Àwọn Ohun Tó Ń Fa Ewu Lẹ́nu Iṣẹ́
Àwọn Ohun Tó Ń Fa Ewu Lẹ́nu Iṣẹ́
“Àwọn èèyàn tó ń kú níbi tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ pọ̀ ju àwọn tó ń kú nínú jàǹbá ọkọ̀ lọ.” Àkọlé yìí ló fara hàn gàdàgbà-gadagba nínú ìwé àlẹ̀mógiri tí àjọ olùdáàbòbò kan tó ń jẹ́ WorkCover ní ìlú New South Wales, ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà ń pín káàkiri.
ÀWỌN jàǹbá tó máa ń yọrí sí ikú wulẹ̀ jẹ́ apá kan ìṣòro yẹn ni. Lọ́dọọdún, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ni jàǹbá tó le koko, kódà tó ń pa ìgbésí ayé ẹni dà sáìdáa ń ṣẹlẹ̀ sí níbi tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́. Ọ̀pọ̀ àwọn míì ló ń kú ikú àìtọ́jọ́ nítorí àwọn èròjà eléwu tí wọ́n ń fà símú lẹ́nu iṣẹ́ tàbí nítorí ìdààmú tí wọ́n ń rí lẹ́nu iṣẹ́.
Níwọ̀n bí ikú àti jàǹbá tó ń wáyé níbi téèyàn ti ń ṣiṣẹ́ kò ti yọ àwọn iléeṣẹ́ lóríṣiríṣi àti àjọ olókòwò èyíkéyìí sílẹ̀, ó bójú mu láti béèrè pé: Ṣé ààbò tó tó wà fún ọ níbi iṣẹ́ rẹ? Irú àwọn ipò wo ló lè máa wu ìlera rẹ àti ìwàláàyè rẹ léwu?
Àwọn Ibi Iṣẹ́ Tó Kún fún Wàhálà
Lọ́pọ̀ ìgbà kékeré kọ́ ni wàhálà tí wọ́n máa ń kó lé àwọn òṣìṣẹ́ láyà kí wọ́n lè jára mọ́ṣẹ́. Ní Japan, ọ̀rọ̀ náà karoshi, èyí tó túmọ̀ sí “ikú tí iṣẹ́ àṣekúdórógbó ń fà” ni wọ́n kọ́kọ́ lò nínú ẹjọ́ máà-jẹ́-n-jìyà-gbé táwọn ìdílé tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ pè. Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan tí wọ́n ṣe níbẹ̀ lọ́dún díẹ̀ sẹ́yìn ti fi hàn, ìdá ogójì nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọ ilẹ̀ Japan tó ń ṣiṣẹ́ ọ́fíìsì lẹ̀rù ń bà pé ó ṣeé ṣe kí àwọn kú nítorí iṣẹ́ àṣekúdórógbó. Amòfin kan tó jẹ́ ògbóǹtagí nínú irú àwọn ẹjọ́ bẹ́ẹ̀ fojú bù ú pé, “ó kéré tán, ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [30,000] òṣìṣẹ́ ló ń kú lọ́dọọdún nílùú Japan nítorí iṣẹ́ àṣekúdórógbó.”
Àwọn ọlọ́pàá ilẹ̀ Japan sọ pé, àwọn ìṣòro tó ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀ràn iṣẹ́ jẹ́ kókó kan lára ohun tó mú kí iye àwọn èèyàn tó jẹ́ ẹni àádọ́ta ọdún sí mọ́kàndínlọ́gọ́ta tó ń fọwọ́ ara wọn para wọn pọ̀ sí i. Gẹ́gẹ́ bí ìwé The Violence-Prone Workplace ṣe sọ, ilé ẹjọ́ kan mú agbanisíṣẹ́ kan pé kó wá dáhùn fún ohun tó fà á tí òṣìṣẹ́ rẹ̀ kan fi fọwọ́ ara rẹ̀ gbẹ̀mí ara rẹ̀ nítorí ìdààmú iṣẹ́ tó pá a lórí.
Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Ọsirélíà náà, The Canberra Times sọ pé ‘àwọn ará Amẹ́ríkà ti gborí lọ́wọ́ àwọn ara Japan nínú ọ̀ràn àwọn tó ń ṣiṣẹ́ fún àkókò tó gùn jù lọ lágbàáyé.’ Ìdí nìyẹn táwọn ìròyìn tó ní àwọn àkọlé bí, “Àwọn Èèyàn Ń Kú Nítorí Ṣíṣiṣẹ́ fún Ọ̀pọ̀ Wákàtí” fi sọ nípa bí àwọn òṣìṣẹ́ tí àárẹ̀ ti mú, irú bí àwọn awakọ̀ ìtọ́jú pàjáwìrì, àwọn awakọ̀ òfuurufú, àwọn kọ́lékọ́lé, àwọn tó ń wakọ̀ èrò àtàwọn tó ń ṣiṣẹ́ alẹ́ ṣe ń kú lẹ́nu iṣẹ́.
Bí àwọn iléeṣẹ́ ti ń ṣe àtúntò tí wọ́n sì ń dín iye òṣìṣẹ́ kù kí èrè tó ń wọlé fún wọn má bàa lọ sílẹ̀, wàhálà tó ń kojú àwọn òṣìṣẹ́ láti túbọ̀ jára mọ́ṣẹ́ kò kéré o. Ìwé ìròyìn British Medical Journal sọ pé, ńṣe ni dídín iye òṣìṣẹ́ kù ń kó bá ìlera àwọn òṣìṣẹ́ tó bá ṣẹ́ kù.
Ìwà Ipá Níbi Iṣẹ́
Kì í ṣe pé àwọn òṣìṣẹ́ tó ń lo ara wọn lálòyọ́ tí wọ́n sì ń ní másùnmáwo ń fi ara wọn sínú ewu
nìkan ni o. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì fi hàn pé, ọ̀pọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ọ́fíìsì àtàwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ kì í fẹ́ gbóhùn ara wọn sétí. Èyí sì máa ń fa ìwà ipá lọ́pọ̀ ìgbà.Ìwé ìròyìn Business Week sọ pé: “Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, nǹkan bí òṣìṣẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ni wọ́n máa ń pa lẹ́nu iṣẹ́ ní Amẹ́ríkà.” Ìwé ìròyìn Harvard Business Review ní tiẹ̀ sọ pé: “Kò sí ọ̀gá iṣẹ́ kankan tó máa ń fẹ́ sọ nípa ìwà ipá tó ń ṣẹlẹ̀ níbi iṣẹ́. Àmọ́ òótọ́ ibẹ̀ ni pé, lọ́dọọdún, ọgọ́rọ̀ọ̀rún òṣìṣẹ́ ló ń bá àwọn alábàáṣiṣẹ́ wọn jà tàbí kí wọ́n tiẹ̀ pa wọ́n pàápàá.”
Ní ìdàkejì ìyẹn, ọ̀pọ̀ ló jẹ́ pé àwọn oníbàárà wọn ló máa ń hu ìwà ipá sí wọn. Ìròyìn ilẹ̀ Ọsirélíà kan nípa ìwà ọ̀daràn sọ pé, ẹ̀rù máa ń ba àwọn dókítà kan gan-an pé wọ́n lè ṣe àwọn léṣe. Èyí ló fi jẹ́ pé tí wọ́n bá ń lọ tọ́jú àwọn èèyàn nínú ilé, wọ́n máa ń mú ẹni tó máa dáàbò bò wọ́n dání. Àwọn mìíràn tí ewu tún ń wu ni àwọn ọlọ́pàá àtàwọn olùkọ́.
Oríṣi ìwà ipá mìíràn tó tún ń ṣẹlẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ni, kíkó ẹdùn ọkàn báni, èyí tí Àjọ Àwọn Òṣìṣẹ́ Lágbàáyé pè ní ìwà ipá tí kò ṣeé fojú rí. Ọ̀nà tí èyí sábàá máa ń gbà ṣẹlẹ̀ ni kí wọ́n máa bú mọ́ni.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Robert L. Veninga ti Yunifásítì ìlú Minnesota ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ pé, “ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ apá ibi gbogbo láyé ni àwọn òṣìṣẹ́ ti ń fojú winá ìdààmú àti àìsàn tí bíbúmọ́ni máa ń fà.” Ó ń bá a lọ pé, “níbàámu pẹ̀lú Ìròyìn Ọdún 1993 ti Àjọ Àwọn Òṣìṣẹ́ Lágbàáyé Látọwọ́ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, èyí tó burú jù nínú ìṣòro ọ̀hún ni pé, tí àwọn alábàáṣiṣẹ́ ẹni kò bá bìkítà fúnni, tó jẹ́ pé òní-eré-ọ̀la-ìjà àti gbúngbùngbún ni ṣáá nígbà gbogbo, àìsàn ló máa ń dá síni lára.”
Ìbéèrè tó wá wà níbẹ̀ ni pé, Kí làwọn agbanisíṣẹ́ àtàwọn òṣìṣẹ́ lè ṣe láti túbọ̀ ní àlàáfíà lẹ́nu iṣẹ́? Èyí lá máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.