Wíwo Ayé
Wíwo Ayé
Owó Rírùn
Ìwé ìròyìn The Globe and Mail ilẹ̀ Kánádà sọ pé: “Àìmọye kòkòrò àrùn ló wà lára àwọn owó bébà.” Ìwádìí tí wọ́n ṣe láìpẹ́ yìí ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà fi hàn pé, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo owó bébà táwọn èèyàn ń ná ló ní àwọn kòkòrò bíi streptococcus, enterobacter, pseudomonas àtàwọn kòkòrò mìíràn lára. Ìwé ìròyìn náà sọ pé, àwọn kòkòrò yìí “lè ṣe àkóbá ńláǹlà fún àwọn èèyàn tí ara wọn kò lè fi bẹ́ẹ̀ gbógun ti àrùn, irú bí àwọn àgbàlagbà tí ara wọn kò le tàbí àwọn èèyàn tó ti ní àrùn Éèdì.” Àwọn owó bébà kan tiẹ̀ tún ní àwọn kòkòrò tó burú jùyẹn lọ lára. Àwọn olùwádìí dámọ̀ràn pé bóyá ni kò ti tó àkókò báyìí téèyàn á dìídì máa “fi ọwọ́ fọ owó.” Ní orílẹ̀-èdè Japan, ó ti ṣeé ṣe fún àwọn òǹrajà láti máa gba owó látinú “ẹ̀rọ ATM asowódọ̀tun,” tó ń fi ooru gbígbóná pa púpọ̀ lára àwọn kòkòrò àrùn tó wà lára owó láìsí pé ó ń sun ún jóná.” Ìwé ìròyìn The Globe kìlọ̀ pé, tó o bá ti di owó mú, “rí i pé o fọ ọwọ́ rẹ!”
Àpọ̀jù Iyọ̀ Lójú Títì Léwu
Ìwé ìròyìn Terre sauvage sọ pé ní gbogbo ìgbà òtútù, nǹkan bí ogún ọ̀kẹ́ [400,000] sí nǹkan bí i mílíọ̀nù kan ààbọ̀ tọ́ọ̀nù iyọ̀ ni wọ́n máa ń dà sí àwọn ojú títì ilẹ̀ Faransé kó lè fa ìrì dídì àti omi dídì tó wà lórí àwọn ọ̀nà náà mu. “Iyọ̀ rẹpẹtẹ yìí ní àkóbá tó ń ṣe fún àyíká o, wọ́n sì ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ṣàwárí rẹ̀ díẹ̀díẹ̀ ni.” Ńṣe làwọn iyọ̀ ojú ọ̀nà yìí máa ń ṣẹ́ jọ sínú iyẹ̀pẹ̀ wọ́n sì lè ba omi kànga táwọn èèyàn ń mu jẹ́, títí kan omi tó dára tó wà lábẹ́ ilẹ̀, adágún, àtàwọn omi kéékèèké. Ó máa ń pa àwọn nǹkan ọ̀gbìn tí wọ́n ò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sójú títì ó sì máa ń ba eteetí gbòǹgbò igi jẹ́. Tí gbòǹgbò igi bá ti fà á mu, kì í jẹ́ kí igi lè gba agbára látinú oòrùn mọ́, èyí tó nílò fún ìlànà photosynthesis. Tí èyí bá ń bá a lọ, á sọ igi di aláìlágbára, igi náà á sì kú. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mọ́tò máa ń gbá àwọn ẹran tó bá wá sí títì láti lá iyọ̀ tàbí kí wọ́n kú nítorí pé wọ́n fí ìkánjú kó iyọ̀ náà jẹ tí wọ́n sì jẹ ẹ́ lájẹjù. Nígbà míì, iyọ̀ tún máa ń mú kí àwọn egunrín yìnyín tó léwu tójú ò lè tètè rí gbára jọ sójú pópó. Àwọn awakọ̀ máa ń ṣọ́ra tí wọ́n bá ń wa mọ́tò lórí títì tí ìrì dídì ti bò bámúbámú, àmọ́ ọ̀pọ̀ ni kì í kíyè sára, wọn ò sì ní í mọ̀ pé egunrín yìnyín yẹn lè ti gbára jọ. Àwọn ògbógi ṣèkìlọ̀ pé: “Ẹ ṣọ́ bẹ́ ẹ ṣe ń da iyọ̀ sójú pópó, ẹ má sì jẹ́ kó pọ̀ jù.”
Igbe Àwọn Òwìwí Jẹ́ Àmì Pé Ara Wọ́n Le
Ìwé ìròyìn The Economist sọ pé, nígbà táwọn òwìwí aláwọ̀ ilẹ̀ rẹ́súrẹ́sú bá ń kígbe, ńṣe ni wọ́n ń fi bí ara wọ́n ṣe le sí hàn. “Stephen Redpath àtàwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n wà ní Ibùdó fún Ẹ̀kọ́ Nípa Ohun Alààyè àti Àyíká Wọn àti Ẹ̀kọ́ Nípa Omi ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì fi àwọn òwìwí aláwọ̀ ilẹ̀ rẹ́súrẹ́sú méjìlélógún ṣèwádìí nínú Igbó Kielder tó wà ní àríwá ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.” Àwọn olùwádìí náà “gbé ohun àwọn ẹyẹ òwìwí tí wọ́n jẹ́ akọ àti abo tí wọ́n ti gbà sílẹ̀ sáfẹ́fẹ́ fún àwọn ẹyẹ tí wọ́n ń lò fún àyẹ̀wò, wọ́n sì wo iye àsìkò tó gbà wọ́n láti dáhùn padà sí ohùn náà.” Ó gba àwọn òwìwí tó ń ṣàìsàn lákòókò díẹ̀ kí wọ́n tó lè kígbe padà, ó sì gba àwọn tó ń ṣàìsàn gan-an ní ìlọ́po méjì àkókò tó gba àwọn òwìwí tí kò ṣàìsàn rárá. Bákan náà, nígbà táwọn òwìwí tó ń ṣàìsàn yìí bá kígbe, igbe wọn kì í lọ sókè bí i tàwọn tára wọ́n le. Ìwé ìròyìn The Economist wá sọ pé: “Ó dájú pé, àmì pé òpin ti ń dé lèyí jẹ́ fún àwọn òwìwí ọ̀hún.”
Èrè Kíkàwé fún Ọmọ
Ìwé ìròyìn ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ilẹ̀ Poland náà Przyjaciółka, sọ pé: “Táwọn [ọmọdé] bá rí i tí màmá àti bàbá wọn ń fi tinútinú kàwé, àwọn náà máa ń gbìyànjú láti fara wé wọn.” Àpilẹ̀kọ náà sọ pé láyé táwọn ọmọ kò mọ̀ ju wíwo tẹlifíṣọ̀n lọ yìí, kíkàwé fún wọn jẹ́ ohun tó bójú mu gan-an, kódà fún àwọn ọmọ tí kò tíì ju ọdún méjì lọ pàápàá, ká máa fi àwòrán hàn wọ́n ká sì máa ṣàlàyé rẹ̀ fún wọn. Àwọn òbí lè béèrè ìbéèrè nípa ohun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kà fún ọmọ kan lọ́wọ́ rẹ̀ kí wọ́n lè mọ̀ bóyá ohun náà yé e. “Bí ó bá sì ṣàdédé sú ọmọ náà . . . , gbìyànjú láti jẹ́ kó gbádùn mọ́ ọn nípa fífi ara ṣàpèjúwe ohun tí ò ń kà kó o sì máa yí ìró ohùn rẹ padà.” Wọ́n rọ àwọn òbí láti mọ ohun tó máa ń gbádùn mọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n sì máa bá wọn sọ̀rọ̀ nípa nǹkan náà. Przyjaciółka sọ pé: “Máa sọ fún wọn nípa àwọn ìwé tó o fẹ́ràn gan-an nígbà tó o wà lọ́mọdé, sì dárúkọ díẹ̀ lára àwọn àkòrí gbígbádùnmọ́ni tó wà nínú wọn. . . . Má ṣe dáwọ́ kíkàwé fún àwọn ọmọ rẹ dúró o, àní nígbà tí wọ́n bá ti mọ̀wé é kà fúnra wọn pàápàá. Nígbà míì, tó o bá ti ka àwọn ojú ìwé àkọ́kọ́ láti lè fún wọn níṣìírí, ó ti tó, pẹ̀lú ìdùnnú lọmọ náà á fi máa ka ìyókù lọ.”
