Àwọn Èèyàn Tó Ń Wá Ibi Ààbò Kiri
Àwọn Èèyàn Tó Ń Wá Ibi Ààbò Kiri
“Ọ̀rúndún ogún wá sópin àmọ́ ìtàjẹ̀sílẹ̀ àti inúnibíni tó ń mú kí àwọn èèyàn sá àsálà fún ẹ̀mí wọn kò wá sópin. Inú àgọ́ àwọn olùwá-ibi-ìsádi àtàwọn ibi téèyàn lè forí pa mọ́ sí ni ẹgbàágbèje èèyàn ti bẹ̀rẹ̀ ẹgbẹ̀rúndún tuntun tiwọn, tẹ́rù ń bà wọ́n pé pípa ni wọ́n máa pa àwọn táwọn bá gbìyànjú láti padà sílé pẹ́nrẹ́n.”—Bill Frelick, Ìgbìmọ̀ Tó Wà fún Àwọn Olùwá-Ibi-Ìsádi ní Ilẹ̀ Amẹ́ríkà.
OHUN kan wà lọ́kàn Jacob tó ń wù ú gan-an. Ó ń fẹ́ ibì kan táwọn èèyàn á ti lè máa gbé ní àlááfíà, tí bọ́ǹbù ò ti ní máa pa àwọn ewúrẹ́ tí ìdílé rẹ̀ ń sìn àti ibi tá á ti lè máa lọ síléèwé.
Àwọn aráàlú rẹ̀ sọ fún un pé irú àgbègbè bẹ́ẹ̀ wà lóòótọ́, àmọ́ ibẹ̀ jìnnà gan-an. Bàbá rẹ̀ sọ fún un pé ìrìn àjò yẹn ti léwu jù, nítorí pé àwọn kan ti kú sọ́nà nítorí àìsí omi àti oúnjẹ. Àmọ́ nígbà tí aládùúgbò wọn kan tí wọ́n ti pa ọkọ rẹ̀ bọ́ sọ́nà pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ méjì, Jacob pinnu pé òun á dá rìnrìn àjò náà láìsí ìdílé òun.
Jacob kò mú oúnjẹ dání bẹ́ẹ̀ ni kò mú aṣọ lọ́wọ́, eré ló sì ń sá lọ rangbandan lọ́jọ́ àkọ́kọ́. Ńṣe ni òkú àwọn èèyàn wà káàkiri lójú ọ̀nà tó lọ síbi ààbò náà. Lọ́jọ́ kejì, ó rí obìnrin kan tó jẹ́ aráàlú rẹ̀, ìyẹn sì sọ fún un pé ó lè máa bá òun àtàwọn tó wà pẹ̀lú òun rìn lọ. Wọ́n rìn rìn rìn fún ọ̀pọ̀ ọjọ́, wọ́n sì ń kọjá lára àwọn abúlé tí kò léèyàn nínú mọ́. Nígbà kan, wọ́n ní láti kọjá níbi tí wọ́n ri àwọn nǹkan abúgbàù sí, ọ̀kan lára wọn sì kú síbẹ̀. Ewé ni wọ́n ń jẹ.
Ọjọ́ mẹ́wàá lẹ́yìn ìgbà yẹn, àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ síí kú nítorí ebi àti àárẹ̀. Kò pẹ́ sígbà yẹn làwọn ọkọ̀ òfuurufú bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀jò ọta lé wọn lórí. Níkẹyìn, Jacob kọjá ní ààlà ẹnubodè wọn ó sì dé ibi àgọ́ àwọn olùwá-ibi-ìsádi kan. Ó ti ń lọ síléèwé báyìí, ìró ọkọ̀ òfuurufú kò sì kó jìnnìjìnnì bá a mọ́. Oúnjẹ ni gbogbo ọkọ̀ òfuurufú tó ń rí báyìí ń kó, kì í ṣe bọ́ǹbù. Àmọ́ àárò ìdílé rẹ̀ ń sọ ọ́ gan-an ni ó sì ń wù ú láti padà sílé.
Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn èèyàn bíi ti Jacob ló wà káàkiri ayé. Jìnnìjìnnì ogun ti dá àìsàn sí ọ̀pọ̀ lára tí ebi àti òùngbẹ sì ń fojú wọn rí màbo. Ìwọ̀nba díẹ̀ péré nínú wọn ló tọ́ adùn inú ìdílé wò rí, ọ̀pọ̀ ò sì ní padà sílé wọn mọ́ láé. Kò sẹ́ni tó kúṣẹ̀ẹ́ tó wọn láyé yìí.
Ọ̀nà méjì ni Kọmíṣọ́nnà Àgbà fún Àwọn Olùwá-Ibi-Ìsádi ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè pín àwọn alárìnkinrin tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ yìí sí. Olùwá-ibi-ìsádi ni ẹni kan tó sá kúrò ní orílẹ̀-èdè rẹ̀ nítorí ìbẹ̀rù inúnibíni tàbí ìwà ipá tó hàn sí gbogbo èèyàn. Ẹni tó sá fi ìlú sílẹ̀ sì ni ẹni tó di ọ̀ràn-an-yàn fún láti fí ilé rẹ̀ sílẹ̀ nítorí ogun tàbí ewu ńláǹlà mìíràn àmọ́ tó jẹ́ pé inú orílẹ̀-èdè rẹ̀ níbẹ̀ ló ṣì ń gbé. a
Kò sẹ́ni tó mọye àwọn olùwá-ibi-ìsádi àtàwọn tí wọ́n sá kúrò nílùú tí wọ́n ń gbìyànjú àtirí nǹkan jẹ nínú àwọn àgọ́ onígbà kúkúrú, tàbí iye àwọn tó ń lọ láti ibì kan sí ibòmíràn láìsí ìrànwọ́, tí wọ́n ń wá ààbò kiri. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ìsọfúnni kan ti fi hàn, àròpọ̀ gbogbo àwọn olùwá-ibi-ìsádi tó wà láyé á máa lọ sí ogójì mílíọ̀nù, ìdajì wọn ló sì jẹ́ àwọn ọmọ kéékèèké. Ibo ni gbogbo wọ́n ti wá?
Ìṣòro Tó Ń Bá Àkókò Wa Fínra
Lẹ́yìn ogun àgbáyé kìíní, ọwọ́ tuntun ni ìṣòro wíwá ibi ìsádi tún yọ. Kété tí ogun yẹn parí, àwọn ilẹ̀ ọba pín sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣenúnibíni sáwọn ẹ̀yà tó bá kéré. Ìyẹn mú kí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ará Yúróòpù wá ààbò lọ sáwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. Ogun Àgbáyé Kejì, èyí tó burú ju tàkọ́kọ́ lọ tún mú kí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn èèyàn mìíràn sá kúrò nílé wọn. Láti ọdún 1945 wá, ogun abẹ́lé ló wá ń jà jù, àmọ́ kò sí ìyàtọ̀ kankan nínú ràbọ̀ràbọ̀ tó ń dá sára àwọn ará ìlú tí wàhálà náà kàn.
Nínú ìwé tí Gil Loescher ṣe lọ́dún 1993, èyí tó pè ní Beyond Charity—International Cooperation and the Global Refugee Crisis, ó sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ pẹ́ tí ogun ti ń fa káwọn èèyàn máa wá ibi sá lọ, ọ̀rúndún ogún yìí lọ̀rọ̀ wá di pé tí orílẹ̀-èdè méjì bá ń bára wọn jà, gbogbo àwọn èèyàn tó wà nínú wọn pátá ló máa fara kááṣá rẹ̀. Bí wọn ò ṣe fì ogun náà mọ sáàárín àwọn tó ń jà nìkan ti yọrí sí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn olùwá-ibi-ìsádi, tí wọ́n ń wá bí wọ́n á ṣe sá àsálà fún ẹ̀mí wọn ní gbogbo ọ̀nà láti lè bọ́ lọ́wọ́ òfò tí ìwà ipá tí kò mojú ẹnì kan ń fà yìí.”
Yàtọ̀ síyẹn, ogun abẹ́lé ló wọ́pọ̀ jù lọ́jọ́ òní, èyí tó jẹ́ pé bó ṣe ń gbẹ̀mí àwọn ọkùnrin tó ti tóó jagun náà ló tún máa ń pa àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé nípakúpa. Bí ìyapa ẹ̀yà ìran àti ti ìsìn tó ti ta gbòǹgbò lọ́kàn àwọn èèyàn ṣe túbọ̀ ń bu epo síná àwọn wàhálà yìí, àfàìmọ̀ ni ò fi ní í yọrí sógun jíjà. Ní orílẹ̀-èdè kan ní Áfíríkà, tí irú ogun abẹ́lé yìí ti ń jà láìdáwọ́dúró fún ọdún méjìdínlógún, mílíọ̀nù mẹ́rin èèyàn ló ṣí lọ sápá ibòmíràn ní orílẹ̀-èdè yẹn tí ẹgbàágbèje sì sá lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn.
Lọ́pọ̀ ìgbà, ọ̀nà kan ṣoṣo tí àwọn aráàlú tí ayé ti sú nítorí ogun fi lè bọ́ lọ́wọ́ ìwà ipá náà ni pé kí wọ́n filé sílẹ̀. Ìwé The State of the World’s Refugees 1997-98 sọ pé: “Àwọn olùwá-ibi-ìsádi máa ń fi ìlú ìbílẹ̀ wọn sílẹ̀ wọ́n á sì máa wá ọ̀nà láti wọ orílẹ̀-èdè míì, kì í ṣe pé ó wù wọ́n bẹ́ẹ̀ tàbí pé ìgbádùn ni wọ́n wá lọ,
àmọ́ nítorí pé ó di dandan.” Àmọ́ lọ́jọ́ tòní, rírí ọ̀nà wọ orílẹ̀-èdè mìíràn lè má fi bẹ́ẹ̀ rọrùn.Láàárín àwọn ọdún 1990, àròpọ̀ gbogbo àwọn olùwá-ibi-ìsádi jákèjádò ayé wá sílẹ̀ láti orí nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́tàdínlógún sí mílíọ̀nù mẹ́rìnlá. Àmọ́ ṣá o, iye tó dún bíi pé nǹkan dára sí i yìí lè ṣi èèyàn lọ́nà. Láàárín ẹ̀wádún yìí kan náà, iye àwọn tí wọ́n fojú bù pé wọ́n ń ṣí kiri láàárín orílẹ̀-èdè wọn wọ mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n sí ọgbọ̀n mílíọ̀nù gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n fojú bù. Kí ló ń ṣẹlẹ̀ gan-an?
Nítorí àwọn ìdí mélòó kan, ó ti túbọ̀ ṣòro gan-an kí ẹni kan tóó lè di ẹni tí ìjọba kà sí olùwá-ibi-ìsádi. Àwọn orílẹ̀-èdè lè máà fẹ́ gba àwọn olùwá-ibi-ìsádi mọ́ra, bóyá nítorí pé apá wọn kò ká bíbójú tó àwọn èèyàn tó pọ̀ bí eṣú bẹ́ẹ̀ ni o tàbí nítorí pé ẹ̀rù ń bà wọ́n pé wàhálà ni wọ́n máa kó bá ọ̀rọ̀ ajé àti ipò òṣèlú àwọn. Nígbà míì kẹ̀, àwọn èèyàn tí ìbẹ̀rùbojo ti mú náà kì í tiẹ̀ ní okun nínú tó, wọn kì í sì í ní oúnjẹ tàbí owó láti rìnrìn àjò ọ̀nà jíjìn náà dé ẹnubodè. Kìkì ohun tí wọ́n lè ṣe kò ju pé kí wọ́n ṣí lọ sí ibi tó bá tún bọ́ lọ́wọ́ ewu díẹ̀ nínú orílẹ̀-èdè tiwọn.
Àwọn Tó Ń Ṣí Kúrò Nílùú Nítorí Ìṣòro Ìṣúnná Owó Túbọ̀ Ń Pọ̀ Sí I
Yàtọ̀ sí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn tó jẹ́ ojúlówó olùwá-ibi-ìsádi, ẹgbàágbèje àwọn mìíràn tún wà tí wọ́n ń wá bí ìgbésí ayé àwọn á ṣe túbọ̀ gbé pẹ́ẹ́lí sí i nípa lílo ọ̀nà kan ṣoṣo tí wọ́n mọ̀, ìyẹn ni ṣíṣí lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù díẹ̀.
Ní February 17, 2001, ọkọ̀ ojú omi kan tó ti di hẹ́gẹhẹ̀gẹ rì létí òkun ilẹ̀ Faransé. Àwọn èèyàn tó wà nínú rẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún, àwọn ọkùnrin, obìnrin àtàwọn ọmọdé tó jẹ́ pé ó ti ń lọ sí bí ọ̀sẹ̀ kan tí wọ́n ti wà lágbami okùn láìjẹ oúnjẹ kankan. Ẹgbẹ̀rún méjì dọ́là lẹnì kọ̀ọ̀kan wọn san fún ìrìn-àjò fẹ̀mí-wewu yìí láìmọ orílẹ̀-èdè wo gan-an ni wọ́n ń lọ. Bí wọ́n ṣe gúnlẹ̀ sí èbúté kan báyìí, ńṣe ni ọ̀gákọ̀ àtàwọn òṣìṣẹ́ ọkọ̀ náà pòórá. Àmọ́, wọ́n bá ire pàdé, àwọn èrò ọkọ̀ tí jìnnìjìnnì ti mú náà rí ẹni wá kó wọn, ìjọba ilẹ̀ Faransé sì ṣèlérí láti gba ẹ̀bẹ̀ wọn rò láti máa gbé níbẹ̀. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ irú wọn ló wà lọ́dọọdún, tí wọ́n máa ń gbìyànjú láti rin irú ìrìn-àjò yẹn.
Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó ń wọ̀lú onílùú nítorí ìṣòro ọrọ̀ ajé ni kì í bìkítà nípa ìṣòro lílekoko tí wọ́n máa kojú àtohun tó lè ṣẹlẹ̀ sí wọn. Wọ́n á ṣáà wá ọ̀nàkọnà láti re owó jọ fún ìrìn àjò náà, nítorí pé nílùú wọn, ipò òṣì, ìwà ipá, kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, tàbí àwọn ìjọba amúnisìn, tàbí kẹ̀, àpapọ̀ gbogbo ìṣòro yìí máa ń mú kó dà bí ẹni pé ìrètí kò sí ní ìgbésí ayé.
Àwọn tó ń ṣègbé níbi tí wọ́n ti ń wá ìgbésí ayé tó sàn kiri kì í ṣe kékeré. Láàárín ẹ̀wádún tó kọjá, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àtààbọ̀ àwọn èèyàn tó fẹ́ wọ orílẹ̀-èdè míì ló rì sómi, tí àwọn kan sì pòórá níbi tí wọ́n ti ń gbìyànjú láti kọjá lórí omi Gibraltar, lágbedeméjì ilẹ̀ Áfíríkà àti Sípéènì. Lọ́dún 2000, ọmọ ilẹ̀ China méjìdínlọ́gọ́ta ni ooru mú pa sẹ́yìn ọkọ̀ akẹ́rù tí wọ́n sá pa mọ́ sí, èyí tó gbé wọn láti ilẹ̀ Belgium lọ sí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Àwọn tí òùngbẹ sì ń pa sí aṣálẹ̀ Sàhárà kò níye nígbà tí ọkọ̀ akẹ́rù wọn tó ti di ahẹrẹpẹ tí ẹrù sì pọ̀ jù ú lọ bá kọṣẹ́ lágbedeméjì aṣálẹ̀ náà.
Síbẹ̀ láìka àwọn ewu yìí sí, ńṣe làwọn tó ń wá ibi sá lọ láyé nítorí ìṣòro ọrọ̀ ajé túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Nǹkan bí ìdajì mílíọ̀nù èèyàn ni wọ́n ń fi fàyàwọ́ kó wọ ilẹ̀ Yúróòpù lọ́dọọdún; tí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún [300,000] àwọn mìíràn sì ń wọ Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Lọ́dún 1993, Àjọ Tí Ń Bójú Tó Owó Àkànlò Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè fún Iye Èèyàn fojú bù ú pé, jákèjádò ayé, àwọn èèyàn tó ń wọ̀lú onílùú á tó ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù, ìdá kan nínú mẹ́ta wọn ló sì ti fìdí kalẹ̀ sí Yúróòpù àti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà báyìí. Látìgbà náà wá, kò sí àní-àní pé iye yẹn á ti lé ní ìlọ́po ìlọ́po.
Ọ̀pọ̀ nínú àwọn tó ń ṣí kiri yìí lọwọ́ wọn kì í tẹ ààbò tí wọ́n ń wá. Ìwọ̀nba àwọn olùwá-ibi-ìsádi ló sì máa ń rí ibi tí kò séwu tí wọ́n á lè máa gbé títí lọ. Ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà ni pé, ńṣe làwọn alárìnkiri yìí máa ń tinú ìṣòro kan bọ́ sí òmíràn. Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí á gbé díẹ̀ lára àwọn ìṣòro yìí àti okùnfà wọn yẹ̀ wò kínníkínní.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nínú ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ yìí, tá a bá ń sọ nípa àwọn èèyàn tí wọ́n ṣí kúrò níbi tí wọ́n ń gbé, kò kan àwọn èèyàn bí àádọ́rùn-ún mílíọ̀nù sí ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù tí wọ́n fipá lé kúrò nílé wọn nítorí àwọn iṣẹ́ ìdàgbàsókè tó ń ṣẹlẹ̀, irú bí ìsédò, ìwakùsà, igbó ọba, tàbí àwọn ètò iṣẹ́ àgbẹ̀.