Àwọn Olùkọ́—Èé Ṣe Tá A Fi Nílò Wọn?
Àwọn Olùkọ́—Èé Ṣe Tá A Fi Nílò Wọn?
“Ọjọ́ kan ṣoṣo tí olùkọ́ tó dáńgájíá fi kọ́ni kì í ṣẹgbẹ́ ẹgbẹ̀rún ọjọ́ téèyàn fi ń dá kẹ́kọ̀ọ́.”—Òwe àwọn ará Japan.
ṢÉ O rántí olùkọ́ tó o fẹ́ràn gan-an nígbà tó o wà nílé ẹ̀kọ́? Tó o bá ṣì jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́, ṣé olùkọ́ kan wà tó o fẹ́ràn gan-an? Tó bá wà, kí ló mú kó o fẹ́ràn rẹ̀?
Olùkọ́ tó mòye máa ń jẹ́ kéèyàn ní ìdánilójú nípa ohun tó kọ́, ó sì ń mú kí ẹ̀kọ́ kíkọ́ jẹ́ iṣẹ́ tó gbádùn mọ́ni. Ṣìnkìn ni inú ẹni àádọ́rin ọdún kan ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì máa ń dùn tó bá rántí olùkọ́ tó kọ́ ọ ní èdè Gẹ̀ẹ́sì nígbà tó wà nílé ìwé nílùú Birmingham. Ó sọ pé: “Ọ̀gbẹ́ni Clewley jẹ́ kí n mọ̀ pé mo lè ṣe àwọn ohun kan tí mi ò mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé mo lè ṣe. Mo máa ń tijú bí akika, n kì í sì í sọ ohun tó wà lọ́kàn mi jáde, síbẹ̀ ó fún mi níṣìírí láti kópa nínú ìdíje eré orí ìtàgé ti ilé ìwé mi, ó sì dá mi lẹ́kọ̀ọ́. Èmi ni mo gba ẹ̀bùn ìdíje eré orí ìtàgé yìí ni ọdún tí mo parí ẹ̀kọ́ mi. Bí kì í bá ṣe ìṣírí tó fún mi ni, mi ò ní lè gba ẹ̀bùn náà. Ó dùn mí gan-an pé mi ò rí i mọ́ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún fífi tí kò fi ọ̀rọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ṣeré.”
Obìnrin dáadáa ni Margit, ó ti lé ní ẹni àádọ́ta ọdún, ọmọ ìlú Munich ní Jámánì ni. Ó sọ pé: “Tíṣà kan wà tí mo fẹ́ràn gan-an. Ó mọ bó ṣe máa ń ṣàlàyé àwọn nǹkan tó bá díjú lọ́nà tó fi máa yé èèyàn. Ó máa ń sọ fún wa pé tí ohun kan kò bá yé wa, ká béèrè ìbéèrè. Kì í kanra mọ́ wa, ó máa ń bá wa ṣeré gan-an. Èyí la fi máa ń gbádùn iṣẹ́ tó ń kọ́ wa.”
Peter, ọmọ ilẹ̀ Ọsirélíà rántí olùkọ́ tó kọ́ ọ ní ìṣirò, ó sọ pé olùkọ́ yìí “jẹ́ ká mọ bí ohun tá à ń kọ́ ti ṣe pàtàkì tó nípa fífún wa ní àwọn àpẹẹrẹ tó ṣe é mú lò. Nígbà tó ń kọ́ wa nípa àwọn nǹkan onígun mẹ́ta, ó kọ́ wa bá a ṣe lè wọn bí ilé kan ṣe ga tó láìjẹ́ pé a fọwọ́ kàn án, ẹnu pé ká kàn lo àwọn ìlànà tí wọ́n fi ń wọn àwọn nǹkan onígun mẹ́ta ni. Mo rántí pé mo ń sọ ọ́ lọ́kàn mi pé: ‘Káàsà, èyí mà ga lọ́lá o!’”
