Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ewu Wo Ló Wà Nínú Títojúbọ Ìbẹ́mìílò?

Ewu Wo Ló Wà Nínú Títojúbọ Ìbẹ́mìílò?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Ewu Wo Ló Wà Nínú Títojúbọ Ìbẹ́mìílò?

ṢÉ ÒÓTỌ́ ni pé àwọn ọ̀dọ́langba nífẹ̀ẹ́ sí ìbẹ́mìílò? Àwùjọ àwọn olùwádìí kan gbìyànjú láti mọ òótọ́ ibẹ̀ nípa fífọ̀rọ̀ wá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lẹ́nu wò ní iléèwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti ti girama márùndínlọ́gọ́fà [115]. Ohun tí ìwádìí náà fi hàn nìyí: Ó lé ní ìdajì lára àwọn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò (ìdá mẹ́rìnléláàádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún) tó sọ pé àwọn nífẹ̀ẹ́ sí ìbẹ́mìílò tí ìdá kan nínú mẹ́rin (ìdá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún) sì sọ pé àwọ́n “nífẹ̀ẹ́ sí i gan-an ni.”

Àwọn olùwádìí ní Yunifásítì Alaska ní ìlú Anchorage kọ̀wé pé: “Ohun tó ń jáde nínú àwọn ìwé ìròyìn nípa bí iṣẹ́ burúkú ọwọ́ àwọn ẹgbẹ́ tó ń jọ́sìn Sátánì ṣe túbọ̀ ń gogò sí i . . . ti wá pọ̀ gan-an láwọn ọdún àìpẹ́ yìí.” Àmọ́, àwọn ògbógi sọ pé ẹ̀rí tó ṣe gúnmọ́ kò fi bẹ́ẹ̀ sí láti ti èrò náà lẹ́yìn pé ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ọ̀dọ́ ló ń lọ́wọ́ nínú ìjọsìn Sátánì. Síbẹ̀, a ò lè jiyàn rẹ̀ pé ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló nífẹ̀ẹ́ sí àwọn apá kan nínú ìjọsìn Sátánì àti ìbẹ́mìílò, àmọ́ ṣá o, ìfẹ́ náà lè má pọ̀.

Àwọn ọ̀dọ́ kan lè wá béèrè pé, ‘Kí ló burú nínú títojúbọ ìbẹ́mìílò?’ Láti lè rí ìdáhùn, ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà táwọn ọ̀dọ́ ń gbà tojú bọ ìbẹ́mìílò.

Ìdí Tí Ìbẹ́mìílò Fi Ń Fà Wọ́n Mọ́ra

Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn U.S. News & World Report sọ pé “àwọn ọmọdé àtàwọn ọ̀dọ́langba òde òní máa ń ní onírúurú àwòrán àti ìsọfúnni tí ń kó ìdààmú báni níkàáwọ́, èyí téèyàn ò lè ronú kàn rárá ní ogún ọdún sẹ́yìn.” Ojúmìító ló máa ń sún ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ka àwọn ìwé àti ìwé ìròyìn tó dá lórí ìbẹ́mìílò, kí wọ́n máa wò ó nínú fídíò tàbí kí wọ́n máa wá àwọn ìsọfúnni tó jẹ mọ́ ọn kiri lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn kan láti iléeṣẹ́ Ìròyìn BBC ṣe sọ, àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ gbígbajúmọ̀ lórí tẹlifíṣọ̀n, èyí tó ní í ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ àjẹ́ àti kí òkú máa gbé agọ̀ èèyàn wọ̀ máa “ń jẹ́ kí àwọn ọmọdé nífẹ̀ẹ́ sí àjẹ́ ṣíṣe.” Àwọn orin onílù dídún kíkankíkan kan tún máa ń ní ọ̀rọ̀ ìpáǹle àti ti ẹlẹ́mìí èṣù nínú. Akọ̀ròyìn Tom Harpur kọ ọ́ nínú ìwé ìròyìn ìlú Toronto náà, The Sunday Star pé: “Mo gbọ́dọ̀ ṣe ìkìlọ̀ tó lágbára nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ [nínú orin]. . . . Mi ò tíì rí nǹkan tó bà jẹ́ bàlùmọ̀ tó bẹ́ẹ̀ rí. Ìsínwín, nínífẹ̀ẹ́ nǹkan lódìlódì, ẹ̀mí èṣù, ìtàjẹ̀sílẹ̀, èpè, ìwà ipá lóríṣiríṣi, títí kan fífipá-báni-lòpọ̀, gígéra-ẹni lọ́bẹ, ìpànìyàn àti fífọwọ́ ara ẹni para ẹni ló kún inú àwọn orin náà. Àwọn ẹṣin ọ̀rọ̀ wọn ni, ikú àti ìparun, àsọtẹ́lẹ̀ ègbé, bíbẹnu àtẹ́ lu gbogbo ohun tó dára àti títẹ́wọ́ gba gbogbo ohun tó burú, tó bògìrì, tó sì jẹ́ ibi.”

