹ́ hàn síra wọn