Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọjọ́ Ìgbéyàwó—Ọjọ́ Olóyinmọmọ Ni Àmọ́ ó Tún Ní Wàhálà Tiẹ̀

Ọjọ́ Ìgbéyàwó—Ọjọ́ Olóyinmọmọ Ni Àmọ́ ó Tún Ní Wàhálà Tiẹ̀

Ọjọ́ Ìgbéyàwó—Ọjọ́ Olóyinmọmọ Ni Àmọ́ ó Tún Ní Wàhálà Tiẹ̀

BÍBÉLÌ jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run, tó mọ ẹ̀dá ènìyàn ju ẹnikẹ́ni mìíràn lọ, ló darí ìgbéyàwó àkọ́kọ́ pàá. Ó ṣètò ìgbéyàwó pé kó jẹ́ ìpìlẹ̀ fún àwùjọ ẹ̀dá. (Jẹ́nẹ́sísì 2:18-24) Tá a bá sì wo inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ní ìmísí, ìyẹn Bíbélì, a óò rí onírúurú ìlànà tó lè tọ́ wa sọ́nà nígbà tá a bá ń múra ìgbéyàwó.

Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ pé kí àwọn Kristẹni “san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì.” (Mátíù 22:21) Ìdí rèé tí wọ́n fi gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí òfin ibi tí wọ́n ń gbé. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà ni ìgbéyàwó tá a bá ṣe lọ́nà tó bá òfin mu máa ń gbà dáàbò bo àwọn tó ń ṣègbéyàwó náà, irú bíi jíjẹ́ kí wọ́n mọ ẹrù iṣẹ́ wọn lórí àwọn ọmọ (títí kan ilé tí wọ́n á gbé, oúnjẹ, aṣọ àti ẹ̀kọ́) àti ẹ̀tọ́ láti jogún àwọn òbí wọn. Àwọn òfin kan tún wà fún dídáàbò bo àwọn mẹ́ńbà ìdílé kúrò lọ́wọ́ ìwà àìdáa tàbí ìkóni-nífà. a

Ìmúrasílẹ̀

Tí ọkùnrin àti obìnrin kan bá ti pinnu láti ṣègbéyàwó tí wọ́n sì fẹ́ ṣe é lọ́nà tó bá òfin àti ìlànà Bíbélì àti òfin ibi tí wọ́n ń gbé mu, àwọn nǹkan tó tọ́ wo ni wọ́n gbọ́dọ̀ gbé yẹ̀ wò? Lára wọn ni ọjọ́ tí wọ́n fẹ́ fi ìgbéyàwó náà sí àti irú ìgbéyàwó tí wọ́n fẹ́ ṣe.

Ìwé kan sọ nípa kókó yìí pé: “Ó lè jẹ́ pé ohun tí tọkọtaya náà ní lọ́kàn kò bá ohun táwọn òbí wọn ní lọ́kàn mu, wọ́n sì lè má mọ ohun tí wọ́n á ṣe lórí bóyá káwọn ṣe é bó ṣe wà lọ́kàn àwọn tàbí káwọn tẹ̀ lé ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe é ní ìdílé àwọn.” Kí ni wọ́n lè ṣe o? Ìwé The Complete Wedding Organiser and Record, sọ pé: “Kò sí ojútùú kankan tó rọrùn sí ọ̀ràn yìí o, àfi kéèyàn fara balẹ̀, kí wọ́n jọ sọ̀rọ̀ ọ̀hún kúnnákúnná kí wọ́n sì jọ fẹnu ọ̀rọ̀ náà jóná síbì kan. Ńṣe ni àyà olúkúlùkù máa ń kó sókè lákòókò náà, àmọ́ béèyàn bá ronú jinlẹ̀ tó sì lo òye, á túbọ̀ mú kí gbogbo ètò náà rọrùn sí i.”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí tó nífẹ̀ẹ́ lè forí ṣe fọrùn ṣe kí ayẹyẹ ọjọ́ náà lè yọrí sí rere, wọn ò gbọ́dọ̀ sọ pé ohun táwọn bá ti wí ni abẹ gé. Bákan náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tí ọkọ àti aya bá sọ pé àwọn fẹ́ ṣe ni abẹ́ gé, wọ́n gbọ́dọ̀ fetí sí àwọn ìmọ̀ràn tó mọ́gbọ́n dání. Nígbà tí wọ́n bá ń ronú lórí àwọn àbá wo ló yẹ káwọn fara mọ́, yóò bọ́gbọ́n mu kí wọ́n fi ìmọ̀ràn Bíbélì yìí sọ́kàn pé: “Ohun gbogbo ni ó bófin mu; ṣùgbọ́n kì í ṣe ohun gbogbo ni ó ṣàǹfààní. Ohun gbogbo ni ó bófin mu; ṣùgbọ́n kì í ṣe ohun gbogbo ní ń gbéni ró. Kí olúkúlùkù má ṣe máa wá àǹfààní ti ara rẹ̀, bí kò ṣe ti ẹnì kejì.”—1 Kọ́ríńtì 10:23, 24.

