Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àǹfààní Wà Nínú—Kẹ̀kẹ́ Gígùn

Àǹfààní Wà Nínú—Kẹ̀kẹ́ Gígùn

Àǹfààní Wà Nínú—Kẹ̀kẹ́ Gígùn

LÁTỌWỌ́ ÒǸKỌ̀WÉ JÍ! NÍ ILẸ̀ GẸ̀Ẹ́SÌ

OHUN ìrìnnà wo ni iye tí wọ́n ń tà á kéré jù lọ, tó sì lè sáré ju ọkọ̀ lọ ní ìgbèríko, tó dára fún ìlera, tó sì ń gbádùn mọ́ni tá a bá ń lò ó? Kẹ̀kẹ́ ni. Eré ìmárale tó wúlò tó sì tún ń gbádùn mọ́ni ni kẹ̀kẹ́ gígùn. Lásìkò tá a wà yìí tó jẹ́ pé ọ̀ràn ìlera ló jẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn lógún, kẹ̀kẹ́ gígùn tó ohun tá à gbé yẹ̀ wò.

Ohun Ìṣeré Ni Tẹ́lẹ̀ Kó Tó Di Ohun Ìrìnnà

Àwọn èèyàn ń gbóríyìn fún ará Jámánì náà, Baron Karl von Drais, nítorí kẹ̀kẹ́ tó ṣe. Ó ṣe kẹ̀kẹ́ kan tó dà bí ìṣeré ọmọdé ní 1817, ó sì dára gan-an. Kẹ̀kẹ́ náà tí wọ́n ń pè ní draisine, ní àgbá méjì, ìjókòó kan àti irin téèyàn lè máa fi yí ọwọ́ rẹ̀ sọ́tùn-ún sósì. Àmọ́ kẹ̀kẹ́ yìí kò ní pẹ́dàlì. Nígbà tó di 1839, alágbẹ̀dẹ ará Scotland kan tó ń jẹ́ Kirkpatrick Macmillan, rọ àwọn irin téèyàn lè dásẹ̀ lé sára àgbá ẹ̀yìn láti fi máa wa kẹ̀kẹ́. Ìgbà náà ni kẹ̀kẹ́ túbọ̀ wá gbajúmọ̀ láàárín àwọn èèyàn. Bàbá kan tó jẹ́ ará ilẹ̀ Faransé, Pierre Michaux àti ọmọ rẹ̀ ọkùnrin Ernest, ṣe pẹ́dàlì méjì tó ṣeé fẹsẹ̀ wà sára àgbá iwájú láti máa fi wa kẹ̀kẹ́ tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní velocipede (inú èdè Látìn ló ti jáde, velox tó túmọ̀ sí “yára,” àti pedis tó túmọ̀ sí “ẹsẹ̀”), kẹ̀kẹ́ tí wọ́n ṣe yìí yara ju àwọn tó kù lọ ó sì dùn ún bójú tó.

Bí àgbá kẹ̀kẹ́ ọwọ́ iwájú bá ṣe tóbi tó ni ìrìn tí wọ́n á rìn ṣe máa yá tó. Ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, wọ́n ṣe oríṣi kẹ̀kẹ́ kan tí àgbá iwájú rẹ̀ tóbi tó mítà kan àtààbọ̀, àgbá tẹ̀yìn kò sì ju kékeré lọ. Wọ́n ń pe kẹ̀kẹ́ yìí ní penny-farthing, nítorí ó fara jọ bí ẹyọ owó onírin penny ṣe tóbi ju farthing, ìyẹn ẹyọ owó tó kéré jù lọ.

Lẹ́yìn èyí ni wọ́n ṣe kẹ̀kẹ́ tí wọ́n sọ pé kò léwu láti gùn, èèyàn lè yí kẹ̀kẹ́ yìí sí ibi tó bá wù ú, àgbá rẹ̀ méjèèjì kò sì tóbi jura lọ tàbí kó kù díẹ̀ kí wọ́n tóra wọn, èèyàn sì lè mára dúró lórí rẹ̀ dáadáa. Ní 1879, ará ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà Henry Lawson, pàtẹ kẹ̀kẹ́ kan ní Paris, àgbá ẹ̀yìn kẹ̀kẹ́ yìí ní ṣéènì tó ń jẹ́ kó máa yí. Nígbà tó yá, wọn pe orúkọ kẹ̀kẹ́ yìí ní bicyclette.

Àgbá iwájú àti tẹ̀yìn ọ̀pọ̀ àwọn kẹ̀kẹ́ òde òní kì í tóbi jura wọn lọ. Nítorí náà, ìyàtọ̀ díẹ̀ ti wà sí ti ìgbà tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe é. Àwọn kẹ̀kẹ́ táwọn èèyàn ń gùn lóde òní, ì báà jẹ́ kẹ̀kẹ́ ológeere ni o, tàbí èyí tí wọ́n fi ń rìnrìn àjò ọ̀nà jíjìn, tàbí èyí tí wọ́n fi ń sáré ìdíje tàbí èyí tí wọ́n fi ń gun àwọn ibi tó rí gbágun-gbàgun, gbogbo wọn ló rọrùn láti gùn nítorí àgbá méjì tí kò wúwo tí wọ́n ní àti táyà onírọ́bà tó wà lẹ́sẹ̀ wọn.

Ó Ń Mú Ara Le

Kẹ̀kẹ́ ni wọ́n ń lò bí ọkọ̀ ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Kì í pariwo, kì í yọ èéfín, ó sì ń yára ju ọkọ̀ lọ tí ibi téèyàn ń lọ kò bá jìnnà. Ní Áfíríkà, Éṣíà àti láwọn ibòmíràn, wọ́n ti sọ kẹ̀kẹ́ di “akẹ́rùkérò,” nítorí òun làwọn èèyàn kan fi ń gbé ẹrù wọn lọ sọ́jà tàbí kí wọ́n fi tì í lọ. Lọ́pọ̀ ìgbà, kì í ṣe ẹni tó ń gun kẹ̀kẹ́ nìkan ló máa ń wà lórí rẹ̀, àwọn èèyàn rẹ̀ tàbí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ náà lè jókòó sórí ọ̀pá kẹ̀kẹ́ lọ́wọ́ iwájú tàbí kí wọ́n jókòó sórí ìgbẹ́rù kẹ̀kẹ́ tó wà lẹ́yìn.

Láwọn orílẹ̀-èdè Ìwọ̀ Oòrùn ayé tó jẹ́ pé ọkọ̀ làwọn èèyàn fẹ́ràn jù lọ ní wíwọ̀, ọ̀rọ̀ nípa ìlera àti wíwọ ọkọ̀ lójoojúmọ́ ayé ti mú káwọn èèyàn tún bẹ̀rẹ̀ sí í gun kẹ̀kẹ́. Kódà, wọ́n ti ṣe ibi táwọn oníkẹ̀kẹ́ á máa gbà sí àwọn ojú pópó. Bí àpẹẹrẹ, ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, àwọn aláṣẹ ìjọba ìbílẹ̀ máa ń fi bí iye kìlómítà tí wọ́n fi ṣe ọ̀nà táwọn oníkẹ̀kẹ́ á máa gbà ṣe pọ̀ tó yangàn.

Bá a bá yọ ti èéfín ọkọ̀ tó lè máa kó síni nímú tá a bá ń gun kẹ̀kẹ́ kúrò, kẹ̀kẹ́ gígùn lè fún èèyàn ní ìlera. Adrian Davis, tó jẹ́ olùgbani-nímọ̀ràn nípa ètò ìrìnnà, sọ pé kẹ̀kẹ́ gígùn “kì í jẹ́ kéèyàn ní àwọn àrùn tó jẹ mọ́ ọkàn àyà àti òpójẹ̀, àwọn àrùn yìí ló ń fa ikú àti ikú àìtọ́jọ́ jù lọ ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.” Okun inú lèèyàn fi máa ń gun kẹ̀kẹ́, nǹkan bí ìdá ọgọ́ta sí ìdá márùndínláàádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo okun téèyàn ní, èyí sì ju ìdá márùndínláàádọ́ta sí ìdá àádọ́ta okun téèyàn ń lò tó bá ń fẹsẹ̀ rìn. Kò fi bẹ́ẹ̀ séwu pé èèyàn lè ṣàkóbá fún eegun ara. Kò dà bíi ti ìgbà téèyàn bá ń fi ẹsẹ̀ sáré kiri nítorí pé wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ lèèyàn á máa fi ẹsẹ̀ wa kẹ̀kẹ́.

Àǹfààní mìíràn tó tún wà nínú kẹ̀kẹ́ gígùn ni ti bó ṣe máa ń dùn mọ́ ẹni tó ń gùn ún. Ìwádìí fi hàn pé kẹ̀kẹ́ gígùn máa ń jẹ́ kí àwọn èròjà kan tí wọ́n ń pè ní endorphins sun jáde nínú ọpọlọ, èyí sì máa ń múnú èèyàn dùn. Yàtọ̀ fún pé ó máa ń múnú èèyàn dùn, ó tún máa ń mú kí ìrísí èèyàn fani mọ́ra. Lọ́nà wo? Ìwé ìròyìn The Guardian sọ pé: “Bí ẹnì kan bá rọra ń gun kẹ̀kẹ́ lọ, nǹkan bíi kálórì méje ló máa ń lò ní ìṣẹ́jú kan, tàbí igba kálórì ní ọgbọ̀n ìṣẹ́jú.” Kí làǹfààní rẹ̀? Ìgbáròkó tó tóbi tẹ́lẹ̀ yóò fọn, tàbí kí itan tó ṣe jọ̀kọ̀tọ̀ tẹ́lẹ̀ wá le pọ́nkí.

Ààbò fún Àwọn Tó Gbádùn Kẹ̀kẹ́ Gígùn

Ọ̀ràn nípa ààbò fún àwọn tó ń gun kẹ̀kẹ́ ni ohun táwọn èèyàn ń ṣàníyàn nípa rẹ̀ láwọn ilẹ̀ tí ọkọ̀ ti pọ̀ gan-an. Bí àpẹẹrẹ, ṣé ó yẹ kéèyàn dé akoto ìdáàbòbò? Òtítọ́ ni pé ó dára kéèyàn máa wọ ohun tó lè dáàbò bò ó. Síbẹ̀, pé èèyàn dé akoto ìdáàbòbò kò túmọ̀ sí pé onítọ̀hún kò lè ṣèṣe. Celia Hall, tó jẹ́ òǹkọ̀wé ìròyìn sọ̀rọ̀ nípa ìwádìí kan tí wọ́n ṣe nípa àwọn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán èèyàn [1,700] kan tí wọ́n gun kẹ̀kẹ́, ọjọ́ orí wọn yàtọ̀ síra, gbogbo wọn ló sì dé akoto ìdáàbòbò. Ohun kan tó yani lẹ́nu nínú ìwádìí náà ni pé àwọn agunkẹ̀kẹ́ yìí bẹ̀rẹ̀ sí ṣeré egéle nítorí pé wọ́n dé akoto. Èyí tó tún burú níbẹ̀ ni pé ìdá mẹ́fà nínú ọgọ́rùn-ún wọn ló dé akoto tí kò bá wọn lórí mu. Téèyàn bá dé akoto tí kò bá a lórí mu, ó ṣeé ṣe kí onítọ̀hún túbọ̀ ṣèṣe gan-an tí jàǹbá bá ṣẹlẹ̀. Bó o bá dé akoto ìdáàbòbò, rí i pé èyí tó bá ọ lórí mu lo dé. Máa yẹ akoto ọmọ rẹ wò látìgbàdégbà. Akoto tó bá tóbi jù lè ṣeni léṣe.

Àwọn awakọ̀ sábà máa ń wo àwọn tó ń gun kẹ̀kẹ́ lójú pópó bí ẹni tó ń ṣe àrífín, wọn kì í sì í kà wọ́n sí. Nítorí náà, rí i pé o wà níbi tójú ti máa rí ọ. Wọ aṣọ tó lè dáàbò bò ọ́, àwọn aṣọ tí àwọ̀ wọn tàn dáadáa ní ọ̀sán àtàwọn tó máa ń tàn yanran lálẹ́. Bákan náà, àwọ̀ kẹ̀kẹ́ rẹ gbọ́dọ̀ máa tàn, ì báà jẹ́ lálẹ́. Òfin sábà máa ń béèrè pé kéèyàn fi àwọn ohun tó ń tàn yanran-yanran sára pẹ́dàlì kẹ̀kẹ́ kéèyàn sì tún fi iná sí i níwájú àti lẹ́yìn, èyí dára púpọ̀. Rí i dájú pé àwọn ohun ààbò tó ò ń lò wà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí òfin orílẹ̀-èdè rẹ sọ.

Kẹ̀kẹ́ téèyàn bá ń tún ṣe déédéé máa ń dáàbò boni. Máa yẹ kẹ̀kẹ́ rẹ wò, jẹ́ kó mọ́ tónítóní kó o sì máa ṣe àwọn àtúnṣe tó bá yẹ látìgbàdégbà. Lẹ́yìn tó o bá ti ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ó lè jẹ́ ohun tó bọ́gbọ́n mu lágbègbè rẹ láti “yẹra fún gígun kẹ̀kẹ́ lójú pópó.” Àmọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀, o gbọ́dọ̀ máa gun irú kẹ̀kẹ́ tó yẹ.—Wo àpótí náà “Irú Kẹ̀kẹ́ Tó Yẹ Ọ́.”

Fífi Kẹ̀kẹ́ Gígùn Ṣe Eré Ìdárayá

Eré ìdárayá làwọn kan ń fi kẹ̀kẹ́ gígùn ṣe. Ìwà tí kò bójú mu táwọn kan hù níbi ìdíje tó lókìkí náà Tour de France lẹ́nu àìpẹ́ yìí ti fi hàn pé wọ́n ti ń lo oògùn olóró wọ́n sì ti ń hùwà ẹ̀tàn nínú eré ìdárayá orí kẹ̀kẹ́. Ìwé ìròyìn Time sọ nínú àpilẹ̀kọ kan tó pe àkọlé rẹ̀ ní “Ẹni Tó Bá Lo Oògùn Olóró Tó Lágbára Jù Lọ Ló Máa Jáwé Olúborí!,” pé ńṣe ni ìdíje náà rí “rúdurùdu.” Oògùn olóró àtàwọn kẹ́míkà mìíràn táwọn tó ń ṣe ìdíje yìí ti bẹ̀rẹ̀ sí í lò kò jẹ́ kí ìdíje náà fi bẹ́ẹ̀ níyì mọ́.

Ó yẹ káwọn olùmọnúúrò tó ń fi kẹ̀kẹ́ ṣeré ìdárayá kíyè sí iye àkókò àti ìsapá tí eré ìdárayá wọn ń ná wọn. Pẹ̀lú bí àwọn èèyàn ṣe nífẹ̀ẹ́ sí kẹ̀kẹ́ gígùn nítorí pé ó dára fún ìlera, àwọn èèyàn tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì mọ̀ pé kì í ṣe eré ìmárale nìkan ló ń mú kára èèyàn le kéèyàn sì pẹ́ láyé. Àmọ́ o, ìgbàkigbà tó o bá ta sórí kẹ̀kẹ́, ṣáà máa gbádùn rẹ̀ lọ!

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Irú Kẹ̀kẹ́ Tó Yẹ Ọ́

Kò síbi téèyàn ò ti lè gun àwọn kẹ̀kẹ́ tí wọ́n ṣe fún gígun láwọn ibi tó rí gbágun-gbàgun, nítorí pé irin tí wọ́n fi ṣe wọ́n ò tóbi púpọ̀ ó sì lágbára, ọwọ́ wọn gún, pẹ́dàlì wọn ga sókè ju tàwọn kẹ̀kẹ́ tó kù lọ, àwọn táyà rẹ̀ sì tóbi tá á fi lè kọjá láwọn ọ̀nà tí kò dára. Ó tún ní oríṣiríṣi jíà, èyí tó ń mú kó rọrùn láti gùn lórí òkè.

Tó bá jẹ́ ọ̀nà tó le koránkorán tó sì rí gbágagbàga lo ti ń gun kẹ̀kẹ́, a jẹ́ pé irú kẹ̀kẹ́ tó yẹ ọ́ ni èyí tí wọ́n ṣe láti fi gun àwọn ibi tó rí gbágungbàgun tó sì tún dà bíi kẹ̀kẹ́ ológeere táwọn èèyàn ń gùn. Táyà irú kẹ̀kẹ́ yìí kì í fi bẹ́ẹ̀ tóbi pẹ́dàlì rẹ̀ kì í sì í ga sókè. Kẹ̀kẹ́ ológeere táwọn èèyàn máa ń gùn kì í ní jíà tó pọ̀, èèyàn kì í bẹ̀rẹ̀ mọ́ ọn tó bá ń wà á.

Oríṣi tó wù kó o yàn, rí i dájú pé irú èyí tó yẹ ọ́ ni. Kọ́kọ́ gùn ún wò ná. Yí ọwọ́ rẹ̀ síbi tó o fẹ́, sún ìjókòó rẹ̀ àti pẹ́dàlì rẹ̀ sí ibi tó máa bá ẹ lára mu. Ó yẹ kí ẹsẹ̀ rẹ méjèèjì lè kanlẹ̀ tó o bá jókòó lórí kẹ̀kẹ́ (wo àwòrán òkè).

Tó o bá fẹ́ gun kẹ̀kẹ́ lọ́nà tí kò léwu kó o sì gbádùn rẹ̀, sún ìjókòó sókè débi pé ẹsẹ̀ rẹ á lè nà dé orí pẹ́dàlì (wo apá òsì). Ọrùn kẹ̀kẹ́ kì í sábàá ga ju ìjókòó kẹ̀kẹ́ lọ.—Ibi tá a ti mú ìsfúnni jáde: Ìwé ìròyìn Which?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Kẹ̀kẹ́ “penny farthing”

[Credit Line]

Police Gazette, 1889

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Kẹ̀kẹ́ “velocipede”

[Credit Line]

Àwọn ọkùnrin: Àwòrán Tá A Rí Nínú Ibi Tí Wọ́n Kó Àwọn Àwòrán Ọ̀rúndún Kọkàndínlógún Pa Mọ́ Sí/ Dover Publications, Inc.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Láwọn ibì kan, òfin béèrè pé káwọn tó ń gun kẹ̀kẹ́ dé akoto

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Kẹ̀kẹ́ làwọn kan ń lo bí ọkọ̀ ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè