“Ọjọ́ Tó Dùn Jù Lọ Nínú Ìgbésí Ayé Wa”
“Ọjọ́ Tó Dùn Jù Lọ Nínú Ìgbésí Ayé Wa”
ỌJỌ́ aládùn lọjọ́ ìgbéyàwó. Ọ̀pọ̀ tọkọtaya ló ti sọ pé: “Òun ni ọjọ́ tó dùn jù lọ nínú ìgbésí ayé wa.” Àmọ́ bẹ́ẹ̀ náà ló tún lè jẹ́ ọjọ́ téèyàn á ṣe wàhálà àṣefẹ́ẹ̀ẹ́kú. Másùnmáwo àti àárẹ̀ tó máa bá ọkọ, ìyàwó àtàwọn ìdílé wọn lè pọ̀ gan-an, nítorí àwọn ìpinnu àti ìmúrasílẹ̀ tí wọ́n máa ṣe àti ọ̀pọ̀ èèyàn tí tọkọtaya máa pàdé lọ́jọ́ náà.
Ìgbéyàwó jẹ́ àmì ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé tuntun fún tọkọtaya. Àmọ́ kì í ṣe àwọn nìkan ló máa sáré sọ́tùn-ún sósì. Níwọ̀n bí ìgbéyàwó ọmọkùnrin ẹni, ọmọbìnrin ẹni, arákùnrin tàbí arábìnrin ẹni ti sábà máa ń túmọ̀ sí pé ẹni náà ń lọ dá agbo ilé tiẹ̀ sílẹ̀, èyí sábà máa ń mú kí ìdílé ní oríṣiríṣi èrò.
Bí wọ́n ṣe ń ṣe ìgbéyàwó yàtọ̀ láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn, a ò sì ní lè jíròrò gbogbo wọn tán níbí. Àwọn àpilẹ̀kọ wọ̀nyí á dá lórí ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ṣe é ní àwọn orílẹ̀-èdè Ìwọ̀ Oòrùn ayé àtàwọn ilẹ̀ mìíràn tó fara jọ ọ́. Láwọn ilẹ̀ yìí, ìnáwó ńlá gbáà ni ìgbéyàwó máa ń jẹ́. Owó táwọn mìíràn ń ná lọ́jọ́ ìgbéyàwó kúrò ní díẹ̀, títí kan owó tí wọ́n fi ń rẹ́ǹtì gbọ̀ngàn ńlá tàbí ilé àrójẹ tí wọ́n ti máa kóni lẹ́nu jọ àti jíjẹ mímu tó máa wáyé níbẹ̀. Wọ́n fojú díwọ̀n rẹ̀ pé iye tí wọ́n fi ń ṣe ìgbéyàwó tí kò la kùkùkẹ̀kẹ̀ lọ ní Ítálì lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] dọ́là. Ní Japan àtàwọn ibòmíràn, iye yẹn lè jù bẹ́ẹ̀ lọ. Kì í ṣe ìyàwó tàbí ọkọ ló sábà máa ń san owó yìí. Àwọn òbí wọn ló máa ń san án.
Òwò ńlá gan-an ni ìgbéyàwó jẹ́ fáwọn ilé iṣẹ́ okòwò. Ohun tí ọ̀pọ̀ wọn máa ń polówó rẹ̀ ni ìgbéyàwó “tó rí bó ṣe yẹ kó rí,” tí kò lálàṣí ohunkóhun. Ohun tí wọ́n máa ń sọ ni pé, ó ṣe tán, “ọjọ́ náà ni ọjọ́ tó dùn jù lọ nínú ìgbésí ayé rẹ!” Wọ́n á wá tipa báyìí ṣe onírúurú àwọn ohun èlò “tó ṣe pàtàkì” láti mú kí ọjọ́ ayọ̀ rẹ “mìrìngìndìn.” Àwọn ìwé ìkésíni tó ṣàrà ọ̀tọ̀ lè wà lára wọn, aṣọ ìgbéyàwó “tó lẹ́wà bí òṣùmàrè” tó o lè lò, aṣọ táwọn ọ̀rẹ́ ìyàwó máa lò àti èyí táwọn ọ̀rẹ́ ọkọ máa lò náà kò gbẹ́yìn. Bákan náà ni wàá tún nílò àwọn òdòdó, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, o sì tún lè nílò ibi tí wàá ti kó àwọn èèyàn lẹ́nu jọ, onífọ́tò, àwọn olórin àtàwọn nǹkan mìíràn. Àwọn nǹkan tí ìyàwó àti ọkọ yóò lò àti àwọn ìnáwó tó máa bá a rìn, lè kó ìdààmú bá ọ̀pọ̀ òbí.
Láàárín àwùjọ lọ́lọ́kan-kò-jọ̀kan, àwọn èèyàn kì í kóyán àṣà ìbílẹ̀ wọn kéré. Àwọn ọ̀nà kan wà látayébáyé tí wọ́n ń gbà ṣe ayẹyẹ náà, àwọn èèyàn á sì máa retí pé kí tọkọtaya yìí ṣe é bẹ́ẹ̀. Ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan ló yẹ kí wọ́n rántí láti ṣe, àmọ́ ìwọ̀nba àkókò díẹ̀ ló wà láti ṣe gbogbo ètò yìí.
Ṣé ọjọ́ tó ń fúnni láyọ̀ ni ọjọ́ ìgbéyàwó rẹ máa jẹ́ ni àbí èyí tó ń bani nínú jẹ́? Ohun yòówù kó o sọ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbéèrè ló máa dìde bó o bá ṣe ń ronú lórí gbogbo nǹkan tí ìgbéyàwó máa ná ọ. Kí ni ṣíṣe ìgbéyàwó túmọ̀ sí lóde òní? Ṣé dandan ni kéèyàn ṣe gbogbo nǹkan tá a sọ lókè yìí kí ìgbéyàwó rẹ̀ tó jẹ́ “ojúlówó”? Báwo la ṣe lè borí onírúurú wàhálà sísá sọ́tùn-ún sósì àti ríronú?
Láìka bí ọjọ́ ìgbéyàwó ṣe ń mú másùnmáwo dání sí, ọ̀pọ̀ ló ti ṣètò tiwọn dáadáa tí wọ́n sì gbádùn ayẹyẹ náà. Ìrírí wọn lè ran àwọn mìíràn tó ń múra láti ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́. Bákan náà, àwọn ìlànà Bíbélì wà tó lè ṣèrànwọ́ béèyàn bá ń múra láti ṣe ìgbéyàwó, kí ọjọ́ náà bàa lè ládùn kó lóyin, kó sì gbé gbogbo èèyàn ró.