Ìmúrasílẹ̀ náà ní ọ̀kan-kò-jọ̀kan ìgbòkègbodò nínú, látorí pípín ìwé ìkésíni títí dórí ṣíṣètò ibi tẹ́ ẹ ti máa kó àwọn èèyàn lẹ́nu jọ. H. Bowman sọ nínú ìwé rẹ̀ Marriage for Moderns, pé: “Bẹ́ ẹ bá ṣe wà létòlétò sí, bẹ́ ẹ bá ṣe múra sílẹ̀ tẹ́ ẹ sì lo orí pípé tó, bẹ́ẹ̀ náà ni sísáré síbí sọ́hùn-ún ṣe máa dín kù tó.” Ó wá kìlọ̀ pé: “Kódà bí gbogbo ètò bá tiẹ̀ ń lọ bó ṣe yẹ pàápàá, ọkàn èèyàn á ṣì wà lókè díẹ̀díẹ̀, ohun tó sì bọ́gbọ́n mu ni pé kéèyàn ṣe gbogbo ohun tó bá lè ṣe kára rẹ̀ lè wálẹ̀ díẹ̀.”

Àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ kan á wà láti ṣe, bẹ́ẹ̀ lèèyàn á tún ní láti tọ́jú àwọn àlejò tó wá. Ǹjẹ́ àwọn ọ̀rẹ́ tàbí àwọn ìbátan lè ran èèyàn lọ́wọ́? Ṣé èèyàn lè fa àwọn iṣẹ́ kan tí kò pọn dandan pé kó jẹ́ ọkọ tàbí ìyàwó ló máa ṣe é lé àwọn èèyàn tó tóótun lọ́wọ́?

Àwọn Ìnáwó

Ìwéwèé bí wọ́n ṣe máa náwó tí kò fi ní pa wọ́n lára ṣe pàtàkì. Kò bọ́gbọ́n mu kò sì ní fi hàn pé ìfẹ́ wà níbẹ̀ téèyàn bá ń retí pé kí tọkọtaya kan tàbí àwọn òbí wọn lọ tọrùn bọ gbèsè láti rówó ṣe ìgbéyàwó tí agbára wọn kò ká. Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n lówó láti ṣe ìgbéyàwó wọn lọ́nà tó hẹ̀rẹ̀ǹtẹ̀ ló ti sọ pé oníráńpẹ́ làwọ́n fẹ́ ṣe é. Ní kúkúrú, àwọn tọkọtaya kan ti rí i pé ó dára gan-an kéèyàn ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan tó máa fi ṣàkọsílẹ̀ iye tó fojú bù pé ìnáwó náà máa tó àti iye náà gan-an tó máa ná. Ó tún máa ń dára kéèyàn ní ìwé kan tó máa fi kọ ìgbà tí àwọn ètò tó yẹ ní ṣíṣe ti gbọ́dọ̀ wà ní sẹpẹ́. Tó o bá ní kó o há gbogbo èyí sórí, wàhálà ni wàá máa fún ara rẹ.

Èló ni ìgbéyàwó náà máa ná ọ? Iye rẹ̀ á yàtọ̀ síra láti ibì kan sí ibòmíràn, àmọ́ ibikíbi tó wù kó o máa gbé, á dára kó o béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé: ‘Ṣé agbára wa máa ká gbogbo nǹkan tá a fẹ́ ṣe yìí? Ṣé dandan ni ká ṣe wọ́n?’ Tina, tó ṣẹ̀ṣẹ̀ lọ sílé ọkọ sọ pé: “Àwọn nǹkan kan tá a kọ́kọ́ ronú pé ‘àìgbọ́dọ̀máṣe’ ni wọ́n tẹ́lẹ̀ la wá rí i pé kò pọn dandan.” Wo nǹkan tí Jésù sọ: “Ta ni nínú yín tí ó fẹ́ kọ́ ilé gogoro kan tí kò ní kọ́kọ́ jókòó, kí ó sì gbéṣirò lé ìnáwó náà, láti rí i bí òun bá ní tó láti parí rẹ̀?” (Lúùkù 14:28) Bó o bá rí i pé agbára rẹ kò ní gbé àwọn ohun kan tó o nífẹ̀ẹ́ sí, yáa yááfì àwọn kan. Ká tiẹ̀ sọ pé agbára rẹ gbé e jù bẹ́ẹ̀ lọ pàápàá, o lè ṣe é lọ́nà tí kò ní la kùkùkẹ̀kẹ̀ lọ.

Ní Ítálì, ìpàtẹ ọjà kan tí wọ́n ṣe láti fi polówó àwọn ohun èèlò ìgbéyàwó jẹ́ ká lè finú ṣírò iye tó ṣeé ṣe kí obìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Ítálì ná sórí ìgbéyàwó rẹ̀. Ṣíṣe ara àti irun lóge, àádọ́ta lé nírínwó [450] dọ́là; owó tí wọ́n á fi háyà ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, ọ̀ọ́dúnrún [300] dọ́là; owó onífídíò, ẹgbẹ̀ta [600] dọ́là; ibi tí wọ́n máa kó àwọn fọ́tò ìgbéyàwó sí (kò mọ́ fọ́tò fúnra rẹ̀ o), dọ́là márùnlélọ́gọ́fà sí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [125-500]; òdòdó lóríṣiríṣi, ó bẹ̀rẹ̀ láti ẹgbẹ̀ta [600] dọ́là; owó oúnjẹ, láti dọ́là márùndínláàádọ́ta sí àádọ́rùn [45-90] fún ẹnì kan; aṣọ ìgbéyàwó, á tó nǹkan bíi ẹgbẹ̀fà [1,200] dọ́là. Béèyàn bá wo bí ayẹyẹ náà ṣe ṣe pàtàkì tó lóòótọ́, ó lè dà bí ẹni pé kéèyàn ṣe é káyé gbọ́ kọ́run mọ̀. Irú ọ̀nà yòówù kéèyàn fẹ́ láti gbà ṣe é, kí onítọ̀hún ṣáà rí i pé òun rò ó dáadáa.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan lè ná ibú owó, ó tẹ́ àwọn mìíràn lọ́rùn láti ṣe é ní oníráńpẹ́, tàbí kó jẹ́ pé kò sí ọgbọ́n mìíràn tí wọ́n lè ta sí i jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ìyàwó kan sọ pé: “Aṣáájú ọ̀nà [oníwàásù alákòókò kíkún] làwa méjèèjì, a ò sì lówó, àmọ́ ìyẹn kọ́ lohun tó ṣe pàtàkì. Màmá ọkọ mi ra aṣọ tá a máa lò fún ìgbéyàwó wa, ọ̀rẹ́ wa kan sì bá wa rán an, rírán an yìí ló fi ṣe ẹ̀bùn tó fún wa fún ìgbéyàwó wa. Ọwọ́ ni ọkọ mi fi kọ ìwé ìkésíni wa, ọ̀rẹ́ wa kan tó jẹ́ Kristẹni sì yá wa ní ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀. A ra àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì tá a máa lò níbi àwẹ̀jẹ-àwẹ̀mu, ẹnì kan sì fi wáìnì ta wá lọ́rẹ. A kò ṣe é ní aláriwo, àmọ́ ó lárinrin.” Gẹ́gẹ́ bí ọkọ kan ṣe sọ, bí àwọn ìbátan àtàwọn ọ̀rẹ́ bá ṣèrànwọ́, “ìnáwó máa ń dín kù gan-an ni.”

Bó ti wù kí àwọn tọkọtaya Kristẹni lówó lọ́wọ́ tó, wọn kò ní fẹ́ ṣe àṣerégèé, wọ́n á fẹ́ yẹra fún ẹ̀mí ayé tàbí ìwà ṣekárími. (1 Jòhánù 2:15-17) Ẹ ò rí i pé á burú gan-an bí ayẹyẹ aláyọ̀ bí ìgbéyàwó bá lọ di èyí tí kò jẹ́ kéèyàn tẹ̀ lé àwọn ìlànà inú Ìwé Mímọ́ nípa wíwà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, èyí tó kìlọ̀ fúnni láti yẹra fún jíjẹ àjẹjù, àmujù, tàbí ohunkóhun tí kò ní jẹ́ kéèyàn jẹ́ “aláìlẹ́gàn”!—Òwe 23:20, 21; 1 Tímótì 3:2.

Yẹra fún èrò náà pé o fẹ́ kí ayẹyẹ ìgbéyàwó rẹ fa kíki ju ti àwọn ẹlòmíràn lọ. Wo ìbòrí táwọn obìnrin méjì kan lò nígbà ìgbéyàwó wọn ní orílẹ̀-èdè kan, ti ọ̀kan jẹ́ mítà mẹ́tàlá ní ìdábùú ó sì wúwo tó okòó lé rúgba [220] kìlógíráàmù. Èkejì gún tó ọ̀ọ́dúnrún [300] mítà, ó sì gba ọgọ́rùn-ún àwọn ọ̀rẹ́ ìyàwó láti máa bá a kó aṣọ náà. Téèyàn bá sọ pé èrò-yà-wá-wò-ó bí irú èyí lòun náà fẹ́ ṣe, ǹjẹ́ irú ẹni bẹ́ẹ̀ ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn inú Bíbélì nípa lílo òye?—Fílípì 4:5.

Ṣé Ó Yẹ Kéèyàn Tẹ̀ Lé Àṣà Ìbílẹ̀?

Bí wọ́n ṣe ń ṣe ìgbéyàwó lọ́nà àṣà ìbílẹ̀ ní orílẹ̀-èdè kan yàtọ̀ sí òmíràn, nítorí náà a ò ní lè mẹ́nu ba gbogbo wọn. Bí tọkọtaya kan bá ń ronú lórí bóyá káwọn tẹ̀ lé àṣà ìbílẹ̀ kan, á dára kí wọ́n béèrè lọ́wọ́ ara wọn pé: ‘Kí ni ìtumọ̀ àṣà yìí? Ǹjẹ́ ó jẹ mọ́ ìgbàgbọ́ nínú ohun asán tó ní i ṣe pẹ̀lú oríire tàbí ìbímọlémọ, irú bí i kí wọ́n máa da ìrẹsì sára ẹni tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìgbéyàwó? Ǹjẹ́ ó ní i ṣe pẹ̀lú ìsìn èké tàbí àwọn àṣà tí Bíbélì kò fara mọ́? Ǹjẹ́ ó fi ìwà ìgbatẹnirò tàbí ìfẹ́ hàn? Ǹjẹ́ ó lè dójú ti àwọn ẹlòmíràn tàbí mú wọn kọsẹ̀? Ǹjẹ́ ó lè mú káwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí ṣiyèméjì nípa tọkọtaya náà? Ǹjẹ́ ó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì?’ Bí èyíkéyìí nínú àwọn ohun tó wà lókè yìí bá ń rú ọ lójú, ó máa dára kó o yàgò fún un, tó bá sì pọn dandan, jẹ́ kí gbogbo àwọn tó o ké sí mọ̀ nípa ìpinnu rẹ ṣáájú àkókò.

Ìdùnnú àti Ìmọ̀lára Téèyàn Máa Ń Ní

Bí ọ̀ràn ṣe máa ń rí lára èèyàn lọ́jọ́ tó bá ń ṣe nǹkan ẹ̀yẹ lè jẹ́ ti ìdùnnú tàbí ti omijé. Ìyàwó kan sọ pé: “Ìdùnnú ṣubú layọ̀ gan-an fún mi, ohun tí mo ti ń wọ̀nà fún látìgbà pípẹ́ ti wá dòun báyìí.” Àmọ́ ọkọ kan sọ pé: “Ọjọ́ náà ni ọjọ́ tó burú jù lọ nínú ìgbésí ayé mi, òun náà ló sì tún dùn jù lọ nínú ìgbésí ayé mi. Ńṣe làwọn àna mi ń sunkún àsun-ùn-dákẹ́ nítorí pé mò ń mú àkọ́bí wọn lọ. Ìyàwó mi náà bẹ̀rẹ̀ sí sunkún nígbà tó rí i pé àwọn òbí rẹ̀ ń ké. Gbẹ̀ẹ́ lèmi náà sì bú sẹ́kún nígbà tára mi kò gbà á mọ́.”