Pauline, ọmọ apá àríwá ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ fún olùkọ́ rẹ̀ pé: “Mi ò fi bẹ́ẹ̀ mọ ìṣirò.” Olùkọ́ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ṣé ó wù ọ́ láti mọ̀ ọ́n? Mo lè ràn ẹ́ lọ́wọ́.” Pauline sọ pé: “Fún bí oṣù mélòó kan lẹ́yìn ìgbà yẹn ló fi mú ọ̀rọ̀ mi lọ́kùn-únkúndùn, ó tiẹ̀ máa ń ràn mí lọ́wọ́ lẹ́yìn aago ìjáde pàápàá. Mo mọ̀ pé ó fẹ́ káyé mi dára ni, ó sì fẹ́ràn mi. Èyí jẹ́ kí èmi náà jára mọ́ṣẹ́, mo sì wá mọ ìṣirò.”
Angie, ọmọ ilẹ̀ Scotland, tó ti lé lọ́gbọ̀n ọdún báyìí náà rántí olùkọ́ tó kọ́ ọ ní ìtàn, ìyẹn Ọ̀gbẹ́ni Graham. Ó sọ pé: “Ó mú kí ẹ̀kọ́ nípa ìtàn dùn mọ̀ràn-ìn mọran-in! Ìtàn ló máa ń fi àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá pa, ó sì máa ń fi ìtara kọ́ wa ní àwọn ẹ̀kọ́ nípa ìtàn náà. Ńṣe ló máa ń mú kí gbogbo rẹ̀ dà bí ohun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ṣẹlẹ̀.” Bákan náà ló tún rántí abílékọ Hewitt, ìyá àgbàlagbà tó kọ́ ọ nígbà tó wà ní ìpele àkọ́kọ́. Ó sọ pé: “Ó ń gba tèèyàn rò ó sì fẹ́ràn èèyàn. Nínú kíláàsì lọ́jọ́ kan, mo lọ béèrè ìbéèrè kan lọ́wọ́ rẹ̀. Ńṣe ló gbé mi janto. Ó jẹ́ kí n mọ̀ pé òun fẹ́ràn mi gan-an.”
Timothy, ọmọ apá gúúsù ilẹ̀ Gíríìsì fi ìmọrírì rẹ̀ hàn. Ó sọ pé: “Mo ṣì rántí olùkọ́ tó kọ́ mi nípa ìmọ̀ ìjìnlẹ̀. Òun ló yí èrò mi nípa ayé tó yí mi ká àti ìwàláàyè padà pátápátá. Bó bá ń kọ́ wa nínú kíláàsì, àgbàyanu lẹ̀kọ́ tó ń kọ́ wa. Ó kọ́ wa láti nífẹ̀ẹ́ sí ìmọ̀ ká sì fẹ́ràn òye.”
Àpẹẹrẹ mìíràn tún ni Ramona, ọmọ ìlú California ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Ó kọ̀wé pé: “Olùkọ́ mi ní ilé ìwé gíga mà fẹ́ràn èdè Gẹ̀ẹ́sì o. Ìtara tó ní sì ran gbogbo wa! Kódà, ńṣe ló máa ń fọ́ àwọn ibi tó le koko nínú iṣẹ́ náà sí wẹ́wẹ́.”
Pẹ̀lú ara yíyá gágá ni Jane, ọmọ ilẹ̀ Kánádà fi sọ̀rọ̀ nípa olùkọ́ tó kọ́ ọ ní ẹ̀kọ́ nípa eré ìmárale pé “ó mọ̀ nípa eré ìmárale gan-an ó sì mọ bí wọ́n ṣe ń kọ́ èèyàn ní nǹkan. Ó kó wa lọ sí ìgbèríko ó sì lọ kọ́ wa ní béèyàn ṣe ń yọ̀ tẹ̀rẹ́ lórí yìnyín àti béèyàn ṣe lè pẹja nínú omi oníyìnyín. A tiẹ̀ tún ṣe búrẹ́dì tó dà bí tàwọn Àmẹ́ríńdíà lórí ààrò tá a fúnra wa
mọ. Ìrírí tó lárinrin lèyí jẹ́ fún ọmọbìnrin tí kò níṣẹ́ mìíràn ju pé kó ṣáà máa kàwé lọ!”Ọmọbìnrin tó máa ń tijú ni Helen, ìlú Shanghai ni wọ́n ti bí i, àmọ́ ìlú Hong Kong ló ti kàwé. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo wà ní ìpele karùn-ún, mo ní olùkọ́ kan tó kọ́ mi ní ẹ̀kọ́ nípa eré ìmárale àti kíkun àwòrán, ìyẹn Ọ̀gbẹ́ni Chan. Ọ̀pẹ́lẹ́ńgẹ́ ni mí, mi ò sì mọ bọ́ọ̀lù aláfọwọ́gbá àti bọ́ọ̀lù alápẹ̀rẹ̀-ẹ́ gbá púpọ̀. Olùkọ́ yìí kò fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ o. Ó jẹ́ kí n gbá ohun ìṣeré tá a ń pè ní badminton kí n sì ṣe àwọn eré ìdárayá mìíràn tí mo mọ̀ ọ́n ṣe. Ó ń gba tèèyàn rò, ó sì lójú àánú.
“Bákan náà ni ti yíya àwòrán, mi ò mọ bí a ṣe ń ya àwòrán èèyàn àtàwọn nǹkan lóríṣiríṣi. Àmọ́ ó jẹ́ kí n ya àwòrán téèyàn lè fi ṣe ọnà sí nǹkan lára, nítorí mo mọ àwọn yẹn yà dáadáa. Ó tún sọ fún mi pé kí n tún kíláàsì yẹn kà nítorí pé mo kéré gan-an sí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó kù. Èyí gan-an ló mú kí tèmi dire ní ti ọ̀ràn ẹ̀kọ́ mi. Ọkàn mi wá balẹ̀ dáadáa mo sì wá mọ̀wé gan-an. Mi ò lè gbàgbé olùkọ́ yìí láé.”
Irú olùkọ́ wo la lè sọ pé ó ń ní ipa tó dára lórí àwọn akẹ́kọ̀ọ́? William Ayers dáhùn ìbéèrè yìí nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní To Teach—The Journey of a Teacher. Ó sọ pé: “Kí olùkọ́ tó lè kọ́ni lọ́nà tó múná dóko, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tó ń ronú jinlẹ̀, tó lè ṣètọ́jú ẹni, tó sì lè ṣe gbogbo ohun tágbára rẹ̀ bá ká láti bójú tó àwọn akẹ́kọ̀ọ́. . . . Pé kí olùkọ́ mọ èèyàn kọ́ dáadáa kì í ṣe ọ̀rọ̀ títẹ̀lé ìlànà kan pàtó, tàbí ṣíṣe àwọn ohun kan tàbí mímúra sílẹ̀ láwọn ọ̀nà kan pàtó. . . . Kíkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ jẹ́ ọ̀ràn ìfẹ́.” Nígbà náà, irú olùkọ́ wo ló dáńgájíá? Òǹkọ̀wé náà dáhùn pé: “Olùkọ́ tó lè dé inú ọkàn rẹ, olùkọ́ tó lóye rẹ, tó fẹ́ràn rẹ, olùkọ́ tó jẹ́ pé ìfẹ́ tó ní fún nǹkan bí orin, ìṣirò, èdè àtohun ìṣeré ti ràn ọ́, tó sì ń mú ìwọ náà ṣe bí i tirẹ̀.”
Ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ olùkọ́ làwọn akẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn òbí wọn pàápàá ti dúpẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn táwọn olùkọ́ náà sì ti tipa bẹ́ẹ̀ rí ìṣírí gbà láti máa bá iṣẹ́ olùkọ́ lọ láìka àwọn ìṣòro tó wà níbẹ̀ sí. Ohun tó ń fa irú àwọn ọ̀rọ̀ ìyìn bẹ́ẹ̀ kò ṣẹ̀yìn ìfẹ́ tó dénú àti inú rere táwọn olùkọ́ wọ̀nyí fi hàn sáwọn akẹ́kọ̀ọ́.
Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe gbogbo olùkọ́ ló ń fi irú ànímọ́ wọ̀nyí hàn sáwọn akẹ́kọ̀ọ́ o. Lẹ́sẹ̀ kan náà, ó yẹ ká rántí pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni másùnmáwo máa ń bá àwọn olùkọ́ tí wọn ò fi ní lè ṣe ojúṣe wọn fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ bó ṣe yẹ. Èyí ló fa ìbéèrè náà pé, Kí ló ń mú àwọn èèyàn ṣe irú iṣẹ́ tó ṣòro yìí?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
“Kíkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ jẹ́ ọ̀ràn ìfẹ́”