Wíwá Ibi Tí Wọ́n Lè Fi Ṣe Ilé
Wíwá Ibi Tí Wọ́n Lè Fi Ṣe Ilé
“Bó ti wù kó kéré tó, ilé ẹni ni ilé ẹni.”—John Howard Payne.
OGUN ló kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀, ó jà jà jà kò tán. Ọ̀dá tún tẹ̀ lé e, ìyẹn náà kọ̀ kò dá. Kò pẹ́ lẹ́yìn rẹ̀ ni ìyàn dé. Làwọn èèyàn bá ṣe ohun kan ṣoṣo tó kù tí wọ́n lè ṣe, wọ́n fi ilé wọn sílẹ̀ láti wá omi, oúnjẹ àti iṣẹ́ lọ.
Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ni wọ́n ń ya dé ẹnubodè. Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, mílíọ̀nù kan àwọn olùwá-ibi-ìsádi ni wọ́n fún láàyè láti wọ orílẹ̀-èdè míì, àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nítòsí sì ti wá yarí báyìí pé àwọn ò gba èèyàn kankan mọ́. Àwọn aṣọ́bodè tó mú kóńdó lọ́wọ́ kò sì jẹ́ kí ẹnì kankan ráyè wọlé.
Òṣìṣẹ́ kan tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn tó ń wọ̀lú sojú abẹ níkòó lórí ohun tó fà á táwọn fi dá yíya tí àwọn olùwá-ibi-ìsádi ń ya wọ̀lú náà dúró. Ó sọ pé: “Wọn kì í sanwó orí. Ńṣe ni wọ́n máa ń ba títì jẹ́. Wọ́n á gé àwọn igi lulẹ̀. Gbogbo omi ni wọ́n máa lò tán pátá. Rárá o, a ò gbà mọ́.” a
Ńṣe ni irú àwọn ìṣòro bí èyí túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Àwọn èèyàn tí wọ́n ń sá kúrò nílùú ń rí i pé rírí ibi tí wọ́n máa fi ṣe ilé túbọ̀ ń nira sí i. Ìròyìn kan tó wá látọ̀dọ̀ Àjọ Abẹ̀bẹ̀ fún Ìdáríjì Lágbàáyé láìpẹ́ yìí sọ pé: “Bí àwọn èèyàn tó ń wá ààbò ṣe ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ náà làwọn orílẹ̀-èdè túbọ̀ ń lọ́ra láti pèsè ààbò fún wọn.”
Àwọn tó ṣeé ṣe fún láti dé àgọ́ olùwá-ibi-ìsádi lè rí ààbò gbà-á-bẹ́ẹ̀-bẹ́ẹ̀, àmọ́ ekukáká ló fi lè dà bí ilé. Bí ipò nǹkan sì ṣe máa ń rí nínú àwọn àgọ́ náà lè máà bójú mu rárá.
Bí Ìgbésí Ayé Ṣe Ń Rí Nínú Àgọ́ Àwọn Olùwá-Ibi Ìsádi
Olùwá-ibi-ìsádi ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà kan dárò pé: “O lè kú ikú ìbọn [nílé], àmọ́ níbí [nínú àgọ́ àwọn olùwá-ibi-ìsádi], ebi ló máa pa àwọn ọmọ rẹ kú.” Gẹ́gẹ́ bí bàbá tí ọ̀rọ̀ sú yìí ti sọ, ọ̀pọ̀ àgọ́ ni àìsí oúnjẹ àti omi tó tó ń bá fínra, títí kan àìsí ìmọ́tótó àti àìrí ibi tó dára láti sùn. Àwọn ohun tó fà á kò ṣòro láti mọ̀ o. Àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, táwọn alára ṣì ń tiraka láti bọ́ àwọn èèyàn wọn lè ṣàdédé rí i tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn olùwá-ibi-ìsádi dé sí sàkání wọn. Kò sí ìrànlọ́wọ́ kan tó mọ́yán lórí tí wọ́n lè ṣe fún omilẹgbẹ èèyàn tó ṣàdédé ń wá ọ̀nà láti wọ orílẹ̀-èdè wọn yìí. Àwọn orílẹ̀-èdè ọlọ́rọ̀ sì rèé, tí ìṣòro tiwọn gan-an tó wọn lẹ́rù lè máa lọ́ra láti ran àwọn olùwá-ibi-ìsádi tí wọ́n wà láwọn orílẹ̀-èdè míì lọ́wọ́.
Nígbà táwọn èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù méjì sá kúrò ní orílẹ̀-èdè kan ní Áfíríkà lọ́dún 1994, àwọn àgọ́ olùwá-ibi-ìsádi tí wọ́n sáré kọ́ bàràbàrà kò ní omi àti ìmọ́tótó tó yẹ. Fún ìdí yìí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ni kọ́lẹ́rà pa kí wọ́n tó kápá rẹ̀. Ohun tó wá mú ọ̀rọ̀ ọ̀hún burú sí i ni pé, àwọn tí wọ́n di nǹkan ìjà mọ́ra dàpọ̀ mọ́ àwọn aráàlú tó ń wá ààbò, kíá ni wọ́n sì já iṣẹ́ pínpín àwọn nǹkan ìrànwọ́ gbà. Kì í ṣe ibí yìí nìkan ni irú ìṣòro yìí ti wáyé. Ìròyìn kan látọ̀dọ̀ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sọ pé: “Bí àwọn ọ̀daràn tó ní nǹkan ìjà lọ́wọ́ ṣe máa ń wà láàárín àwọn olùwá-ibi-ìsádi ti túbọ̀ fi àwọn èèyàn náà sínú ewu. Ó ti mú kí wọ́n má lè gba ara wọn sílẹ̀, tí jìnnìjìnnì bá wọn, tí wọ́n ń fòòró ẹ̀mí wọn, tí wọ́n sì ń fipá mú kí wọ́n lọ́wọ́ nínú ìjà.”
Àwọn aráàlú gan-an lè fara gbá nínú bí àwọn olùwá-ibi-ìsádi tí ebi ń pa ṣe ń ya wọ̀lú. Lágbègbè òkun Great Lakes ní Áfíríkà, àwọn òṣìṣẹ́ ọba kan ṣàròyé pé: “[Àwọn olùwá-ibi-ìsádi] ti rẹ́yìn oúnjẹ tá a ní nípamọ́, wọ́n ti pa àwọn oko wa, àwọn màlúù wa àtàwọn igbó wa run, wọ́n ti dá ìyàn sílẹ̀ wọ́n sì ti tan àrùn kálẹ̀ . . . [Wọ́n] ń rí ìrànwọ́ oúnjẹ gbà ní tiwọn, bẹ́ẹ̀ làwa kò sì rí nǹkankan gbà.”
Síbẹ̀, èyí tó burú jù nínú ìṣòro ọ̀hún ni pé, púpọ̀ àwọn àgọ́ tí wọ́n ṣe fúngbà díẹ̀ yìí ló máa ń di ibi táwọn olùwá-ibi-ìsádi á máa gbé títí lọ. Bí àpẹẹrẹ, ní orílẹ̀-èdè kan ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé, nǹkan bí ọ̀kẹ́ mẹ́wàá [200,000] àwọn olùwá-ibi-ìsádi ni wọ́n fún pa pọ̀ sínú àgọ́ kan tí wọ́n kọ́ fún ìdá mẹ́rin iye yẹn. Ọ̀kan lára wọn sọ pẹ̀lú ìbànújẹ́ pé: “A ò ní ibì kankan tá a lè forí lé.” Àwọn olùwá-ibi-ìsádi tó ti ń jìyà bọ̀ láti ọjọ́ pípẹ́ yìí máa ń kojú àìríṣẹ́ṣe tó burú jáì láwọn orílẹ̀-èdè tó gbà wọ́n tira, iye tí wọ́n sì fojú bù pé kò níṣẹ́ lọ́wọ́ nínú wọn tàbí tí iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe kò ní láárí á tó ìdá márùndínlọ́gọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún. Òṣìṣẹ́ kan tó ń bójú tó ọ̀ràn àwọn olùwá-ibi-ìsádi sọ pé: “Mi ò ní parọ́, bí [wọ́n] ṣe ń rọ́gbọ́n dá sí i kò yé mi.”
Àmọ́ tí ipò nǹkan bá burú tó báyìí nínú àgọ́ àwọn olùwá-ibi-ìsádi, ó lè bògìrì fún àwọn èèyàn tí wọ́n ń sá kúrò nílùú wọn àmọ́ tí wọn ò rọ́nà fi orílẹ̀-èdè wọn sílẹ̀.
Ìbànújẹ́ Tí Ṣíṣí Kúrò Nílùú Máa Ń Fà
Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Kọmíṣọ́nnà Àgbà fún Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tó wà fún Àwọn Olùwá-Ibi-Ìsádi sọ, “bí ìṣòro yìí ṣe tóbi tó àti bó ṣe gbòòrò tó, ìyà tó ń jẹ ẹ̀dá èèyàn, èyí tó jẹ́ orísun ìṣòro náà àti bó ṣe ń kó bá àlàáfíà àti ìfọ̀kànbalẹ̀ gbogbo àgbáyé ti mú kó di ọ̀ràn tó ń kó àwọn orílẹ̀-èdè sí àníyàn tó pàpọ̀jù.” Fún àwọn ìdí kan, àwọn èèyàn tí kò nílé lórí láàárín ìlú sábà máa ń jìyà ju àwọn olùwá-ibi-ìsádi lọ.
Kò sí àjọ kankan lágbàáyé tó bìkítà nípa àwọn èèyàn tí wọ́n ń sá kiri láàárín orílẹ̀-èdè wọn, bẹ́ẹ̀ làwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ dá sí ìyà tó ń jẹ wọ́n. Àwọn ìjọba wọn, tó jẹ́ pé wàhálà ọ̀rọ̀ ogun ni wọ́n gbájú mọ́ lè má ṣe tán láti dáàbò bò wọ́n tàbí kí wọ́n máà lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀. Gbogbo ìgbà làwọn ìdílé máa ń pín sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ níbi tí wọ́n bá ti ń sá kolobá kolobà kiri lágbègbè tí ogun ti ń gbóná janjan. Bó ṣe jẹ́ pé lọ́pọ̀ ìgbà, kò sí ohun mìíràn tí wọ́n lè ṣe ju kí wọ́n máa fẹsẹ̀ wọn rìn lọ, àwọn kan tó kúrò nílùú kì í rí òpin ìrìn-àjò yẹn wọn ò sì ní í dé ibi tí ààbò yẹn wà.
Inú àwọn ìlú ńlá ni ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n ṣí kúrò nílùú náà máa ń wá ààbò sí, níbi tí wọ́n ti máa ń gbé lábẹ́ àwọn ipò tó nira, ní àwọn àdúgbò tí kò bójú mu rárá tàbí nínú àwọn ilé táwọn èèyàn ti pa tì. Àwọn mìíràn máa ń kóra jọ sínú àwọn àgọ́ tí wọ́n ti sọ di ilé, tó jẹ́ pé nígbà míì, àwọn tó ní nǹkan ìjà lọ́wọ́ á wá kọ lù wọ́n níbẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, iye tó ń kú nínú wọn máa ń ju iye èèyàn èyíkéyìí mìíràn tó ń kú lórílẹ̀-èdè náà lọ.
Kódà, àwọn ìrànwọ́ tí wọ́n fi tinútinú pèsè láti dín ìyà àwọn èèyàn tó sá kúrò nílùú kù tún lè yọrí sí wàhálà mìíràn. Ìwé The State of the World’s Refugees 2000 sọ pé: “Láàárín ẹ̀wádún tó kẹ́yìn ní ọ̀rúndún ogún, àwọn àjọ aṣèrànwọ́-fún-ẹ̀dá tó wà láwọn orílẹ̀-èdè tí ogun ti fà ya dá ẹ̀mí ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn sí wọ́n sì ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti dín ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn kù. Síbẹ̀, ọ̀kan lára àwọn ẹ̀kọ́
pàtàkì tá a rí kọ́ ní ẹ̀wádún yìí ni pé, tí ìjà bá ń lọ lọ́wọ́, àwọn ẹgbẹ́ tó ń bára wọn jà lè bẹ̀rẹ̀ sí í lo àwọn nǹkan tí wọ́n fi ṣàánú àwọn èèyàn fún àǹfààní ti ara wọn, ó sì lè túbọ̀ mú kí ipò àwọn aláṣẹ tó ń tẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú náà lágbára sí i, bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ohun tí àwọn nǹkan náà wà fún nìyẹn. Bákan náà, àwọn nǹkan ìrànwọ́ táwọn àjọ tó ń ṣèrànwọ́ pèsè tún lè jẹ́ kóríyá fún ogun náà, tá á túbọ̀ jẹ́ kí ẹ̀mí ogun náà gùn sí i tí kò sì ní wá sópin bọ̀rọ̀.”Wíwá Ìgbésí Ayé Tó Sàn Kiri
Yàtọ̀ sáwọn olùwá-ibi-ìsádi àtàwọn èèyàn tó sá fi ìlú wọn sílẹ̀, ńṣe làwọn tó ń ṣí kúrò nílùú nítorí ipò ìṣúnná owó ń pọ̀ sí i. Ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń fa èyí. Ńṣe ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀ àtàwọn tó kúṣẹ̀ẹ́ túbọ̀ ń pọ̀ sí i, ojoojúmọ́ sì làwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí tẹlifíṣọ̀n ń fi ìgbésí ayé yọ̀tọ̀mì táwọn orílẹ̀-èdè kan ń gbé ṣe fọ́rífọ́rí fún àwọn èèyàn tó jẹ́ pé àwọn ló kúṣẹ̀ẹ́ jù lọ lágbàáyé. Ìrìn-àjò jákèjádò ayé kò tún fi bẹ́ẹ̀ ṣòro mọ́, bẹ́ẹ̀ làwọn ààlà ẹnubodè sì ti túbọ̀ rọrùn láti wọ̀. Ogun abẹ́lé àti kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ìran àti ti ìsìn tún ń fún àwọn èèyàn níṣìírí láti máa ṣí lọ sáwọn ilẹ̀ tó rọ́wọ́ mú ju tiwọn lọ.
Àmọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé pẹ̀lú ìrọ̀rùn làwọn kan máa ń wọ àwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà, àgàgà àwọn tó ní ẹbí níbẹ̀, àwọn mìíràn ti ba ìgbésí ayé ara wọn jẹ́. Ewu tó ń dojú kọ àwọn tó bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọ̀daràn tó ń jí èèyàn gbé tún kàmàmà. (Wo àpótí tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí.) Á dára kí ìdílé kan tó fẹ́ ṣí kúrò nílùú nítorí ìṣòro ìṣúnná owó gbé àwọn ewu yìí yẹ̀ wò dáadáa kí wọ́n tó ṣe bẹ́ẹ̀.
Lọ́dún 1996, ọkọ̀ ojú omi kan tó ti gbó dojú dé nínú Okun Mẹditaréníà, ọ̀rìn lé nígba [280] èèyàn ló sì rì sómi. Ará Íńdíà, Pakistan àti Sri Lanka làwọn èèyàn tó ń ṣí lọ yìí, owó tí wọ́n sì san tó ẹgbẹ̀rún mẹ́fà sí ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ dọ́là láti lè sọdá sí ilẹ̀ Yúróòpù. Kó tó di pé ọkọ̀ wọ́n rì, ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ ni wọ́n ti fi pa ebi àti òùngbẹ mọ́nú tí wọ́n sì ti ṣe wọ́n níṣekúṣe. Ìyọnu ni “ìrìn àjò lọ síbi tí aásìkí wà” náà kó wọn sí, ó sì jálẹ̀ sí ìbànújẹ́.
Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí olùwá-ibi-ìsádi kan, ẹnì kan tó sá fi ìlú rẹ̀ sílẹ̀, tàbí ẹni tó gbọ̀nà ẹ̀bùrú wọ orílẹ̀-èdè míì tí kò ní í ní ohun ìbànújẹ́ kan láti sọ. Ohun yòówù tó lè fà á tí àwọn èèyàn yìí fi fi ilé wọn sílẹ̀, yálà nítorí ogun ni o, inúnibíni tàbí ìṣẹ́ ni o, ohun tójú wọn ń kàn gbé ìbéèrè yìí dìde: Ṣé ìṣòro yìí lè ní ojútùú? Àbí ńṣe ni yíya tí àwọn olùwá-ibi-ìsádi ń ya bí omi á túbọ̀ máa ròkè sí i?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Orílẹ̀-èdè kan ní Éṣíà ni ohun tá a mẹ́nu bà lókè yìí ti ṣẹlẹ̀ ní oṣù March 2001. Àmọ́ irú àwọn wàhálà yìí tún ti yọjú láwọn ilẹ̀ kan ní Áfíríkà.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Ohun Tójú Àwọn Tó Ń Gbọ̀nà Ẹ̀bùrú Wọ Orílẹ̀-Èdè Míì Ń Rí
Yàtọ̀ sáwọn olùwá-ibi-ìsádi àtàwọn tó sá fi ìlú sílẹ̀, nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí ọgbọ̀n mílíọ̀nù “àwọn tó ń gbọ̀nà ẹ̀bùrú wọ orílẹ̀-èdè míì” ló wà jákèjádò ayé. Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn èèyàn yìí ló jẹ́ torí àtibọ́ lọ́wọ́ ìṣẹ́ tàbí kó jẹ́ pé torí àtibọ́ lọ́wọ́ ẹ̀tanú àti inúnibíni ló mú wọn sá lọ sáwọn orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀ ju tiwọn lọ.
Bí àǹfààní láti wọ orílẹ̀-èdè mìíràn lọ́nà tó bófin mu ṣe túbọ̀ ń dín kù láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, òwò tuntun kan, ti ṣíṣe fàyàwọ́ àwọn èèyàn wọlé ti yọjú báyìí. Àní, jíjí èèyàn gbé àti kíkó wọn wọ̀lú láìbófinmu ti wá di òwò tó ń mú owó jaburata wọlé fún àwọn àjọ arúfin. Àwọn olùwádìí kan ṣírò rẹ̀ pé, èrè tí wọ́n ń jẹ lọ́dún kan tó bílíọ̀nù méjìlá dọ́là, kò sì fi bẹ́ẹ̀ sí àdánù kankan tó ń bá àwọn onífàyàwọ́ yìí. Pino Arlacchi tó jẹ́ akọ̀wé àgbà fún Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè pè é ní “òwò àwọn ọ̀daràn tó ń yára gbèrú jù lọ láyé.”
Àwọn tó ń gbọ̀nà ẹ̀bùrú wọ orílẹ̀-èdè míì kì í ní ààbò kankan lábẹ́ òfin, ọ̀pọ̀ ìgbà sì ni àwọn onífàyàwọ́ náà máa ń gba ìwé àṣẹ ìrìn àjò wọn lọ́wọ́ wọn. Àwọn iṣẹ́ tí kò ní láárí ló wọ́pọ̀ tí àwọn èèyàn yìí ń ṣe, wọ́n máa ń ṣiṣẹ́ nínú ilé àwọn èèyàn, wọ́n ń pa ẹja tà tàbí kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ oko. Aṣẹ́wó làwọn kan máa ń dà gbẹ̀yìn. Tí ìjọba bá rí wọn gbá mú, ńṣe ni wọ́n máa ń dá wọn padà sórílẹ̀-èdè wọn láìsí kọ́bọ̀ lọ́wọ́ wọn. Tí wọ́n bá sì ráhùn nípa iṣẹ́ wọn pẹ́nrẹ́n, àwọn tó gbà wọ́n síṣẹ́ lè nà wọ́n játijàti, kí wọ́n fipá bá wọn sùn tàbí kí wọ́n tiẹ̀ lọ máa halẹ̀ mọ́ àwọn èèyàn wọn nílé.
Lọ́pọ̀ ìgbà, ìlérí iṣẹ́ olówó gegere táwọn àjọ arúfin máa ń ṣe fáwọn àtọ̀húnrìnwá yìí ni wọ́n fi ń rí wọn mú. Fún ìdí yìí, ìdílé kan tí ìyà ń jẹ lójú méjèèjì kò kọ̀ láti fi gbogbo nǹkan ìní wọn ṣọfà láti lè rán ẹyọ ẹnì kan ṣoṣo lọ sí ilẹ̀ Yúróòpù tàbí ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Tí agbára ẹni tó fẹ́ lọ sí òkè òkun yìí kò bá gbé ìnáwó náà, wọ́n á sọ pé kó ṣiṣẹ́ dí gbèsè rẹ̀, èyí tó lè máa lọ sí bí ọ̀kẹ́ méjì [40,000] dọ́là. ‘Ìgbésí ayé tuntun’ tí wọ́n ṣèlérí fún un á wá di ìsìnrú mọ́ ọn lọ́wọ́.
[Àwòrán]
Àwọn tó gbọ̀nà ẹ̀bùrú wọ orílẹ̀-èdè Sípéènì
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Àìmọ̀kan Kó O Sí Wàhálà
Orí àwọn òkè tó wà ní Gúúsù ìlà oòrùn Éṣíà ni ìdílé Siri ń gbé níbi táwọn òbí rẹ̀ ti ń bójú tó oko ìrẹsì wọn. Lọ́jọ́ kan, obìnrin kan sọ fún àwọn òbí rẹ̀ pé òún lè bá Siri rí iṣẹ́ olówó gọbọi ní ìlú ńlá. Ó ṣòro fún wọn láti kọ ẹgbàá dọ́là [$2,000] tó ṣèlérí rẹ̀ fún wọn, èyí tó jẹ́ owó rẹpẹtẹ lójú àwọn àgbẹ̀ tó ń dáko lórí òkè náà. Àmọ́ kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn, Siri bá ara rẹ̀ nínú ìgbèkùn ní ilé aṣẹ́wó kan. Àwọn tó ni ibẹ̀ sọ fún un pé, tó bá fẹ́ di òmìnira, ó ní láti san ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ dọ́là [$8,000] fún wọn. Ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ni Siri nígbà yẹn.
Kò sí ọ̀nà tí Siri fi lè rí owó yìí san. Ìyà àti bí wọ́n ṣe ń fi ìbálòpọ̀ fìtínà rẹ̀ mú un fọwọ́ sowọ́ pọ̀ ní tipátipá. Níwọ̀n ìgbà tó bá ṣì ń wúlò fún wọn, kò lè ráyè bọ́. Ohun tó tún wá báni nínú jẹ́ nínú ọ̀ràn náà ni pé, nígbà tí wọ́n bá fi máa dá ọ̀pọ̀ irú àwọn aṣẹ́wó bẹ́ẹ̀ sílẹ̀ níkẹyìn, ńṣe ni wọ́n máa padà sí abúlé wọn lọ kú nítorí àrùn Éèdì.
Irú òwò yìí kan náà ń lọ pẹrẹwu láwọn apá ibòmíràn láyé. Ìròyìn ọdún 1999 kan tí wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní, International Trafficking in Women to the United States fojú bù ú pé, nǹkan bí ọ̀kẹ́ márùndínlógójì [700,000] sí mílíọ̀nù méjì àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé ni wọ́n ń ṣe fàyàwọ́ wọn kọjá lọ́dọọdún, ọ̀pọ̀ wọn ló sì jẹ́ fún iṣẹ́ aṣẹ́wó. Wọ́n máa ń tan àwọn kan, jíjí ni wọ́n sì máa ń jí àwọn mìíràn gbé; àmọ́, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo wọn ni wọ́n máa ń fipá mu ṣe iṣẹ́ tí kò tẹ́ wọn lọ́rùn. Ọ̀dọ́langba kan tó ti Ìlà Oòrùn Yúróòpù wá, tí wọ́n gbà sílẹ̀ lọ́wọ́ àjọ arúfin kan tó ń lò ó fún iṣẹ́ aṣẹ́wó sọ nípa àwọn tó mú un náà pé: “Mi ò ronú rẹ̀ rí pé irú nǹkan báyìí lè máa ṣẹlẹ̀. Ẹranko gbáà làwọn èèyàn yìí.”
Àgọ́ àwọn olùwá-ibi-ìsádi ni wọ́n ti máa ń rí àwọn míì tàn jẹ, níbi tí kò ti ṣeé ṣe fún àwọn èèyàn náà láti kọ iṣẹ́ àti owó gegere tí wọ́n ṣèlérí rẹ̀ fún wọn ní ilẹ̀ Yúróòpù tàbí ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Àìlóǹkà obìnrin ló ti bára wọn lóko ẹrú ìbálòpọ̀ níbi tí wọ́n ti ń wá ìgbésí ayé tó sàn kiri.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Rò Ó Re Kó O Tó Ṣí Lọ sí Ibi Tí Nǹkan Ti Rọ̀ṣọ̀mù
Bí ọ̀pọ̀ àjọ arúfin ṣe ń gbọ̀nà ẹ̀bùrú kó àwọn èèyàn wọ orílẹ̀-èdè àti bí kò ṣe rọrùn láti wọ àwọn ilẹ̀ tó ti gòkè àgbà lọ́nà tó bófin mu, àwọn tó jẹ́ ọkọ àti bàbá gbọ́dọ̀ fara balẹ̀ gbé àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí yẹ̀ wò kí wọ́n tó ṣe ìpinnu.
1. Ǹjẹ́ ìṣòro owó tó ń bá wa fínra burú débi pé ó di dandan kí ọ̀kan tàbí gbogbo ìdílé wa ṣí lọ sí orílẹ̀-èdè tí iṣẹ́ olówó gọbọi wà?
2. Báwo ni gbèsè tá a máa jẹ láti lè rìnrìn-àjò náà á ṣe pọ̀ tó, báwo lá sì ṣe máa rí i san padà?
3. Ṣé owó tá a máa rí tó ohun tá a ń torí rẹ̀ pín ìdílé níyà, èyí tó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ lè máà rí bá a ṣe rò? Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbọ̀nà ẹ̀bùrú wọ àwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà ló ń rí i pé kì í ṣeé ṣe rárá ni láti rí iṣẹ́ gidi ṣe.
4. Ṣé ó yẹ kí n gba ohun táwọn kan ń sọ nípa owó rẹpẹtẹ àti ìgbádùn tó wà níbẹ̀ gbọ́? Bíbélì sọ pé “ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìní ìrírí ń ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”—Òwe 14:15.
5. Kí ló mú un dá mi lójú pé a ò ní lọ bọ́ sọ́wọ́ àwọn àjọ arúfin?
6. Tó bá lọ jẹ́ pé irú àwọn ẹgbẹ́ arúfin bẹ́ẹ̀ ló ṣètò ìrìn-àjò náà, ǹjẹ́ mo mọ̀ bóyá ìyàwó mi tàbí ọmọ mi obìnrin náà lè di ẹni tí wọ́n ń fipá mú wọnú iṣẹ́ aṣẹ́wó?
7. Ǹjẹ́ mo mọ̀ pé tí n bá lọ wọ orílẹ̀ èdè míì lọ́nà tí kò bófin mu, mo lè máà ríṣẹ́ tó ní láárí ṣe àti pé wọ́n lè dá mi padà síbi tí mo ti wá, tí màá sì pàdánù gbogbo owó tí mo ti ná sórí ìrìn-àjò náà?
8. Ṣé màá fẹ́ wọ orílẹ̀-èdè mìíràn láìbófinmu tàbí màá fẹ́ ṣe àwọn nǹkan tó mú àbòsí dání torí kí n ṣáà lè ráyè wọ orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀ ju tèmi lọ?—Mátíù 22:21; Hébérù 13:18.
[Àwòrán/Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 20, 21]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Bí Àwọn Olùwá-ibi-ìsádi àtàwọn Òṣìṣẹ́ tó ń wọ orílẹ̀-èdè mìíràn láìbófinmu ṣe ń ṣí kiri
Àwọn àgbègbè tí àwọn olùwá-ibi-ìsádi àtàwọn èèyàn tí wọ́n sá kúrò nílùú pọ̀ sí
→ Bí àwọn òṣìṣẹ́ tí kò ní ìwé àṣẹ ṣe máa ń rìn
[Àwọn Credit Line]
Inú Ìwé Tá A Ti Rí Ìsọfúnni: The State of the World’s Refugees; The Global Migration Crisis; àti World Refugee Survey 1999.
Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Olùwá-ibi-ìsádi kan tó sá kúrò nílùú ń wá bó ṣe máa bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀ padà
[Credit Line]
FỌ́TÒ UN 186226/M. Grafman