Ìdè Tó Yẹ Kó Wà Pẹ́ Títí Ni Ìgbéyàwó
Ìdè Tó Yẹ Kó Wà Pẹ́ Títí Ni Ìgbéyàwó
GẸ́GẸ́ bó ṣe máa ń rí nínú ọ̀pọ̀ sinimá, nǹkan tó ń wu gbogbo èèyàn láti ṣe ni ìgbéyàwó jẹ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, ọkùnrin àti obìnrin náà á wà pa pọ̀, wọ́n á ṣègbéyàwó, wọ́n á sì máa gbé lọ “láyọ̀ títí láé.” Ohun tó sábà ń gbẹ̀yìn rẹ̀ nìyẹn nínú àwọn eré orí tẹlifíṣọ̀n.
Àmọ́ ní tòdodo, ìgbéyàwó kì í ṣe òpin ìgbésí ayé tuntun tí àwọn méjèèjì fẹ́ gbé, ìbẹ̀rẹ̀ ló jẹ́. A sì nírètí pé yóò rí bí Oníwàásù 7:8 ti sọ, “òpin ọ̀ràn kan ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ sàn ju ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ rẹ̀ lọ.”
Ìdè Tó Wà Pẹ́ Títí
Èèyàn gbọ́dọ̀ ronú nípa ọjọ́ iwájú. Ìdè ìgbéyàwó gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tó lágbára dáadáa kó bàa lè pẹ́ kó sì mìrìngìndìn. Láìjẹ́ bẹ́ẹ̀, hílàhílo tó máa bá èèyàn lẹ́yìn ìgbéyàwó á burú ju ti ìṣáájú lọ. Kristẹni kan kò lè torí bọ ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó kó sì máa ronú pé: ‘Bí ìná ò bá wọ̀ mọ́, mo lè jáwèé ìkọ̀sílẹ̀.’ Ìdè tó máa wà pẹ́ títí ni ìgbéyàwó.
Nígbà tí Jésù ń dáhùn ìbéèrè kan tí ẹnì kan bi í nípa ohun tó lè mú kéèyàn jáwèé ìkọ̀sílẹ̀, ó fi yéni pé ìdè tó máa wà títí lọ ni ìgbéyàwó jẹ́. Ó sọ pé: “Ẹ kò ha kà pé [Ọlọ́run] tí ó dá wọn láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ṣe wọ́n ní akọ àti abo, ó sì wí pé, ‘Nítorí ìdí yìí ọkùnrin yóò fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan’? Tí ó fi jẹ́ pé wọn kì í ṣe méjì mọ́, bí kò ṣe ara kan. Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.”—Mátíù 19:4-6.
Lẹ́yìn Ọjọ́ Ìgbéyàwó
Àwọn kan ti sọ pé nínú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì nínú ìgbésí ayé Kristẹni kan, ìgbéyàwó ló wà ní ipò kejì sí ìyàsímímọ́ rẹ̀ láti sin Ọlọ́run. Ìyàsímímọ́ ló máa ń so èèyàn mọ́ Ẹlẹ́dàá rẹ̀ títí láé, ìrìbọmi ló sì ń fi èyí hàn ní gbangba. Bẹ́ẹ̀ náà ni ìgbéyàwó ṣe jẹ́ pípolongo ní gbangba pé èèyàn ti jẹ́jẹ̀ẹ́ láti wà pẹ̀lú ẹlòmíràn títí láé. Ohun tó burú gbáà sì ni kéèyàn ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run tàbí kó wọnú ìdè ìgbéyàwó nígbà tó ṣì ní àwọn ohun kan tó ń ṣiyè méjì rẹ̀. Nítorí náà, á dára kí àwọn tó ń gbèrò láti ṣe ìgbéyàwó ṣàyẹ̀wò fínnífínní nípa ohun tí ẹni tí wọ́n fẹ́ fẹ́ gbà gbọ́, àwọn ohun tó ń lé, ìwà rẹ̀ àti bí nǹkan ṣe máa ń rí lára onítọ̀hún.
Béèyàn ṣe ń múra ìgbéyàwó, inú rere, ríronú jinlẹ̀ àti ẹ̀mí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ṣe pàtàkì gan-an. Àwọn ànímọ́ yẹn tún ṣe pàtàkì lẹ́yìn ìgbéyàwó 1 Kọ́ríńtì 13:5, 8) Bí ìfẹ́ bá ń bẹ, ó máa rọrùn láti ní àwọn ànímọ́ mìíràn bí ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìwà tútù àti ìkóra-ẹni-níjàánu, àwọn wọ̀nyí ni èso ẹ̀mí Ọlọ́run. Àwọn ànímọ́ wọ̀nyí ṣe kókó kí ìgbéyàwó bàa lè yọrí sí rere.—Gálátíà 5:22, 23.
kó bàa lè yọrí sí rere. Ìfẹ́ ti kó sí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìgbéyàwó náà lórí, àmọ́ lẹ́yìn ìgbéyàwó, wọ́n gbọ́dọ̀ máa rántí lójoojúmọ́ pé, ìfẹ́ “kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan.” “Ìfẹ́ kì í kùnà láé” bí wọ́n bá ń mú un lò bí ọdún ṣe ń gorí ọdún. (Ibi tó ṣòro níbẹ̀ ni bíbá a nìṣó láti máa fi àwọn ànímọ́ wọ̀nyí ṣèwà hù lẹ́yìn ọjọ́ ìgbéyàwó. Àmọ́ ṣá, àṣírí ohun tó lè mú kó o ṣàṣeyọrí nínú fífi àwọn ànímọ́ dídára yìí hàn rèé: Fẹ́ràn ẹni tó o bá ṣègbéyàwó, kó o sì múra tán láti yááfì àwọn ohun kan.
Jésù sọ pé òfin tó ga jù lọ fún ẹ̀dá ni láti fẹ́ràn Jèhófà, ó tún sọ pé èkejì ni pé, “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” (Mátíù 22:39) Ẹni tó sún mọ́ ẹnì kan tó ti ṣègbéyàwó jù lọ ni ọkọ rẹ̀ tàbí aya rẹ̀, nítorí pé kò tún sí nǹkan mìíràn láyé yìí tó lè so èèyàn méjì pọ̀ tó ìgbéyàwó.
Bó ti wù kó rí, jíjọ wà pa pọ̀ kò túmọ̀ sí pé bákan náà ni nǹkan ṣe rí lára wọn. Pé èèyàn méjì jọ wà pa pọ̀ kò túmọ̀ si pé ọkàn wọn ṣọ̀kan. Kí ìbálòpọ̀ tó lè dùn dé ibi tó yẹ, ó tún ń béèrè fún irú ìṣọ̀kan mìíràn, ìyẹn ni pé kí ọkàn àwọn méjèèjì ṣọ̀kan kí wọ́n sì ní irú ohun kan náà lọ́kàn láti ṣe. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa ń ná èèyàn ní yíyááfì àwọn ohun kan nítorí ẹnì kejì kí ìgbéyàwó bàa lè yọrí sí rere. Ta ló yẹ kó yááfì àwọn nǹkan? Ṣé ọkọ ni? Àbí ìyàwó?
Nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀ Kó O Sì Bọlá fún Un
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Nínú bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ mú ipò iwájú.” (Róòmù 12:10) Tó o bá lè ṣe é, ìwọ ni kó o kọ́kọ́ yááfì àwọn ohun kan kó tó di pé ẹnì kejì rẹ ní kó o ṣe bẹ́ẹ̀. Ó ṣe tán, nǹkan téèyàn ti bẹ̀bẹ̀ àbẹ̀ẹ̀dábọ̀ fún kó tó rí i gbà kì í fi bẹ́ẹ̀ níyì mọ́. Dípò kí irú ìyẹn wáyé, ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìgbéyàwó gbọ́dọ̀ máa lo ìdánúṣe láti bu ọlá fún ẹnì kejì.
Bí àpẹẹrẹ, a pa á láṣẹ fún àwọn ọkọ pé kí wọ́n máa “fi ọlá fún [aya] gẹ́gẹ́ bí fún ohun èlò tí ó túbọ̀ jẹ́ aláìlera, ọ̀kan tí ó jẹ́ abo, . . . kí àdúrà [wọn] má bàa ní ìdènà.” (1 Pétérù 3:7) Bí ọkọ kan kò bá fi ọlá fún aya rẹ̀, àdúrà tó ń gbà sí Ọlọ́run máa ní ìdènà. Àmọ́, kí ló túmọ̀ sí láti fi ọlá fún aya ẹni? Ó túmọ̀ sí pé kéèyàn máa gba tiẹ̀ rò nígbà gbogbo, kéèyàn máa tẹ́tí sóhun tó fẹ́ sọ, kéèyàn sì jẹ́ kó kọ́kọ́ máa sọ ohun tó wù ú lọ́pọ̀ ìgbà. Aya náà sì lè fi ọlá fún ọkọ rẹ̀ lọ́nà kan náà, kó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ tó ń fọwọ́sowọ́pọ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 21:12; Òwe 31:10-31.
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ó yẹ kí àwọn ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnra wọn. Ẹni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀, nítorí pé kò sí ènìyàn kankan tí ó jẹ́ kórìíra ara òun fúnra rẹ̀; ṣùgbọ́n a máa bọ́ ọ, a sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti ń ṣe sí ìjọ.” Báwo ni Kristi ṣe fẹ́ràn àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tó? Ó múra tán láti kú nítorí wọn. Bíbélì tún sọ pé: “Kí olúkúlùkù yín [àwọn ọkọ] lẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ.” (Éfésù 5:28-33) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún sọ fún àwọn aya pé kí wọ́n “nífẹ̀ẹ́ àwọn ọkọ wọn,” kí wọ́n ‘fi ara wọn sábẹ́ àwọn ọkọ wọn, kí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run má bàa di èyí tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ tèébútèébú.’—Títù 2:4, 5.
Máa Gbójú Fo Àṣìṣe
Àwọn èèyàn á máa ṣe àṣìṣe nítorí inú àìpé la gbé bí wọn. (Róòmù 3:23; 5:12; 1 Jòhánù 1:8-10) Àmọ́ dípò tí wàá fi máa fẹ àṣìṣe lójú, fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò pé: “Lékè ohun gbogbo, ẹ ní ìfẹ́ gbígbóná janjan fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, nítorí ìfẹ́ a máa bo ògìdìgbó ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.” (1 Pétérù 4:8) Ọ̀nà tó dára jù lọ láti yanjú àwọn àṣìṣe pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ ni pé kéèyàn yéé máa ronú nípa wọn, kéèyàn gbójú fò wọ́n dá. Èèyàn tún lè ṣe bákan náà sáwọn àṣìṣe tó rinlẹ̀. Ìwé Kólósè 3:12-14 sọ pé: “Ẹ fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, àti ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ. Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn. Àní gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti dárí jì yín ní fàlàlà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe. Ṣùgbọ́n, yàtọ̀ sí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ẹ fi ìfẹ́ wọ ara yín láṣọ, nítorí ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.”
Ìgbà mélòó ló yẹ ká dárí àwọn àṣìṣe pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ àti àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ aya tàbí ọkọ ẹni jì í? Pétérù béèrè lọ́wọ́ Jésù pé: “‘Olúwa, ìgbà mélòó ni arákùnrin mi yóò ṣẹ̀ mí, tí èmi yóò sì dárí jì í? Títí dé ìgbà méje ni bí?’ Jésù wí fún un pé: ‘Mo wí fún ọ, kì í ṣe, Títí dé ìgbà méje, bí kò ṣe, Títí dé ìgbà àádọ́rin lé méje.’” (Mátíù 18:21, 22) Ìgbà tó jẹ́ pé àwọn tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya ni Jésù ń sọ irú ọ̀rọ̀ yìí fún, ẹ ò wá rí i pé dídárí ji ara ẹni túbọ̀ ṣe pàtàkì gan-an láàárín àwọn lọ́kọláya!
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ètò ìgbéyàwó ti fojú winá àtakò láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àmọ́ bó bá yá, ó máa rù ú là nítorí pé Ọlọ́run ló ṣètò rẹ̀. Gbogbo nǹkan tí Jèhófà bá sì ṣètò rẹ̀ ló ń “dára gan-an.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:31) Ètò ìgbéyàwó kò ní di nǹkan àpatì. Ó lè yọrí sí rere àgàgà láàárín àwọn tó bọ̀wọ̀ fún àṣẹ Ọlọ́run tí wọ́n sì ń pa á mọ́. Ìpèníjà tó kàn wà níbẹ̀ ni pé: Ṣé àwọn èèyàn méjì yìí á tẹ̀ lé ìlérí tí wọ́n ṣe lọ́jọ́ ìgbéyàwó wọn pé àwọn á nífẹ̀ẹ́ ara àwọn, àwọn á sì máa ṣìkẹ́ ara àwọn? Ó dájú pé èyí lè jẹ́ ìpèníjà ńláǹlà, ó lè máà rọrùn rárá láti tẹ̀ lé ìlérí náà. Àmọ́ ohun tó máa tìdí rẹ̀ jáde tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ!
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 10]
PÍPÍNYÀ ÀTI ÌKỌ̀SÍLẸ̀
Ọlọ́run, tó jẹ́ Ẹni tó dá ìgbéyàwó sílẹ̀ ṣètò pé kó jẹ́ àjọṣe tó máa wà títí lọ. Àmọ́ ṣé ìdí èyíkéyìí wà tó bá Ìwé Mímọ́ mu téèyàn fi lè kọ aya tàbí ọkọ rẹ̀ sílẹ̀ tí olúwarẹ̀ á sì láǹfààní láti fẹ́ ẹlòmíràn? Nígbà tí Jésù ń jíròrò ọ̀rọ̀ yìí, ó sọ pé: “Mo wí fún yín pé ẹnì yòówù tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, bí kò ṣe lórí ìpìlẹ̀ àgbèrè, tí ó sì gbé òmíràn níyàwó, ṣe panṣágà.” (Mátíù 19:9) Kí ọkọ tàbí aya lọ máa ní ìbálòpọ̀ lóde ìgbéyàwó nìkan ni ìdí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tí wọ́n fi lè kọra wọn sílẹ̀ tí ẹni tí kò mọwọ́mẹsẹ̀ nínú àwọn méjèèjì sì lè fẹ́ ẹlòmíràn.
Ní àfikún, bó tilẹ̀ jẹ́ pé nínú 1 Kọ́ríńtì 7:10-16, Bíbélì rọ tọkọtaya láti má ṣe kọ ara wọn sílẹ̀, síbẹ̀ ó fàyè gba ìpínyà. Lẹ́yìn tí àwọn kan ti forí ṣe fọrùn ṣe pé kí ìgbéyàwó àwọn máà tú ká, wọ́n wá rí i pé kò sọ́gbọ́n táwọn lè ta sí i ju pé káwọn pínyà lọ. Àwọn nǹkan wo ni Ìwé Mímọ́ fọwọ́ sí pé ó lè mú wọn gbé irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀?
Ọ̀kan lára wọn ni bí ọkọ kan kì í báá gbọ́ bùkátà ìdílé rẹ̀. Nígbà tí ọkùnrin kan bá fẹ́yàwó, ó ti di ẹrù iṣẹ́ rẹ̀ láti máa gbọ́ bùkátà ìyàwó àti àwọn ọmọ. Bí ọkùnrin kan bá mọ̀ọ́mọ̀ kọ̀ láti pèsè àwọn ohun kòṣeémánìí ìgbésí ayé fún ìdílé rẹ̀, ó “ti sẹ́ ìgbàgbọ́, ó sì burú ju ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́.” (1 Tímótì 5:8) Fún ìdí yìí, wọ́n lè pínyà.
Ìdí mìíràn tún ni lílù tí àwọn kan máa ń lu ìyàwó wọn ní àlùbami. Bí ọkùnrin kan bá ń lu ìyàwó rẹ̀ lóòrèkóòrè, ìyàwó náà lè kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ fúngbà díẹ̀ ná. (Gálátíà 5:19-21; Títù 1:7) “Ọkàn [Ọlọ́run] kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.”—Sáàmù 11:5.
Ohun mìíràn tó tún lè mú kí wọ́n pínyà ni bí ipò tẹ̀mí alábàáṣègbéyàwó kan bá wà nínú ewu, ìyẹn àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. Àwọn onígbàgbọ́ kan tí rí i pé ó di dandan káwọn pínyà nítorí àtakò alábàáṣègbéyàwó wọn, bóyá tí kò tiẹ̀ jẹ́ kí wọ́n lè máa jọ́sìn lọ́nà tó tọ́ tó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi ipò tẹ̀mí wọn sínú ewu. a—Mátíù 22:37; Ìṣe 5:27-32.
Àmọ́ ṣá o, tó bá jẹ́ àwọn nǹkan wọ̀nyí ló mú kí tọkọtaya jáwèé ìkọ̀sílẹ̀, ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ò ní lè ṣègbéyàwó pẹ̀lú ẹlòmíràn o. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, ìdí kan ṣoṣo tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tí tọkọtaya fi lè jáwèé ìkọ̀sílẹ̀ tí wọ́n á sì lè bá ẹlòmíràn ṣègbéyàwó ni panṣágà tàbí “àgbèrè.”—Mátíù 5:32.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún àlàyé nípa ìpínyà, wo Ilé-Ìṣọ́nà November 1, 1988, ojú ìwé 22 àti 23.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ìdè tó máa wà pẹ́ títí ni ìgbéyàwó
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Jésù sọ pé ká dárí jini ní “ìgbà àádọ́rin lé méje”