Ṣé òótọ́ ni pé títẹ́tí sí irú àwọn orin bẹ́ẹ̀ lè mú kéèyàn ṣìwà hù? Bẹ́ẹ̀ ni, ó kéré tan nínú ọ̀ràn kan, ìyẹn ti ọmọ ọdún mẹ́rìnlá kan tó gún ìyá rẹ̀ lọ́bẹ pa ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà tó sì pa ara rẹ̀ lẹ́yìn náà. Ńṣe ló lẹ àwòrán àwọn olórin onílù dídún kíkankíkan mọ́ gbogbo ara ògiri iyàrá rẹ̀. Bàbá rẹ̀ sọ lẹ́yìn ìgbà náà pé: “Ẹ sọ fún àwọn òbí pé kí wọ́n máa ṣọ́ irú orin táwọn ọmọ wọn ń gbọ́.” Ó sọ pé ọ̀sẹ̀ kan ṣáájú ìgbà tí ọmọ òun pa ìyá rẹ̀, orin rọ́ọ̀kì tó ń sọ nípa “ẹ̀jẹ̀ àti pé kéèyàn pa ìyá rẹ̀” ló ń kọ ṣáá.

Àwọn eré ìdárayá orí kọ̀ǹpútà kan tún wà nínú èyí téèyàn ti lè kó ipa tó bá wù ú, àwọn kan nínú wọn sì fún àwọn olùkópa láyè láti ṣe bí oṣó tàbí ọmọ ẹgbẹ́ mìíràn nínú ìbẹ́mìílò. Púpọ̀ eré yìí ló jẹ́ pé ìwà ipá ẹlẹ́mìí èṣù ni wọ́n ń gbé yọ. a

Síbẹ̀, àjọ olùwádìí ti Mediascope ròyìn pé: “Àwọn ìwádìí ti fi hàn pé yíyan orin onílù dídún kíkankíkan láàyò lé jẹ́ kókó ohun tó ń fa yíya-ara-ẹni-sọ́tọ̀, lílo oògùn olóró, kí ọpọlọ dàrú, gbígbìyànjú láti para ẹni . . . tàbí híhu àwọn ìwà tó lè gbẹ̀mí èèyàn nígbà ọ̀dọ́langba, àmọ́ orin lásán kọ́ ló ń fa àwọn ìṣesí yìí. Àwọn kan gbà pé, àwọn ọ̀dọ́langba tí àwọn ìṣòro yẹn ti ń bá fínra tẹ́lẹ̀ lè bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ sí orin onílù dídún kíkankíkan, nítorí pé ohun tó ń yọ wọ́n lẹ́nu gan-an ni àwọn ọ̀rọ̀ orin náà gbé jáde.”

Ẹnu àwọn olùwádìí lè má kò nípa àwọn ewu tó wà nínú gbígbọ́ àwọn orin elèṣù. Àmọ́ ṣé títẹ́tí sí orin tó dá lórí ìwà ipá àti bíba ayé ara ẹni jẹ́ nígbà gbogbo, wíwò wọ́n nínú fídíò àti ṣíṣe àwọn eré ìdárayá tó jẹ mọ́ ọn kò wá ní ṣe ìpalára kankan fún èèyàn? Fún àwọn Kristẹni, títojúbọ ìbẹ́mìílò tiẹ̀ tún ní ewu tó jùyẹn lọ nínú.

Ojú Tí Ọlọ́run Fi Ń Wo Bíbá Ẹ̀mí Lò

1 Kọ́ríńtì 10:20, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fún àwọn Kristẹni pé: “Èmi kò sì fẹ́ kí ẹ di alájọpín pẹ̀lú àwọn ẹ̀mí èṣù.” Àwọn wo tiẹ̀ làwọn ẹ̀mí èṣù, ìdí wo ló sì fi léwu gan-an láti ní àjọṣe kankan pẹ̀lú wọn? Ní ṣókí, àwọn ẹ̀mí èṣù làwọn tó jẹ́ áńgẹ́lì tẹ́lẹ̀ rí tí wọ́n wá yàn láti tọ Sátánì Èṣù lẹ́yìn. Sátánì túmọ̀ sí “Alátakò” tí Èṣù sì túmọ̀ sí “Afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́.” Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, áńgẹ́lì tó jẹ́ ọmọ Ọlọ́run nígbà kan rí yìí sọ ara rẹ̀ di alátakò àti afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́ nípa yíyàn láti ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. Bí àkókò ti ń lọ, ó tan àwọn áńgẹ́lì mìíràn láti dára pọ̀ mọ́ ọn nínú ìwà ọ̀tẹ̀ rẹ̀. Àwọn alájọṣe rẹ̀ yìí sì tipa bẹ́ẹ̀ di ẹ̀mí èṣù.—Jẹ́nẹ́sísì 3:1-15; 6:1-4; Júúdà 6.

Jésù pe Sátánì ní “olùṣàkóso ayé yìí.” (Jòhánù 12:31) Inú “ìbínú ńlá” ni Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ wà nítorí ìparun wọn tó ti sún mọ́lé. (Ìṣípayá 12:9-12) Abájọ tí àwọn tó ti ní àjọṣe pẹ̀lú àwọn ẹ̀mí èṣù fi rí i pé òǹrorò ni wọ́n. Obìnrin kan láti ilẹ̀ Suriname tó dàgbà nínú ìdílé tí wọ́n ti ń bá ẹ̀mí lò fojú ara rẹ̀ rí bí àwọn ẹ̀mí èṣù ṣe máa “ngbadun dídá àwọn ẹran-ìjẹ wọn tí wọn fi agbara mú lóró.” b Èyí fi hàn pé níní àjọṣe lọ́nà èyíkéyìí pẹ̀lú àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí rírorò yìí léwu gidigidi!

Èyí ló mú kí Ọlọ́run pa á láṣẹ fún àwọn èèyàn rẹ̀ ìgbàanì, ìyẹn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, láti yẹra fún gbogbo àṣà ìbẹ́mìílò. Diutarónómì 18:10-12 kìlọ̀ pé “gbogbo àwọn tí ń ṣe nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà.” Bákan náà ni a tún kìlọ̀ fún àwọn Kristẹni pé, ìparun láti ọwọ́ Ọlọ́run ló máa kẹ́yìn “àwọn tí ń bá ẹ̀mí lò.” (Ìṣípayá 21:8) Kódà, Ọlọ́run dá títojúbọ ìbẹ́mìílò lẹ́bi. Bíbélì pàṣẹ pé ‘ẹ jáwọ́ nínú fífọwọ́kan ohun àìmọ́.’—2 Kọ́ríńtì 6:17.

Bó O Ṣe Lè Yọwọ́yọsẹ̀ Nínú Àṣà Ìbẹ́mìílò

Ṣé o ti ṣèèṣì lọ lọ́wọ́ nínú ìbẹ́mìílò? Ó dáa, wo ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ìlú Éfésù ti ọ̀rúndún kìíní. Ọ̀pọ̀ àwọn tó wà níbẹ̀ ló ń “fi idán pípa ṣiṣẹ́ ṣe.” Àmọ́ iṣẹ́ agbára tí Pọ́ọ̀lù ń ṣe pẹ̀lú ìrànwọ́ ẹ̀mí mímọ́ wú àwọn kan lórí. Kí ni àbájáde rẹ̀? “Ọ̀pọ̀ lára àwọn tí wọ́n fi idán pípa ṣiṣẹ́ ṣe, kó àwọn ìwé wọn pa pọ̀, wọ́n sì dáná sun wọ́n níwájú gbogbo ènìyàn. Wọ́n sì ṣe àròpọ̀ iye owó wọn, wọ́n sì rí i pé wọ́n tó ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ẹyọ fàdákà. Nípa báyìí, ọ̀rọ̀ Jèhófà ń bá a nìṣó ní gbígbilẹ̀ àti ní bíborí lọ́nà tí ó ní agbára ńlá.”—Ìṣe 19:11-20.

Kí ni èyí ń sọ fún wa? Pé tí ẹnì kan bá fẹ́ bọ́ nínú páńpẹ́ àwọn ẹ̀mí èṣù, ẹni náà gbọ́dọ̀ pa gbogbo ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn Sátánì run! Èyí kan gbogbo ìwé, ìwé ìròyìn, àwòrán ara ògiri, àwọn ìwé àkàrẹ́rìn-ín, fídíò, oògùn ìṣọ́ra (àwọn oògùn táwọn kan ń wọ̀ fún “ààbò”), àti àwọn ìsọfúnni ẹlẹ́mìí èṣù téèyàn gbà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. (Diutarónómì 7:25, 26) Kó gbogbo nǹkan tó o lè máa lò fún iṣẹ́ wíwò dànù, àwọn nǹkan bíi bọ́ọ̀lù kírísítálì àti ọpọ́n ìwoṣẹ́. Bákan náà, da àwọn orin àti fídíò tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn Sátánì sígbó.

Ìgboyà àti ìpinnu tó ga ló ń béèrè láti gbé irú ìgbésẹ̀ àìṣojo bẹ́ẹ̀. Àmọ́ àwọn àǹfààní tí wàá rí níbẹ̀ kì í ṣe kékeré o. Kristẹni obìnrin kan tó ń jẹ́ Jean c ra eré ìdárayá orí kọ̀ǹpútà kan tó dà bíi pé kò léwu rárá níbẹ̀rẹ̀. Bó ṣe ń lọ láti ìpele kan sí òmíràn nínú eré náà, ó rí àwọn apá kan nínú rẹ̀ tó ń sọ nípa ìbẹ́mìílò. Kò pẹ́ kò jìnnà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í lá àlá burúkú! Jean sọ pé: “Àárín òru ni mo dìde tí mo sì kó àwọn àwo eré ìdárayá náà dà nù.” Kì ni àbájáde rẹ̀? Ó sọ pé: “Mi ò ní ìdààmú kankan mọ́ látìgbà yẹn.”

Tó o bá fi hàn lóòótọ́ pé o fẹ́ ja àjàbọ́, á ṣeé ṣe fún ẹ. Rántí bí Jésù kò ṣe gba gbẹ̀rẹ́ nígbà tí Èṣù gbìyànjú láti tàn án jẹ́ kó lè jọ́sìn òun. “Jésù wí fún un pé: ‘Kúrò lọ́dọ̀ mi, Sátánì! Nítorí a kọ̀wé rẹ̀ pé, “Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni ìwọ gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni ìwọ gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún.”’ Nígbà náà ni Èṣù fi í sílẹ̀.”—Mátíù 4:8-11.

Má Ṣe Dá Ìjà Náà Jà O

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rán wá létí pé gbogbo Kristẹni “ní gídígbò kan . . . lòdì sí àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú ní àwọn ibi ọ̀run.” (Éfésù 6:12) Àmọ́ má ṣe gbìyànjú láti bá Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ jà ní ìwọ nìkan. Ní kí àwọn òbí rẹ tí wọ́n jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run àtàwọn alàgbà tó wà nínú ìjọ Kristẹni tó wà ládùúgbò rẹ ràn ọ́ lọ́wọ́. Ó lè jẹ́ ohun ìtìjú fún ọ láti jẹ́wọ́ pé o ti ń lọ́wọ́ nínú ìbẹ́mìílò, àmọ́ ìyẹn ló máa jẹ́ kó o rí ìrànwọ́ tó o nílò lójú méjèèjì.—Jákọ́bù 5:14, 15.

Tún rántí pé Bíbélì sọ pé: “Ẹ kọ ojú ìjà sí Èṣù, yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín. Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.” (Jákọ́bù 4:7, 8) Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà Ọlọ́run lè tì ọ́ lẹ́yìn! Á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti bọ́ lọ́wọ́ ìdẹkùn bíbá ẹ̀mí lò.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Is There Any Danger in Role-Playing Games,?” nínú ìtẹ̀jáde Jí! ti August 22, 1999.

b Wo àpilẹ̀kọ náà, “Títaari Àjàgà Bíbá-Ẹ̀mí-Lò Kúrò,” èyí tó wà nínú ìtẹ̀jáde September 1, 1987 nínú ìwé ìròyìn wa kejì, Ilé Ìṣọ́, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.

c A ti yí orúkọ yẹn padà.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Kó gbogbo ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn Sátánì dà nù

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Ṣọ́ra fún àwọn ohun tó ń gbé ìbẹ́mìílò lárugẹ nínú Íńtánẹ́ẹ̀tì, lórí kọ̀ǹpútà