Ayé Kan Tó Máa Dẹrùn fún Gbogbo Èèyàn
Ayé Kan Tó Máa Dẹrùn fún Gbogbo Èèyàn
“Níwọ̀n bí ọ̀ràn àwọn olùwá-ibi-ìsádi ti jẹ́ ìṣòro tó kan gbogbo ayé, gbogbo ayé náà ló gbọ́dọ̀ pawọ́ pọ̀ wá ojútùú sí i.”—Gil Loescher, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú àjọṣepọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè.
ÒRU dúdú làwọn tọkọtaya ọ̀dọ́ náà sá jáde. Bí ààbò ẹ̀mí wọn ṣe ń jẹ wọ́n lọ́kàn, ọkọ náà kò fàkókò ṣòfò rárá, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ní ọmọ kékeré kan lọ́wọ́. Ó ti gbọ́ pé alákòóso ìlú náà tí kò láàánú lójú tó sì jẹ́ aláṣẹ bóofẹ́bóokọ̀ ti ń wéwèé láti wá pa àwọn èèyàn nínú ìlú náà. Lẹ́yìn tí wọ́n ti rin ìrìn tó ju ọgọ́jọ kìlómítà lọ tó sì ti rẹ̀ wọ́n tẹnutẹnu, ìdílé náà kọjá ẹnubodè níkẹyìn wọ́n sì bọ́ lọ́wọ́ ewu.
Ìdílé tí kò fi bẹ́ẹ̀ rí jájẹ yìí wá di èyí tí gbogbo ayé mọ̀ lẹ́yìn náà. Jésù lorúkọ ọmọ ọ̀hún, àwọn òbí rẹ̀ sì ni Màríà àti Jósẹ́fù. Kì í ṣe torí àtiní ọrọ̀ ló mú àwọn olùwá-ibi-ìsádi yìí ṣí kúrò ní ilẹ̀ wọn o. Kàkà bẹ́ẹ̀, torí pé ẹ̀mí wọn wà nínú ewu ni. Àní, ọmọ wọn gan-an ni wọ́n fẹ́ pa!
Bíi ti ọ̀pọ̀ àwọn olùwá-ibi-ìsádi tó kù, Jósẹ́fù àti ìdílé rẹ̀ padà sí ìlú wọn níkẹyìn nígbà tí ìṣòro ọ̀ràn ìṣèlú náà ti rọlẹ̀. Àmọ́ kò sí iyèméjì pé sísá tí wọ́n sá lọ lásìkò ló dá ẹ̀mí ọmọ wọn jòjòló náà sí. (Mátíù 2:13-16) Ọjọ́ pẹ́ tí ilẹ̀ Íjíbítì, ìyẹn orílẹ̀-èdè tí wọ́n sá lọ, ti máa ń gba àwọn tó sá kúrò nílùú nítorí ọ̀ràn ìṣèlú àti nítorí ipò ìṣúnná owó tira. Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ṣáájú ìgbà yẹn, àwọn baba ńlá Jésù rí ààbò ní ilẹ̀ Íjíbítì nígbà tí ìyàn kan sọ ilẹ̀ Kénáánì dahoro.—Jẹ́nẹ́sísì 45:9-11.
Wọ́n Rí Ààbò àmọ́ Wọn Ò Rí Ìtẹ́lọ́rùn
Ìwé Mímọ́ àtàwọn àpẹẹrẹ ọjọ́ òní jẹ́rìí sí i pé sísá àsálà lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn lè dáàbò bo èèyàn lọ́wọ́ ikú. Síbẹ̀, kò sí ìdílé kankan tó máa ń bá lára mu láti fi ilé wọn sílẹ̀. Bó ti wù kí ilé wọn kéré tó, ó dájú pé ọ̀pọ̀ owó àti àkókò ni wọ́n ti ná lé e lórí. Ó sì lè jẹ́ ogún ìdílé wọn ni, èyí tó ń rán wọn létí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wọn àti ilẹ̀ wọn. Láfikún sí i, ìwọ̀nba ni ẹrù tó máa ń ṣeé ṣe fáwọn olùwá-ibi-ìsádi láti mú dání, ìyẹn tí wọ́n bá tiẹ̀ lè mú ohunkóhun lọ rárá. Nípa bẹ́ẹ̀, kò sí bí àwọn olùwá-ibi-ìsádi kò ṣe ní bára wọn nínú ìṣẹ́, láìka irú ipò yòówù tí wọ́n ti wà tẹ́lẹ̀ sí.
Ìtura tí wọ́n máa ń ní tí wọ́n bá kọ́kọ́ débi ààbò lè pòórá kíákíá tó bá jẹ́ pé gbogbo ìrètí wọn fún ọjọ́ iwájú kò ju pé kí wọ́n máa gbé nínú àgọ́ lọ. Bí ìṣòro wọn bá sì ṣe ń pẹ́ sí i tí kò yanjú, bẹ́ẹ̀ ni nǹkan á máa nira sí i fún wọn, àgàgà tí kò bá sí àjọṣe kankan láàárín àwọn àtàwọn èèyàn àdúgbò náà. Ó wu àwọn olùwá-ibi-ìsádi pé káwọn èèyàn fẹ́ràn wọn bíi tàwọn mìíràn. Ó dájú pé àgọ́ àwọn olùwá-ibi-ìsádi kì í ṣe ibi tó dára láti bójú tó ìdílé ẹni. Ṣé ìgbà kan á wà tí gbogbo èèyàn á ní ibì kan tí wọ́n lè pè ní ilé wọn?
Ṣé Lílé Wọn Padà Sílùú Wọn Ló Máa Yanjú Ọ̀rọ̀?
Láàárín àwọn ọdún 1990, nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́sàn-án èèyàn tó ṣí lọ ló darí padà sílé. Fún àwọn kan lára wọn, àkókò ayọ̀ ló jẹ́, kíá ni wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í tún ìgbésí ayé wọn tò padà. Àmọ́ ní ti àwọn mìíràn, wọn ò rí bá ti ṣe é. Ohun tó mú wọn padà kò ju pé ìṣòro wọn ti kọjá ohun tí wọ́n lè fara dà ní orílẹ̀-èdè tí wọ́n wá ààbò lọ. Ohun tójú wọn rí nígbèkùn le débi tí wọ́n fi pinnu pé ó sàn káwọn kúkú padà sílé, láìka àìsí ìfọ̀kànbalẹ̀ tó ti dájú pé wọ́n máa wá kojú rẹ̀ sí.
Àní ká tiẹ̀ ní nǹkan ò fi bẹ́ẹ̀ nira pàápàá,
pípadà sílé máa ń mú ìṣòro lọ́wọ́, torí pé ńṣe ló túmọ̀ sí pé wọ́n tún máa ṣí kúrò pátápátá nígbà kejì. Ìwé The State of the World’s Refugees 1997-98 sọ pé: “Gbogbo ìgbà téèyàn bá ń ṣí kiri lá máa pàdánù ohun tó fi ń gbọ́ bùkátà, irú bí ilẹ̀, iṣẹ́, ilé àtàwọn nǹkan ọ̀sìn. Bẹ́ẹ̀ náà láá sì máa ṣòro fún èèyàn láti bẹ̀rẹ̀ padà.” Ìwádìí tí wọ́n ṣe nípa àwọn olùwá-ibi-ìsádi tó padà sí ilẹ̀ wọn láti àárín gbùngbùn Áfíríkà sọ pé “tá a bá ń sọ nípa àwọn olùwá-ibi-ìsádi kan tó ti rí ìrànwọ́ gbà nígbèkùn, àtipadà sílé lè nira fún wọn ju ìṣòro tó kojú wọn nígbèkùn lọ.”Àmọ́ èyí tó bani lọ́kàn jẹ́ jù ni ìṣòro tó ń kojú àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn olùwá-ibi-ìsádi tí wọ́n fipá dá padà sí orílẹ̀-èdè wọn láìṣe pé ó tọkàn wọn wá. Kí ló ń dúró dè wọ́n nílé? Ìròyìn kan látọ̀dọ̀ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sọ pé: “Àwọn tó ń padà sílé lè bára wọn níbi táwọn èèyàn ò ti bọ̀wọ̀ fún òfin rárá, tí ìwà jàǹdùkú àti ìwà ọ̀daràn ti ń lọ ní pẹrẹwu, táwọn sójà tí kò rí ogun jà mọ́ á ti sọ àwọn èèyàn di ẹran ìjẹ, tí ohun ìjà pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ á sì wà lọ́wọ́ ogunlọ́gọ̀ èèyàn.” Ó dájú pé, irú àyíká burúkú bẹ́ẹ̀ kò fún àwọn èèyàn tí wọ́n lé padà yìí ní ààbò tí wọ́n nílò.
Ayé Kan Níbi Tọ́kàn Gbogbo Èèyàn Á Ti Balẹ̀
Fífipá dá àwọn olùwá-ibi-ìsádi padà sílùú wọn láìṣe pé ó tọkàn wọn wá kò lè yanjú ìṣòro wọn àyàfi tá a bá kọ́kọ́ bójú tó àwọn ohun tó fà á. Abílékọ Sadako Ogata tó jẹ́ Kọmíṣọ́nnà Àgbà fún Bíbójú Tó Àwọn Olùwá-Ibi-Ìsádi ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sọ lọ́dún 1999 pé: “Àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní ẹ̀wádún yìí, pàápàá àwọn tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún tó kọjá fi hàn gbangba pé, kò ṣeé ṣe láti jíròrò ọ̀ràn àwọn olùwá-ibi-ìsádi láìmẹ́nu kan ọ̀rọ̀ ààbò.”
Àìsí ìfọ̀kànbalẹ̀ tó le kú ń bá àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn fínra káàkiri ayé. Kofi Annan, ọ̀gá àgbà fún Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sọ pé: “Láwọn apá ibì kan nínú ayé, ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ló ti di akúrẹtẹ̀ nítorí ogun abẹ́lé àti ìjà láàárín ìletò kan àti òmíràn, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò sì fún àwọn èèyàn wọn ní ààbò tó péye kankan. Láwọn ibòmíì, inú ewu làwọn ìjọba fi ààbò àwọn èèyàn wọn sí nípa kíkọ̀ láti ṣe ohun tó máa ṣe wọ́n láǹfààní, nípa ṣíṣe inúnibíni sáwọn èèyàn tí kò ṣe ohun tí wọ́n fẹ́ tàbí nípa fífi ìyà jẹ àwọn aláìṣẹ̀ tó wá látinú àwùjọ kékeré.”
Ogun, inúnibíni àti ìwà ipá tó ń wá látinú kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ni olórí àwọn ohun tó ń fa àìsí ààbò tí Kofi Annan mẹ́nu kàn, wọ́n sì sábà máa ń wá látinú ìkórìíra, ẹ̀tanú àti ìwà ìrẹ́nijẹ. Mímú àwọn ìwà láabi yìí kúrò kì í ṣe ohun tó rọrùn. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé ńṣe ni ìṣòro àwọn olùwá-ibi-ìsádi á máa burú sí i ni?
Tá a bá fi àwọn ìṣòro yìí dá èèyàn, kò sí-tàbí-ṣùgbọ́n pé ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nìyẹn. Àmọ́ nínú Bíbélì, Ọlọ́run ṣèlérí pé òun á “mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé.” (Sáàmù 46:9) Nípasẹ̀ wòlíì rẹ̀ Aísáyà, ó tún sọ nípa àkókò kan pé àwọn èèyàn “yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn. . . . Wọn kì yóò ṣe làálàá lásán, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò bímọ fún ìyọlẹ́nu; nítorí pé àwọn ni ọmọ tí ó para pọ̀ jẹ́ alábùkún lọ́dọ̀ Jèhófà, àti àwọn ọmọ ìran wọn pẹ̀lú wọn.” (Aísáyà 65:21-23) Ó dájú pé irú àwọn ipò báyìí yóò fòpin sí ìṣòro àwọn olùwá-ibi-ìsádi. Àmọ́ ṣé ọwọ́ lè tẹ àwọn ipò náà?
Apá tó ṣáájú nínú àkọsílẹ̀ ìwé òfin Àjọ Ètò Ẹ̀kọ́, Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀, àti Àṣà Ìbílẹ̀ ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sọ pé: “Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé inú ọkàn àwọn èèyàn ni ogun ti ń bẹ̀rẹ̀, ọkàn wọn náà la gbọ́dọ̀ dá lẹ́kọ̀ọ́ kí àlàáfíà tó ó lè wà.” Ẹlẹ́dàá wa mọ̀ dájú pé àwọn èèyàn gbọ́dọ̀ yí bí wọ́n ṣe ń ronú padà. Wòlíì yìí kan náà sọ ohun tó máa mú kí gbogbo èèyàn lórí ilẹ̀ ayé lè máa gbé nínú ààbò lọ́jọ́ kan pé: “Wọn kì yóò ṣe ìpalára èyíkéyìí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò fa ìparun èyíkéyìí ní gbogbo òkè ńlá mímọ́ mi; nítorí pé, ṣe ni ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.”—Aísáyà 11:9.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti mọ̀ ní tiwọn pé níní ìmọ̀ Jèhófà lè ṣẹ́pá ẹ̀tanú àti ìkórìíra. Nínú iṣẹ́ ìwàásù wọn tí wọ́n ń ṣe yíká ayé, wọ́n ń gbìyànjú láti máa fi ìlànà Ìwé Mímọ́ kọ́ gbogbo èèyàn, èyí tó ń gbin ìfẹ́ síni lọ́kàn dípò ìkórìíra, kódà láwọn orílẹ̀-èdè tí ogun ti ṣe báṣubàṣu pàápàá. Wọ́n tún ńṣe ìrànwọ́ èyíkéyìí tí agbára wọn ká fún àwọn olùwá-ibi-ìsádi.
Àmọ́ o, wọ́n mọ̀ pé ọwọ́ Jésù Kristi, Ọba tí Ọlọ́run ti yàn náà ni ojútùú gidi sí ìṣòro àwọn olùwá-ibi-ìsádi wà. Dájúdájú, ó mọ bí ìkórìíra àti ìwà ipá ṣe lè tètè bá ìgbésí ayé àwọn èèyàn jẹ́. Bíbélì mú un dá wa lójú pé Jésù yóò fi òdodo ṣe ìdájọ́ àwọn ẹni rírẹlẹ̀. (Aísáyà 11:1-5) Lábẹ́ àkóso rẹ̀ láti ọ̀run wá, ìfẹ́ Ọlọ́run á di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé, gẹ́gẹ́ bíi ti ọ̀run. (Mátíù 6:9, 10) Nígbà tí àkókò yẹn bá dé, kò ní sí ìdí fún ẹnì kankan láti máa wá ibi ìsádi mọ́. Gbogbo èèyàn ló sì máa ni ibi tí wọ́n á lè pè ní ilé wọn.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 4]
Báwo La Ṣe Lè Yanjú Ìṣòro Àwọn Olùwá-Ibi-Ìsádi?
“Yíyanjú ìṣòro àwọn èèyàn tí wọ́n ń sá fi ìlú wọn sílẹ̀, yálà àwọn tó ń sá lọ sí orílẹ̀-èdè míì ni o tàbí láàárín orílẹ̀-èdè wọn níbẹ̀, ju wíwulẹ̀ pèsè ààbò àti ìrànwọ́ onígbà kúkúrú fún wọn lọ. Ó jẹ́ kíkọ́kọ́ wá ojútùú sí inúnibíni, ìwà ipá àti wàhálà tó ń fa sísá kúrò nílùú. Ó jẹ́ fífún àwọn èèyàn ní ẹ̀tọ́ wọn láti gbádùn àlàáfíà, ààbò, àti iyì, lọ́kùnrin, lóbìnrin àti lọ́mọdé láìsí pé wọ́n ń sá kúrò nínú ilé wọn.”—The State of the World’s Refugees 2000.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ojútùú Wo Ni Ìjọba Ọlọ́run Ń Mú Bọ̀?
“Dájúdájú, ìdájọ́ òdodo yóò sì máa gbé aginjù, àní òdodo yóò sì máa gbé inú ọgbà igi eléso. Iṣẹ́ òdodo tòótọ́ yóò sì di àlàáfíà; iṣẹ́ ìsìn òdodo tòótọ́ yóò sì di ìdákẹ́jẹ́ẹ́ àti ààbò fún àkókò tí ó lọ kánrin. Àwọn ènìyàn mi yóò sì máa gbé ní ibi gbígbé tí ó kún fún àlàáfíà àti ní àwọn ibùgbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìgbọ́kànlé àti ní àwọn ibi ìsinmi tí kò ní ìyọlẹ́nu.”—Aísáyà 32:16-18.