Oúnjẹ Tí Kò Léwu Máa Wà fún Gbogbo Èèyàn
Oúnjẹ Tí Kò Léwu Máa Wà fún Gbogbo Èèyàn
JÍJẸ oúnjẹ tó ń ṣara lóore máa ń gbádùn mọ́ni. Àmọ́ bí a ti rí i, kì í fìgbà gbogbo rọrùn láti rí irú oúnjẹ bẹ́ẹ̀. Èyí tó tiẹ̀ tún wá burú jù ni pé, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn ló wà tó jẹ́ pé kì í ṣe ọ̀rọ̀ bóyá oúnjẹ wọn kò lè wu wọ́n léwu tàbí pé ó ṣara lóore lohun tó bá wọn. Wàhálà wọn kò ju bí wọ́n á ṣe rí ìwọ̀nba oúnjẹ tó máa so ẹ̀mí wọn ró lọ. Ṣé bí Ọlọ́run ṣe sọ pé kí nǹkan rí rèé?
Rò ó wò ná. Nígbà tí Ọlọ́run dá ọkùnrin àti obìnrin sáyé, ǹjẹ́ ohun kan tiẹ̀ wà tó lè mú kí wọ́n dààmú nípa oúnjẹ? Rárá o! Àkọsílẹ̀ tó wà nínú Bíbélì nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run mú kí olúkúlùkù igi tí ó fani mọ́ra ní wíwò, tí ó sì dára fún oúnjẹ hù láti inú ilẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:9) Nípa bẹ́ẹ̀, Ádámù àti Éfà ní oríṣiríṣi oúnjẹ tó gbádùn mọ́ni gan-an láti jẹ, wọ́n ní in lọ́pọ̀ yanturu débi pé kò lè tán. Ọlọ́run tó dá wọn mọ irú oúnjẹ náà gan-an tó máa ṣara wọn lóore; ó tún mọ ohun tó máa fún wọn láyọ̀. Lóòótọ́, a ò sí ní ọgbà Édẹ́nì lónìí. Àmọ́ ṣé Ọlọ́run ti wá yí ohun tó ní lọ́kàn níbẹ̀rẹ̀ fún ìran èèyàn àti ilẹ̀ ayé padà ni?
A ní ìdí tá a lè gbára lé láti gbà gbọ́ pé láìpẹ́, gbogbo ẹni tó bá wà lórí ilẹ̀ ayé ló máa gbádùn oúnjẹ tó dára tó sì ń ṣara lóore lọ́pọ̀ yanturu! Ìgbàgbọ́ yìí lè ṣèrànwọ́ fún wa gan-an láti ní èrò tó tọ́ lórí ọ̀ràn àwọn oúnjẹ tí kò lè ṣeni ní jàǹbá lóde òní. Tí ìrètí tá a ní yìí bá dúró sán-ún tá a sì gbára lé e, ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún níní èrò òdì tàbí dídi aláṣejù.
Kí ló jẹ́ kó dá wa lójú pé kò ní pẹ́ mọ́ tí ìgbésí ayé máa yí padà? Àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa mọ̀ pé lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, a ti ń gbé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ti ètò àwọn nǹkan yìí. Ọgbọ́n èèyàn ni wọ́n ń lò láti fi darí àwọn nǹkan lásìkò tá a wà yìí, èyí tí kò fúnni ní ìdánilójú kankan nínú gbogbo apá ìgbésí ayé tó sì jẹ́ pé orí èyí-jẹ́-èyí-kò-jẹ ni wọ́n gbé ohun gbogbo kà. Lórí ọ̀rọ̀ fífi ìmọ̀ ẹ̀rọ yí oúnjẹ padà yìí náà, kò sí ìdánilójú kankan pé bóyá ó léwu tàbí kò léwu. Ìbẹ̀rù, àìfìmọ̀-ṣọ̀kan àti ìpínyà ni irú àìsí ìdánilójú bẹ́ẹ̀ sì ń dá sílẹ̀.—2 Tímótì 3:1-5.