Àwọn Tí Wọn Kì í Madùn Oúnjẹ Lẹ́nu
Gẹ́gẹ́ bí Hiroshi Tomita, ògbóǹkangí nínú ìtọ́jú etí, imú, àti ọ̀fun ti sọ, lọ́dọọdún, ní Japan, ó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogóje [140,000] èèyàn tí kì í madùn oúnjẹ lẹ́nu, títí kan àwọn ọmọdé tí iye wọn túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Ìwé ìròyìn The Daily Yomiuri sọ pé, bó tilẹ̀ jẹ́ oògùn tàbí àìlera ara lè fa àìsàn yìí, ohun tó dá Tomita lójú ni pé, nǹkan bí ìdá ọgbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí àìsàn náà ń ṣe ló
jẹ́ pé àìsí èròjà zinc tó nínú ara wọn ló fà á. Àpilẹ̀kọ náà sọ pé, “èròjà zinc yìí máa ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti pèsè àwọn èròjà tín-tìn-tín tuntun tó máa ń mú oúnjẹ dùn lórí ahọ́n, àmọ́ tí kò bá tó lára, díẹ̀díẹ̀ lẹnu èèyàn á bẹ̀rẹ̀ sí kú tàìtai.” Àwọn oúnjẹ tí kò ṣara lóore, oúnjẹ tí wọ́n ti yí padà, àti jíjẹ oríṣi oúnjẹ kan náà nígbà gbogbo lè dá kún ìṣòro ọ̀hún. Àpilẹ̀kọ náà ṣàlàyé pé “ńṣe làwọn nǹkan amóúnjẹ-dùn, irú bíi phosphate, tó máa ń wà nínú ọ̀pọ̀ oúnjẹ tí wọ́n ti ṣe sílẹ̀ máa ń dín èròjà zinc kù nínú ara kò sì tún ń jẹ́ kí ara lè gbà á dúró.” Tomita dámọ̀ràn pé kí àwọn tí oúnjẹ kì í dùn lẹ́nu wọn máa jẹ àwọn oúnjẹ tó ní èròjà zinc dáadáa. Àwọn nǹkan bí ìṣọ́n, ẹja wẹ́wẹ́ àti ẹ̀dọ̀ ẹran wà lára wọn. Tomita sọ pé jíjẹ oúnjẹ aṣaralóore lóríṣiríṣi lè mú kí ẹnu èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í madùn oúnjẹ, àmọ́ tí ọ̀rọ̀ náà bá burú gan-an, tí wọn ò sì wá ìtọ́jú sí i láàárín oṣù mẹ́fà, kò fi bẹ́ẹ̀ dájú pé àtúnṣe á wà.Mọ́ṣáláṣí Ń Pọ̀ Sí I Gan-an ní Ilẹ̀ Amẹ́ríkà
Ìwé ìròyìn The New York Times sọ pé: “Mọ́ṣáláṣí tó wà ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ti lé ní ẹgbẹ̀fà, ìyẹn sì jẹ́ ìdá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún láàárín ọdún mẹ́fà,” èyí tó fi hàn pé àwọn Mùsùlùmí ń pọ̀ sí i níbẹ̀. John Esposito, tó jẹ́ olùdarí Ibùdó fún Ìgbọ́ra-Ẹni-Yé Láàárín Mùsùlùmí àti Kristẹni ní Yunifásítì ìlú Georgetown gbà pé àwọn Mùsùlùmí tó wà níbẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ á tó “nǹkan bí i mílíọ̀nù mẹ́rin sí mẹ́fà.” Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan tí ẹgbẹ́ Ìsìláàmù mẹ́rin ní Amẹ́ríkà ṣe, iye yẹn tiẹ̀ lè jù bẹ́ẹ̀ lọ. Esposito sọ pé, ohun yòówù tó lè jẹ́, “bí àwọn Mùsùlùmí ṣe ń ṣí wá àti bí ọ̀pọ̀ nínú wọn ṣe máa ń bímọ púpọ̀” á mú kí iye wọn máa pọ̀ sí i. “Ká tó rí ẹ̀wádún díẹ̀ sí i, Ìsìláàmù á di ẹ̀sìn tó tóbi ṣìkejì ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà.” Ìwé ìròyìn Times sọ pé, “àwọn ọkùnrin lò máa ń pọ̀ jù” nínú àwọn tó máa ń wá sí mọ́ṣáláṣí. Ìwádìí ọ̀hún tún fi hàn pé “oríṣiríṣi ẹ̀yà làwọn tó ń wá jọ́sìn: ìdá kan nínú mẹ́ta wọn jẹ́ ará Gúúsù Éṣíà, ìdá ọgbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún jẹ́ àwọn aláwọ̀ dúdú ará Amẹ́ríkà tí ìdá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún sì jẹ́ Áráàbù.”
Àwọn Ilé Tó Ń Fi Àìsàn Ṣeni
Ìwé ìròyìn New Scientist sọ pé: “Àwọn ilé tí kò tíì pé ọdún kan tí wọ́n kọ́ wọn ní ìlú Melbourne ní orílẹ̀-èdè [Ọsirélíà] máa ń ní àwọn kẹ́míkà tí òórùn wọn fi ìlọ́po ogún ju ohun tí Àjọ Tó Ń Bójú Tó Ìlera àti Ìwádìí Ìṣègùn Ti Ìjọba dámọ̀ràn pé ó bójú mu fún ìlera lọ.” Wọ́n ń pe ọ̀kan nínú àwọn kẹ́míkà yìí ní formaldehyde, “èyí tó máa ń fa ara yíyún tó sì tún lè fa àrùn jẹjẹrẹ.” Ìròyìn náà sọ pé, formaldehyde máa ń tú sínú afẹ́fẹ́ láti ara àwọn nǹkan ìkọ́lé bí i pátákó tí wọ́n tẹ́ sílẹ̀ àtàwọn ìjókòó. Àwọn kápẹ́ẹ̀tì tuntun máa tú èròjà styrene jáde, èyí tí wọ́n fura sí pé òun náà ń fa àrùn jẹjẹrẹ, “nígbà tí ọ̀dà àtàwọn èròjà tí ń mú nǹkan yòrò sì máa ń tú oríṣiríṣi àwọn nǹkan olóró mìíràn sáfẹ́fẹ́. Àwọn kẹ́míkà náà kò fi bẹ́ẹ̀ léwu fún ìlera ọ̀pọ̀ èèyàn. Àmọ́ wọ́n lè fa ẹ̀fọ́rí kí wọ́n sì ṣe ìpalára tó burú jáì fún àwọn èèyàn tára wọn kò bá bá a mu.”
Ọ̀gá Nínú Àwọn Tó Ń Pèsè Mílíìkì Lágbàáyé
Ilẹ̀ Íńdíà ló ń mú ipò iwájú báyìí nínú àwọn tó ń pèsè mílíìkì lágbàáyé ni ohun tí ìwé ìròyìn The Hindustan Times sọ. Ìròyìn náà sọ pé: “Ẹ̀ka Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Àgbáyé tó ní í ṣe pẹ̀lú àyíká [ní ìlú Washington, D.C.] ti gbóríyìn fún àyípadà tó wáyé nínú ìpèsè mílíìkì ní Íńdíà. Láti ọdún 1994 ni mílíìkì ti gborí nínú iṣẹ́ àgbẹ̀ àwọn ara Íńdíà, nígbà tó sì di 1997, orílẹ̀-èdè náà gbapò mọ́ ilẹ̀ Amẹ́ríkà lọ́wọ́ tó sì di ọ̀gá pátápátá nínú àwọn tó ń pèsè mílíìkì lágbàáyé.” Wọ́n fa ọ̀rọ̀ Lester Brown, alága Ẹ̀ka Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Àgbáyé náà yọ pé: “Ohun tó jọni lójú ni pé, àwọn ohun tí wọn ò lò mọ́ lóko àtàwọn ohun tó ṣẹ́ kù lẹ́yìn tí wọ́n bá ti kórè tán ni wọ́n ń fi bọ́ àwọn ẹran náà dípò kí wọ́n máa fún wọn ní ọkà jẹ. Ilẹ̀ Íńdíà ti mú kí èròjà protein tó ń pèsè pọ̀ sí i láìsí pé ó ń fi ọkà tí èèyàn ń jẹ bọ́ màlúù.”
Owó Níná Dìrọ̀rùn
Ìwé ìròyìn Calgary Herald sọ pé ìmọ̀ ẹ̀rọ tó túbọ̀ ń ga sí i ti mú kí èèyàn le ra ọjà ní gbogbo wákàtí mẹ́rìnlélógún tó wà nínú ọjọ́ kan, àti ní gbogbo ọjọ́ méje tó wà nínú ọ̀sẹ̀, ó sì ti di ohun tí ọ̀pọ̀ àwọn ará Kánádà fi ń najú báyìí. “Àwọn tó ń rajà lè máa rajà nìṣó lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì láìdáwọ́dúró, wọ́n sì lè kọ̀wé béèrè fún àwọn nǹkan tí wọ́n fẹ́ tàbí kí wọ́n fi káàdì ìrajà àwìn wọn rajà lójú ẹsẹ̀ bí wọ́n ti ń wo oríṣiríṣi ọjà lórí tẹlifíṣọ̀n.” Àwọn káàdì tó fàyè gba jíjẹ gbèsè rẹpẹtẹ ń fún àwọn èèyàn níṣìírí láti rajà ju bó ṣe yẹ lọ. Àwọn káàdì ìrajà àwìn kan sì ní àwọn àǹfààní kan tó máa ń mú kí ọjà àwìn túbọ̀ wu àwọn èèyàn láti rà. Larry Wood, tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ọ̀ràn ìnáwó ní Yunifásítì Calgary sọ pé: “Àwọn èèyàn á ní owó tí wọ́n lè fi rajà lọ́wọ́ o, àmọ́ wọ́n á ní kí wọ́n ṣírò rẹ̀ sínú káàdì ìrajà àwìn àwọn kí wọ́n lè rí àwọn àǹfààní náà gbà, pẹ̀lú èrò pé, tí oṣù bá parí àwọn á fi owó náà san gbèsè ọ̀hún. Ni wọ́n á bá ná gbogbo owó tán, gbèsè á sì wà nílẹ̀ láti san.” Àmọ́ ọ̀gbẹ́ni Wood sọ pé ìṣòro ọ̀hún kò tíì tán o. Bí àwọn òǹrajà ti ń gbìyànjú láti ní gbogbo ohun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde, wọn ò kọ̀ láti wọko gbèsè dípò kí wọ́n dín ohun tí wọ́n ń rà kù. Níbàámu pẹ̀lú Ìṣirò kan tí wọ́n ṣe ní Kánádà ní 1999, àròpọ̀ gbèsè tí káàdì ìrajà àwìn kó àwọn ará Kánádà sí ti lé ní bílíọ̀nù mẹ́rìnlá dọ́là.