Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ta Ni Máíkẹ́lì Olú-Áńgẹ́lì Náà?

Ta Ni Máíkẹ́lì Olú-Áńgẹ́lì Náà?

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ta Ni Máíkẹ́lì Olú-Áńgẹ́lì Náà?

GẸ́GẸ́ bí Bíbélì ṣe sọ, àìmọye mílíọ̀nù àwọn áńgẹ́lì ló wà ní ilẹ̀ ọba ẹ̀mí. (Dáníẹ́lì 7:9, 10; Ìṣípayá 5:11) Láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin Ìwé Mímọ́ la ti tọ́ka sí àwọn áńgẹ́lì tí wọ́n dúró ṣinṣin sọ́dọ̀ Ọlọ́run. Síbẹ̀, méjì péré lára àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí yìí la dárúkọ wọn. Ọ̀kan ni áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì, ẹni tó lé ní ẹgbẹ̀ta ọdún tó fi jíṣẹ́ Ọlọ́run fún àwọn èèyàn mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. (Dáníẹ́lì 9:20-22; Lúùkù 1:8-19, 26-28) Èkejì tá a tún dárúkọ rẹ̀ nínú Bíbélì ni Máíkẹ́lì.

Ó ṣe kedere pé áńgẹ́lì tó tayọ àwọn tó kù ni Máíkẹ́lì jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, nínú ìwé Dáníẹ́lì, a sọ pé Máíkẹ́lì bá àwọn ẹ̀mí búburú wọ̀yá ìjà nítorí àwọn èèyàn Jèhófà. (Dáníẹ́lì 10:13; 12:1) Nínú lẹ́tà onímìísí tí Júúdà kọ, awuyewuye kan wáyé láàárín Máíkẹ́lì àti Sátánì lórí òkú Mósè. (Júúdà 9) Ìwé Ìṣípayá fi hàn pé Máíkẹ́lì bá Sátánì àtàwọn ìsọ̀ǹgbè rẹ̀ jagun ó sì lé wọn kúrò ní òkè ọ̀run. (Ìṣípayá 12:7-9) Kò sí áńgẹ́lì mìíràn tá a tún sọ pé ó ní irú agbára ńlá bẹ́ẹ̀ tó sì tún ní àṣẹ lórí àwọn ọ̀tá Ọlọ́run. Kò yani lẹ́nu nígbà náà pé Bíbélì pe Máíkẹ́lì ní “olú-áńgẹ́lì.” Ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ náà “olú” túmọ̀ sí “olórí,” tàbí “ọ̀gá.”

Àríyànjiyàn Nípa Ẹni Tí Máíkẹ́lì Jẹ́

Èrò tí ọ̀pọ̀ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, ìsìn àwọn Júù àtàwọn ẹlẹ́sìn Ìsìláàmù ní lórí ọ̀rọ̀ áńgẹ́lì kò bára wọn mu rárá. Àwọn àlàyé mìíràn kì í tiẹ̀ yé èèyàn rárá. Bí àpẹẹrẹ, The Anchor Bible Dictionary sọ pé: “Ó ṣeé ṣe kí áńgẹ́lì kan wà tó máa jẹ́ olórí gbogbo àwọn tó kù/tàbí kí àwọn tó jẹ́ olú-áńgẹ́lì tó bíi mélòó kan (wọ́n sábà máa ń jẹ́ mẹ́rin tàbí méje).” The Imperial Bible-Dictionary sọ pé, Máíkẹ́lì jẹ́ “orúkọ ẹnì kan tó lágbára ju ẹ̀dá ènìyàn lọ, èrò méjì tó ta kora làwọn èèyàn sì ń ní nípa ẹni yìí, pé bóyá òun ni Jésù Kristi Olúwa tó jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run, tàbí pé ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí wọ́n ń pè ní olú-áńgẹ́lì méje.”

Nínú ìgbàgbọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Júù, àwọn olú-áńgẹ́lì méje wọ̀nyí ni Gébúrẹ́lì, Jérémíẹ́lì, Máíkẹ́lì, Rágúélì, Ráfẹ́lì, Sáríélì àti Úríélì. Àmọ́ ṣá, olú-áńgẹ́lì mẹ́rin ni ẹ̀sìn Ìsìláàmù gbà gbọ́ pé ó wà, orúkọ wọn ni Jìbìrílà, Míkáílà, Ìsíráílà, àti Ìsìràfílà. Ẹ̀sìn Kátólíìkì náà gbà gbọ́ nínú olú-áńgẹ́lì mẹ́rin, àwọn ni: Máíkẹ́lì, Gébúrẹ́lì, Ráfẹ́lì àti Úríẹ́lì. Kí lohun tí Bíbélì sọ? Ṣé ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ olú-áńgẹ́lì ló wà?

Ìdáhùn Bíbélì

Bá a bá ti yọwọ́ Máíkẹ́lì, kò sí olú-áńgẹ́lì mìíràn tá a tún dárúkọ rẹ̀ nínú Bíbélì, Ìwé Mímọ́ kò sì lo ọ̀rọ̀ náà “olú-áńgẹ́lì” lọ́nà tó fi hàn pé wọ́n ju ẹyọ kan lọ. Bíbélì pe Máíkẹ́lì ní olú-áńgẹ́lì náà, tó fi hàn pé òun nìkan ló ń jẹ́ orúkọ yẹn. Ìdí rèé téèyàn ò fi kùnà bó bá sọ pé Jèhófà Ọlọ́run ti fún ọ̀kan péré lára àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀ tó wà lọ́run láṣẹ láti jẹ́ olórí fún gbogbo àwọn áńgẹ́lì tó kù.

Yàtọ̀ sí Ẹlẹ́dàá fúnra rẹ̀, ẹnì kan ṣoṣo péré tó jẹ́ olóòótọ́ tá a tún mẹ́nu kàn pé ó jẹ́ olórí fún àwọn áńgẹ́lì ni Jésù Kristi. (Mátíù 13:41; 16:27; 24:31) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù dárúkọ “Jésù Olúwa” ní pàtó, ó tún dárúkọ “àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ alágbára.” (2 Tẹsalóníkà 1:7) Pétérù náà sì sọ nípa Jésù tá a jí dìde pé: “Ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, nítorí tí ó bá ọ̀nà rẹ̀ lọ sí ọ̀run; a sì fi àwọn áńgẹ́lì àti àwọn aláṣẹ àti àwọn agbára sábẹ́ rẹ̀.”—1 Pétérù 3:22.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò sí ibi tá a ti là á mọ́lẹ̀ nínú Bíbélì pé Jésù ni Máíkẹ́lì olú-áńgẹ́lì, ẹsẹ ìwé mímọ́ kan wà tó so iṣẹ́ Jésù pọ̀ mọ́ olú-áńgẹ́lì. Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Tẹsalóníkà, ó sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Olúwa fúnra rẹ̀ yóò sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run wá pẹ̀lú ìpè àṣẹ, pẹ̀lú ohùn olú-áńgẹ́lì àti pẹ̀lú kàkàkí Ọlọ́run, àwọn tí ó kú ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi ni yóò sì kọ́kọ́ dìde.” (1 Tẹsalóníkà 4:16) Nínú ẹsẹ ìwé mímọ́ yìí, a sọ pé Jésù gba agbára gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà Ọba tí Ọlọ́run yàn. Síbẹ̀, “ohùn olú-áńgẹ́lì” ló fi ń sọ̀rọ̀. Tún kíyè sí i pé ó ní agbára láti jí òkú dìde.

Nígbà tí Jésù wà láyé bí ẹ̀dá ènìyàn, ó jí àwọn òkú mélòó kan dìde. Pẹ̀lú èyí, gbogbo ohun tó fi ohùn rẹ sọ ló ń rí bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó ń jí ọmọ opó kan dìde ní ìlú Náínì, ó sọ pé: “Ọ̀dọ́kùnrin, mo wí fún ọ, Dìde!” (Lúùkù 7:14, 15) Lẹ́yìn ìyẹn, nígbà tí Jésù fẹ́ jí ọ̀rẹ́ rẹ̀ Lásárù dìde, ó “ké jáde ní ohùn rara pé: ‘Lásárù, jáde wá!’” (Jòhánù 11:43) Àmọ́ láwọn àkókò wọ̀nyí, ohùn ẹ̀dá èèyàn pípé ni ohùn Jésù.

Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, a gbé e “sí ipò gíga” ní ọ̀run gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí. (Fílípì 2:9) Ní báyìí tí kì í ṣe ẹ̀dá èèyàn mọ́, ohùn rẹ̀ ti di ti olú-áńgẹ́lì. Nítorí náà, nígbà tí kàkàkí Ọlọ́run pe ìpè fún “àwọn tí ó kú ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi” láti jí wọn dìde sí ọ̀run, Jésù ló pe “ìpè àṣẹ,” “ohùn olú-áńgẹ́lì” ló sì fi sọ̀rọ̀. Ó bọ́gbọ́n mu láti sọ pé olú-áńgẹ́lì nìkan ló lè fi “ohùn olú-áńgẹ́lì” sọ̀rọ̀.

Lóòótọ́, àwọn áńgẹ́lì mìíràn tún wà tí ipò wọn ga, irú bí àwọn séráfù àtàwọn kérúbù. (Jẹ́nẹ́sísì 3:24; Aísáyà 6:2) Síbẹ̀, Jésù Kristi tá a jí dìde ni Ìwé Mímọ́ tọ́ka sí pé òun ni olórí gbogbo àwọn áńgẹ́lì, ìyẹn Máíkẹ́lì olú-áńgẹ́lì náà.