Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Lóòótọ́ ni Èṣù—Ẹni Ibi Náà Wà?

Ṣé Lóòótọ́ ni Èṣù—Ẹni Ibi Náà Wà?

Ṣé Lóòótọ́ ni Èṣù—Ẹni Ibi Náà Wà?

OHUN kan tí kò sí níbì kankan làwọn èèyàn ka Èṣù sí nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìsìn. Wọ́n ní ẹ̀dá ọmọ aráyé ló hùmọ̀ rẹ̀. Èyí ló mú kí arukutu sọ lórí ohun tí Dionigi Tettamanzi, ìyẹn bíṣọ́ọ̀bù àgbà Genoa, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn kádínà tó gbapò iwájú ní Ítálì, kọ sínú lẹ́tà olójú ìwé 40 tó kọ sí àwùjọ àwọn àlùfáà nípa bí wọ́n ṣe lè kọjú ìjà sí Èṣù. “Òfin mẹ́wàá” ló wà nínú rẹ̀.

Èkínní: “Má ṣe gbàgbé pé èṣù wà,” nítorí “àkọ́kọ́ nínú ẹ̀tàn” tó ń lò ni pé “ká lè gbà pé kò sóhun tó ń jẹ́ èṣù.”

Ìkejì: “Má ṣe gbàgbé pé adánniwò ni èṣù. . . . Má rò pé ọwọ́ rẹ̀ kò lè tó ẹ tàbí pé kò lè rí ẹ gbé ṣe.”

Ìkẹta: “Má ṣe gbàgbé pé èṣù ní làákàyè púpọ̀ ó sì tún ní ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí. Kò ṣíwọ́ dídẹ pańpẹ́ láti mú àwọn èèyàn nípa títàn wọn jẹ gẹ́gẹ́ bó ti ṣe fún ọkùnrin àkọ́kọ́.”

Ìkẹrin: “Máa wà lójúfò: ṣí ojú àti ọkàn rẹ payá dáadáa. Jẹ́ akọni: ní ọkàn kó o sì máa hùwà rere.”

Ìkarùn-ún: “Ní ìgbàgbọ́ tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ pé Kristi lágbára ju adánniwò náà lọ” nítorí èyí “á dáàbò bò ọ́ á sì jẹ́ kó o lè dúró gbọn-in kódà nígbà tó bá kó ogun gbígbóná janjan tì ọ́.”

Ìkẹfà: “Má ṣe gbàgbé pé ìwọ àti Kristi lẹ jọ ṣẹ́gun rẹ̀.”

Ìkeje: “Máa gbọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé.”

Ìkẹjọ: “Má ṣe gbéra ga kó o sì fara dà á bí ẹnì kan bá hùwà láabi sí ọ.”

Ìkẹsàn-án: “Máa gbàdúrà nígbà gbogbo, má ṣe jẹ́ kó rẹ̀ ọ́,” kó o bàa lè borí àdánwò.

Ìkẹwàá: “Jọ́sìn Olúwa Ọlọ́run rẹ nìkan ṣoṣo, kó o sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.”

Báwo làwọn èèyàn ṣe tẹ́wọ́ gba lẹ́tà sí àwọn àlùfáà yìí? Àwọn ìmọ̀ràn tó wà níbẹ̀ kò bá àwọn èèyàn lára mu páàpáà ní Ibùdó Ẹ̀kọ́ Nípa Ìsìn ní Milan. Ibùdó yìí yarí pé irú “ẹ̀kọ́ yìí kò yàtọ̀ sí tayé ojú dúdú.” Agbẹnusọ kan sọ pé “tó bá jẹ́ èṣù nìkan làwọn èèyàn kàn ń di ẹ̀bi rù, wọn ò ní mọ̀ pé àwọn [fúnra àwọn] ní lọ́wọ́.”

Bíbélì kò sọ pé àwọn èèyàn ò ní jíhìn fún ohun tí wọ́n bá ṣe o, àmọ́ ó sọ ọ́ kedere pé Sátánì Èṣù ni “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí,” òun ló sì dán Jésù wò. Ó tún sọ nípa agbára tí Sátánì ní àtohun tó ń gbèrò, ìyẹn láti ‘fọ́ èrò inú àwọn aláìgbàgbọ́.’—2 Kọ́ríńtì 4:4; Mátíù 4:1-11.

Kódà, àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé Sátánì dà “bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà láti pani jẹ́.” (1 Pétérù 5:8) Abájọ tí àpọ́sítélì Jòhánù fi sọ fún àwọn onígbàgbọ́ pé: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19) Tá a bá gbọ́n, a ò ní kọ etí dídi sí ìkìlọ̀ Ìwé Mímọ́ yìí o.