Irú ìmọ̀lára báyìí kò gbọ́dọ̀ kó ìpayà bá ọ nítorí pé bọ́ràn ṣe rí lára olúkúlùkù ló fà á. Kì í sì í ṣe ohun tuntun pé ayẹyẹ náà lè mú kí àwọn ìbátan, kódà tọkọtaya pàápàá yarí fúnra wọn nígbà míì. Ìwé The Complete Wedding Organiser and Record sọ pé: “Ó ṣe tán, ó lè jẹ́ pé ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n jọ máa ṣayẹyẹ ńlá kan pa pọ̀ rèé, ó sì ṣeé ṣe kí ìdùnnú náà nípa lórí àjọṣe wọn lọ́nà kan. Kò ní í dáa kéèyàn bínú nítorí pé nǹkan kò lọ ní mẹ̀lọmẹ̀lọ béèyàn ṣe rò, àǹfààní ńláǹlà ló sì wà nínú kéèyàn lọ fara balẹ̀ gbàmọ̀ràn àti àtìlẹ́yìn nírú àkókò báyìí.”

Ọkọ kan sọ pé: “Ohun tí mi ò bá ti mọrírì jù lọ ni ẹnì kan tó lè gbà mí nímọ̀ràn, tí màá lè finú hàn, tí màá sì lè sọ gbogbo nǹkan tó wà lọ́kàn mi fún. Ẹ̀wẹ̀, mi ò bá sì kábàámọ̀ gidigidi, ká ní mi ò ní irú ẹni bẹ́ẹ̀.” Kò sí ẹlòmíràn tó lè ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ fúnni ju ọ̀rẹ́ kan tó dàgbà dénú tàbí ìbátan kan tàbí ẹnì kan tó nírìírí nínú ìjọ Kristẹni.

Nígbà táwọn òbí bá wò ó pé ọmọ àwọn ń fi àwọn sílẹ̀ rèé, inú wọn á dùn, orí wọn á wú, á tún dà bí i pé kí ọmọ náà máà lọ mọ́, ẹ̀rù á sì máa bà wọ́n. Bó ti wù kó rí, wọ́n gbọ́dọ̀ rántí pé àkókò ti tó tí ọmọ wọn á “fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀” tá á sì fà mọ́ ọkọ tàbí aya rẹ̀ tí “wọn yóò sì di ara kan,” gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá ṣe fẹ́ kó rí. (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Nígbà tí ìyá kan ń sọ̀rọ̀ nípa bára rẹ̀ ṣe rí nígbà tí ọmọkùnrin rẹ̀ àkọ́bí ń gbéyàwó, ó sọ pé: “Mo sunkun sunkun, bẹ́ẹ̀ náà ni omijé ayọ̀ tún jáde lójú mi nítorí pé mo fẹ́ràn aya tí ọmọ mi fẹ́.”

Kí ayẹyẹ náà bàa lè lárinrin kó sì gbéni ró, àwọn òbí àtàwọn tọkọtaya náà ní láti fi àwọn ànímọ́ Kristẹni hàn, bí ìfọwọ́sowọ́pọ̀, sùúrù, àìmọtara-ẹni-nìkan, kí wọ́n sì máa tẹ́tí sí èrò àwọn ẹlòmíràn.—1 Kọ́ríńtì 13:4-8; Gálátíà 5:22-24; Fílípì 2:2-4.

Àwọn ìyàwó mìíràn máa ń jáyà pé láburú kan á ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ìgbéyàwó wọn, pé táyà ọkọ̀ á jò tí wọn ò sì ní lè tètè dé ibi ayẹyẹ náà, pé ojú ọjọ́ á ṣe gùdẹ̀, tàbí pé kinní kan á ṣẹlẹ̀ sí aṣọ ìgbéyàwó wọn nígbà tí àsìkò ti lọ tán. Èyíkéyìí lára nǹkan wọ̀nyí lè má ṣẹlẹ̀. Àmọ́ ṣá o, má ronú pé nǹkan kan kò lè ṣẹlẹ̀. Nítorí a kì í mọ̀ ọ́n rìn kí orí má mì. Ńṣe lèèyàn á gba kámú pẹ̀lú àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tó bá wáyé. (Oníwàásù 9:11) Má ṣe jẹ́ káwọn ìṣòro wọ̀nyí mú kó o lejú ko-ko-ko, ṣùgbọ́n fi í sọ́kàn pé nǹkan á dára. Bó bá ṣẹlẹ̀ pé nǹkan kan wà tí kò rí bó ṣe yẹ kó rí, fi sọ́kàn pé tó o bá ń pa ìtàn náà lọ́jọ́ iwájú, ó lè jẹ́ ẹ̀rín ni wàá máa fi rín. Má ṣe jẹ́ káwọn ohun tí kò rí bó ṣe yẹ kó rí pa ayọ̀ ìgbéyàwó náà o.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Lórí kókó yìí, ọ̀kan-kò-jọ̀kan orílẹ̀-èdè ló ka níní ìyàwó tàbí ọkọ sílé kó tún lọ fẹ́ òmíràn, níní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ìbátan ẹni, ẹ̀tàn, ṣíṣe ẹni téèyàn fẹ́ níṣekúṣe àti ìgbéyàwó èwe léèwọ̀.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 7]

“Àwọn nǹkan kan tá a kọ́kọ́ ronú pé ‘àìgbọ́dọ̀máṣe’ ni wọ́n tẹ́lẹ̀ la wá rí i pé kò pọn dandan.”—TINA, TÓ RELÉ ỌKỌ

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

ÀPẸẸRẸ ÌTÒLẸ́SẸẸSẸ OHUN TÓ YẸ NÍ ṢÍṢE b

Tó bá ku oṣù mẹ́fà tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ

❑ Bá ọkọ rẹ tàbí aya rẹ lọ́la, àwọn àna àti àwọn òbí rẹ jíròrò àwọn ètò tó o ti ṣe

❑ Yan irú ìgbéyàwó tó o fẹ́ ṣe

❑ Ṣírò iye tó o ní lọ́wọ́ àti iye tó o máa ná

❑ Wádìí àwọn ohun tí òfin béèrè

❑ Lọ ṣètò fún ibi tó o ti má a ṣe ayẹyẹ àwẹ̀jẹ-àwẹ̀mu

❑ Lọ wá ẹni tó máa bá a yín ya fọ́tò

Tó bá ku oṣù mẹ́rin

❑ Mọ irú aṣọ ìgbéyàwó tó o máa lò (bóyá nínú àwọn tó o ní sílé), o lè rà á tàbí kó o lọ rán tuntun

❑ Lọ bá àwọn tó ń ta òdòdó, sọ iye tó o fẹ́

❑ Wo irú ìwé ìkésíni tó o fẹ́ kó o sì ní kí wọ́n bá ọ tẹ̀ ẹ́

Tó bá ku oṣù méjì

❑ Há ìwé ìkésíni fún àwọn èèyàn

❑ Lọ ra òrùka

❑ Lọ gba àwọn ìwé àṣẹ tó yẹ ní gbígbà

Tó bá ku oṣù kan

❑ Wọ aṣọ ìgbéyàwó rẹ wò bóyá ó dára

❑ Rí i dájú pé àwọn nǹkan tó o ní kí wọ́n bá ọ ṣe àtàwọn tó o fa iṣẹ́ lé lọ́wọ́ ti wà ní sẹpẹ́

❑ Kọ lẹ́tà ìdúpẹ́ sáwọn tó ti fún ọ lẹ́bùn

Tó bá ku ọ̀sẹ̀ méjì

❑ Bẹ̀rẹ̀ sí kó àwọn ẹrù lọ sílé tí wàá máa gbé lẹ́yìn ìgbéyàwó

Tó bá ku ọ̀sẹ̀ kan

❑ Rí i dájú pé gbogbo àwọn tó máa ràn ọ́ lọ́wọ́ ló ti mọ nǹkan tó o fẹ́ kí wọ́n ṣe

❑ Ṣètò bó o ṣe máa dá àwọn ohun èèlò tó o yá padà

❑ Fa gbogbo ìṣètò tó o bá rí i pé àwọn mìíràn lè bójú tó lé wọn lọ́wọ́

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

b A lè yọ àwọn ohun kan kúrò nínú rẹ̀ tàbí fi kún un kó lè bá ohun tí òfin àgbègbè béèrè mu àti ipò téèyàn wà.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

“Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀”