Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Ǹjẹ́ O Mọ̀?
(A lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí, a sì kọ àwọn ìdáhùn náà ní kíkún sí ojú ìwé 16. Fún àfikún ìsọfúnni, wo ìtẹ̀jáde “Insight on the Scriptures,” tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.)
1. Gẹ́gẹ́ bí Jákọ́bù ti sọ, kí làwọn àmì tó ń fi Kristẹni tòótọ́ hàn? (Jákọ́bù 1:27)
2. Èwo ló gbẹ̀yìn nínú àwọn ìyọnu àjàkálẹ̀ tó bá àwọn ará Íjíbítì, èyí tó mú kí wọ́n dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀? (Ẹ́kísódù 11:1, 5)
3. Àwọn ọ̀rọ̀ Gíríìkì wo la fi ń tọ́ka sí Jèhófà? (Ìṣípayá 1:8)
4. Èé ṣe tí Jèhófà kò fi tètè lé gbogbo àwọn tó ń gbé Ilẹ̀ Ìlérí náà kúrò nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì? (Ẹ́kísódù 23:29, 30)
5. Ohun mẹ́ta wo la ní kí Ráhábù ṣe ká bàa lè dá ẹ̀mí òun àti ìdílé rẹ̀ sí? (Jóṣúà 2:18-20)
6. Àrùn ara wo ni Sátánì fi hàn Jóòbù léèmọ̀? (Jóòbù 2:7, 8)
7. Kí ló mú Sákéù lọ gun igi ọ̀pọ̀tọ́ mọ́líbẹ́rì? (Lúùkù 19:3, 4)
8. Ẹ̀gbọ́n ọkùnrin mélòó ni Dáfídì ní? (1 Kíróníkà 2:15)
9. Báwo ni ọbabìnrin Ṣébà ṣe dán ọgbọ́n Sólómọ́nì wò? (1 Ọba 10:1)
10. Ọ̀rọ̀ Hébérù wo là ń lò fún “Olúwa”? (Jẹ́nẹ́sísì 15:2)
11. Àmì wo la sọ pé tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù bá ti rí kí wọ́n sá lọ sí Jùdíà? (Máàkù 13:14)
12. Kí ló mú ká lè ní ìrètí lóòótọ́ pé a máa ní ìyè àìnípẹ̀kun? (Títù 1:2)
13. Kí ni wọ́n fi ṣe àpótí tí wọ́n gbé ọmọ ọwọ́ náà Mósè sínú rẹ̀? (Ẹ́kísódù 2:3)
14. Ohun èlò wo tó jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo la dárúkọ rẹ̀ nínú Bíbélì ni wọ́n fi kọrin nígbà tí wọ́n ń ṣayẹyẹ gbígbé tí wọ́n gbé Àpótí náà lọ sí Jerúsálẹ́mù? (2 Sámúẹ́lì 6:5)
15. Nínú ìgbòkègbodò ìwàásù rẹ̀ tó gbẹ̀yìn ní Jùdíà, ọmọ ẹ̀yìn mélòó ni Jésù rán lọ kóun fúnra rẹ̀ tó ó lọ? (Lúùkù 10:1)
16. Kí làwọn Farisí ní lọ́kàn láti ṣe nígbà tí wọ́n ń da ìbéèrè bo Jésù? (Mátíù 22:15)
17. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí “orúkọ àwọn ẹni burúkú”? (Òwe 10:7)
Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè
1. ‘Pípa ara ẹni mọ́ láìní èérí kúrò nínú ayé,’ kéèyàn sì máa gba tàwọn tí ọkọ tàbí àwọn òbí wọn ti ṣaláìsí rò
2. Ikú gbogbo àkọ́bí, látorí èèyàn dórí ẹranko
3. Álífà àti Ómégà
4. Kí àwọn ẹranko má bàa di púpọ̀ débi tí wọ́n á fi ṣe wọ́n ní jàǹbá ní ilẹ̀ tó dahoro láìròtẹ́lẹ̀
5. Kí ó kó gbogbo ìdílé rẹ̀ sínú ilé rẹ̀, kó so okùn rírẹ̀-dòdò kan mọ́ fèrèsé rẹ̀ kí ó má sì sọ nípa ìbẹ̀wò àwọn amí náà fún ẹnikẹ́ni
6. Oówo afòòró-ẹ̀mí látorí lọ dé àtẹ́lẹsẹ̀
7. Bó ṣe kéré ní ìrísí kò jẹ́ kó lè rí Jésù
8. Mẹ́fà
9. Ó béèrè àwọn “ìbéèrè apinnilẹ́mìí” lọ́wọ́ rẹ̀
10. Adonay [tàbí Adhonai]
11. “Ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro tí ó dúró níbi tí kò yẹ”
12. Ọlọ́run ló ṣèlérí rẹ̀, kò sì lè parọ́
13. Òrépèté
14. Sítírọ́mù
15. Àádọ́rin (méjìméjì ni wọ́n lọ́nà márùndínlógójì)
16. “Láti dẹ pańpẹ́ mú un nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀”
17. Ó máa “jẹrà” téèyàn ò sì ní rí i mọ́