Ǹjẹ́ Ó Yẹ Káwọn Kristẹni Máa Ṣayẹyẹ Ọdún Tuntun?
Ojú Ìwòye Bíbélì
Ǹjẹ́ Ó Yẹ Káwọn Kristẹni Máa Ṣayẹyẹ Ọdún Tuntun?
FERNANDO tó jẹ́ oníṣègùn òyìnbó ní ilẹ̀ Brazil sọ pé: “Kì í sí wàhálà kankan ní ọ̀sán Ọjọ́ Ọdún Tuntun o. Àmọ́ tó bá di aago mọ́kànlá alẹ́ báyìí ni wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí í ya dé, ìyẹn àwọn tí wọ́n ti gún lọ́bẹ tàbí yìnbọn fún, àwọn ọ̀dọ́langba tí jàǹbá ọkọ̀ ti ṣe léṣe àtàwọn obìnrin tí ọkọ wọn ti lù bolẹ̀. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ọtí líle ló máa ń fa gbogbo rẹ̀.”
Pẹ̀lú ohun tó wà lókè yìí, kò lè jẹ́ ìyàlẹ́nu béèyàn bá ka ohun tí ìwé ìròyìn ilẹ̀ Brazil kan sọ pé, ọjọ́ kìíní nínú ọdún jẹ́ ọjọ́ táwọn èèyàn kárí ayé ń ṣera wọn léṣe lẹ́yìn tí wọ́n bá ti mutí yó. Iléeṣẹ́ ìròyìn ilẹ̀ Yúróòpù kan sọ pé “àwọn tí wọn ò mọ̀ ju kí wọ́n máa gbafẹ́ nìkan ni ayẹyẹ Ọdún Tuntun wà fún,” ó fi kún un pé “ó tún jẹ́ ìjàkadì tí kò dáwọ́ dúró láàárín ẹ̀dá èèyàn àti ọtí líle.”
Òótọ́ ni pé kì í ṣe gbogbo èèyàn ló ń mutí yó bìnàkò tí wọ́n sì ń hùwà ipá lọ́jọ́ Ọdún Tuntun. Kódà, ṣìnkìn nínú àwọn kan máa ń dùn bí wọ́n bá rántí àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ náà. Fernando tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ níbẹ̀rẹ̀ sọ pé: “Ńṣe ló máa ń ṣe àwa ọmọdé bíi pé kí ọjọ́ Ọdún Tuntun ti dé. Oríṣiríṣi eré ìdárayá la máa ń ṣe, oúnjẹ àti ohun mímu á sì pọ̀ rẹpẹtẹ. Bó bá di déédéé aago méjìlá òru, àá gbára wa mú, àá fẹnu kora wa lẹ́nu, àá sì máa kí ara wa pé: ‘Ẹ Kú Àlàjá Ọdún O!’”
Bákan náà, ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ló rò pé àwọn kì í kúkú ti àṣejù bọ ayẹyẹ Ọdún Tuntun. Bó bá tiẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ wo ibi tí ayẹyẹ tó gbajúmọ̀ yìí ti ṣẹ̀ wá àti ìdí tí wọ́n fi ń ṣe é. Ǹjẹ́ ayẹyẹ Ọdún Tuntun ta ko ohun tí Bíbélì fi kọ́ni?
Àwọn Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ Láyé Àtijọ́
Ayẹyẹ Ọdún Tuntun kì í ṣe nǹkan tuntun. Àwọn àkọlé ìgbà láéláé fi hàn pé wọ́n ṣe é ní Bábílónì ní ẹgbẹ̀rúndún kẹta Ṣááju Sànmánì Tiwa. Wọn kì í fi ayẹyẹ yìí, tí wọ́n máa ń ṣe láàárín oṣù March ṣeré rárá. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World
Book Encyclopedia sọ pé: “Àkókò yẹn ni òrìṣà Mádọ́kì máa sọ bí nǹkan ṣe máa rí fún orílẹ̀-èdè náà nínú ọdún tí wọ́n fẹ́ bọ́ sí.” Ọjọ́ mọ́kànlá gbáko làwọn ará Bábílónì fi ń ṣayẹyẹ ọdún tuntun, wọ́n á rúbọ, wọ́n á wọ́de, wọ́n á sì ṣe àwọn ààtò ìbímọlémọ.Nígbà kan rí, oṣù March làwọn ará Róòmù náà máa ń bẹ̀rẹ̀ ọdún tiwọn. Àmọ́ lọ́dún 46 Ṣááju Sànmánì Tiwa, Olú Ọba Julius Caesar pàṣẹ pé ọjọ́ kìíní oṣù January ni kí wọ́n máa ṣe é. Janus, tí í ṣe ọlọ́run ìbẹ̀rẹ̀ ni wọ́n ń fi ọjọ́ yìí sìn tẹ́lẹ̀, ní báyìí, ó tún máa wá di ọjọ́ àkọ́kọ́ nínú ọdún àwọn ará Róòmù. Wọ́n yí ọjọ́ ayẹyẹ yìí padà, àmọ́ bí wọ́n ṣe ń ṣe pọ̀pọ̀ṣìnṣìn rẹ̀ kò yí padà. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, Cyclopedia ti McClintock àti Strong sọ pé ní ọjọ́ kìíní oṣù January, ńṣe làwọn èèyàn “máa ń kira bọ onírúurú ìwà ìpáǹle àti àṣà àwọn abọ̀rìṣà láìbojúwẹ̀yìn.”
Lọ́jọ́ tòní náà, wọ́n máa ń ṣe àwọn ààtò kan tó jẹ́ tàwọn abọ̀rìṣà nígbà ayẹyẹ Ọdún Tuntun. Bí àpẹẹrẹ, láwọn apá ibì kan ní Gúúsù Amẹ́ríkà, ọ̀pọ̀ máa ń fi ẹsẹ̀ wọn ọ̀tún nìkan tẹlẹ̀ tí wọ́n á ká èkejì rọ̀ tí Ọdún Tuntun bá ti dé. Àwọn mìíràn á máa fun fèrè tí wọ́n á sì máa yìnbọn ọdún. Gẹ́gẹ́ bí àṣà àwọn ará Czech, ọjọ́ Ọdún Tuntun ni àkókò tí wọ́n ń jẹ ọbẹ̀ tí wọ́n fi ẹ̀wà lẹ́ńtìlì sè, àṣà àwọn ará Slovak sì ni pé káwọn èèyàn máa fi owó tàbí ìpẹ́pẹ́ ẹja sábẹ́ aṣọ tí wọ́n tẹ́ sórí tábìlì. Àwọn ààtò wọ̀nyí, tí wọ́n láwọn ń fi lé ohun búburú lọ kí nǹkan sì tùbà kó tùṣẹ fún àwọn wulẹ̀ ń gbé ohun táwọn èèyàn ìgbà láéláé gbà gbọ́ lárugẹ ni pé ìbẹ̀rẹ̀ ọdún làwọ́n máa yan bí ayé àwọn ṣe máa rí.
Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Rẹ̀
Bíbélì gba àwọn Kristẹni níyànjú láti “máa rìn lọ́nà bíbójúmu, kì í ṣe nínú àwọn àríyá aláriwo àti mímu àmuyíràá.” a (Róòmù 13:12-14; Gálátíà 5:19-21; 1 Pétérù 4:3) Àwọn Kristẹni kì í lọ́wọ́ nínú àwọn ayẹyẹ Ọdún Tuntun nítorí àwọn àṣejù tí Bíbélì kà léèwọ̀ ló ń kúnnú rẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà. Èyí kò túmọ̀ sí pé àwọn Kristẹni kì í gbádùn ara wọn o. Bẹ́ẹ̀ kọ́, wọ́n mọ̀ pé léraléra ni Bíbélì sọ fáwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́ náà pé kí wọ́n gbádùn ara wọn, ó sì ní kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ fún àwọn ìdí kan. (Diutarónómì 26:10, 11; Sáàmù 32:11; Òwe 5:15-19; Oníwàásù 3:22; 11:9) Bíbélì tiẹ̀ tún sọ pé oúnjẹ àti ọtí máa ń mú èèyàn yọ̀.—Sáàmù 104:15; Oníwàásù 9:7a.
Gẹ́gẹ́ bá a ti rí i, inú àṣà àwọn kèfèrí ni ayẹyẹ Ọdún Tuntun ti jáde. Ohun tí kò mọ́ ni ìjọsìn èké jẹ́ lójú Jèhófà Ọlọ́run, ó sì kórìíra rẹ̀, àwọn Kristẹni kì í sì í lọ́wọ́ nínú àwọn nǹkan tó wá láti irú orísun bẹ́ẹ̀. (Diutarónómì 18:9-12; Ìsíkíẹ́lì 22:3, 4) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ ọ́ pé: “Àjọṣe wo ni òdodo àti ìwà àìlófin ní? Tàbí àjọpín wo ni ìmọ́lẹ̀ ní pẹ̀lú òkùnkùn? Síwájú sí i, ìbáramu wo ni ó wà láàárín Kristi àti Bélíálì?” Ìdí rèé tí Pọ́ọ̀lù ṣe fi kún un pé: “Ẹ jáwọ́ nínú fífọwọ́kan ohun àìmọ́.”—2 Kọ́ríńtì 6:14-17a.
Àwọn Kristẹni tún mọ̀ pé lílọ́wọ́ nínú àwọn ààtò tó jẹ mọ́ ìgbàgbọ́ nínú ohun asán kò lè fún èèyàn ní ayọ̀ tàbí aásìkí, pàápàá jù lọ níwọ̀n bó ti lè mú kí Ọlọ́run bínú sí èèyàn. (Oníwàásù 9:11; Aísáyà 65:11, 12) Síwájú sí i, Bíbélì sọ pé kí àwọn Kristẹni wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì kí wọ́n sì ní ìkóra-ẹni-níjàánu. (1 Tímótì 3:2, 11) Láìṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ, ó lòdì bí ẹni tó lóun ń tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ Kristi bá ń lọ́wọ́ nínú ayẹyẹ tó ní ìwà ìpáǹle nínú.
Bó ṣe wù kí ayẹyẹ Ọdún Tuntun máa fa èèyàn mọ́ra tàbí kó wu èèyàn ṣe tó, ohun tí Bíbélì sọ fún wa ni pé ká “jáwọ́ nínú fífọwọ́kan ohun àìmọ́” ká sì “wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí.” Ní ti àwọn tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà fún wọn ní ìdánilójú tó ń mọ́kàn yọ̀ náà pé: “Èmi yóò . . . gbà yín wọlé. Èmi yóò sì jẹ́ baba yín, ẹ ó sì jẹ́ ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin mi.” (2 Kọ́ríńtì 6:17b–7:1) Kódà, ó ṣèlérí ìbùkún àti aásìkí ayérayé fún àwọn tó bá dúró ṣinṣin.—Sáàmù 37:18, 28; Ìṣípayá 21:3, 4, 7.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ó ṣeé ṣe kí “àríyá aláriwo àti mímu àmuyíràá” tí Pọ́ọ̀lù mẹ́nu bà, jẹ́ irú èyí tó máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà ayẹyẹ Ọdún Tuntun, nítorí pé àwọn nǹkan wọ̀nyí wọ́pọ̀ gan-an ní Róòmù ní ọ̀rúndún kìíní.