Ẹlẹ́dàá ìran èèyàn ti ṣèlérí pé òun á fi ètò àwọn nǹkan tuntun rọ́pò èyí tá a wà nínú rẹ̀ yìí. Ohun tó ní lọ́kàn tẹ́lẹ̀ pé kí gbogbo ayé jẹ́ ibi ẹlẹ́wà bí ọgbà Édẹ́nì, tí àwọn èèyàn aláyọ̀ tára wọ́n le á sì kúnnú rẹ̀ yóò di èyí tó ṣẹ. Agbára tí ń múni ṣọ̀kan, tí ọgbọ́n Ọlọ́run tí kò lábùkù á mú kó ṣeé ṣe yóò wá di èyí tó gba gbogbo ayé kan. (Aísáyà 11:9) Ọgbọ́n èèyàn tí kò dáni lójú kò ní rọ́wọ́ mú mọ́. Ètò tuntun látọwọ́ Ọlọ́run yóò mú gbogbo iyèméjì téèyàn lè máa ní kúrò nípa bóyá oúnjẹ wa lè ṣe wá ní jàǹbá tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Ǹjẹ́ kò bọ́gbọ́n mu láti gbà pé Ọlọ́run tó dá èèyàn tún mọ irú àwọn oúnjẹ tá a nílò fún ìlera wa?
Ẹlẹ́dàá Máa Pèsè Oúnjẹ Tí Kò Léwu
Bíbélì ní àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tá a lè fojú inú rí nípa bí ìgbésí ayé á ṣe rí lábẹ́ ètò àwọn nǹkan tó ń bọ̀. Wòlíì Aísáyà kọ̀wé pé: “Dájúdájú, [Ọlọ́run] yóò sì rọ òjò sí irúgbìn rẹ, èyí tí o fún sí ilẹ̀, àti gẹ́gẹ́ bí èso ilẹ̀, èyíinì ni oúnjẹ, tí yóò di sísanra àti olóròóró. Ní ọjọ́ yẹn, ohun ọ̀sìn rẹ yóò máa jẹko ní pápá ìjẹko aláyè gbígbòòrò. Àwọn màlúù àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó ti dàgbà tán, tí wọ́n ń ro ilẹ̀ yóò sì máa jẹ oúnjẹ ẹran tí a fi ewéko olómi-kíkan sí, èyí tí a fi ṣọ́bìrì àti àmúga fẹ́.”
Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà tún sọ pé: “Dájúdájú, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun yóò sì se àkànṣe àsè tí ó jẹ́ oúnjẹ tí a fi òróró dùn fún gbogbo àwọn ènìyàn ní òkè ńlá yìí, àkànṣe àsè wáìnì tí ń bẹ lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀, ti àwọn oúnjẹ tí a fi òróró dùn, èyí tí ó kún fún mùdùnmúdùn, ti wáìnì sísẹ́, èyí tí ń bẹ lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀.”—Aísáyà 25:6; 30:23, 24.
Ṣé ìyẹn dùn mọ́ ọ láti gbọ́? Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà mú un dá wa lójú pé gbogbo àwọn tó ń gbé lábẹ́ ètò tuntun Ọlọ́run ní yóò ní oúnjẹ tara ní ànító tí wọ́n á sì jẹ àjẹṣẹ́kù. Ṣé oúnjẹ náà kò ní ṣe ìpalára fún èèyàn? Ìyẹn dájú ṣáká. Àsọtẹ́lẹ̀ mìíràn mú un dá wa lójú pé àwọn èèyàn Ọlọ́run ‘yóò jókòó ní ti tòótọ́, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kì yóò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì.’ (Míkà 4:4) Ìjọba Ọlọ́run nípasẹ̀ Mèsáyà náà, èyí tí yóò bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lórí ayé láìpẹ́ yóò rí sí i pé irú ààbò tí kò kù síbì kan bẹ́ẹ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀.—Aísáyà 9:6, 7.
Kò tún ní í sí iyèméjì kankan mọ́ nípa bóyá oúnjẹ kan lè ṣèèyàn ní jàǹbá tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, pẹ̀lú ìdùnnú la ó fi máa sọ fún ara wa pé: “Á gbabiire o.”
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 22]
Láìpẹ́, gbogbo ẹni tó wà lórí ilẹ̀ ayé á gbádùn oúnjẹ tó dára tó sì ń ṣara lóore lọ́pọ̀ yanturu
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Ọlọ́run ṣèlérí pé oúnjẹ tí kò ní ṣèèyàn ní jàǹbá yóò wà fún gbogbo èèyàn, yóò sì pọ̀ yanturu